Judges 13 (BOYCB)
1 Àwọn ọmọ Israẹli sì túnṣe ohun tí ó burú ní ojú OLÚWA, OLÚWA sì fi wọ́n lé àwọn ará Filistini lọ́wọ́ fún ogójì ọdún. 2 Ọkùnrin ará Sora kan wà, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Manoa láti ẹ̀yà Dani. Aya rẹ̀ yàgàn kò sì bímọ. 3 Angẹli OLÚWA fi ara han obìnrin náà, ó sì wí fún un pé, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ yàgàn, ìwọ kò sì tí ì bímọ, ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan. 4 Báyìí rí i dájúdájú pé ìwọ kò mu wáìnì tàbí ọtí líle kankan àti pé ìwọ kò jẹ ohun aláìmọ́ kankan, 5 nítorí ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan. Má ṣe fi abẹ kan orí rẹ̀, nítorí pé Nasiri, ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún Ọlọ́run ni ọmọ náà yóò jẹ́ láti ọjọ́ ìbí rẹ̀. Òun ni yóò bẹ̀rẹ̀ ìdáǹdè àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní ọwọ́ àwọn ará Filistini.” 6 Nígbà náà ni obìnrin náà tọ ọkọ rẹ̀ lọ, o sì sọ fún un wí pé, “Ènìyàn Ọlọ́run kan tọ̀ mí wá. Ó jọ angẹli Ọlọ́run, ó ba ènìyàn lẹ́rù gidigidi. Èmi kò béèrè ibi tí ó ti wá, òun náà kò sì sọ orúkọ rẹ̀ fún mi. 7 Ṣùgbọ́n ó sọ fún mi wí pé, ‘Ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan, fún ìdí èyí, má ṣe mu wáìnì tàbí àwọn ọtí líle mìíràn bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ má ṣe jẹ ohunkóhun tí í ṣe aláìmọ́, nítorí pé Nasiri Ọlọ́run ni ọmọ náà yóò jẹ́ láti ọjọ́ ìbí rẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.’ ” 8 Nígbà náà ni Manoa gbàdúrà sí OLÚWA wí pé, “Háà OLÚWA, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ènìyàn Ọlọ́run tí ìwọ rán sí wa padà tọ̀ wá wá láti kọ́ wa bí àwa yóò ti ṣe tọ́ ọmọ tí àwa yóò bí náà.” 9 Ọlọ́run fetí sí ohùn Manoa, angẹli Ọlọ́run náà tún padà tọ obìnrin náà wá nígbà tí ó wà ní oko ṣùgbọ́n ọkọ rẹ̀ Manoa kò sí ní ọ̀dọ̀ rẹ̀. 10 Nítorí náà ni obìnrin náà ṣe yára lọ sọ fún ọkọ rẹ̀ pé, “Ọkùnrin tí ó fi ara hàn mí ní ọjọ́sí ti tún padà wá.” 11 Manoa yára dìde, ó sì tẹ̀lé aya rẹ̀, nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ ọkùnrin náà ó ní, “Ǹjẹ́ ìwọ ni o bá obìnrin yìí sọ̀rọ̀?”Ọkùnrin náà dáhùn pé, “Èmi ni.” 12 Manoa bi ọkùnrin náà pé, “Nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ kí ni yóò jẹ́ ìlànà fún ìgbé ayé àti iṣẹ́ ọmọ náà?” 13 Angẹli OLÚWA náà dáhùn wí pé, “Aya rẹ gbọdọ̀ ṣe gbogbo ohun tí mo ti sọ fún un 14 kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí ó bá ti inú èso àjàrà jáde wá, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ mu wáìnì tàbí àwọn ọtí líle mìíràn tàbí jẹ ohunkóhun tí ó bá jẹ́ aláìmọ́. Ó ní láti ṣe ohun gbogbo tí mo ti pàṣẹ fún un.” 15 Manoa sọ fún angẹli OLÚWA náà pé, “Jọ̀wọ́ dára dúró títí àwa yóò fi pèsè ọ̀dọ́ ewúrẹ́ kan fún ọ.” 16 Angẹli OLÚWA náà dá Manoa lóhùn pé, “Bí ẹ̀yin tilẹ̀ dá mi dúró, èmi kì yóò jẹ ọ̀kankan nínú oúnjẹ tí ẹ̀yin yóò pèsè. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá fẹ́ ẹ pèsè ọrẹ ẹbọ sísun, kí ẹ sì fi rú ẹbọ sí OLÚWA.” (Manoa kò mọ̀ pé angẹli OLÚWA ní i ṣe.) 17 Manoa sì béèrè lọ́wọ́ angẹli OLÚWA náà pé, “Kí ni orúkọ rẹ, kí àwa bá à lè fi ọlá fún ọ nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ?” 18 Ṣùgbọ́n angẹli OLÚWA náà dáhùn pé, “Èéṣe tí ìwọ ń béèrè orúkọ mi? Ìyanu ni, ó kọjá ìmọ̀.” 19 Lẹ́yìn náà ni Manoa mú ọ̀dọ́ ewúrẹ́, pẹ̀lú ẹbọ ọkà, ó sì fi rú ẹbọ lórí àpáta kan sí OLÚWA. Nígbà tí Manoa àti ìyàwó dúró tí wọn ń wò OLÚWA ṣe ohun ìyanu kan. 20 Bí ẹ̀là ahọ́n iná ti là jáde láti ibi pẹpẹ ìrúbọ náà sí ọ̀run, angẹli OLÚWA gòkè re ọ̀run láàrín ahọ́n iná náà. Nígbà tí wọ́n rí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, Manoa àti aya rẹ̀ wólẹ̀ wọ́n sì dojúbolẹ̀. 21 Nígbà tí angẹli OLÚWA náà kò tún fi ara rẹ̀ han Manoa àti aya rẹ̀ mọ́, Manoa wá mọ̀ pé angẹli OLÚWA ni. 22 Manoa sọ fún aya rẹ̀ pé, “Dájúdájú àwa yóò kú nítorí àwa ti fi ojú rí Ọlọ́run.” 23 Ṣùgbọ́n ìyàwó rẹ̀ dáhùn pé, “Bí OLÚWA bá ní èrò àti pa wá kò bá tí gba ẹbọ sísun àti ọrẹ ọkà wa, tàbí fi gbogbo nǹkan wọ̀nyí hàn wá tó sọ nǹkan ìyanu yìí fún wa.” 24 Obìnrin náà sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Samsoni. Ọmọ náà dàgbà OLÚWA sì bùkún un. 25 Ẹ̀mí OLÚWA sì bẹ̀rẹ̀ sí ru sókè nígbà tí ó wà ní Mahane-Dani ní agbede-méjì Sora àti Eṣtaoli.
In Other Versions
Judges 13 in the ANGEFD
Judges 13 in the ANTPNG2D
Judges 13 in the AS21
Judges 13 in the BAGH
Judges 13 in the BBPNG
Judges 13 in the BBT1E
Judges 13 in the BDS
Judges 13 in the BEV
Judges 13 in the BHAD
Judges 13 in the BIB
Judges 13 in the BLPT
Judges 13 in the BNT
Judges 13 in the BNTABOOT
Judges 13 in the BNTLV
Judges 13 in the BOATCB
Judges 13 in the BOATCB2
Judges 13 in the BOBCV
Judges 13 in the BOCNT
Judges 13 in the BOECS
Judges 13 in the BOGWICC
Judges 13 in the BOHCB
Judges 13 in the BOHCV
Judges 13 in the BOHLNT
Judges 13 in the BOHNTLTAL
Judges 13 in the BOICB
Judges 13 in the BOILNTAP
Judges 13 in the BOITCV
Judges 13 in the BOKCV
Judges 13 in the BOKCV2
Judges 13 in the BOKHWOG
Judges 13 in the BOKSSV
Judges 13 in the BOLCB
Judges 13 in the BOLCB2
Judges 13 in the BOMCV
Judges 13 in the BONAV
Judges 13 in the BONCB
Judges 13 in the BONLT
Judges 13 in the BONUT2
Judges 13 in the BOPLNT
Judges 13 in the BOSCB
Judges 13 in the BOSNC
Judges 13 in the BOTLNT
Judges 13 in the BOVCB
Judges 13 in the BPBB
Judges 13 in the BPH
Judges 13 in the BSB
Judges 13 in the CCB
Judges 13 in the CUV
Judges 13 in the CUVS
Judges 13 in the DBT
Judges 13 in the DGDNT
Judges 13 in the DHNT
Judges 13 in the DNT
Judges 13 in the ELBE
Judges 13 in the EMTV
Judges 13 in the ESV
Judges 13 in the FBV
Judges 13 in the FEB
Judges 13 in the GGMNT
Judges 13 in the GNT
Judges 13 in the HARY
Judges 13 in the HNT
Judges 13 in the IRVA
Judges 13 in the IRVB
Judges 13 in the IRVG
Judges 13 in the IRVH
Judges 13 in the IRVK
Judges 13 in the IRVM
Judges 13 in the IRVM2
Judges 13 in the IRVO
Judges 13 in the IRVP
Judges 13 in the IRVT
Judges 13 in the IRVT2
Judges 13 in the IRVU
Judges 13 in the ISVN
Judges 13 in the JSNT
Judges 13 in the KAPI
Judges 13 in the KBT1ETNIK
Judges 13 in the KBV
Judges 13 in the KJV
Judges 13 in the KNFD
Judges 13 in the LBA
Judges 13 in the LBLA
Judges 13 in the LNT
Judges 13 in the LSV
Judges 13 in the MAAL
Judges 13 in the MBV
Judges 13 in the MBV2
Judges 13 in the MHNT
Judges 13 in the MKNFD
Judges 13 in the MNG
Judges 13 in the MNT
Judges 13 in the MNT2
Judges 13 in the MRS1T
Judges 13 in the NAA
Judges 13 in the NASB
Judges 13 in the NBLA
Judges 13 in the NBS
Judges 13 in the NBVTP
Judges 13 in the NET2
Judges 13 in the NIV11
Judges 13 in the NNT
Judges 13 in the NNT2
Judges 13 in the NNT3
Judges 13 in the PDDPT
Judges 13 in the PFNT
Judges 13 in the RMNT
Judges 13 in the SBIAS
Judges 13 in the SBIBS
Judges 13 in the SBIBS2
Judges 13 in the SBICS
Judges 13 in the SBIDS
Judges 13 in the SBIGS
Judges 13 in the SBIHS
Judges 13 in the SBIIS
Judges 13 in the SBIIS2
Judges 13 in the SBIIS3
Judges 13 in the SBIKS
Judges 13 in the SBIKS2
Judges 13 in the SBIMS
Judges 13 in the SBIOS
Judges 13 in the SBIPS
Judges 13 in the SBISS
Judges 13 in the SBITS
Judges 13 in the SBITS2
Judges 13 in the SBITS3
Judges 13 in the SBITS4
Judges 13 in the SBIUS
Judges 13 in the SBIVS
Judges 13 in the SBT
Judges 13 in the SBT1E
Judges 13 in the SCHL
Judges 13 in the SNT
Judges 13 in the SUSU
Judges 13 in the SUSU2
Judges 13 in the SYNO
Judges 13 in the TBIAOTANT
Judges 13 in the TBT1E
Judges 13 in the TBT1E2
Judges 13 in the TFTIP
Judges 13 in the TFTU
Judges 13 in the TGNTATF3T
Judges 13 in the THAI
Judges 13 in the TNFD
Judges 13 in the TNT
Judges 13 in the TNTIK
Judges 13 in the TNTIL
Judges 13 in the TNTIN
Judges 13 in the TNTIP
Judges 13 in the TNTIZ
Judges 13 in the TOMA
Judges 13 in the TTENT
Judges 13 in the UBG
Judges 13 in the UGV
Judges 13 in the UGV2
Judges 13 in the UGV3
Judges 13 in the VBL
Judges 13 in the VDCC
Judges 13 in the YALU
Judges 13 in the YAPE
Judges 13 in the YBVTP
Judges 13 in the ZBP