Isaiah 9 (BOYCB)
1 Síbẹ̀síbẹ̀, kò ní sí ìpòrúru kankan mọ́ fún àwọn tí ó wà nínú ìbànújẹ́. Nígbà kan rí ó rẹ ilẹ̀ Sebuluni sílẹ̀ àti ilẹ̀ Naftali pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ iwájú, yóò bu ọ̀wọ̀ fún Galili ti àwọn aláìkọlà, ní ọ̀nà Òkun, ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ Jordani. 2 Àwọn ènìyàn tí ń rìn nínú òkùnkùnti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá;lórí àwọn tí ń gbé nínú ilẹ̀ òjìji ikú,ní ara wọn ni ìmọ́lẹ̀ mọ́ sí. 3 Ìwọ ti sọ orílẹ̀-èdè di ńlá;wọ́n sì yọ̀ níwájú rẹgẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ti í yọ ayọ̀ ìkórè,gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ti í yọ̀nígbà tí à ń pín ìkógun. 4 Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí a ṣẹ́gun Midiani,ìwọ ti fọ́ ọ túútúúàjàgà ti ń pa wọ́n lẹ́rù,ọ̀pá tí ó dábùú èjìká wọn,ọ̀gọ aninilára wọn. 5 Gbogbo bàtà jagunjagun tí a ti lò lójú ogunàti gbogbo ẹ̀wù tí a yí nínú ẹ̀jẹ̀,ni yóò wà fún ìjóná,àti ohun èlò iná dídá. 6 Nítorí a bí ọmọ kan fún wa,a fi ọmọkùnrin kan fún wa,ìjọba yóò sì wà ní èjìká rẹ̀.A ó sì máa pè é níÌyanu Olùdámọ̀ràn, Ọlọ́run Alágbára,Baba ayérayé, Ọmọ ọba aládé Àlàáfíà. 7 Ní ti gbígbòòrò Ìjọba rẹ̀ àti àlàáfíà rẹ̀ ni kì yóò ní ìpẹ̀kun.Yóò jẹ ọba lórí ìtẹ́ Dafidiàti lórí ẹ̀kún un rẹ̀ gbogbo,nípa ìfìdímúlẹ̀ àti ìgbéró rẹ̀,pẹ̀lú òtítọ́ àti òdodoláti ìgbà náà lọ àti títí láéláé.Ìtara OLÚWA àwọn ọmọ-ogunni yóò mú èyí ṣẹ. 8 Olúwa ti dojú iṣẹ́ kan kọ Jakọbu;yóò sì wá sórí Israẹli. 9 Gbogbo ènìyàn ni yóò sì mọ̀ ọ́n—Efraimu àti gbogbo olùgbé Samaria—tí ó sọ pẹ̀lú ìgbéragaàti gààrù àyà pé. 10 Àwọn bíríkì ti wó lulẹ̀ṣùgbọ́n a ó tún un kọ́ pẹ̀lú òkúta dídán,a ti gé àwọn igi sikamore lulẹ̀ṣùgbọ́n igi kedari ní a ó fi dípò wọn. 11 Ṣùgbọ́n OLÚWA fún àwọn ọ̀tá Resini ní agbára láti dojúkọ wọ́nó sì ti rú àwọn ọ̀tá wọn sókè. 12 Àwọn ará Aramu láti ìlà-oòrùn àti Filistini láti ìwọ̀-oòrùn.Wọ́n sì fi gbogbo ẹnu jẹ Israẹli run. Ní gbogbo èyí ìbínú rẹ̀ kò yí kúròṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ nà jáde síbẹ̀. 13 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kò tí ì yípadàsí ẹni náà tí ó lù wọ́nbẹ́ẹ̀ ni wọ́n kò wá OLÚWA àwọn ọmọ-ogun. 14 Nítorí náà ni OLÚWA yóò ṣe ké àti orí àti ìrùkúrò ní Israẹli,àti ọ̀wá ọ̀pẹ àti koríko odò ní ọjọ́ kan ṣoṣo, 15 àwọn àgbàgbà, àti àwọn gbajúmọ̀ ní orí,àwọn wòlíì tí ń kọ́ni ní irọ́ ni ìrù. 16 Àwọn tí ó ń tọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣì wọ́n lọ́nà,àwọn tí a sì tọ́ ni a ń sin sí ìparun. 17 Nítorí náà, Olúwa kì yóò dunnú sí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrintàbí kí ó káàánú àwọn aláìní baba àti opó,nítorí pé gbogbo wọn jẹ́ ìkà àti aláìmọ Ọlọ́run,ibi ni ó ti ẹnu wọn jáde. Síbẹ̀, fún gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò yí kúròọwọ́ rẹ̀ sì wà ní gbígbéró. 18 Nítòótọ́ ìwà búburú ń jóni bí iná,yóò jó ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún run,yóò sì rán nínú pàǹtí igbó,tó bẹ́ẹ̀ tí yóò fi gòkè lọ bí ọ̀wọ́n èéfín ti í gòkè. 19 Nípasẹ̀ ìbínú OLÚWA àwọn ọmọ-ogunilẹ̀ náà yóò di gbígbẹàwọn ènìyàn yóò sì di ohun ìdáná,ẹnìkan kì yóò sì dá arákùnrin rẹ̀ sí. 20 Ní apá ọ̀tún wọn yóò jẹrun,síbẹ̀ ebi yóò sì máa pa wọ́n,ní apá òsì, wọn yóò jẹ,ṣùgbọ́n, kò ní tẹ́ wọn lọ́rùn.Ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò sì máa jẹ ẹran-ara apá rẹ̀. 21 Manase yóò máa jẹ Efraimu, nígbà tí Efraimu yóò jẹ Manasewọn yóò parapọ̀ dojúkọ Juda. Síbẹ̀síbẹ̀, ìbínú un rẹ̀ kò yí kúròỌwọ́ọ rẹ̀ sì wà ní gbígbéró.
In Other Versions
Isaiah 9 in the ANGEFD
Isaiah 9 in the ANTPNG2D
Isaiah 9 in the AS21
Isaiah 9 in the BAGH
Isaiah 9 in the BBPNG
Isaiah 9 in the BBT1E
Isaiah 9 in the BDS
Isaiah 9 in the BEV
Isaiah 9 in the BHAD
Isaiah 9 in the BIB
Isaiah 9 in the BLPT
Isaiah 9 in the BNT
Isaiah 9 in the BNTABOOT
Isaiah 9 in the BNTLV
Isaiah 9 in the BOATCB
Isaiah 9 in the BOATCB2
Isaiah 9 in the BOBCV
Isaiah 9 in the BOCNT
Isaiah 9 in the BOECS
Isaiah 9 in the BOGWICC
Isaiah 9 in the BOHCB
Isaiah 9 in the BOHCV
Isaiah 9 in the BOHLNT
Isaiah 9 in the BOHNTLTAL
Isaiah 9 in the BOICB
Isaiah 9 in the BOILNTAP
Isaiah 9 in the BOITCV
Isaiah 9 in the BOKCV
Isaiah 9 in the BOKCV2
Isaiah 9 in the BOKHWOG
Isaiah 9 in the BOKSSV
Isaiah 9 in the BOLCB
Isaiah 9 in the BOLCB2
Isaiah 9 in the BOMCV
Isaiah 9 in the BONAV
Isaiah 9 in the BONCB
Isaiah 9 in the BONLT
Isaiah 9 in the BONUT2
Isaiah 9 in the BOPLNT
Isaiah 9 in the BOSCB
Isaiah 9 in the BOSNC
Isaiah 9 in the BOTLNT
Isaiah 9 in the BOVCB
Isaiah 9 in the BPBB
Isaiah 9 in the BPH
Isaiah 9 in the BSB
Isaiah 9 in the CCB
Isaiah 9 in the CUV
Isaiah 9 in the CUVS
Isaiah 9 in the DBT
Isaiah 9 in the DGDNT
Isaiah 9 in the DHNT
Isaiah 9 in the DNT
Isaiah 9 in the ELBE
Isaiah 9 in the EMTV
Isaiah 9 in the ESV
Isaiah 9 in the FBV
Isaiah 9 in the FEB
Isaiah 9 in the GGMNT
Isaiah 9 in the GNT
Isaiah 9 in the HARY
Isaiah 9 in the HNT
Isaiah 9 in the IRVA
Isaiah 9 in the IRVB
Isaiah 9 in the IRVG
Isaiah 9 in the IRVH
Isaiah 9 in the IRVK
Isaiah 9 in the IRVM
Isaiah 9 in the IRVM2
Isaiah 9 in the IRVO
Isaiah 9 in the IRVP
Isaiah 9 in the IRVT
Isaiah 9 in the IRVT2
Isaiah 9 in the IRVU
Isaiah 9 in the ISVN
Isaiah 9 in the JSNT
Isaiah 9 in the KAPI
Isaiah 9 in the KBT1ETNIK
Isaiah 9 in the KBV
Isaiah 9 in the KJV
Isaiah 9 in the KNFD
Isaiah 9 in the LBA
Isaiah 9 in the LBLA
Isaiah 9 in the LNT
Isaiah 9 in the LSV
Isaiah 9 in the MAAL
Isaiah 9 in the MBV
Isaiah 9 in the MBV2
Isaiah 9 in the MHNT
Isaiah 9 in the MKNFD
Isaiah 9 in the MNG
Isaiah 9 in the MNT
Isaiah 9 in the MNT2
Isaiah 9 in the MRS1T
Isaiah 9 in the NAA
Isaiah 9 in the NASB
Isaiah 9 in the NBLA
Isaiah 9 in the NBS
Isaiah 9 in the NBVTP
Isaiah 9 in the NET2
Isaiah 9 in the NIV11
Isaiah 9 in the NNT
Isaiah 9 in the NNT2
Isaiah 9 in the NNT3
Isaiah 9 in the PDDPT
Isaiah 9 in the PFNT
Isaiah 9 in the RMNT
Isaiah 9 in the SBIAS
Isaiah 9 in the SBIBS
Isaiah 9 in the SBIBS2
Isaiah 9 in the SBICS
Isaiah 9 in the SBIDS
Isaiah 9 in the SBIGS
Isaiah 9 in the SBIHS
Isaiah 9 in the SBIIS
Isaiah 9 in the SBIIS2
Isaiah 9 in the SBIIS3
Isaiah 9 in the SBIKS
Isaiah 9 in the SBIKS2
Isaiah 9 in the SBIMS
Isaiah 9 in the SBIOS
Isaiah 9 in the SBIPS
Isaiah 9 in the SBISS
Isaiah 9 in the SBITS
Isaiah 9 in the SBITS2
Isaiah 9 in the SBITS3
Isaiah 9 in the SBITS4
Isaiah 9 in the SBIUS
Isaiah 9 in the SBIVS
Isaiah 9 in the SBT
Isaiah 9 in the SBT1E
Isaiah 9 in the SCHL
Isaiah 9 in the SNT
Isaiah 9 in the SUSU
Isaiah 9 in the SUSU2
Isaiah 9 in the SYNO
Isaiah 9 in the TBIAOTANT
Isaiah 9 in the TBT1E
Isaiah 9 in the TBT1E2
Isaiah 9 in the TFTIP
Isaiah 9 in the TFTU
Isaiah 9 in the TGNTATF3T
Isaiah 9 in the THAI
Isaiah 9 in the TNFD
Isaiah 9 in the TNT
Isaiah 9 in the TNTIK
Isaiah 9 in the TNTIL
Isaiah 9 in the TNTIN
Isaiah 9 in the TNTIP
Isaiah 9 in the TNTIZ
Isaiah 9 in the TOMA
Isaiah 9 in the TTENT
Isaiah 9 in the UBG
Isaiah 9 in the UGV
Isaiah 9 in the UGV2
Isaiah 9 in the UGV3
Isaiah 9 in the VBL
Isaiah 9 in the VDCC
Isaiah 9 in the YALU
Isaiah 9 in the YAPE
Isaiah 9 in the YBVTP
Isaiah 9 in the ZBP