Jeremiah 15 (BOYCB)
1 Nígbà náà ni OLÚWA sọ fún mi pé: “Kódà kí Mose àti Samuẹli dúró níwájú mi, ọkàn mi kì yóò lọ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Mú wọn kúrò níwájú mi! Jẹ́ kí wọn ó lọ! 2 Tí wọ́n bá sì bi ọ́ pé, ‘Níbo ni kí a lọ?’ Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni OLÚWA wí:“ ‘Àwọn tí a kọ ikú mọ́, sí ikú;àwọn tí a kọ idà mọ́, sí idà;àwọn tí a kọ ìyàn mọ́, sí ìyàn;àwọn tí a kọ ìgbèkùn mọ́ sí ìgbèkùn.’ 3 “Èmi yóò rán oríṣìí ìjìyà mẹ́rin láti kọlù wọ́n,” ni OLÚWA wí, “Idà láti pa, àwọn ajá láti wọ́ wọn lọ, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹranko orí ilẹ̀ láti jẹ àti láti parun. 4 N ó sọ wọ́n di ẹni ìkórìíra níwájú gbogbo ìjọba ayé torí ohun tí Manase ọmọ Hesekiah ọba Juda ṣe ní Jerusalẹmu. 5 “Ta ni yóò ṣàánú rẹ, ìwọ Jerusalẹmu?Ta ni yóò dárò rẹ?Ta ni yóò dúró béèrè àlàáfíà rẹ? 6 O ti kọ̀ mí sílẹ̀,” ni OLÚWA wí,“Ìwọ sì wà nínú ìpadàsẹ́yìn.Nítorí náà, Èmi yóò dáwọ́lé ọ, èmi ó sì pa ọ́ run,Èmi kò sì ní fi ojú àánú wò ọ́ mọ́. 7 Èmi kò tún lè fi ìfẹ́ hàn si ọ,Èmi yóò fi àtẹ fẹ́ wọn sí ẹnu-ọ̀nà ìlú náà.Èmi yóò mú ìṣọ̀fọ̀ àti ìparunbá àwọn ènìyàn mi nítorí pé wọnkò tí ì yípadà kúrò lọ́nà wọn. 8 Èmi yóò jẹ́ kí àwọn opó wọn pọ̀ juyanrìn Òkun lọ.Ní ọjọ́-kanrí ni èmi ó mú apanirunkọlu àwọn ìyá ọmọkùnrin wọn.Lójijì ni èmi yóò múìfòyà àti ìbẹ̀rù bá wọn. 9 Ìyá ọlọ́mọ méje yóò dákú,yóò sì mí ìmí ìgbẹ̀yìn.Òòrùn rẹ yóò wọ̀ lọ́sàn án gangan,yóò di ẹni ẹ̀tẹ́ òun àbùkù.Èmi yóò fi àwọn tí ó bá yè síwájúàwọn ọ̀tá wọn tí idà wà lọ́wọ́ wọn,”ni OLÚWA wí. 10 Háà! Ó ṣe tí ìyá mi bí mi,ọkùnrin tí gbogbo ilẹ̀ dojúkọ tí wọ́n sì bá jà!Èmi kò wínni, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò yá lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni,síbẹ̀, gbogbo ènìyàn ló ń fi mí ré. 11 OLÚWA sọ pé,“Dájúdájú èmi ò dá ọ sí fún ìdí kan pàtó;dájúdájú mo mú kí àwọn ọ̀tá rẹ tẹríba níwájú rẹnígbà ibi àti ìpọ́njú. 12 “Ǹjẹ́ ẹnìkan lè fi ọwọ́ ṣẹ́ irinirin láti àríwá tàbí idẹ? 13 “Gbogbo ọlá àti ìṣúra rẹni èmi ó fi sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìkógun láìgbanǹkan kan nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹjákèjádò orílẹ̀-èdè rẹ. 14 Èmi yóò fi ọ́ ṣẹrú fún àwọn ọ̀tá rẹní ìlú tí ìwọ kò mọ̀ nítorí ìbínúmi yóò rán iná tí yóò jó ọ.” 15 Ó yé ọ, ìwọ OLÚWA;rántí mi kí o sì ṣe ìtọ́jú mi.Gbẹ̀san mi lára àwọn tó dìtẹ̀ mi.Ìwọ ti jìyà fún ìgbà pípẹ́, má ṣe mú mi lọ;nínú bí mo ṣe jìyà nítorí tìrẹ. 16 Nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ dé, mo jẹ wọ́n,àwọn ni ìdùnnú àti ayọ̀ ọkàn mi,nítorí pé orúkọ rẹ ni a fi ń pè mí,Ìwọ OLÚWA Ọlọ́run Alágbára. 17 Èmi kò fìgbà kan jókòó láàrín àwọn ẹlẹ́gàn,n ko bá wọn yọ ayọ̀ pọ̀;mo dá jókòó torí pé ọwọ́ rẹ wà lára mi,ìwọ sì ti fi ìbínú rẹ kún inú mi. 18 Èéṣe tí ìrora mi kò lópin,tí ọgbẹ́ mi kò sì ṣe é wòsàn?Ní òtítọ́ ìwọ yóò dàbí kànga ẹ̀tàn sí mi,gẹ́gẹ́ bí ìsun tó kọ̀ tí kò sun? 19 Nítorí náà báyìí ni OLÚWA wí,“Tí o bá ronúpìwàdà, Èmi ó dá ọ padà wákí o lè máa sìn mí;tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ tó dára,ìwọ yóò di agbẹnusọ mi.Jẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí kọjú sí ọ;ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ kọjú sí wọn. 20 Èmi fi ọ́ ṣe odi idẹ tí ó lágbára,sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí;wọn ó bá ọ jàṣùgbọ́n wọn kò ní lè borí rẹ,nítorí pé, mo wà pẹ̀lú rẹláti gbà ọ́ là, kí n sì dáàbò bò ọ́,”ni OLÚWA wí. 21 “Èmi yóò gbà ọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ìkà ènìyàn,Èmi yóò sì rà ọ́ padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹni búburú.”
In Other Versions
Jeremiah 15 in the ANGEFD
Jeremiah 15 in the ANTPNG2D
Jeremiah 15 in the AS21
Jeremiah 15 in the BAGH
Jeremiah 15 in the BBPNG
Jeremiah 15 in the BBT1E
Jeremiah 15 in the BDS
Jeremiah 15 in the BEV
Jeremiah 15 in the BHAD
Jeremiah 15 in the BIB
Jeremiah 15 in the BLPT
Jeremiah 15 in the BNT
Jeremiah 15 in the BNTABOOT
Jeremiah 15 in the BNTLV
Jeremiah 15 in the BOATCB
Jeremiah 15 in the BOATCB2
Jeremiah 15 in the BOBCV
Jeremiah 15 in the BOCNT
Jeremiah 15 in the BOECS
Jeremiah 15 in the BOGWICC
Jeremiah 15 in the BOHCB
Jeremiah 15 in the BOHCV
Jeremiah 15 in the BOHLNT
Jeremiah 15 in the BOHNTLTAL
Jeremiah 15 in the BOICB
Jeremiah 15 in the BOILNTAP
Jeremiah 15 in the BOITCV
Jeremiah 15 in the BOKCV
Jeremiah 15 in the BOKCV2
Jeremiah 15 in the BOKHWOG
Jeremiah 15 in the BOKSSV
Jeremiah 15 in the BOLCB
Jeremiah 15 in the BOLCB2
Jeremiah 15 in the BOMCV
Jeremiah 15 in the BONAV
Jeremiah 15 in the BONCB
Jeremiah 15 in the BONLT
Jeremiah 15 in the BONUT2
Jeremiah 15 in the BOPLNT
Jeremiah 15 in the BOSCB
Jeremiah 15 in the BOSNC
Jeremiah 15 in the BOTLNT
Jeremiah 15 in the BOVCB
Jeremiah 15 in the BPBB
Jeremiah 15 in the BPH
Jeremiah 15 in the BSB
Jeremiah 15 in the CCB
Jeremiah 15 in the CUV
Jeremiah 15 in the CUVS
Jeremiah 15 in the DBT
Jeremiah 15 in the DGDNT
Jeremiah 15 in the DHNT
Jeremiah 15 in the DNT
Jeremiah 15 in the ELBE
Jeremiah 15 in the EMTV
Jeremiah 15 in the ESV
Jeremiah 15 in the FBV
Jeremiah 15 in the FEB
Jeremiah 15 in the GGMNT
Jeremiah 15 in the GNT
Jeremiah 15 in the HARY
Jeremiah 15 in the HNT
Jeremiah 15 in the IRVA
Jeremiah 15 in the IRVB
Jeremiah 15 in the IRVG
Jeremiah 15 in the IRVH
Jeremiah 15 in the IRVK
Jeremiah 15 in the IRVM
Jeremiah 15 in the IRVM2
Jeremiah 15 in the IRVO
Jeremiah 15 in the IRVP
Jeremiah 15 in the IRVT
Jeremiah 15 in the IRVT2
Jeremiah 15 in the IRVU
Jeremiah 15 in the ISVN
Jeremiah 15 in the JSNT
Jeremiah 15 in the KAPI
Jeremiah 15 in the KBT1ETNIK
Jeremiah 15 in the KBV
Jeremiah 15 in the KJV
Jeremiah 15 in the KNFD
Jeremiah 15 in the LBA
Jeremiah 15 in the LBLA
Jeremiah 15 in the LNT
Jeremiah 15 in the LSV
Jeremiah 15 in the MAAL
Jeremiah 15 in the MBV
Jeremiah 15 in the MBV2
Jeremiah 15 in the MHNT
Jeremiah 15 in the MKNFD
Jeremiah 15 in the MNG
Jeremiah 15 in the MNT
Jeremiah 15 in the MNT2
Jeremiah 15 in the MRS1T
Jeremiah 15 in the NAA
Jeremiah 15 in the NASB
Jeremiah 15 in the NBLA
Jeremiah 15 in the NBS
Jeremiah 15 in the NBVTP
Jeremiah 15 in the NET2
Jeremiah 15 in the NIV11
Jeremiah 15 in the NNT
Jeremiah 15 in the NNT2
Jeremiah 15 in the NNT3
Jeremiah 15 in the PDDPT
Jeremiah 15 in the PFNT
Jeremiah 15 in the RMNT
Jeremiah 15 in the SBIAS
Jeremiah 15 in the SBIBS
Jeremiah 15 in the SBIBS2
Jeremiah 15 in the SBICS
Jeremiah 15 in the SBIDS
Jeremiah 15 in the SBIGS
Jeremiah 15 in the SBIHS
Jeremiah 15 in the SBIIS
Jeremiah 15 in the SBIIS2
Jeremiah 15 in the SBIIS3
Jeremiah 15 in the SBIKS
Jeremiah 15 in the SBIKS2
Jeremiah 15 in the SBIMS
Jeremiah 15 in the SBIOS
Jeremiah 15 in the SBIPS
Jeremiah 15 in the SBISS
Jeremiah 15 in the SBITS
Jeremiah 15 in the SBITS2
Jeremiah 15 in the SBITS3
Jeremiah 15 in the SBITS4
Jeremiah 15 in the SBIUS
Jeremiah 15 in the SBIVS
Jeremiah 15 in the SBT
Jeremiah 15 in the SBT1E
Jeremiah 15 in the SCHL
Jeremiah 15 in the SNT
Jeremiah 15 in the SUSU
Jeremiah 15 in the SUSU2
Jeremiah 15 in the SYNO
Jeremiah 15 in the TBIAOTANT
Jeremiah 15 in the TBT1E
Jeremiah 15 in the TBT1E2
Jeremiah 15 in the TFTIP
Jeremiah 15 in the TFTU
Jeremiah 15 in the TGNTATF3T
Jeremiah 15 in the THAI
Jeremiah 15 in the TNFD
Jeremiah 15 in the TNT
Jeremiah 15 in the TNTIK
Jeremiah 15 in the TNTIL
Jeremiah 15 in the TNTIN
Jeremiah 15 in the TNTIP
Jeremiah 15 in the TNTIZ
Jeremiah 15 in the TOMA
Jeremiah 15 in the TTENT
Jeremiah 15 in the UBG
Jeremiah 15 in the UGV
Jeremiah 15 in the UGV2
Jeremiah 15 in the UGV3
Jeremiah 15 in the VBL
Jeremiah 15 in the VDCC
Jeremiah 15 in the YALU
Jeremiah 15 in the YAPE
Jeremiah 15 in the YBVTP
Jeremiah 15 in the ZBP