Judges 5 (BOYCB)

1 Nígbà náà ni Debora àti Baraki ọmọ Abinoamu kọ orin ní ọjọ́ náà wí pé, 2 “Nítorí bí àwọn olórí ti síwájú ní Israẹli,nítorí bi àwọn ènìyàn ti fi tọkàntọkàn wa,ẹ fi ìbùkún fún OLÚWA! 3 “Ẹ gbọ́ ẹ̀yin ọba! Ẹ fetí yín sílẹ̀ ẹ̀yin ọmọ-aládé!Èmi yóò kọrin sí OLÚWA,èmi yóò kọrin ìyìn sí OLÚWA: Ọlọ́run Israẹli. 4 “OLÚWA nígbà tí o jáde kúrò ní Seiri,nígbà tí ìwọ ń yan jáde wá láti pápá Edomu,ilẹ̀ mì tìtì, àwọn ọ̀run sì kán sílẹ̀,àní àwọsánmọ̀ pẹ̀lú kàn omi sílẹ̀. 5 Àwọn òkè ńlá wárìrì ní iwájú OLÚWA, bẹ́ẹ̀ ni Sinai ní iwájú OLÚWAỌlọ́run Israẹli. 6 “Ní ọjọ́ Ṣamgari ọmọ Anati,ní ọjọ́ Jaeli, àwọn ọ̀nà òpópó dá;àwọn arìnrìn-àjò sì ń gba ọ̀nà ìkọ̀kọ̀. 7 Àwọn olórí tán ní Israẹli,wọ́n tán, títí èmi Debora fi dìdebí ìyá ní Israẹli. 8 Wọ́n ti yan ọlọ́run tuntun,nígbà náà ni ogun wà ní ibodèa ha rí asà tàbí ọ̀kọ̀ kanláàrín ọ̀kẹ́ méjì (40,000) ní Israẹli bí. 9 Àyà mi fà sí àwọn aláṣẹ Israẹliàwọn tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn tinútinú láàrín àwọn ènìyàn.Ẹ fi ìbùkún fún OLÚWA! 10 “Ẹ kéde rẹ̀: ẹ̀yin tí ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ funfun,ẹ̀yin tí ń jókòó lórí ẹní dáradára,àti ẹ̀yin tí ó ń rìn ní ọ̀nà.Ní ọ̀nà jíjìn sí 11 ariwo àwọn tafàtafà, ní ibi tí a gbé ń fa omi.Níbẹ̀ ni wọ́n gbé ń sọ ti iṣẹ́ òdodo OLÚWA,àní iṣẹ́ òdodo ìjọba rẹ̀ ní Israẹli. “Nígbà náà ni àwọn ènìyàn OLÚWAsọ̀kalẹ̀ lọ sí ibodè. 12 ‘Jí, jí, Debora!Jí, jí, kọ orin dìde!Dìde ìwọ Baraki!Kó àwọn ìgbèkùn rẹ ní ìgbèkùn ìwọ ọmọ Abinoamu.’ 13 “Nígbà náà ni àwọn tókù sọ̀kalẹ̀ àwọn ọlọ́lá lọ;àwọn ènìyàn OLÚWA tọ̀ mí wá pẹ̀lú àwọn alágbára. 14 Àwọn kan jáde wá láti Efraimu, àwọn tí gbòǹgbò wọn wà ní Amaleki;Benjamini wà pẹ̀lú àwọn tí ó tẹ̀lé ọ.Láti Makiri ni àwọn aláṣẹ ti sọ̀kalẹ̀ wá,láti Sebuluni ni àwọn ẹni tí ń mú ọ̀pá oyè lọ́wọ́. 15 Àwọn ọmọ-aládé Isakari wá pẹ̀lú Debora;bí Isakari ti ṣe olóòtítọ́ sí Baraki,wọ́n fi ẹsẹ̀ súré tẹ̀lé wọn lọ sí àfonífojì náà.Ní ipadò Reubenini ìgbèrò púpọ̀ wà. 16 Èéṣe tí ìwọ fi dúró pẹ́ láàrín agbo àgùntànláti máa gbọ́ fèrè olùṣọ́-àgùntàn?Ní ipadò Reubenini ìgbèrò púpọ̀ wà. 17 Gileadi dúró ní òkè odò Jordani.Èéṣe tí Dani fi dúró nínú ọkọ̀ ojú omi?Aṣeri jókòó ní etí bèbè Òkun,ó sì ń gbé èbúté rẹ̀. 18 Àwọn ènìyàn Sebuluni fi ẹ̀mí wọn wéwu ikú;bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ènìyàn Naftali ní ibi gíga pápá. 19 “Àwọn ọba wá, wọ́n sì jà;àwọn ọba Kenaani jàní Taanaki ní etí odo Megido,ṣùgbọ́n wọn kò sì gba èrè owó. 20 Àwọn ìràwọ̀ já láti ojú ọ̀run wáláti inú ipa ọ̀nà wọn ni wọ́n bá Sisera jà. 21 Odò Kiṣoni gbá wọn lọ,odò ìgbàanì, odò Kiṣoni.Máa yan lọ, ìwọ ọkàn mi, nínú agbára! 22 Nígbà náà ni pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin ki ilẹ̀,nítorí eré sísá, eré sísá àwọn alágbára wọn. 23 ‘Ẹ fi Merosi bú,’ ni angẹli OLÚWA wí.‘Ẹ fi àwọn ènìyàn inú rẹ̀ bú ìbú kíkorò,nítorí wọn kò wá sí ìrànlọ́wọ́ OLÚWA,láti dojúkọ àwọn alágbára.’ 24 “Ìbùkún ni fún Jaeli,aya Heberi ará Keni ju àwọn obìnrin lọ,ìbùkún ni fún un ju àwọn obìnrin tí ń gbé nínú àgọ́. 25 Ó béèrè omi, ó fún un ní wàrà;ó mú òrí-àmọ́ tọ̀ ọ́ wá nínú àwo iyebíye tí ó yẹ fún àwọn ọlọ́lá. 26 Ó na ọwọ́ rẹ̀ mú ìṣó àgọ́,ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú òòlù awọ gbẹ́nàgbẹ́nà,òòlù náà ni ó sì fi lu Sisera, ó gbá a mọ́ ọn ní orí,ó sì gun, ó sì kàn ẹ̀bátí rẹ̀ mọ́lẹ̀ ṣinṣin. 27 Ní ẹsẹ̀ rẹ̀ ó wólẹ̀,ó ṣubú; ó dùbúlẹ̀.Ó wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó ṣubú níbi tí ó gbé ń wólẹ̀;níbẹ̀ náà ni ó ṣubú kú sí. 28 “Ìyá Sisera yọjú láti ojú fèrèsé,ó sì kígbe, ó kígbe ní ojú fèrèsé ọlọ́nà pé,‘Èéṣe tí kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ fi pẹ́ bẹ́ẹ̀ láti dé?Èéṣe tí ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀ fi dúró lẹ́yìn?’ 29 Àwọn amòye obìnrin rẹ̀ dá a lóhùn;àní òun náà pẹ̀lú ti dá ara rẹ̀ lóhùn pé, 30 ‘Wọn kò ha ń wa kiri, wọn kò ha ti pín ìkógun bi:ọmọbìnrin kan tàbí méjì fún ọkùnrin kan,fún Sisera ìkógun aṣọ aláràbarà,ìkógun aṣọ aláràbarà àti ọlọ́nà,àwọn aṣọ ọlọ́nà iyebíye fún ọrùn mi,gbogbo èyí tí a kó ní ogun?’ 31 “Bẹ́ẹ̀ ni kí ó jẹ́ kí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ kí ó ṣègbé OLÚWA!Ṣùgbọ́n jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ ọ ràn bí oòrùn,nígbà tí ó bá yọ nínú agbára rẹ̀.”Ilẹ̀ náà sì sinmi ní ogójì ọdún.

In Other Versions

Judges 5 in the ANGEFD

Judges 5 in the ANTPNG2D

Judges 5 in the AS21

Judges 5 in the BAGH

Judges 5 in the BBPNG

Judges 5 in the BBT1E

Judges 5 in the BDS

Judges 5 in the BEV

Judges 5 in the BHAD

Judges 5 in the BIB

Judges 5 in the BLPT

Judges 5 in the BNT

Judges 5 in the BNTABOOT

Judges 5 in the BNTLV

Judges 5 in the BOATCB

Judges 5 in the BOATCB2

Judges 5 in the BOBCV

Judges 5 in the BOCNT

Judges 5 in the BOECS

Judges 5 in the BOGWICC

Judges 5 in the BOHCB

Judges 5 in the BOHCV

Judges 5 in the BOHLNT

Judges 5 in the BOHNTLTAL

Judges 5 in the BOICB

Judges 5 in the BOILNTAP

Judges 5 in the BOITCV

Judges 5 in the BOKCV

Judges 5 in the BOKCV2

Judges 5 in the BOKHWOG

Judges 5 in the BOKSSV

Judges 5 in the BOLCB

Judges 5 in the BOLCB2

Judges 5 in the BOMCV

Judges 5 in the BONAV

Judges 5 in the BONCB

Judges 5 in the BONLT

Judges 5 in the BONUT2

Judges 5 in the BOPLNT

Judges 5 in the BOSCB

Judges 5 in the BOSNC

Judges 5 in the BOTLNT

Judges 5 in the BOVCB

Judges 5 in the BPBB

Judges 5 in the BPH

Judges 5 in the BSB

Judges 5 in the CCB

Judges 5 in the CUV

Judges 5 in the CUVS

Judges 5 in the DBT

Judges 5 in the DGDNT

Judges 5 in the DHNT

Judges 5 in the DNT

Judges 5 in the ELBE

Judges 5 in the EMTV

Judges 5 in the ESV

Judges 5 in the FBV

Judges 5 in the FEB

Judges 5 in the GGMNT

Judges 5 in the GNT

Judges 5 in the HARY

Judges 5 in the HNT

Judges 5 in the IRVA

Judges 5 in the IRVB

Judges 5 in the IRVG

Judges 5 in the IRVH

Judges 5 in the IRVK

Judges 5 in the IRVM

Judges 5 in the IRVM2

Judges 5 in the IRVO

Judges 5 in the IRVP

Judges 5 in the IRVT

Judges 5 in the IRVT2

Judges 5 in the IRVU

Judges 5 in the ISVN

Judges 5 in the JSNT

Judges 5 in the KAPI

Judges 5 in the KBT1ETNIK

Judges 5 in the KBV

Judges 5 in the KJV

Judges 5 in the KNFD

Judges 5 in the LBA

Judges 5 in the LBLA

Judges 5 in the LNT

Judges 5 in the LSV

Judges 5 in the MAAL

Judges 5 in the MBV

Judges 5 in the MBV2

Judges 5 in the MHNT

Judges 5 in the MKNFD

Judges 5 in the MNG

Judges 5 in the MNT

Judges 5 in the MNT2

Judges 5 in the MRS1T

Judges 5 in the NAA

Judges 5 in the NASB

Judges 5 in the NBLA

Judges 5 in the NBS

Judges 5 in the NBVTP

Judges 5 in the NET2

Judges 5 in the NIV11

Judges 5 in the NNT

Judges 5 in the NNT2

Judges 5 in the NNT3

Judges 5 in the PDDPT

Judges 5 in the PFNT

Judges 5 in the RMNT

Judges 5 in the SBIAS

Judges 5 in the SBIBS

Judges 5 in the SBIBS2

Judges 5 in the SBICS

Judges 5 in the SBIDS

Judges 5 in the SBIGS

Judges 5 in the SBIHS

Judges 5 in the SBIIS

Judges 5 in the SBIIS2

Judges 5 in the SBIIS3

Judges 5 in the SBIKS

Judges 5 in the SBIKS2

Judges 5 in the SBIMS

Judges 5 in the SBIOS

Judges 5 in the SBIPS

Judges 5 in the SBISS

Judges 5 in the SBITS

Judges 5 in the SBITS2

Judges 5 in the SBITS3

Judges 5 in the SBITS4

Judges 5 in the SBIUS

Judges 5 in the SBIVS

Judges 5 in the SBT

Judges 5 in the SBT1E

Judges 5 in the SCHL

Judges 5 in the SNT

Judges 5 in the SUSU

Judges 5 in the SUSU2

Judges 5 in the SYNO

Judges 5 in the TBIAOTANT

Judges 5 in the TBT1E

Judges 5 in the TBT1E2

Judges 5 in the TFTIP

Judges 5 in the TFTU

Judges 5 in the TGNTATF3T

Judges 5 in the THAI

Judges 5 in the TNFD

Judges 5 in the TNT

Judges 5 in the TNTIK

Judges 5 in the TNTIL

Judges 5 in the TNTIN

Judges 5 in the TNTIP

Judges 5 in the TNTIZ

Judges 5 in the TOMA

Judges 5 in the TTENT

Judges 5 in the UBG

Judges 5 in the UGV

Judges 5 in the UGV2

Judges 5 in the UGV3

Judges 5 in the VBL

Judges 5 in the VDCC

Judges 5 in the YALU

Judges 5 in the YAPE

Judges 5 in the YBVTP

Judges 5 in the ZBP