Isaiah 7 (BOYCB)

1 Nígbà tí Ahasi ọmọ Jotamu ọmọ Ussiah jẹ́ ọba Juda, ọba Resini ti Aramu àti Peka ọmọ Remaliah ọba Israẹli gòkè wá láti bá Jerusalẹmu jà, ṣùgbọ́n wọn kò sì le è borí i rẹ̀. 2 Báyìí, a sọ fún ilé Dafidi pé, “Aramu mà ti lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ Efraimu”; fún ìdí èyí, ọkàn Ahasi àti àwọn ènìyàn rẹ̀ wárìrì gẹ́gẹ́ bí igi oko ṣe ń wárìrì níwájú afẹ́fẹ́. 3 Lẹ́yìn èyí, OLÚWA sọ fún Isaiah pé, “Jáde, ìwọ àti ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ Ṣeari-Jaṣubu láti pàdé Ahasi ní ìpẹ̀kun ìṣàn omi ti adágún òkè, ní òpópó ọ̀nà tí ó lọ sí pápá Alágbàfọ̀. 4 Sọ fún un, ‘Ṣọ́ra à rẹ, fi ọkàn balẹ̀, kí o má ṣe bẹ̀rù. Má ṣe ba ọkàn jẹ́ nítorí kùkùté igi ìdáná méjèèjì yìí, nítorí ìbínú gbígbóná Resini àti Aramu àti ti ọmọ Remaliah. 5 Aramu, Efraimu àti Remaliah ti dìtẹ̀ ìparun rẹ, wọ́n wí pé, 6 “Jẹ́ kí a kọlu Juda; jẹ́ kí a fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, kí a sì pín in láàrín ara wa, kí a sì fi ọmọ Tabeli jẹ ọba lórí i rẹ̀.” 7 Síbẹ̀ èyí ni ohun tí OLÚWA Olódùmarè wí:“ ‘Èyí kò ní wáyéèyí kò le ṣẹlẹ̀, 8 nítorí Damasku ni orí Aramu,orí Damasku sì ni Resini.Láàrín ọdún márùnlélọ́gọ́taEfraimu yóò ti fọ́ tí kì yóò le jẹ́ ènìyàn mọ́. 9 Orí Efraimu sì ni Samaria,orí Samaria sì ni ọmọ Remaliah.Bí ẹ̀yin kí yóò bá gbàgbọ́,lóòtítọ́, a kì yóò fi ìdí yín múlẹ̀.’ ” 10 Bákan náà OLÚWA tún bá Ahasi sọ̀rọ̀, 11 “Béèrè fún àmì lọ́wọ́ OLÚWA Ọlọ́run rẹ, bóyá ní ọ̀gbun tí ó jì jùlọ tàbí àwọn òkè tí ó ga jùlọ.” 12 Ṣùgbọ́n Ahasi sọ pé, “Èmi kì yóò béèrè; Èmi kò ní dán OLÚWA wò.” 13 Lẹ́yìn náà Isaiah sọ pé, “Gbọ́ ní ìsinsin yìí, ìwọ ilé Dafidi, kò ha tọ́ láti tán ènìyàn ní sùúrù, ìwọ yóò ha tan Ọlọ́run ní sùúrù bí? 14 Nítorí náà, Olúwa fúnra ara rẹ̀ ni yóò fún ọ ní àmì kan. Wúńdíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Emmanueli. 15 Òun yóò jẹ wàrà àti oyin nígbà tí ó bá ní ìmọ̀ tó láti kọ ẹ̀bi àti láti yan rere. 16 Ṣùgbọ́n kí ọ̀dọ́mọkùnrin náà tó mọ bí a ti ń kọ ẹ̀bi àti láti yan rere, ilẹ̀ àwọn ọba méjèèjì tí ń bà ọ́ lẹ́rù wọ̀nyí yóò ti di ahoro. 17 OLÚWA yóò mú àsìkò mìíràn wá fún ọ àti àwọn ènìyàn rẹ àti lórí ilé baba rẹ irú èyí tí kò sí láti ìgbà tí Efraimu ti yà kúrò ní Juda, yóò sì mú ọba Asiria wá.” 18 Ní ọjọ́ náà ni OLÚWA yóò súfèé pe àwọn eṣinṣin láti àwọn odò tó jìnnà ní Ejibiti wá, àti fún àwọn oyin láti ilẹ̀ Asiria. 19 Gbogbo wọn yóò sì wá dó sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè àti pàlàpálá òkúta, lára koríko ẹ̀gún àti gbogbo ibi ihò omi. 20 Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò lo abẹ fífẹ́lẹ́ tí a yá láti ìkọjá odò Eufurate, ọba Asiria, láti fá irun orí àti ti àwọn ẹsẹ̀ ẹ yín, àti láti mú irùngbọ̀n yín kúrò pẹ̀lú. 21 Ní ọjọ́ náà, ọkùnrin kan yóò máa sin ọ̀dọ́ abo màlúù kan àti ewúrẹ́ méjì. 22 Àti nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàrà tí wọn yóò máa fún un, yóò ní wàràǹkàṣì láti jẹ. Gbogbo àwọn tí ó bá kù ní ilẹ̀ náà yóò jẹ wàràǹkàṣì àti oyin. 23 Ní ọjọ́ náà, ni gbogbo ibi tí àjàrà tí ó tó ẹgbẹ̀rún (1,000) ṣékélì fàdákà, ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n nìkan ni yóò wà níbẹ̀. 24 Àwọn ènìyàn yóò máa lọ síbẹ̀ pẹ̀lú ọrun àti ọfà nítorí pé ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n ni yóò bo gbogbo ilẹ̀ náà. 25 Àti ní orí àwọn òkè kéékèèké tí a ti ń fi ọkọ́ ro nígbà kan rí, ẹ kò ní lọ síbẹ̀ mọ́ nítorí ìbẹ̀rù ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n, wọn yóò di ibi tí a ń da màlúù lọ, àti ibi ìtẹ̀mọ́lẹ̀ fún àwọn àgùntàn kéékèèké.

In Other Versions

Isaiah 7 in the ANGEFD

Isaiah 7 in the ANTPNG2D

Isaiah 7 in the AS21

Isaiah 7 in the BAGH

Isaiah 7 in the BBPNG

Isaiah 7 in the BBT1E

Isaiah 7 in the BDS

Isaiah 7 in the BEV

Isaiah 7 in the BHAD

Isaiah 7 in the BIB

Isaiah 7 in the BLPT

Isaiah 7 in the BNT

Isaiah 7 in the BNTABOOT

Isaiah 7 in the BNTLV

Isaiah 7 in the BOATCB

Isaiah 7 in the BOATCB2

Isaiah 7 in the BOBCV

Isaiah 7 in the BOCNT

Isaiah 7 in the BOECS

Isaiah 7 in the BOGWICC

Isaiah 7 in the BOHCB

Isaiah 7 in the BOHCV

Isaiah 7 in the BOHLNT

Isaiah 7 in the BOHNTLTAL

Isaiah 7 in the BOICB

Isaiah 7 in the BOILNTAP

Isaiah 7 in the BOITCV

Isaiah 7 in the BOKCV

Isaiah 7 in the BOKCV2

Isaiah 7 in the BOKHWOG

Isaiah 7 in the BOKSSV

Isaiah 7 in the BOLCB

Isaiah 7 in the BOLCB2

Isaiah 7 in the BOMCV

Isaiah 7 in the BONAV

Isaiah 7 in the BONCB

Isaiah 7 in the BONLT

Isaiah 7 in the BONUT2

Isaiah 7 in the BOPLNT

Isaiah 7 in the BOSCB

Isaiah 7 in the BOSNC

Isaiah 7 in the BOTLNT

Isaiah 7 in the BOVCB

Isaiah 7 in the BPBB

Isaiah 7 in the BPH

Isaiah 7 in the BSB

Isaiah 7 in the CCB

Isaiah 7 in the CUV

Isaiah 7 in the CUVS

Isaiah 7 in the DBT

Isaiah 7 in the DGDNT

Isaiah 7 in the DHNT

Isaiah 7 in the DNT

Isaiah 7 in the ELBE

Isaiah 7 in the EMTV

Isaiah 7 in the ESV

Isaiah 7 in the FBV

Isaiah 7 in the FEB

Isaiah 7 in the GGMNT

Isaiah 7 in the GNT

Isaiah 7 in the HARY

Isaiah 7 in the HNT

Isaiah 7 in the IRVA

Isaiah 7 in the IRVB

Isaiah 7 in the IRVG

Isaiah 7 in the IRVH

Isaiah 7 in the IRVK

Isaiah 7 in the IRVM

Isaiah 7 in the IRVM2

Isaiah 7 in the IRVO

Isaiah 7 in the IRVP

Isaiah 7 in the IRVT

Isaiah 7 in the IRVT2

Isaiah 7 in the IRVU

Isaiah 7 in the ISVN

Isaiah 7 in the JSNT

Isaiah 7 in the KAPI

Isaiah 7 in the KBT1ETNIK

Isaiah 7 in the KBV

Isaiah 7 in the KJV

Isaiah 7 in the KNFD

Isaiah 7 in the LBA

Isaiah 7 in the LBLA

Isaiah 7 in the LNT

Isaiah 7 in the LSV

Isaiah 7 in the MAAL

Isaiah 7 in the MBV

Isaiah 7 in the MBV2

Isaiah 7 in the MHNT

Isaiah 7 in the MKNFD

Isaiah 7 in the MNG

Isaiah 7 in the MNT

Isaiah 7 in the MNT2

Isaiah 7 in the MRS1T

Isaiah 7 in the NAA

Isaiah 7 in the NASB

Isaiah 7 in the NBLA

Isaiah 7 in the NBS

Isaiah 7 in the NBVTP

Isaiah 7 in the NET2

Isaiah 7 in the NIV11

Isaiah 7 in the NNT

Isaiah 7 in the NNT2

Isaiah 7 in the NNT3

Isaiah 7 in the PDDPT

Isaiah 7 in the PFNT

Isaiah 7 in the RMNT

Isaiah 7 in the SBIAS

Isaiah 7 in the SBIBS

Isaiah 7 in the SBIBS2

Isaiah 7 in the SBICS

Isaiah 7 in the SBIDS

Isaiah 7 in the SBIGS

Isaiah 7 in the SBIHS

Isaiah 7 in the SBIIS

Isaiah 7 in the SBIIS2

Isaiah 7 in the SBIIS3

Isaiah 7 in the SBIKS

Isaiah 7 in the SBIKS2

Isaiah 7 in the SBIMS

Isaiah 7 in the SBIOS

Isaiah 7 in the SBIPS

Isaiah 7 in the SBISS

Isaiah 7 in the SBITS

Isaiah 7 in the SBITS2

Isaiah 7 in the SBITS3

Isaiah 7 in the SBITS4

Isaiah 7 in the SBIUS

Isaiah 7 in the SBIVS

Isaiah 7 in the SBT

Isaiah 7 in the SBT1E

Isaiah 7 in the SCHL

Isaiah 7 in the SNT

Isaiah 7 in the SUSU

Isaiah 7 in the SUSU2

Isaiah 7 in the SYNO

Isaiah 7 in the TBIAOTANT

Isaiah 7 in the TBT1E

Isaiah 7 in the TBT1E2

Isaiah 7 in the TFTIP

Isaiah 7 in the TFTU

Isaiah 7 in the TGNTATF3T

Isaiah 7 in the THAI

Isaiah 7 in the TNFD

Isaiah 7 in the TNT

Isaiah 7 in the TNTIK

Isaiah 7 in the TNTIL

Isaiah 7 in the TNTIN

Isaiah 7 in the TNTIP

Isaiah 7 in the TNTIZ

Isaiah 7 in the TOMA

Isaiah 7 in the TTENT

Isaiah 7 in the UBG

Isaiah 7 in the UGV

Isaiah 7 in the UGV2

Isaiah 7 in the UGV3

Isaiah 7 in the VBL

Isaiah 7 in the VDCC

Isaiah 7 in the YALU

Isaiah 7 in the YAPE

Isaiah 7 in the YBVTP

Isaiah 7 in the ZBP