Isaiah 44 (BOYCB)

1 “Ṣùgbọ́n gbọ́ nísinsin yìí, ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi,àti Israẹli, ẹni tí mo ti yàn. 2 Ohun tí OLÚWA wí nìyìíẹni tí ó dá ọ, ẹni tí ó ti mọ̀ ọ́nláti inú ìyá rẹ wá,àti ẹni tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ pẹ̀lú.Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu, ìránṣẹ́ mi,Jeṣuruni ẹni tí mo ti yàn. 3 Nítorí èmi yóò da omi sí ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹàti àwọn odò ní ilẹ̀ gbígbẹ,Èmi yóò tú Ẹ̀mí mi sí ara àwọn ọmọ rẹ,àti ìbùkún mi sórí àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ. 4 Wọn yóò dàgbàsókè gẹ́gẹ́ bí i koríko nínú pápá oko tútù,àti gẹ́gẹ́ bí igi Poplari létí odò tí ń sàn. 5 Ọ̀kan yóò wí pé, ‘Èmi jẹ́ ti OLÚWA’;òmíràn yóò pe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orúkọ Jakọbu;bẹ́ẹ̀ ni òmíràn yóò kọ ọ́ sí ọwọ́ rẹ̀, ‘Ti OLÚWA,’yóò sì máa jẹ́ orúkọ náà Israẹli. 6 “Ohun tí OLÚWA wí nìyìíọba Israẹli àti Olùdáǹdè, àní OLÚWA àwọn ọmọ-ogun.Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn,lẹ́yìn mi kò sí Ọlọ́run kan. 7 Ta ni ó dàbí ì mi? Jẹ́ kí o kéde rẹ̀.Jẹ́ kí ó wí kí ó sì gbé síwájú mikí ni ó ti ṣẹlẹ̀ láti ìgbà tí mo fi ìdí àwọn ènìyàn ìṣẹ̀ǹbáyé kalẹ̀,àti kí ni ohun tí ń sì ń bọ̀,bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí ń bọ̀ wá. 8 Má ṣe wárìrì, má ṣe bẹ̀rù.Ǹjẹ́ èmi kò ti kéde èyí tí mo sì ti sọàsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ tipẹ́tipẹ́?Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi. Ǹjẹ́ Ọlọ́run kanha ń bẹ lẹ́yìn mi?Bẹ́ẹ̀ kọ́, kò sí àpáta mìíràn; Èmi kò mọ ọ̀kankan.” 9 Gbogbo àwọn tí ń gbẹ́ ère jásí asán,àti àwọn ohun tí wọn ń kó pamọ́kò jámọ́ nǹkan kan.Àwọn tí yóò sọ̀rọ̀ fún wọn fọ́ lójú;wọ́n jẹ́ aláìmọ̀kan sí ìtìjú ara wọn. 10 Ta ni ó mọ òrìṣà kan tí ó sì ya ère,tí kò lè mú èrè kankan wá fún un? 11 Òun àti nǹkan rẹ̀ wọ̀nyí ni a ó dójútì;àwọn oníṣọ̀nà kò yàtọ̀, ènìyàn ni wọ́n.Jẹ́ kí gbogbo wọn gbárajọ kí wọ́n sìfi ìdúró wọn hàn;gbogbo wọn ni a ó mú bọ́ sínú ìpayà àti àbùkù. 12 Alágbẹ̀dẹ mú ohun èlò,ó fi ń ṣiṣẹ́ nínú èédú;ó fi òòlù ya ère kan,ó ṣe é pẹ̀lú agbára apá rẹ̀,ebi ń pa á, àárẹ̀ sì mú un;kò mu omi rárá, ìrẹ̀wẹ̀sì dé bá a. 13 Gbẹ́nàgbẹ́nà fi ìwọ̀n wọ́n ọ́nó sì fi lẹ́ẹ̀dì ṣe àmì sí ara rẹ̀,Ó tún fi ìfà fá a jádeó tún fi òsùwọ̀n ṣe àmì sí i.Ó gbẹ́ ẹ ní ìrí ènìyàngẹ́gẹ́ bí ènìyàn nínú ògo rẹ̀,kí ó lè máa gbé nínú ilé òrìṣà. 14 Ó gé igi kedari lulẹ̀,tàbí bóyá ó mú sípírẹ́ṣì tàbí igi óákù.Ó jẹ́ kí ó dàgbà láàrín àwọn igi inú igbó,ó sì le gbin igi páínì, èyí tí òjò mú kí ó dàgbà. 15 Ohun èlò ìdáná ni fún ènìyàn;díẹ̀ nínú rẹ̀ ni ó mú láti mú kíara rẹ̀ lọ́wọ́ọ́rọ́,ó dá iná ó sì fi ṣe àkàrà.Ṣùgbọ́n bákan náà ni ó ṣe òrìṣà tí ó sì ń sìn ín;ó yá ère, ó sì ń foríbalẹ̀ fún un. 16 Ìlàjì igi náà ni ó jó nínú iná;lórí i rẹ̀ ni ó ti ń tọ́jú oúnjẹ rẹ̀,ó dín ẹran rẹ̀ ó sì jẹ àjẹyó.Ó tún mú ara rẹ̀ gbóná ó sì sọ pé,“Á à! Ara mi gbóná, mo rí iná.” 17 Nínú èyí tí ó kù ni ó ti ṣe òrìṣà, ère rẹ̀;ó foríbalẹ̀ fún un, ó sì sìn ín.Ó gbàdúrà sí i, ó wí pé,“Gbà mí, ìwọ ni Ọlọ́run mi.” 18 Wọn kò mọ nǹkan kan, nǹkan kan kò yé wọn;a fi ìbòjú bo ojú wọn, wọn kò lè rí nǹkan kan;bẹ́ẹ̀ ni àyà wọn sébọ́, wọn kò lè mọ nǹkan kan. 19 Kò sí ẹni tí ó dúró láti ronú,kò sí ẹni tí ó ní ìmọ̀ tàbí òyeláti sọ wí pé,“Ìlàjì rẹ̀ ni mo fi dáná;mo tilẹ̀ ṣe àkàrà lórí èédú rẹ̀,mo dín ẹran, mo sì jẹ ẹ́.Ǹjẹ́ ó wá yẹ kí n ṣe ohun ìríra kannínú èyí tí ó ṣẹ́kù bí?Ǹjẹ́ èmi yóò ha foríbalẹ̀ fún ìtì igi?” 20 Ó ń jẹ eérú, ọkàn ẹlẹ́tàn ni ó ṣì í lọ́nà;òun kò lè gba ara rẹ̀ là, tàbí kí ó wí pé,“Ǹjẹ́ nǹkan tí ó wà lọ́wọ́ ọ̀tún mi yìí irọ́ kọ́?” 21 “Rántí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ìwọ Jakọbu,nítorí ìránṣẹ́ mi ni ìwọ, ìwọ Israẹli.Èmi ti dá ọ, ìránṣẹ́ mi ni ìwọ ṣe,ìwọ Israẹli, Èmi kì yóò gbàgbé rẹ. 22 Èmi ti gbá gbogbo ìkùnà rẹ dànù bí i kurukuru,àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ bí ìrì òwúrọ̀.Padà sọ́dọ̀ mi,nítorí mo ti rà ọ́ padà.” 23 Kọrin fáyọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, nítorí OLÚWA ló ti ṣe èyí;kígbe sókè, ìwọ ilẹ̀ ayé nísàlẹ̀.Bú sí orin, ẹ̀yin òkè ńlá,ẹ̀yin igbó àti gbogbo igi yín,nítorí OLÚWA ti ra Jakọbu padà,ó ti fi ògo rẹ̀ hàn ní Israẹli. 24 “Ohun tí OLÚWA wí nìyìíOlùràpadà rẹ tí ó mọ ọ́láti inú ìyá rẹ wá: “Èmi ni OLÚWAtí ó ti ṣe ohun gbogbotí òun nìkan ti na àwọn ọ̀runtí o sì tẹ́ ayé pẹrẹsẹ òun tìkára rẹ̀, 25 ta ni ó ba àmì àwọn wòlíì èké jẹ́tí ó sì sọ àwọn aláfọ̀ṣẹ di òmùgọ̀,tí ó dojú ìmọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n délẹ̀tí ó sì sọ wọ́n di òmùgọ̀, 26 ẹni tí ó gbé ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jádetí ó sì mú àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ wá sí ìmúṣẹ, “ẹni tí ó wí nípa ti Jerusalẹmu pé, ‘A ó máa gbé inú rẹ̀,’àti ní ti àwọn ìlú Juda, ‘A ó tún kọ́,’àti àwọn ahoro rẹ̀, ‘Èmi yóò mú un bọ̀ sípò,’ 27 ta ni ó sọ fún omi jíjìn pé, ‘Ìwọ gbẹ,èmi yóò sì mú omi odò rẹ gbẹ,’ 28 ta ni ó sọ nípa Kirusi pé, ‘Òun ni Olùṣọ́-àgùntàn miàti pé òun yóò ṣe ohun gbogbo tí mo fẹ́;òun yóò sọ nípa Jerusalẹmu pé, “Jẹ́ kí a tún kọ́,”àti nípa tẹmpili, “Jẹ́ kí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé ilẹ̀.” ’ ”

In Other Versions

Isaiah 44 in the ANGEFD

Isaiah 44 in the ANTPNG2D

Isaiah 44 in the AS21

Isaiah 44 in the BAGH

Isaiah 44 in the BBPNG

Isaiah 44 in the BBT1E

Isaiah 44 in the BDS

Isaiah 44 in the BEV

Isaiah 44 in the BHAD

Isaiah 44 in the BIB

Isaiah 44 in the BLPT

Isaiah 44 in the BNT

Isaiah 44 in the BNTABOOT

Isaiah 44 in the BNTLV

Isaiah 44 in the BOATCB

Isaiah 44 in the BOATCB2

Isaiah 44 in the BOBCV

Isaiah 44 in the BOCNT

Isaiah 44 in the BOECS

Isaiah 44 in the BOGWICC

Isaiah 44 in the BOHCB

Isaiah 44 in the BOHCV

Isaiah 44 in the BOHLNT

Isaiah 44 in the BOHNTLTAL

Isaiah 44 in the BOICB

Isaiah 44 in the BOILNTAP

Isaiah 44 in the BOITCV

Isaiah 44 in the BOKCV

Isaiah 44 in the BOKCV2

Isaiah 44 in the BOKHWOG

Isaiah 44 in the BOKSSV

Isaiah 44 in the BOLCB

Isaiah 44 in the BOLCB2

Isaiah 44 in the BOMCV

Isaiah 44 in the BONAV

Isaiah 44 in the BONCB

Isaiah 44 in the BONLT

Isaiah 44 in the BONUT2

Isaiah 44 in the BOPLNT

Isaiah 44 in the BOSCB

Isaiah 44 in the BOSNC

Isaiah 44 in the BOTLNT

Isaiah 44 in the BOVCB

Isaiah 44 in the BPBB

Isaiah 44 in the BPH

Isaiah 44 in the BSB

Isaiah 44 in the CCB

Isaiah 44 in the CUV

Isaiah 44 in the CUVS

Isaiah 44 in the DBT

Isaiah 44 in the DGDNT

Isaiah 44 in the DHNT

Isaiah 44 in the DNT

Isaiah 44 in the ELBE

Isaiah 44 in the EMTV

Isaiah 44 in the ESV

Isaiah 44 in the FBV

Isaiah 44 in the FEB

Isaiah 44 in the GGMNT

Isaiah 44 in the GNT

Isaiah 44 in the HARY

Isaiah 44 in the HNT

Isaiah 44 in the IRVA

Isaiah 44 in the IRVB

Isaiah 44 in the IRVG

Isaiah 44 in the IRVH

Isaiah 44 in the IRVK

Isaiah 44 in the IRVM

Isaiah 44 in the IRVM2

Isaiah 44 in the IRVO

Isaiah 44 in the IRVP

Isaiah 44 in the IRVT

Isaiah 44 in the IRVT2

Isaiah 44 in the IRVU

Isaiah 44 in the ISVN

Isaiah 44 in the JSNT

Isaiah 44 in the KAPI

Isaiah 44 in the KBT1ETNIK

Isaiah 44 in the KBV

Isaiah 44 in the KJV

Isaiah 44 in the KNFD

Isaiah 44 in the LBA

Isaiah 44 in the LBLA

Isaiah 44 in the LNT

Isaiah 44 in the LSV

Isaiah 44 in the MAAL

Isaiah 44 in the MBV

Isaiah 44 in the MBV2

Isaiah 44 in the MHNT

Isaiah 44 in the MKNFD

Isaiah 44 in the MNG

Isaiah 44 in the MNT

Isaiah 44 in the MNT2

Isaiah 44 in the MRS1T

Isaiah 44 in the NAA

Isaiah 44 in the NASB

Isaiah 44 in the NBLA

Isaiah 44 in the NBS

Isaiah 44 in the NBVTP

Isaiah 44 in the NET2

Isaiah 44 in the NIV11

Isaiah 44 in the NNT

Isaiah 44 in the NNT2

Isaiah 44 in the NNT3

Isaiah 44 in the PDDPT

Isaiah 44 in the PFNT

Isaiah 44 in the RMNT

Isaiah 44 in the SBIAS

Isaiah 44 in the SBIBS

Isaiah 44 in the SBIBS2

Isaiah 44 in the SBICS

Isaiah 44 in the SBIDS

Isaiah 44 in the SBIGS

Isaiah 44 in the SBIHS

Isaiah 44 in the SBIIS

Isaiah 44 in the SBIIS2

Isaiah 44 in the SBIIS3

Isaiah 44 in the SBIKS

Isaiah 44 in the SBIKS2

Isaiah 44 in the SBIMS

Isaiah 44 in the SBIOS

Isaiah 44 in the SBIPS

Isaiah 44 in the SBISS

Isaiah 44 in the SBITS

Isaiah 44 in the SBITS2

Isaiah 44 in the SBITS3

Isaiah 44 in the SBITS4

Isaiah 44 in the SBIUS

Isaiah 44 in the SBIVS

Isaiah 44 in the SBT

Isaiah 44 in the SBT1E

Isaiah 44 in the SCHL

Isaiah 44 in the SNT

Isaiah 44 in the SUSU

Isaiah 44 in the SUSU2

Isaiah 44 in the SYNO

Isaiah 44 in the TBIAOTANT

Isaiah 44 in the TBT1E

Isaiah 44 in the TBT1E2

Isaiah 44 in the TFTIP

Isaiah 44 in the TFTU

Isaiah 44 in the TGNTATF3T

Isaiah 44 in the THAI

Isaiah 44 in the TNFD

Isaiah 44 in the TNT

Isaiah 44 in the TNTIK

Isaiah 44 in the TNTIL

Isaiah 44 in the TNTIN

Isaiah 44 in the TNTIP

Isaiah 44 in the TNTIZ

Isaiah 44 in the TOMA

Isaiah 44 in the TTENT

Isaiah 44 in the UBG

Isaiah 44 in the UGV

Isaiah 44 in the UGV2

Isaiah 44 in the UGV3

Isaiah 44 in the VBL

Isaiah 44 in the VDCC

Isaiah 44 in the YALU

Isaiah 44 in the YAPE

Isaiah 44 in the YBVTP

Isaiah 44 in the ZBP