Isaiah 43 (BOYCB)
1 Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí, ohun tí OLÚWA wí nìyìí,ẹni tí ó dá ọ, ìwọ Jakọbu,ẹni tí ó mọ ọ́, ìwọ Israẹli:“Má bẹ̀rù, nítorí Èmi ti dá ọ nídè;Èmi ti pè ọ́ ní orúkọ; tèmi ni ìwọ ṣe. 2 Nígbà tí ìwọ bá ń la omi kọjá,Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ;àti nígbà tí ìwọ bá ń la odò kọjáwọn kì yóò bò ọ́ mọ́lẹ̀.Nígbà tí ìwọ bá la iná kọjá,kò ní jó ọ;ahọ́n iná kò ní jó ọ lára. 3 Nítorí Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run rẹ,Ẹni Mímọ́ Israẹli Olùgbàlà rẹ;Èmi fi Ejibiti ṣe ìràpadà rẹ,Kuṣi àti Seba dípò rẹ. 4 Nítorí pé o ṣe iyebíye àti ọ̀wọ́n níwájú mi,àti nítorí pé mo fẹ́ràn rẹ,Èmi yóò fi ènìyàn rọ́pò fún ọ,àti ènìyàn dípò ẹ̀mí rẹ. 5 Má bẹ̀rù nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ;Èmi yóò mú àwọn ọmọ rẹ láti ìlà-oòrùn wáèmi ó sì kó ọ jọ láti ìwọ̀-oòrùn. 6 Èmi yóò sọ fún àríwá pé, ‘Fi wọ́n sílẹ̀!’Àti fún gúúsù, ‘Má ṣe dá wọn dúró.’Mú àwọn ọmọkùnrin mi láti ọ̀nà jíjìn wáàti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin mi láti ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé— 7 ẹnikẹ́ni tí a ń pe orúkọ mi mọ́,tí mo dá fún ògo mi,tí mo mọ̀ àti tí mo ṣe.” 8 Sin àwọn tí ó ní ojú ṣùgbọ́n tí wọ́n fọ́jú jáde,tí wọ́n ní etí ṣùgbọ́n tí wọn dití. 9 Gbogbo orílẹ̀-èdè kó ra wọn jọàwọn ènìyàn sì kó ra wọn papọ̀.Ta ni nínú wọn tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìítí ó sì kéde fún wa àwọn nǹkan ti tẹ́lẹ̀?Jẹ́ kí wọ́n mú àwọn ẹlẹ́rìí wọn wọlé wáláti fihàn pé wọ́n tọ̀nàtó bẹ́ẹ̀ tí àwọn mìíràn yóò gbọ́,tí wọn yóò sọ pé, “Òtítọ́ ni.” 10 “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni OLÚWA wí,“Àti ìránṣẹ́ mi tí èmi ti yàn,tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin yóò fi mọ̀ àti tí ẹ̀yin ó fi gbà mí gbọ́tí yóò sì yé e yín pé èmi ni ẹni náà.Ṣáájú mi kò sí ọlọ́run tí a dá,tàbí a ó wa rí òmíràn lẹ́yìn mi. 11 Èmi, àní Èmi, Èmi ni OLÚWA,yàtọ̀ sí èmi, kò sí olùgbàlà mìíràn. 12 Èmi ti fihàn, mo gbàlà mo sì ti kédeÈmi, kì í sì í ṣe àwọn àjèjì òrìṣà láàrín yín.Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni OLÚWA wí, “Pé Èmi ni Ọlọ́run. 13 Bẹ́ẹ̀ ni, àti láti ayérayé Èmi ni ẹni náà.Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ mi.Nígbà tí mo bá ṣe nǹkan, ta ni ó lè yí i padà?” 14 Èyí ni ohun tí OLÚWA wí,olùràpadà rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli:“Nítorí rẹ Èmi yóò ránṣẹ́ sí Babeliláti mú wọn sọ̀kalẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá, gbogbo ará Babeli,nínú ọkọ̀ ojú omi nínú èyí tí wọ́n fi ń ṣe ìgbéraga. 15 Èmi ni OLÚWA, Ẹni Mímọ́ rẹ,Ẹlẹ́dàá Israẹli, ọba rẹ.” 16 Èyí ni ohun tí OLÚWA wí,Ẹni náà tí ó la ọ̀nà nínú Òkun,ipa ọ̀nà láàrín alagbalúgbú omi, 17 ẹni tí ó wọ́ àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jáde,àwọn jagunjagun àti ohun ìjà papọ̀,wọ́n sì sùn síbẹ̀, láìní lè dìde mọ́,wọ́n kú pirá bí òwú-fìtílà: 18 “Gbàgbé àwọn ohun àtẹ̀yìnwá;má ṣe gbé nínú ohun àtijọ́. 19 Wò ó, Èmi ń ṣe ohun tuntun!Nísinsin yìí, ó ti yọ sókè; àbí o kò rí i bí?Èmi ń ṣe ọ̀nà kan nínú aṣálẹ̀àti odò nínú ilẹ̀ ṣíṣá. 20 Àwọn ẹhànnà ẹranko bọ̀wọ̀ fún mi,àwọn ajáko àti àwọn òwìwí,nítorí pé mo pèsè omi nínú aṣálẹ̀àti odò nínú ilẹ̀ sísá,láti fi ohun mímu fún àwọn ènìyàn mi, àyànfẹ́ mi, 21 àwọn ènìyàn tí mo dá fún ara mikí wọn kí ó lè kéde ìyìn mi. 22 “Síbẹ̀síbẹ̀ ìwọ kò tí ì ké pè mí, ìwọ Jakọbu,àárẹ̀ kò tí ì mú ọ nítorí mi ìwọ Israẹli. 23 Ìwọ kò tí ì mú àgùntàn wá fún mi fún ẹbọ sísun,tàbí kí o bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ẹbọ rẹ.Èmi kò tí ì wàhálà rẹ pẹ̀lú ọrẹ ìyẹ̀funtàbí kí n dààmú rẹ pẹ̀lú ìbéèrè fún tùràrí. 24 Ìwọ kò tí ì ra kalamusi olóòórùn dídùn fún mi,tàbí kí o da ọ̀rá ẹbọ rẹ bò mí.Ṣùgbọ́n ẹ ti wàhálà mi pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ yínẹ sì ti dààmú mi pẹ̀lú àìṣedéédéé yín. 25 “Èmi, àní Èmi, Èmi ni ẹni tí ó wẹàwọn àìṣedéédéé rẹ nù, nítorí èmi fún ara mi,tí n kò sì rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ mọ́. 26 Bojú wo ẹ̀yìn rẹ fún mi,jẹ́ kí a jọ ṣe àríyànjiyàn ọ̀rọ̀ náà papọ̀;ro ẹjọ́ láti fihàn pé o kò lẹ́sẹ̀ lọ́rùn. 27 Baba yín àkọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀;àwọn agbẹnusọ yín ṣọ̀tẹ̀ sí mi. 28 Nítorí náà, èmi ti sọ àwọn olórí ibi mímọ́ náà di àìmọ́,bẹ́ẹ̀ ni èmi ti fi Jakọbu fún ègúnàti Israẹli fún ẹ̀gàn.
In Other Versions
Isaiah 43 in the ANGEFD
Isaiah 43 in the ANTPNG2D
Isaiah 43 in the AS21
Isaiah 43 in the BAGH
Isaiah 43 in the BBPNG
Isaiah 43 in the BBT1E
Isaiah 43 in the BDS
Isaiah 43 in the BEV
Isaiah 43 in the BHAD
Isaiah 43 in the BIB
Isaiah 43 in the BLPT
Isaiah 43 in the BNT
Isaiah 43 in the BNTABOOT
Isaiah 43 in the BNTLV
Isaiah 43 in the BOATCB
Isaiah 43 in the BOATCB2
Isaiah 43 in the BOBCV
Isaiah 43 in the BOCNT
Isaiah 43 in the BOECS
Isaiah 43 in the BOGWICC
Isaiah 43 in the BOHCB
Isaiah 43 in the BOHCV
Isaiah 43 in the BOHLNT
Isaiah 43 in the BOHNTLTAL
Isaiah 43 in the BOICB
Isaiah 43 in the BOILNTAP
Isaiah 43 in the BOITCV
Isaiah 43 in the BOKCV
Isaiah 43 in the BOKCV2
Isaiah 43 in the BOKHWOG
Isaiah 43 in the BOKSSV
Isaiah 43 in the BOLCB
Isaiah 43 in the BOLCB2
Isaiah 43 in the BOMCV
Isaiah 43 in the BONAV
Isaiah 43 in the BONCB
Isaiah 43 in the BONLT
Isaiah 43 in the BONUT2
Isaiah 43 in the BOPLNT
Isaiah 43 in the BOSCB
Isaiah 43 in the BOSNC
Isaiah 43 in the BOTLNT
Isaiah 43 in the BOVCB
Isaiah 43 in the BPBB
Isaiah 43 in the BPH
Isaiah 43 in the BSB
Isaiah 43 in the CCB
Isaiah 43 in the CUV
Isaiah 43 in the CUVS
Isaiah 43 in the DBT
Isaiah 43 in the DGDNT
Isaiah 43 in the DHNT
Isaiah 43 in the DNT
Isaiah 43 in the ELBE
Isaiah 43 in the EMTV
Isaiah 43 in the ESV
Isaiah 43 in the FBV
Isaiah 43 in the FEB
Isaiah 43 in the GGMNT
Isaiah 43 in the GNT
Isaiah 43 in the HARY
Isaiah 43 in the HNT
Isaiah 43 in the IRVA
Isaiah 43 in the IRVB
Isaiah 43 in the IRVG
Isaiah 43 in the IRVH
Isaiah 43 in the IRVK
Isaiah 43 in the IRVM
Isaiah 43 in the IRVM2
Isaiah 43 in the IRVO
Isaiah 43 in the IRVP
Isaiah 43 in the IRVT
Isaiah 43 in the IRVT2
Isaiah 43 in the IRVU
Isaiah 43 in the ISVN
Isaiah 43 in the JSNT
Isaiah 43 in the KAPI
Isaiah 43 in the KBT1ETNIK
Isaiah 43 in the KBV
Isaiah 43 in the KJV
Isaiah 43 in the KNFD
Isaiah 43 in the LBA
Isaiah 43 in the LBLA
Isaiah 43 in the LNT
Isaiah 43 in the LSV
Isaiah 43 in the MAAL
Isaiah 43 in the MBV
Isaiah 43 in the MBV2
Isaiah 43 in the MHNT
Isaiah 43 in the MKNFD
Isaiah 43 in the MNG
Isaiah 43 in the MNT
Isaiah 43 in the MNT2
Isaiah 43 in the MRS1T
Isaiah 43 in the NAA
Isaiah 43 in the NASB
Isaiah 43 in the NBLA
Isaiah 43 in the NBS
Isaiah 43 in the NBVTP
Isaiah 43 in the NET2
Isaiah 43 in the NIV11
Isaiah 43 in the NNT
Isaiah 43 in the NNT2
Isaiah 43 in the NNT3
Isaiah 43 in the PDDPT
Isaiah 43 in the PFNT
Isaiah 43 in the RMNT
Isaiah 43 in the SBIAS
Isaiah 43 in the SBIBS
Isaiah 43 in the SBIBS2
Isaiah 43 in the SBICS
Isaiah 43 in the SBIDS
Isaiah 43 in the SBIGS
Isaiah 43 in the SBIHS
Isaiah 43 in the SBIIS
Isaiah 43 in the SBIIS2
Isaiah 43 in the SBIIS3
Isaiah 43 in the SBIKS
Isaiah 43 in the SBIKS2
Isaiah 43 in the SBIMS
Isaiah 43 in the SBIOS
Isaiah 43 in the SBIPS
Isaiah 43 in the SBISS
Isaiah 43 in the SBITS
Isaiah 43 in the SBITS2
Isaiah 43 in the SBITS3
Isaiah 43 in the SBITS4
Isaiah 43 in the SBIUS
Isaiah 43 in the SBIVS
Isaiah 43 in the SBT
Isaiah 43 in the SBT1E
Isaiah 43 in the SCHL
Isaiah 43 in the SNT
Isaiah 43 in the SUSU
Isaiah 43 in the SUSU2
Isaiah 43 in the SYNO
Isaiah 43 in the TBIAOTANT
Isaiah 43 in the TBT1E
Isaiah 43 in the TBT1E2
Isaiah 43 in the TFTIP
Isaiah 43 in the TFTU
Isaiah 43 in the TGNTATF3T
Isaiah 43 in the THAI
Isaiah 43 in the TNFD
Isaiah 43 in the TNT
Isaiah 43 in the TNTIK
Isaiah 43 in the TNTIL
Isaiah 43 in the TNTIN
Isaiah 43 in the TNTIP
Isaiah 43 in the TNTIZ
Isaiah 43 in the TOMA
Isaiah 43 in the TTENT
Isaiah 43 in the UBG
Isaiah 43 in the UGV
Isaiah 43 in the UGV2
Isaiah 43 in the UGV3
Isaiah 43 in the VBL
Isaiah 43 in the VDCC
Isaiah 43 in the YALU
Isaiah 43 in the YAPE
Isaiah 43 in the YBVTP
Isaiah 43 in the ZBP