Genesis 11 (BOYCB)
1 Lẹ́yìn náà, gbogbo àgbáyé sì ń sọ èdè kan ṣoṣo. 2 Bí àwọn ènìyàn ṣe ń tẹ̀síwájú lọ sí ìhà ìlà-oòrùn, wọ́n rí pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan ní ilẹ̀ Ṣinari, wọ́n sì tẹ̀dó síbẹ̀. 3 Wọ́n sì wí fún ara wọn pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a mọ bíríkì kí a sì sún wọ́n jìnà.” Bíríkì ni wọ́n ń lò ní ipò òkúta, àti ọ̀dà ilẹ̀ tí wọn ń lò láti mú wọn papọ̀ dípò ẹfun (òkúta láìmù tí wọ́n fi ń ṣe símẹ́ńtì àti omi). 4 Nígbà náà ni wọ́n wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a tẹ ìlú kan dó fún ara wa, kí a sì kọ́ ilé ìṣọ́ kan tí yóò kan ọ̀run, kí a ba à lè ní orúkọ, kí a má sì tú káàkiri sórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” 5 Ṣùgbọ́n, OLÚWA sọ̀kalẹ̀ láti wo ìlú àti ilé ìṣọ́ tí àwọn ènìyàn náà ń kọ́. 6 OLÚWA wí pé, “Bí àwọn ènìyàn bá ń jẹ́ ọ̀kan àti èdè kan tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ yìí, kò sí ohun tí wọ́n gbèrò tí wọn kò ní le ṣe yọrí. 7 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a sọ̀kalẹ̀ lọ, kí a da èdè wọn rú kí èdè wọn má ba à yé ara wọn mọ́.” 8 OLÚWA sì tú wọn ká sórí ilẹ̀ gbogbo, wọ́n sì ṣíwọ́ ìlú náà tí wọn ń tẹ̀dó. 9 Ìdí èyí ni a fi pè é ní Babeli nítorí ní ibẹ̀ ni OLÚWA ti da èdè gbogbo ayé rú. OLÚWA tí sì tú àwọn ènìyàn ká sí gbogbo orí ilẹ̀ ayé. 10 Wọ̀nyí ni ìran Ṣemu. Ọdún méjì lẹ́yìn ìkún omi, tí Ṣemu pé ọgọ́rùn-ún ọdún ni ó bí Arfakṣadi. 11 Lẹ́yìn tí ó bí Arfakṣadi, Ṣemu tún wà láààyè fún ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún (500), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. 12 Nígbà tí Arfakṣadi pé ọdún márùndínlógójì ni ó bí Ṣela. 13 Arfakṣadi sì wà láààyè fún ọdún mẹ́tàlénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Ṣela, ó sì bí àwọn ọmọbìnrin àti àwọn ọmọkùnrin mìíràn. 14 Nígbà tí Ṣela pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Eberi. 15 Ṣela sì wà láààyè fún ọdún mẹ́tàlénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Eberi tán, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. 16 Eberi sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n, ó sì bí Pelegi. 17 Eberi sì wà láààyè fún irinwó ọdún ó lé ọgbọ̀n (430) lẹ́yìn tí ó bí Pelegi, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. 18 Nígbà tí Pelegi pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Reu. 19 Pelegi sì tún wà láààyè fún igba ọdún ó lé mẹ́sàn-án (209) lẹ́yìn tí ó bí Reu, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. 20 Nígbà tí Reu pé ọdún méjìlélọ́gbọ̀n ni ó bí Serugu. 21 Reu tún wà láààyè lẹ́yìn tí ó bí Serugu fún igba ọdún ó lé méje (207), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mìíràn. 22 Nígbà tí Serugu pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Nahori. 23 Serugu sì wà láààyè fún igba ọdún lẹ́yìn tí ó bí Nahori, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. 24 Nígbà tí Nahori pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n, ó bí Tẹra. 25 Nahori sì wà láààyè fún ọdún mọ́kàn dín lọ́gọ́fà lẹ́yìn ìbí Tẹra, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. 26 Lẹ́yìn tí Tẹra pé ọmọ àádọ́rin ọdún ó bí Abramu, Nahori àti Harani. 27 Wọ̀nyí ni ìran Tẹra. Tẹra ni baba Abramu, Nahori àti Harani. Harani sì bí Lọti. 28 Harani sì kú ṣáájú Tẹra baba rẹ̀ ní ilẹ̀ ìbí rẹ̀ ní Uri ti ilẹ̀ Kaldea. 29 Abramu àti Nahori sì gbéyàwó. Orúkọ aya Abramu ni Sarai, nígbà tí aya Nahori ń jẹ́ Milka, tí ṣe ọmọ Harani. Harani ni ó bí Milka àti Iska. 30 Sarai sì yàgàn, kò sì bímọ. 31 Tẹra sì mú ọmọ rẹ̀ Abramu àti Lọti ọmọ Harani, ọmọ ọmọ rẹ̀, ó sì mú Sarai tí i ṣe aya ọmọ rẹ̀. Abramu pẹ̀lú gbogbo wọn sì jáde kúrò ní Uri ti Kaldea láti lọ sí ilẹ̀ Kenaani. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọn dé Harani wọ́n tẹ̀dó síbẹ̀. 32 Nígbà tí Tẹra pé ọmọ igba ọdún ó lé márùn-ún (205) ni ó kú ní Harani.
In Other Versions
Genesis 11 in the ANGEFD
Genesis 11 in the ANTPNG2D
Genesis 11 in the AS21
Genesis 11 in the BAGH
Genesis 11 in the BBPNG
Genesis 11 in the BBT1E
Genesis 11 in the BDS
Genesis 11 in the BEV
Genesis 11 in the BHAD
Genesis 11 in the BIB
Genesis 11 in the BLPT
Genesis 11 in the BNT
Genesis 11 in the BNTABOOT
Genesis 11 in the BNTLV
Genesis 11 in the BOATCB
Genesis 11 in the BOATCB2
Genesis 11 in the BOBCV
Genesis 11 in the BOCNT
Genesis 11 in the BOECS
Genesis 11 in the BOGWICC
Genesis 11 in the BOHCB
Genesis 11 in the BOHCV
Genesis 11 in the BOHLNT
Genesis 11 in the BOHNTLTAL
Genesis 11 in the BOICB
Genesis 11 in the BOILNTAP
Genesis 11 in the BOITCV
Genesis 11 in the BOKCV
Genesis 11 in the BOKCV2
Genesis 11 in the BOKHWOG
Genesis 11 in the BOKSSV
Genesis 11 in the BOLCB
Genesis 11 in the BOLCB2
Genesis 11 in the BOMCV
Genesis 11 in the BONAV
Genesis 11 in the BONCB
Genesis 11 in the BONLT
Genesis 11 in the BONUT2
Genesis 11 in the BOPLNT
Genesis 11 in the BOSCB
Genesis 11 in the BOSNC
Genesis 11 in the BOTLNT
Genesis 11 in the BOVCB
Genesis 11 in the BPBB
Genesis 11 in the BPH
Genesis 11 in the BSB
Genesis 11 in the CCB
Genesis 11 in the CUV
Genesis 11 in the CUVS
Genesis 11 in the DBT
Genesis 11 in the DGDNT
Genesis 11 in the DHNT
Genesis 11 in the DNT
Genesis 11 in the ELBE
Genesis 11 in the EMTV
Genesis 11 in the ESV
Genesis 11 in the FBV
Genesis 11 in the FEB
Genesis 11 in the GGMNT
Genesis 11 in the GNT
Genesis 11 in the HARY
Genesis 11 in the HNT
Genesis 11 in the IRVA
Genesis 11 in the IRVB
Genesis 11 in the IRVG
Genesis 11 in the IRVH
Genesis 11 in the IRVK
Genesis 11 in the IRVM
Genesis 11 in the IRVM2
Genesis 11 in the IRVO
Genesis 11 in the IRVP
Genesis 11 in the IRVT
Genesis 11 in the IRVT2
Genesis 11 in the IRVU
Genesis 11 in the ISVN
Genesis 11 in the JSNT
Genesis 11 in the KAPI
Genesis 11 in the KBT1ETNIK
Genesis 11 in the KBV
Genesis 11 in the KJV
Genesis 11 in the KNFD
Genesis 11 in the LBA
Genesis 11 in the LBLA
Genesis 11 in the LNT
Genesis 11 in the LSV
Genesis 11 in the MAAL
Genesis 11 in the MBV
Genesis 11 in the MBV2
Genesis 11 in the MHNT
Genesis 11 in the MKNFD
Genesis 11 in the MNG
Genesis 11 in the MNT
Genesis 11 in the MNT2
Genesis 11 in the MRS1T
Genesis 11 in the NAA
Genesis 11 in the NASB
Genesis 11 in the NBLA
Genesis 11 in the NBS
Genesis 11 in the NBVTP
Genesis 11 in the NET2
Genesis 11 in the NIV11
Genesis 11 in the NNT
Genesis 11 in the NNT2
Genesis 11 in the NNT3
Genesis 11 in the PDDPT
Genesis 11 in the PFNT
Genesis 11 in the RMNT
Genesis 11 in the SBIAS
Genesis 11 in the SBIBS
Genesis 11 in the SBIBS2
Genesis 11 in the SBICS
Genesis 11 in the SBIDS
Genesis 11 in the SBIGS
Genesis 11 in the SBIHS
Genesis 11 in the SBIIS
Genesis 11 in the SBIIS2
Genesis 11 in the SBIIS3
Genesis 11 in the SBIKS
Genesis 11 in the SBIKS2
Genesis 11 in the SBIMS
Genesis 11 in the SBIOS
Genesis 11 in the SBIPS
Genesis 11 in the SBISS
Genesis 11 in the SBITS
Genesis 11 in the SBITS2
Genesis 11 in the SBITS3
Genesis 11 in the SBITS4
Genesis 11 in the SBIUS
Genesis 11 in the SBIVS
Genesis 11 in the SBT
Genesis 11 in the SBT1E
Genesis 11 in the SCHL
Genesis 11 in the SNT
Genesis 11 in the SUSU
Genesis 11 in the SUSU2
Genesis 11 in the SYNO
Genesis 11 in the TBIAOTANT
Genesis 11 in the TBT1E
Genesis 11 in the TBT1E2
Genesis 11 in the TFTIP
Genesis 11 in the TFTU
Genesis 11 in the TGNTATF3T
Genesis 11 in the THAI
Genesis 11 in the TNFD
Genesis 11 in the TNT
Genesis 11 in the TNTIK
Genesis 11 in the TNTIL
Genesis 11 in the TNTIN
Genesis 11 in the TNTIP
Genesis 11 in the TNTIZ
Genesis 11 in the TOMA
Genesis 11 in the TTENT
Genesis 11 in the UBG
Genesis 11 in the UGV
Genesis 11 in the UGV2
Genesis 11 in the UGV3
Genesis 11 in the VBL
Genesis 11 in the VDCC
Genesis 11 in the YALU
Genesis 11 in the YAPE
Genesis 11 in the YBVTP
Genesis 11 in the ZBP