Hebrews 3 (BOYCB)
1 Nítorí náà ẹ̀yin ará mímọ́, alábápín ìpè ọ̀run, ẹ gba ti aposteli àti olórí àlùfáà ìjẹ́wọ́ wa rò, àní Jesu; 2 ẹni tí o ṣe olóòtítọ́ si ẹni tí ó yàn án, bí Mose pẹ̀lú tí ṣe olóòtítọ́ nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo nínú ilé Ọlọ́run. 3 Nítorí a ka ọkùnrin yìí ni yíyẹ sí ògo ju Mose lọ níwọ̀n bí ẹni tí ó kọ́ ilé ti lọ́lá ju ilé lọ. 4 Láti ọwọ́ ènìyàn kan ni a sá à ti kọ́ olúkúlùkù ilé; ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run. 5 Mose nítòótọ́ sì ṣe olóòtítọ́ nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run, bí ìránṣẹ́, fún ẹ̀rí ohun tí a ó sọ̀rọ̀ wọ́n ní ìgbà ìkẹyìn. 6 Ṣùgbọ́n Kristi jẹ́ olóòtítọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ lórí ilé Ọlọ́run; ilé ẹni tí àwa jẹ́, bí àwa bá gbẹ́kẹ̀lé e, tí a sì di ìṣògo ìrètí wa mu ṣinṣin títí dé òpin. 7 Nítorí náà gẹ́gẹ́ bi Ẹ̀mí Mímọ́ tí wí:“Lónìí bí ẹ̀yin bá gbọ́ ohùn rẹ̀, 8 ẹ má ṣe sé ọkàn yín le,bí ìgbà ìṣọ̀tẹ̀,bí i ní ọjọ́ ìdánwò ní aginjù, 9 níbi tí àwọn baba yín ti dán mi wò,tí wọ́n sì rí iṣẹ́ mi ní ogójì ọdún. 10 Nítorí náà a mú inú bí mi si ìran náà,mo sì wí pé, ‘Nígbà gbogbo ni wọn ṣìnà ní ọkàn wọn;wọn kò sì mọ ọ̀nà mi.’ 11 Bí mo tí búra nínú ìbínú mi,‘Wọn kí yóò wọ inú ìsinmi mi.’ ” 12 Ẹ kíyèsára, ará, kí ọkàn búburú ti àìgbàgbọ́ má ṣe wà nínú ẹnikẹ́ni yín, ní lílọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè. 13 Ṣùgbọ́n ẹ máa gba ara yín ní ìyànjú ní ojoojúmọ́, níwọ̀n ìgbà tí a bá ń pè ní “Òní,” kí a má ba à sé ọkàn ẹnikẹ́ni nínú yín le nípa ẹ̀tàn ẹ̀ṣẹ̀. 14 Nítorí àwa di alábápín pẹ̀lú Kristi, bí àwa bá di ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé wa mú ṣinṣin títí dé òpin. 15 Nígbà tí a ń wí pé,“Lónìí bí ẹ̀yin bá gbọ́ ohùn rẹ̀,ẹ má sé ọkàn yin le,bí ìgbà ìṣọ̀tẹ̀.” 16 Àwọn ta ni ó gbọ́ tí ó sì tún ṣọ̀tẹ̀? Kì í ha ṣe gbogbo àwọn tí o jáde kúrò ní Ejibiti ní abẹ́ àkóso Mose? 17 Àwọn ta ni ó sì bínú sí fún ogójì ọdún? Kì í ha ṣe sí àwọn tí ó dẹ́ṣẹ̀, òkú àwọn tí ó sùn ní aginjù? 18 Àwọn wo ni ó búra fún pé wọn kì yóò wọ inú ìsinmi òun, bí kò ṣe fún àwọn tí ó ṣe àìgbọ́ràn? 19 Àwa sì rí i pé wọn kò lè wọ inú rẹ̀ nítorí àìgbàgbọ́.
In Other Versions
Hebrews 3 in the ANGEFD
Hebrews 3 in the ANTPNG2D
Hebrews 3 in the AS21
Hebrews 3 in the BAGH
Hebrews 3 in the BBPNG
Hebrews 3 in the BBT1E
Hebrews 3 in the BDS
Hebrews 3 in the BEV
Hebrews 3 in the BHAD
Hebrews 3 in the BIB
Hebrews 3 in the BLPT
Hebrews 3 in the BNT
Hebrews 3 in the BNTABOOT
Hebrews 3 in the BNTLV
Hebrews 3 in the BOATCB
Hebrews 3 in the BOATCB2
Hebrews 3 in the BOBCV
Hebrews 3 in the BOCNT
Hebrews 3 in the BOECS
Hebrews 3 in the BOGWICC
Hebrews 3 in the BOHCB
Hebrews 3 in the BOHCV
Hebrews 3 in the BOHLNT
Hebrews 3 in the BOHNTLTAL
Hebrews 3 in the BOICB
Hebrews 3 in the BOILNTAP
Hebrews 3 in the BOITCV
Hebrews 3 in the BOKCV
Hebrews 3 in the BOKCV2
Hebrews 3 in the BOKHWOG
Hebrews 3 in the BOKSSV
Hebrews 3 in the BOLCB
Hebrews 3 in the BOLCB2
Hebrews 3 in the BOMCV
Hebrews 3 in the BONAV
Hebrews 3 in the BONCB
Hebrews 3 in the BONLT
Hebrews 3 in the BONUT2
Hebrews 3 in the BOPLNT
Hebrews 3 in the BOSCB
Hebrews 3 in the BOSNC
Hebrews 3 in the BOTLNT
Hebrews 3 in the BOVCB
Hebrews 3 in the BPBB
Hebrews 3 in the BPH
Hebrews 3 in the BSB
Hebrews 3 in the CCB
Hebrews 3 in the CUV
Hebrews 3 in the CUVS
Hebrews 3 in the DBT
Hebrews 3 in the DGDNT
Hebrews 3 in the DHNT
Hebrews 3 in the DNT
Hebrews 3 in the ELBE
Hebrews 3 in the EMTV
Hebrews 3 in the ESV
Hebrews 3 in the FBV
Hebrews 3 in the FEB
Hebrews 3 in the GGMNT
Hebrews 3 in the GNT
Hebrews 3 in the HARY
Hebrews 3 in the HNT
Hebrews 3 in the IRVA
Hebrews 3 in the IRVB
Hebrews 3 in the IRVG
Hebrews 3 in the IRVH
Hebrews 3 in the IRVK
Hebrews 3 in the IRVM
Hebrews 3 in the IRVM2
Hebrews 3 in the IRVO
Hebrews 3 in the IRVP
Hebrews 3 in the IRVT
Hebrews 3 in the IRVT2
Hebrews 3 in the IRVU
Hebrews 3 in the ISVN
Hebrews 3 in the JSNT
Hebrews 3 in the KAPI
Hebrews 3 in the KBT1ETNIK
Hebrews 3 in the KBV
Hebrews 3 in the KJV
Hebrews 3 in the KNFD
Hebrews 3 in the LBA
Hebrews 3 in the LBLA
Hebrews 3 in the LNT
Hebrews 3 in the LSV
Hebrews 3 in the MAAL
Hebrews 3 in the MBV
Hebrews 3 in the MBV2
Hebrews 3 in the MHNT
Hebrews 3 in the MKNFD
Hebrews 3 in the MNG
Hebrews 3 in the MNT
Hebrews 3 in the MNT2
Hebrews 3 in the MRS1T
Hebrews 3 in the NAA
Hebrews 3 in the NASB
Hebrews 3 in the NBLA
Hebrews 3 in the NBS
Hebrews 3 in the NBVTP
Hebrews 3 in the NET2
Hebrews 3 in the NIV11
Hebrews 3 in the NNT
Hebrews 3 in the NNT2
Hebrews 3 in the NNT3
Hebrews 3 in the PDDPT
Hebrews 3 in the PFNT
Hebrews 3 in the RMNT
Hebrews 3 in the SBIAS
Hebrews 3 in the SBIBS
Hebrews 3 in the SBIBS2
Hebrews 3 in the SBICS
Hebrews 3 in the SBIDS
Hebrews 3 in the SBIGS
Hebrews 3 in the SBIHS
Hebrews 3 in the SBIIS
Hebrews 3 in the SBIIS2
Hebrews 3 in the SBIIS3
Hebrews 3 in the SBIKS
Hebrews 3 in the SBIKS2
Hebrews 3 in the SBIMS
Hebrews 3 in the SBIOS
Hebrews 3 in the SBIPS
Hebrews 3 in the SBISS
Hebrews 3 in the SBITS
Hebrews 3 in the SBITS2
Hebrews 3 in the SBITS3
Hebrews 3 in the SBITS4
Hebrews 3 in the SBIUS
Hebrews 3 in the SBIVS
Hebrews 3 in the SBT
Hebrews 3 in the SBT1E
Hebrews 3 in the SCHL
Hebrews 3 in the SNT
Hebrews 3 in the SUSU
Hebrews 3 in the SUSU2
Hebrews 3 in the SYNO
Hebrews 3 in the TBIAOTANT
Hebrews 3 in the TBT1E
Hebrews 3 in the TBT1E2
Hebrews 3 in the TFTIP
Hebrews 3 in the TFTU
Hebrews 3 in the TGNTATF3T
Hebrews 3 in the THAI
Hebrews 3 in the TNFD
Hebrews 3 in the TNT
Hebrews 3 in the TNTIK
Hebrews 3 in the TNTIL
Hebrews 3 in the TNTIN
Hebrews 3 in the TNTIP
Hebrews 3 in the TNTIZ
Hebrews 3 in the TOMA
Hebrews 3 in the TTENT
Hebrews 3 in the UBG
Hebrews 3 in the UGV
Hebrews 3 in the UGV2
Hebrews 3 in the UGV3
Hebrews 3 in the VBL
Hebrews 3 in the VDCC
Hebrews 3 in the YALU
Hebrews 3 in the YAPE
Hebrews 3 in the YBVTP
Hebrews 3 in the ZBP