Isaiah 19 (BOYCB)

1 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Ejibiti.Kíyèsi i, OLÚWA gun àwọsánmọ̀ tí ó yára lẹ́ṣinó sì ń bọ̀ wá sí Ejibiti.Àwọn ère òrìṣà Ejibiti wárìrì níwájú rẹ̀,ọkàn àwọn ará Ejibiti sì ti domi nínú wọn. 2 “Èmi yóò rú àwọn ará Ejibiti sókè sí ara wọnarákùnrin yóò bá arákùnrin rẹ̀ jà,aládùúgbò yóò dìde sí aládùúgbò rẹ̀,ìlú yóò dìde sí ìlú,ilẹ̀ ọba sí ilẹ̀ ọba. 3 Àwọn ará Ejibiti yóò sọ ìrètí nù,èmi yóò sì sọ èrò wọn gbogbo di òfo;wọn yóò bá àwọn òrìṣà àti ẹ̀mí àwọn òkú sọ̀rọ̀,àwọn awoṣẹ́ àti àwọn abókùúsọ̀rọ̀. 4 Èmi yóò fi Ejibiti lé agbáraàwọn ìkà amúnisìn lọ́wọ́,ọba aláìláàánú ni yóò jẹ ọba lé wọn lórí,”ni Olúwa, OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí. 5 Gbogbo omi inú odò ni yóò gbẹ,gbogbo ilẹ̀ àyíká odò ni yóò gbẹ tí yóò sì sáàpá. 6 Adágún omi yóò sì di rírùn;àwọn odò ilẹ̀ Ejibiti yóò máa dínkùwọn yóò sì gbẹ.Àwọn koríko odò àti ìrẹ̀tẹ̀ yóò gbẹ, 7 àwọn igi ipadò Naili pẹ̀lú,tí ó wà ní orísun odò,gbogbo oko tí a dá sí ipadò Nailiyóò gbẹ dànù tí yóò sì fẹ́ dànùtí kò sì ní sí mọ́. 8 Àwọn apẹja yóò sọkún kíkorò,àti gbogbo àwọn tí ó ń ju ìwọ̀ sínú odò;odò náà yóò sì máa rùn. 9 Àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọ̀gbọ̀ yóò kọminúàwọn ahunṣọ ọ̀gbọ̀ yóò sọ ìrètí nù. 10 Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ aṣọ yóò rẹ̀wẹ̀sì,gbogbo àwọn oníṣẹ́ oṣù ni àìsàn ọkàn yóò ṣe. 11 Àwọn oníṣẹ́ Ṣoani ti di aláìgbọ́n,àwọn ọlọ́gbọ́n olùdámọ̀ràn Faraoń mú ìmọ̀ràn àìgbọ́n wá.Báwo ló ṣe lè sọ fún Farao pé,“Mo jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn,ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn ọba àtijọ́.” 12 Níbo ni àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn rẹ wà báyìí?Jẹ́ kí wọn fihàn ọ́ kí wọn sì sọ ọ́ di mí mọ̀ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogunti pinnu lórí Ejibiti. 13 Àwọn ọmọ-aládé Ṣoani ti di aṣiwèrè,a ti tan àwọn ọmọ-aládé Memfisi jẹ;àwọn òkúta igun ilé tí í ṣe ti ẹ̀yà rẹti ṣi Ejibiti lọ́nà. 14 OLÚWA ti da ẹ̀mí òòyì sínú wọn;wọ́n mú Ejibiti ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nínúohun gbogbo tí ó ń ṣe,gẹ́gẹ́ bí ọ̀mùtí ti í ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nínú èébì rẹ̀. 15 Kò sí ohun tí Ejibiti le ṣe—orí tàbí ìrù, ọ̀wá ọ̀pẹ tàbí koríko odò. 16 Ní ọjọ́ náà ni àwọn ará Ejibiti yóò dàbí obìnrin. Wọn yóò gbọ̀n jìnnìjìnnì pẹ̀lú ẹ̀rù nítorí ọwọ́ OLÚWA àwọn ọmọ-ogun tí a gbé sókè sí wọn. 17 Ilẹ̀ Juda yóò sì di ẹ̀rù fún Ejibiti; gbogbo àwọn tí a bá ti dárúkọ Juda létí wọn ni yóò wárìrì, nítorí ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun gbèrò láti ṣe sí wọn. 18 Ní ọjọ́ náà ìlú márùn-ún ní ilẹ̀ Ejibiti yóò sọ èdè àwọn ará Kenaani, wọn yóò sì búra àtìlẹ́yìn fún OLÚWA àwọn ọmọ-ogun. Ọ̀kan nínú wọn ni a ó sì máa pè ní ìlú ìparun. 19 Ní ọjọ́ náà pẹpẹ kan yóò wà fún OLÚWA ní àárín gbùngbùn Ejibiti, àti ọ̀wọ́n kan fún OLÚWA ní etí bodè rẹ̀. 20 Yóò sì jẹ́ àmì àti ẹ̀rí sí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ní ilẹ̀ Ejibiti. Nígbà tí wọ́n bá ké pe OLÚWA nítorí àwọn aninilára wọn, yóò rán olùgbàlà àti olùgbèjà kan sí wọn tí yóò sì gbà wọ́n sílẹ̀. 21 Báyìí ni OLÚWA yóò sọ ara rẹ̀ di mí mọ̀ fún àwọn ará Ejibiti àti ní ọjọ́ náà ni wọn yóò gba OLÚWA gbọ́. Wọn yóò sìn ín pẹ̀lú ẹbọ ọrẹ ìyẹ̀fun, wọn yóò jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLÚWA wọn yóò sì mú un ṣẹ. 22 OLÚWA yóò fi àjàkálẹ̀-ààrùn kan bá Ejibiti jà; yóò bá wọn jà yóò sì tún wò wọ́n sàn. Wọn yóò yípadà sí OLÚWA, Òun yóò sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn yóò sì wò wọ́n sàn. 23 Ní ọjọ́ náà òpópónà kan yóò wá láti Ejibiti lọ sí Asiria. Àwọn ará Asiria yóò lọ sí Ejibiti àti àwọn ará Ejibiti lọ sí Asiria. Àwọn ará Ejibiti àti ará Asiria yóò jọ́sìn papọ̀. 24 Ní ọjọ́ náà Israẹli yóò di ẹ̀kẹta pẹ̀lú Ejibiti àti Asiria, àní orísun ìbùkún ní ilẹ̀ ayé. 25 OLÚWA àwọn ọmọ-ogun yóò bùkún wọn yóò wí pé, “Ìbùkún ni fún Ejibiti ènìyàn mi, Asiria iṣẹ́ ọwọ́ mi, àti Israẹli ìní mi.”

In Other Versions

Isaiah 19 in the ANGEFD

Isaiah 19 in the ANTPNG2D

Isaiah 19 in the AS21

Isaiah 19 in the BAGH

Isaiah 19 in the BBPNG

Isaiah 19 in the BBT1E

Isaiah 19 in the BDS

Isaiah 19 in the BEV

Isaiah 19 in the BHAD

Isaiah 19 in the BIB

Isaiah 19 in the BLPT

Isaiah 19 in the BNT

Isaiah 19 in the BNTABOOT

Isaiah 19 in the BNTLV

Isaiah 19 in the BOATCB

Isaiah 19 in the BOATCB2

Isaiah 19 in the BOBCV

Isaiah 19 in the BOCNT

Isaiah 19 in the BOECS

Isaiah 19 in the BOGWICC

Isaiah 19 in the BOHCB

Isaiah 19 in the BOHCV

Isaiah 19 in the BOHLNT

Isaiah 19 in the BOHNTLTAL

Isaiah 19 in the BOICB

Isaiah 19 in the BOILNTAP

Isaiah 19 in the BOITCV

Isaiah 19 in the BOKCV

Isaiah 19 in the BOKCV2

Isaiah 19 in the BOKHWOG

Isaiah 19 in the BOKSSV

Isaiah 19 in the BOLCB

Isaiah 19 in the BOLCB2

Isaiah 19 in the BOMCV

Isaiah 19 in the BONAV

Isaiah 19 in the BONCB

Isaiah 19 in the BONLT

Isaiah 19 in the BONUT2

Isaiah 19 in the BOPLNT

Isaiah 19 in the BOSCB

Isaiah 19 in the BOSNC

Isaiah 19 in the BOTLNT

Isaiah 19 in the BOVCB

Isaiah 19 in the BPBB

Isaiah 19 in the BPH

Isaiah 19 in the BSB

Isaiah 19 in the CCB

Isaiah 19 in the CUV

Isaiah 19 in the CUVS

Isaiah 19 in the DBT

Isaiah 19 in the DGDNT

Isaiah 19 in the DHNT

Isaiah 19 in the DNT

Isaiah 19 in the ELBE

Isaiah 19 in the EMTV

Isaiah 19 in the ESV

Isaiah 19 in the FBV

Isaiah 19 in the FEB

Isaiah 19 in the GGMNT

Isaiah 19 in the GNT

Isaiah 19 in the HARY

Isaiah 19 in the HNT

Isaiah 19 in the IRVA

Isaiah 19 in the IRVB

Isaiah 19 in the IRVG

Isaiah 19 in the IRVH

Isaiah 19 in the IRVK

Isaiah 19 in the IRVM

Isaiah 19 in the IRVM2

Isaiah 19 in the IRVO

Isaiah 19 in the IRVP

Isaiah 19 in the IRVT

Isaiah 19 in the IRVT2

Isaiah 19 in the IRVU

Isaiah 19 in the ISVN

Isaiah 19 in the JSNT

Isaiah 19 in the KAPI

Isaiah 19 in the KBT1ETNIK

Isaiah 19 in the KBV

Isaiah 19 in the KJV

Isaiah 19 in the KNFD

Isaiah 19 in the LBA

Isaiah 19 in the LBLA

Isaiah 19 in the LNT

Isaiah 19 in the LSV

Isaiah 19 in the MAAL

Isaiah 19 in the MBV

Isaiah 19 in the MBV2

Isaiah 19 in the MHNT

Isaiah 19 in the MKNFD

Isaiah 19 in the MNG

Isaiah 19 in the MNT

Isaiah 19 in the MNT2

Isaiah 19 in the MRS1T

Isaiah 19 in the NAA

Isaiah 19 in the NASB

Isaiah 19 in the NBLA

Isaiah 19 in the NBS

Isaiah 19 in the NBVTP

Isaiah 19 in the NET2

Isaiah 19 in the NIV11

Isaiah 19 in the NNT

Isaiah 19 in the NNT2

Isaiah 19 in the NNT3

Isaiah 19 in the PDDPT

Isaiah 19 in the PFNT

Isaiah 19 in the RMNT

Isaiah 19 in the SBIAS

Isaiah 19 in the SBIBS

Isaiah 19 in the SBIBS2

Isaiah 19 in the SBICS

Isaiah 19 in the SBIDS

Isaiah 19 in the SBIGS

Isaiah 19 in the SBIHS

Isaiah 19 in the SBIIS

Isaiah 19 in the SBIIS2

Isaiah 19 in the SBIIS3

Isaiah 19 in the SBIKS

Isaiah 19 in the SBIKS2

Isaiah 19 in the SBIMS

Isaiah 19 in the SBIOS

Isaiah 19 in the SBIPS

Isaiah 19 in the SBISS

Isaiah 19 in the SBITS

Isaiah 19 in the SBITS2

Isaiah 19 in the SBITS3

Isaiah 19 in the SBITS4

Isaiah 19 in the SBIUS

Isaiah 19 in the SBIVS

Isaiah 19 in the SBT

Isaiah 19 in the SBT1E

Isaiah 19 in the SCHL

Isaiah 19 in the SNT

Isaiah 19 in the SUSU

Isaiah 19 in the SUSU2

Isaiah 19 in the SYNO

Isaiah 19 in the TBIAOTANT

Isaiah 19 in the TBT1E

Isaiah 19 in the TBT1E2

Isaiah 19 in the TFTIP

Isaiah 19 in the TFTU

Isaiah 19 in the TGNTATF3T

Isaiah 19 in the THAI

Isaiah 19 in the TNFD

Isaiah 19 in the TNT

Isaiah 19 in the TNTIK

Isaiah 19 in the TNTIL

Isaiah 19 in the TNTIN

Isaiah 19 in the TNTIP

Isaiah 19 in the TNTIZ

Isaiah 19 in the TOMA

Isaiah 19 in the TTENT

Isaiah 19 in the UBG

Isaiah 19 in the UGV

Isaiah 19 in the UGV2

Isaiah 19 in the UGV3

Isaiah 19 in the VBL

Isaiah 19 in the VDCC

Isaiah 19 in the YALU

Isaiah 19 in the YAPE

Isaiah 19 in the YBVTP

Isaiah 19 in the ZBP