Ezekiel 3 (BOYCB)
1 Síwájú sí i, ó sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, jẹ ohun tí ó wà níwájú rẹ, jẹ ìwé kíká yìí; kí o sì lọ fi bá ilé Israẹli sọ̀rọ̀.” 2 Mo sì ya ẹnu mi, ó sì mú mi jẹ ìwé kíká náà. 3 Ó tún sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, jẹ ìwé kíká tí mo fún ọ yìí, fi bọ́ inú àti ikùn rẹ.” Nígbà náà ni mo jẹ ẹ́, dídùn rẹ̀ dàbí oyin ní ẹnu mi. 4 Ó sì tún sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, lọ ni ìsinsin yìí bá mi sọ ọ̀rọ̀ mi fún ilé Israẹli. 5 A kò rán ọ sí àwọn tó ń sọ èdè àjèjì tàbí tí èdè wọn ṣòro láti gbọ́, ṣùgbọ́n orílẹ̀-èdè Israẹli ni mo rán ọ sí 6 kì í ṣe sí ọ̀pọ̀ ènìyàn tó ń sọ àjèjì èdè tàbí tí èdè wọn ṣòro láti gbọ́, àwọn tí ọ̀rọ̀ wọn le fún ọ láti gbọ́ yé. Dájúdájú bí mo bá rán ọ sí wọn, wọn ìbá sì fetísílẹ̀ sí ọ. 7 Ṣùgbọ́n ilé Israẹli kò fẹ́ gbọ́ tìrẹ nítorí pé wọn kò fẹ́ láti gbọ́ tèmi, torí pé aláìgbọ́ràn àti ọlọ́kàn líle ni gbogbo ilé Israẹli. 8 Ṣùgbọ́n bí i tiwọn lèmi náà yóò ṣe jẹ́ kí ojú àti ọkàn rẹ le. 9 Èmi yóò ṣe iwájú orí rẹ bí òkúta tó le jùlọ, ànító le ju òkúta-ìbọn lọ. Má ṣe bẹ̀rù wọn tàbí jẹ́ kí wọn ó dáyà já ọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.” 10 Ó sì sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ń sọ, kí o sì gba gbogbo ọ̀rọ̀ yìí sí ọkàn rẹ. 11 Lọ nísinsin yìí sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ tó wà ní ìgbèkùn. Sọ fún wọn pé báyìí ni OLÚWA Olódùmarè wí yálà wọ́n gbọ́ tàbí wọn kò gbọ́.” 12 Nígbà náà ni ẹ̀mí gbé mi sókè, mo sì gbọ́ ohùn ìró ńlá lẹ́yìn mi tó sọ pé, kí a gbé ògo OLÚWA ga láti ibùgbé rẹ̀ wá! 13 Bẹ́ẹ̀ ni mo tún gbọ́ ariwo ìyẹ́ apá àti kẹ̀kẹ́ àwọn ẹ̀dá alààyè náà pẹ̀lú ariwo tó dàbí àrá ńlá. 14 Ẹ̀mí náà sì gbé mi sókè, ó sì mú mi lọ, mo lọ pẹ̀lú ọkàn kíkorò àti ìbínú nínú ẹ̀mí mi, pẹ̀lú ọwọ́ líle OLÚWA ni ara mi. 15 Nígbà náà ni mo lọ sí etí odò Kebari níbi tí àwọn ìgbèkùn ń gbé ni Teli-Abibu. Níbẹ̀ níbi tí wọ́n ń gbé, mo jókòó láàrín wọn pẹ̀lú ìyanu, fún ọjọ́ méje. 16 Lẹ́yìn ọjọ́ méje, ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ̀ mí wá wí pé, 17 “Ọmọ ènìyàn, mo ti fi ọ́ ṣe olùṣọ́ fún ilé Israẹli; nítorí náà gbọ́ ọ̀rọ̀ tí mo ń sọ, fún wọn ní ìkìlọ̀ láti ọ̀dọ̀ mi. 18 Bí mo bá sọ fún ènìyàn búburú pé, dájúdájú, ‘Ìwọ yóò kú,’ tí ìwọ kò sì kìlọ̀ fún ènìyàn búburú yìí láti dáwọ́ ìwà ibi rẹ̀ dúró, kí o sì gba ẹ̀mí rẹ̀ là, ènìyàn búburú náà yóò kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ní ọwọ́ rẹ ni èmi yóò ti béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. 19 Ṣùgbọ́n bí o bá kìlọ̀ fún ènìyàn búburú, tí ó kọ̀ tí kò fi ìwà búburú rẹ̀ sílẹ̀, yóò kú sínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; ṣùgbọ́n ọrùn tìrẹ ti mọ́. 20 “Bákan náà, bí olódodo kan bá yípadà, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àìṣòdodo, tí mo sì fi ohun ìkọ̀sẹ̀ sí ọ̀nà rẹ̀, yóò kú sínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Nítorí pé ìwọ kọ̀ láti kìlọ̀ fún un, yóò kú sínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, a ó gbàgbé gbogbo ìwà rere tó ti hù tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n ní ọwọ́ rẹ̀ ni èmi yóò ti béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. 21 Ṣùgbọ́n bí o bá kìlọ̀ fún olódodo tó sì dáwọ́ ìwà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ dúró, dájúdájú òun yóò yè nítorí pé ó ti gba ìkìlọ̀, ọrùn tìrẹ sì mọ́.” 22 Ọwọ́ OLÚWA wà lára mi níbẹ̀, ó sì wí fún mi pé, “Dìde, lọ sí ibi tí ó tẹ́jú, èmi yóò sì bá ọ sọ̀rọ̀ níbẹ̀.” 23 Mo sì dìde, mo lọ sí ibi tí ó tẹ́jú. Ògo OLÚWA dúró níbẹ̀, ó dàbí irú ògo tí mo rí létí odò Kebari, mo sì dojúbolẹ̀. 24 Nígbà náà ni Ẹ̀mí wọ inú mi, tí ó sì tún gbé mi dúró. Ó sì wí fún mi pé, “Lọ, ti ara rẹ mọ́ inú ilé rẹ 25 ṣùgbọ́n ìwọ, ọmọ ènìyàn, wọn yóò fi okùn dè ọ́ mọ́lẹ̀; dé ibi pé ìwọ kò ní í le rìn káàkiri láàrín àwọn ènìyàn. 26 Èmi yóò mú kí ahọ́n rẹ lẹ̀ mọ́ àjà ẹnu rẹ, tó bẹ́ẹ̀ ti ìwọ yóò wà ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́. Ìwọ kò sì ní lè bá wọn wí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ̀tẹ̀ ilé ní wọn. 27 Ṣùgbọ́n nígbà tí èmi bá bá ọ sọ̀rọ̀, Èmi yóò ṣí ọ lẹ́nu, ìwọ yóò sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí OLÚWA Olódùmarè wí.’ Ẹni tó bá fẹ́ kí ó gbọ́, ẹni tó bá fẹ́ kọ̀, kó kọ̀ nítorí ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n.
In Other Versions
Ezekiel 3 in the ANGEFD
Ezekiel 3 in the ANTPNG2D
Ezekiel 3 in the AS21
Ezekiel 3 in the BAGH
Ezekiel 3 in the BBPNG
Ezekiel 3 in the BBT1E
Ezekiel 3 in the BDS
Ezekiel 3 in the BEV
Ezekiel 3 in the BHAD
Ezekiel 3 in the BIB
Ezekiel 3 in the BLPT
Ezekiel 3 in the BNT
Ezekiel 3 in the BNTABOOT
Ezekiel 3 in the BNTLV
Ezekiel 3 in the BOATCB
Ezekiel 3 in the BOATCB2
Ezekiel 3 in the BOBCV
Ezekiel 3 in the BOCNT
Ezekiel 3 in the BOECS
Ezekiel 3 in the BOGWICC
Ezekiel 3 in the BOHCB
Ezekiel 3 in the BOHCV
Ezekiel 3 in the BOHLNT
Ezekiel 3 in the BOHNTLTAL
Ezekiel 3 in the BOICB
Ezekiel 3 in the BOILNTAP
Ezekiel 3 in the BOITCV
Ezekiel 3 in the BOKCV
Ezekiel 3 in the BOKCV2
Ezekiel 3 in the BOKHWOG
Ezekiel 3 in the BOKSSV
Ezekiel 3 in the BOLCB
Ezekiel 3 in the BOLCB2
Ezekiel 3 in the BOMCV
Ezekiel 3 in the BONAV
Ezekiel 3 in the BONCB
Ezekiel 3 in the BONLT
Ezekiel 3 in the BONUT2
Ezekiel 3 in the BOPLNT
Ezekiel 3 in the BOSCB
Ezekiel 3 in the BOSNC
Ezekiel 3 in the BOTLNT
Ezekiel 3 in the BOVCB
Ezekiel 3 in the BPBB
Ezekiel 3 in the BPH
Ezekiel 3 in the BSB
Ezekiel 3 in the CCB
Ezekiel 3 in the CUV
Ezekiel 3 in the CUVS
Ezekiel 3 in the DBT
Ezekiel 3 in the DGDNT
Ezekiel 3 in the DHNT
Ezekiel 3 in the DNT
Ezekiel 3 in the ELBE
Ezekiel 3 in the EMTV
Ezekiel 3 in the ESV
Ezekiel 3 in the FBV
Ezekiel 3 in the FEB
Ezekiel 3 in the GGMNT
Ezekiel 3 in the GNT
Ezekiel 3 in the HARY
Ezekiel 3 in the HNT
Ezekiel 3 in the IRVA
Ezekiel 3 in the IRVB
Ezekiel 3 in the IRVG
Ezekiel 3 in the IRVH
Ezekiel 3 in the IRVK
Ezekiel 3 in the IRVM
Ezekiel 3 in the IRVM2
Ezekiel 3 in the IRVO
Ezekiel 3 in the IRVP
Ezekiel 3 in the IRVT
Ezekiel 3 in the IRVT2
Ezekiel 3 in the IRVU
Ezekiel 3 in the ISVN
Ezekiel 3 in the JSNT
Ezekiel 3 in the KAPI
Ezekiel 3 in the KBT1ETNIK
Ezekiel 3 in the KBV
Ezekiel 3 in the KJV
Ezekiel 3 in the KNFD
Ezekiel 3 in the LBA
Ezekiel 3 in the LBLA
Ezekiel 3 in the LNT
Ezekiel 3 in the LSV
Ezekiel 3 in the MAAL
Ezekiel 3 in the MBV
Ezekiel 3 in the MBV2
Ezekiel 3 in the MHNT
Ezekiel 3 in the MKNFD
Ezekiel 3 in the MNG
Ezekiel 3 in the MNT
Ezekiel 3 in the MNT2
Ezekiel 3 in the MRS1T
Ezekiel 3 in the NAA
Ezekiel 3 in the NASB
Ezekiel 3 in the NBLA
Ezekiel 3 in the NBS
Ezekiel 3 in the NBVTP
Ezekiel 3 in the NET2
Ezekiel 3 in the NIV11
Ezekiel 3 in the NNT
Ezekiel 3 in the NNT2
Ezekiel 3 in the NNT3
Ezekiel 3 in the PDDPT
Ezekiel 3 in the PFNT
Ezekiel 3 in the RMNT
Ezekiel 3 in the SBIAS
Ezekiel 3 in the SBIBS
Ezekiel 3 in the SBIBS2
Ezekiel 3 in the SBICS
Ezekiel 3 in the SBIDS
Ezekiel 3 in the SBIGS
Ezekiel 3 in the SBIHS
Ezekiel 3 in the SBIIS
Ezekiel 3 in the SBIIS2
Ezekiel 3 in the SBIIS3
Ezekiel 3 in the SBIKS
Ezekiel 3 in the SBIKS2
Ezekiel 3 in the SBIMS
Ezekiel 3 in the SBIOS
Ezekiel 3 in the SBIPS
Ezekiel 3 in the SBISS
Ezekiel 3 in the SBITS
Ezekiel 3 in the SBITS2
Ezekiel 3 in the SBITS3
Ezekiel 3 in the SBITS4
Ezekiel 3 in the SBIUS
Ezekiel 3 in the SBIVS
Ezekiel 3 in the SBT
Ezekiel 3 in the SBT1E
Ezekiel 3 in the SCHL
Ezekiel 3 in the SNT
Ezekiel 3 in the SUSU
Ezekiel 3 in the SUSU2
Ezekiel 3 in the SYNO
Ezekiel 3 in the TBIAOTANT
Ezekiel 3 in the TBT1E
Ezekiel 3 in the TBT1E2
Ezekiel 3 in the TFTIP
Ezekiel 3 in the TFTU
Ezekiel 3 in the TGNTATF3T
Ezekiel 3 in the THAI
Ezekiel 3 in the TNFD
Ezekiel 3 in the TNT
Ezekiel 3 in the TNTIK
Ezekiel 3 in the TNTIL
Ezekiel 3 in the TNTIN
Ezekiel 3 in the TNTIP
Ezekiel 3 in the TNTIZ
Ezekiel 3 in the TOMA
Ezekiel 3 in the TTENT
Ezekiel 3 in the UBG
Ezekiel 3 in the UGV
Ezekiel 3 in the UGV2
Ezekiel 3 in the UGV3
Ezekiel 3 in the VBL
Ezekiel 3 in the VDCC
Ezekiel 3 in the YALU
Ezekiel 3 in the YAPE
Ezekiel 3 in the YBVTP
Ezekiel 3 in the ZBP