Isaiah 49 (BOYCB)
1 Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin erékùṣù:gbọ́ èyí, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè jíjìnnà réré:kí a tó bí mi OLÚWA ti pè mí;láti ìgbà bíbí mi ni ó ti dá orúkọ mi. 2 Ó ṣe ẹnu mi bí idà tí a pọ́n,ní abẹ́ òjìji ọwọ́ rẹ̀ ni ó ti pa mí mọ́:ó ṣe mí ní ọfà tí a ti dán,ó sì fi mí pamọ́ sínú àpò rẹ̀. 3 Ó sọ fún mi pé, “Ìránṣẹ́ mi ni ìwọ í ṣe,Israẹli nínú ẹni tí n ó ti fi ògo mi hàn.” 4 Ṣùgbọ́n èmi sọ pé, “Mo ti ṣe wàhálà lórí asán;mo ti lo gbogbo ipá mi lórí asán àti ìmúlẹ̀mófo.Síbẹ̀síbẹ̀ ohun tí ó tọ́ sí mi ṣì wà lọ́wọ́ OLÚWA,èrè mi sì ń bẹ pẹ̀lú Ọlọ́run mi.” 5 Nísinsin yìí OLÚWA wí péẹni tí ó mọ̀ mí láti inú wá láti jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀láti mú Jakọbu padà tọ̀ mí wáàti láti kó Israẹli jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀,nítorí pé a bọ̀wọ̀ fún mi ní ojú OLÚWAỌlọ́run mi sì ti jẹ́ agbára mi, 6 Òun wí pé:“Ó jẹ́ ohun kékeré fún ọ láti jẹ́ ìránṣẹ́ miláti mú ẹ̀yà Jakọbu padà bọ̀ sípòàti láti mú àwọn ti Israẹli tí mo ti pamọ́.Èmi yóò sì fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn kèfèrí,kí ìwọ kí ó lè mú ìgbàlà mi wásí òpin ilẹ̀ ayé.” 7 Ohun tí OLÚWA wí nìyìí,Olùdáǹdè àti Ẹni Mímọ́ Israẹli—sí ẹni náà tí a gàn tí a sì kórìíralọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè,sí ìránṣẹ́ àwọn aláṣẹ:“Àwọn ọba yóò rí ọ wọn yóò sì dìde sókè,àwọn ọmọ ọba yóò rí i wọn yóò sì wólẹ̀,nítorí OLÚWA ẹni tí í ṣe olóòtítọ́,Ẹni Mímọ́ Israẹli tí ó ti yàn ọ́.” 8 Ohun tí OLÚWA wí nìyìí:“Ní àkókò ojúrere mi, èmi yóò dá ọ lóhùn,àti ní ọjọ́ ìgbàlà, èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́;Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn,láti mú ilẹ̀ padà bọ̀ sípòàti láti ṣe àtúnpín ogún rẹ̀ tí ó ti dahoro, 9 láti sọ fún àwọn ìgbèkùn pé, ‘Ẹ jáde wá,’àti fún àwọn tí ó wà nínú òkùnkùn pé, ‘Ẹ gba òmìnira!’ “Wọn yóò máa jẹ ní ẹ̀bá ọ̀nààti koríko tútù lórí òkè aláìléwéko. 10 Ebi kì yóò pa wọ́n bẹ́ẹ̀ ni òǹgbẹ kì yóò gbẹ wọ́n,tàbí kí ooru inú aṣálẹ̀ tàbí oòrùn kí ó pa wọ́n.Ẹni tí ó ṣàánú fún wọn ni yóò máa tọ́ wọn,tí yóò sì mú wọn lọ sí ibi orísun omi. 11 Èmi yóò sọ gbogbo àwọn òkè ńlá mi di ojú ọ̀nààti gbogbo òpópónà mi ni a ó gbé sókè. 12 Kíyèsi i, wọn yóò wá láti ọ̀nà jíjìnàwọn díẹ̀ láti àríwá àti àwọn díẹ̀ láti ìwọ̀-oòrùn,àwọn díẹ̀ láti ẹkùn Siene.” 13 Ẹ hó fún ayọ̀, ẹyin ọ̀run;yọ̀, ìwọ ilẹ̀ ayé;bú sórin, ẹ̀yin òkè ńlá!Nítorí OLÚWA tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínúyóò sì ṣàánú fún àwọn ẹnití a ń pọ́n lójú. 14 Ṣùgbọ́n Sioni sọ pé, “OLÚWA ti kọ̀ mí sílẹ̀,Olúwa ti gbàgbé è mi.” 15 “Ǹjẹ́ abiyamọ ha le gbàgbé ọmọ ọmú rẹ̀kí ó má sì ṣàánú fún ọmọ rẹ̀ tí ó ti bí?Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun le gbàgbé,Èmi kì yóò gbàgbé rẹ! 16 Kíyèsi i, mo ti kọ ọ́ sí àtẹ́lẹwọ́ miògiri rẹ wà níwájú mi nígbà gbogbo. 17 Àwọn ọmọ rẹ ti kánjú padà,àti àwọn tí ó sọ ọ́ dahoro ti padà lẹ́yìn rẹ. 18 Gbójú rẹ sókè kí o sì wò yíká;gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ kórajọwọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ.Níwọ́n ìgbà tí mo bá wà láààyè,” ni OLÚWA wí,“Ìwọ yóò wọ gbogbo wọ́n gẹ́gẹ́ bí ohun ọ̀ṣọ́;ìwọ yóò wọ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bí ìyàwó. 19 “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a tí run ọ́, a sì sọ ọ́ di ahorotí gbogbo ilẹ̀ rẹ sì di ìparun,ní ìsinsin yìí, ìwọ yóò kéré jù fún àwọn ènìyàn rẹ,bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ó jẹ ọ́ run ni yóòwà láti ọ̀nà jíjìn réré. 20 Àwọn ọmọ tí a bí ní àkókò ọ̀fọ̀ rẹyóò sọ ní etígbọ̀ọ́ rẹ,‘Ibi yìí ti kéré jù fún wa;ẹ fún wa láyè sí i tí a ó máa gbé.’ 21 Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ ní ọkàn rẹ pé,‘Ta ló bí àwọn yìí fún mi?Mo ti ṣọ̀fọ̀ mo sì yàgàn;a sọ mi di àtìpó a sì kọ̀ mí sílẹ̀.Ta ló wo àwọn yìí dàgbà?A fi èmi nìkan sílẹ̀,ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí níbo ni wọ́n ti wá?’ ” 22 Ohun tí OLÚWA Olódùmarè wí nìyìí,“Kíyèsi i, Èmi yóò ké sí àwọn aláìkọlà,Èmi yóò gbé àsíá mi sókè sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn;wọn yóò kó àwọn ọmọkùnrin yín wá ní apá wọnwọn yóò sì gbé àwọn ọ̀dọ́mọbìnrinní èjìká wọn. 23 Àwọn ọba ni yóò jẹ́ alágbàtọ́ baba fún ọ,àwọn ayaba wọn ni yóò sì jẹ́ ìyá-alágbàtọ́.Wọn yóò foríbalẹ̀ ní iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ojú wọn dídàbolẹ̀;wọn yóò máa lá erùpẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ.Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé, Èmi ni OLÚWA;gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìrètí nínú mini a kì yóò jákulẹ̀.” 24 Ǹjẹ́ a le gba ìkógun lọ́wọ́ jagunjagun,tàbí kí á gba ìgbèkùn lọ́wọ́ akíkanjú? 25 Ṣùgbọ́n ohun tí OLÚWA wí nìyìí:“Bẹ́ẹ̀ ni, a ó gba àwọn ìgbèkùn lọ́wọ́ àwọn jagunjagun,àti ìkógun lọ́wọ́ àwọn akíkanjú;ẹni tí ó bá ọ jà ni èmi ó bá jà,àti àwọn ọmọ rẹ ni èmi ó gbàlà. 26 Èmi yóò mú kí àwọn aninilára rẹ̀ jẹ ẹran-ara wọn;wọn yóò mu ẹ̀jẹ̀ ara wọn yó bí ẹni mu wáìnì.Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn yóò mọ̀pé, Èmi, OLÚWA, èmi ni Olùgbàlà rẹ,Olùdáǹdè rẹ, Alágbára kan ṣoṣo ti Jakọbu.”