Jeremiah 2 (BOYCB)

1 Ọ̀rọ̀ OLÚWA sì tọ̀ mí wá wí pé: 2 “Lọ kí o sì kéde sí etí Jerusalẹmu pé: “Báyìí ni OLÚWA wí,“ ‘Èmi rántí ìṣeun ìgbà èwe rẹ,ìfẹ́ ìgbéyàwó rẹàti nígbà tí ìwọ tẹ̀lé mi nínú ijù,nínú ìyàngbẹ ilẹ̀. 3 Israẹli jẹ́ mímọ́ sí OLÚWA,àkọ́kọ́ èso ìkórè rẹ̀,gbogbo ẹnikẹ́ni tí ó jẹ run ni a ó dá lẹ́bi,ibi yóò sì wá sí orí wọn,’ ”bẹ́ẹ̀ ni OLÚWA wí. 4 Gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA, ẹ̀yin ìdílé Jakọbuàti gbogbo ẹ̀yin ará ilé Israẹli. 5 Báyìí ni OLÚWA wí:“Irú àìṣedéédéé wo ni baba yín rí lọ́wọ́ mi,tí wọ́n fi jìnnà sí mi?Wọ́n tẹ̀lé àwọn òrìṣà asán,àwọn fúnra wọn sì di asán. 6 Wọn kò béèrè, ‘Níbo ni OLÚWA wà,tí ó mú wa jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá,tí ó mú wa la aginjù já,tí ó mú wa la àárín pẹ̀tẹ́lẹ̀ àti ihò,ìyàngbẹ ilẹ̀ àti òkùnkùn biribiri,ilẹ̀ ibi tí ẹnikẹ́ni kò là kọjá, tí ẹnikẹ́ni kò sì tẹ̀dó sí?’ 7 Èmi mú yín wá sí ilẹ̀ ọlọ́ràáláti máa jẹ èso ibẹ̀ àti ọrọ̀ rẹ̀,ṣùgbọ́n ẹ̀yin wọ inú rẹ̀, ẹ sì bà á jẹ́,ẹ sì sọ ogún mi di ohun ìríra. 8 Àwọn àlùfáà kò béèrè wí pé,‘Níbo ni OLÚWA wà?’Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú òfin kò si mọ̀ mí,àwọn olùṣọ́ sì ṣẹ̀ sí mi.Àwọn wòlíì sì ń sọtẹ́lẹ̀ nípa òrìṣà Baali,wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọn òrìṣà asán. 9 “Nítorí náà, mo fi ẹ̀sùn kàn yín lẹ́ẹ̀kan sí i,”ni OLÚWA wí.“Èmi ó sì fi ẹ̀sùn kan àwọn ọmọ ọwọ́ rẹ. 10 Rékọjá lọ sí erékùṣù àwọn ara Kittimu, kí ẹ sì wò ó,ránṣẹ́ lọ sí ìlú Kedari, kí ẹ sì kíyèsi gidigidi;kí ẹ wò bí irú nǹkan báyìí bá ń bẹ níbẹ̀? 11 Orílẹ̀-èdè kan ha á pa ọlọ́run rẹ̀ dà?(Síbẹ̀, wọ́n kì í ṣe iṣẹ́ ọlọ́run.)Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi ti pààrọ̀Ọlọ́run ògo wọn fún àwọn ère tí kò níyì. 12 Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́ṣẹ̀ méjìkí ẹ sì wárìrì pẹ̀lú ìbẹ̀rù ńlá,”ni OLÚWA wí. 13 “Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́ṣẹ̀ méjì,wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀,Èmi orísun omi ìyè,wọ́n sì ti ṣe àmù,àmù fífọ́ tí kò lè gba omi dúró. 14 Israẹli ha á jẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀ ẹrú nípa ìbí?Kí ló ha a dé tí ó fi di ìkógun? 15 Àwọn kìnnìún ké ramúramù;wọ́n sì ń bú mọ́ wọn.Wọ́n ti fi ilẹ̀ rẹ̀ ṣòfò;ìlú rẹ̀ ti di jíjóná, ó sì ti di ìkọ̀sílẹ̀. 16 Bákan náà, àwọn ọkùnrin Memfisi àti Tafanesiwọ́n ti fa adé orí rẹ yọ. 17 Ẹ̀yin kò ha a ti fa èyí sórí ara yínnípa kíkọ OLÚWA Ọlọ́run sílẹ̀nígbà tí ó tọ́ ọ lójú ọ̀nà? 18 Kí ló dé tí o ṣe wá lọ Ejibitiláti lọ mu omi ní Ṣihori?Kí ló dé tí o sì fi lọ sí Asirialáti lọ mú omi ni odò Eufurate náà? 19 Iṣẹ́ búburú yín yóò fìyà jẹ yínìpadàsẹ́yìn rẹ yóò sì bá ọ wímọ̀ kí o sì rí i wí pé ibi àtiohun búburú yóò sì jẹ́ tìrẹnígbà tí o ti kọ OLÚWA Ọlọ́run sílẹ̀,ẹ kò sì ní ìbẹ̀rù fún mi,”ni Olúwa, OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí. 20 “Nígbà àtijọ́, o ti fọ́ àjàgà rẹ sọnù,ìwọ sì já ìdè rẹ;ìwọ wí pé, ‘Èmi kì yóò sìn ọ́!’Lóòtítọ́, lórí gbogbo òkè gíga niàti lábẹ́ igi tí ó tànkálẹ̀ni ìwọ dùbúlẹ̀ sí gẹ́gẹ́ bí panṣágà. 21 Èmi ti gbìn ọ́ gẹ́gẹ́ bí àjàrà ọ̀tọ̀,gẹ́gẹ́ bí ìṣúra ọlọ́lá.Báwo wá ni ìwọ ṣe yípadà sí midi àjàrà búburú àti aláìmọ́? 22 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o wẹ ara rẹ pẹ̀lú sódàtí o sì lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọṣẹsíbẹ̀síbẹ̀ èérí ni ẹ̀ṣẹ̀ rẹ níwájú,”ni OLÚWA Olódùmarè wí. 23 “Báwo ni ìwọ ṣe wí pé, ‘Èmi kò ṣe aláìmọ́,Èmi kò sá à tẹ̀lé àwọn Baali’?Wo bí o ṣe hùwà ní àfonífojì;wo ohun tí o ṣe.Ìwọ jẹ́ abo ìbákasẹtí ń sá síyìn-ín sọ́hùn-ún. 24 Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tí ń gbé aginjùtí ń fa ẹ̀fúùfù ìfẹ́ sí i mu rẹ,ta ni ó le è mú dúró ní àkókò rẹ̀?Kí gbogbo àwọn akọ ẹran tí o wá a kiri kì ó má ṣe dá ara wọn lágara,nítorí wọn yóò rí ní àkókò oṣù rẹ̀. 25 Dá ẹsẹ̀ dúró láìwọ bàtà,àti ọ̀fun rẹ nínú òǹgbẹ.Ṣùgbọ́n ìwọ wí pé, ‘Asán ni!Èmi fẹ́ràn àwọn ọlọ́run àjèjì,àwọn ni èmi yóò tọ̀ lẹ́yìn.’ 26 “Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ń dójútì olè nígbà tí a bá mú u,bẹ́ẹ̀ náà ni ojú yóò ti ilé Israẹli—àwọn ọba àti àwọn ìjòyè wọn,àwọn àlùfáà àti wòlíì wọn pẹ̀lú. 27 Wọ́n sọ fún igi pé, ‘Ìwọ ni baba mi,’àti sí òkúta wí pé, ‘Ìwọ ni ó bí mi,’wọ́n ti kọ ẹ̀yìn wọn sí mi,wọn kò kọ ojú sí misíbẹ̀ nígbà tí wọ́n bá wà nínú ìṣòro,wọn yóò wí pé, ‘Wá kí o sì gbà wá!’ 28 Níbo wá ni àwọn ọlọ́run tí ẹ ṣe fúnra yín ha a wà?Jẹ́ kí wọ́n wá kí wọ́n sì gbà yínnígbà tí ẹ bá wà nínú ìṣòro!Nítorí pé ẹ̀yin ní àwọn ọlọ́run púpọ̀,gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe ni àwọn ìlú, ìwọ Juda. 29 “Kí ló dé tí o ṣe wá ń fi ẹ̀sùn kàn mí?Gbogbo yín ni ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi,”ni OLÚWA wí. 30 “Nínú asán mo fìyà jẹ àwọn ènìyàn yín,wọn kò sì gba ìbáwí.Idà yín ti pa àwọn wòlíì yín run,gẹ́gẹ́ bí kìnnìún tí ń bú ramúramù. 31 “Ẹ̀yin ìran yìí, ẹ kíyèsi ọ̀rọ̀ OLÚWA:“Mo ha ti di aginjù sí Israẹlitàbí mo jẹ ilẹ̀ olókùnkùn biribiri?Èéṣe tí àwọn ènìyàn mi ṣe wí pé, ‘A ní àǹfààní láti máa rìn kiri;àwa kì yóò tọ̀ ọ́ wá mọ́?’ 32 Wúńdíá ha le gbàgbé ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀,tàbí ìyàwó ohun ọ̀ṣọ́ ìgbéyàwó rẹ̀?Síbẹ̀, àwọn ènìyàn mi ti gbàgbé miní ọjọ́ àìníye. 33 Ìwọ ti jẹ́ ọlọ́gbọ́n tó nípa ọ̀rọ̀ ìfẹ́!Àwọn obìnrin búburú yóò kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀nà rẹ. 34 Lórí aṣọ rẹ ni wọ́n báẹ̀jẹ̀ àwọn tálákà aláìṣẹ̀,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kò ká wọn mọ́ níbi tí wọ́n ti ń rùn wọlé.Síbẹ̀ nínú gbogbo èyí 35 ìwọ sọ wí pé, ‘Èmi jẹ́ aláìṣẹ̀;kò sì bínú sí mi.’Èmi yóò mú ìdájọ́ mi wá sórí rẹnítorí pé ìwọ wí pé, ‘Èmi kò dẹ́ṣẹ̀.’ 36 Èéṣe tí ìwọ fi ń lọ káàkiriláti yí ọ̀nà rẹ padà?Ejibiti yóò dójútì ọ́gẹ́gẹ́ bí i ti Asiria. 37 Ìwọ yóò sì fi ibẹ̀ sílẹ̀pẹ̀lú kíkáwọ́ rẹ lé orí rẹ,nítorí pé OLÚWA ti kọ̀ àwọn tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé sílẹ̀,kì yóò sí ìrànlọ́wọ́ kankan fún ọ láti ọ̀dọ̀ wọn.

In Other Versions

Jeremiah 2 in the ANGEFD

Jeremiah 2 in the ANTPNG2D

Jeremiah 2 in the AS21

Jeremiah 2 in the BAGH

Jeremiah 2 in the BBPNG

Jeremiah 2 in the BBT1E

Jeremiah 2 in the BDS

Jeremiah 2 in the BEV

Jeremiah 2 in the BHAD

Jeremiah 2 in the BIB

Jeremiah 2 in the BLPT

Jeremiah 2 in the BNT

Jeremiah 2 in the BNTABOOT

Jeremiah 2 in the BNTLV

Jeremiah 2 in the BOATCB

Jeremiah 2 in the BOATCB2

Jeremiah 2 in the BOBCV

Jeremiah 2 in the BOCNT

Jeremiah 2 in the BOECS

Jeremiah 2 in the BOGWICC

Jeremiah 2 in the BOHCB

Jeremiah 2 in the BOHCV

Jeremiah 2 in the BOHLNT

Jeremiah 2 in the BOHNTLTAL

Jeremiah 2 in the BOICB

Jeremiah 2 in the BOILNTAP

Jeremiah 2 in the BOITCV

Jeremiah 2 in the BOKCV

Jeremiah 2 in the BOKCV2

Jeremiah 2 in the BOKHWOG

Jeremiah 2 in the BOKSSV

Jeremiah 2 in the BOLCB

Jeremiah 2 in the BOLCB2

Jeremiah 2 in the BOMCV

Jeremiah 2 in the BONAV

Jeremiah 2 in the BONCB

Jeremiah 2 in the BONLT

Jeremiah 2 in the BONUT2

Jeremiah 2 in the BOPLNT

Jeremiah 2 in the BOSCB

Jeremiah 2 in the BOSNC

Jeremiah 2 in the BOTLNT

Jeremiah 2 in the BOVCB

Jeremiah 2 in the BPBB

Jeremiah 2 in the BPH

Jeremiah 2 in the BSB

Jeremiah 2 in the CCB

Jeremiah 2 in the CUV

Jeremiah 2 in the CUVS

Jeremiah 2 in the DBT

Jeremiah 2 in the DGDNT

Jeremiah 2 in the DHNT

Jeremiah 2 in the DNT

Jeremiah 2 in the ELBE

Jeremiah 2 in the EMTV

Jeremiah 2 in the ESV

Jeremiah 2 in the FBV

Jeremiah 2 in the FEB

Jeremiah 2 in the GGMNT

Jeremiah 2 in the GNT

Jeremiah 2 in the HARY

Jeremiah 2 in the HNT

Jeremiah 2 in the IRVA

Jeremiah 2 in the IRVB

Jeremiah 2 in the IRVG

Jeremiah 2 in the IRVH

Jeremiah 2 in the IRVK

Jeremiah 2 in the IRVM

Jeremiah 2 in the IRVM2

Jeremiah 2 in the IRVO

Jeremiah 2 in the IRVP

Jeremiah 2 in the IRVT

Jeremiah 2 in the IRVT2

Jeremiah 2 in the IRVU

Jeremiah 2 in the ISVN

Jeremiah 2 in the JSNT

Jeremiah 2 in the KAPI

Jeremiah 2 in the KBT1ETNIK

Jeremiah 2 in the KBV

Jeremiah 2 in the KJV

Jeremiah 2 in the KNFD

Jeremiah 2 in the LBA

Jeremiah 2 in the LBLA

Jeremiah 2 in the LNT

Jeremiah 2 in the LSV

Jeremiah 2 in the MAAL

Jeremiah 2 in the MBV

Jeremiah 2 in the MBV2

Jeremiah 2 in the MHNT

Jeremiah 2 in the MKNFD

Jeremiah 2 in the MNG

Jeremiah 2 in the MNT

Jeremiah 2 in the MNT2

Jeremiah 2 in the MRS1T

Jeremiah 2 in the NAA

Jeremiah 2 in the NASB

Jeremiah 2 in the NBLA

Jeremiah 2 in the NBS

Jeremiah 2 in the NBVTP

Jeremiah 2 in the NET2

Jeremiah 2 in the NIV11

Jeremiah 2 in the NNT

Jeremiah 2 in the NNT2

Jeremiah 2 in the NNT3

Jeremiah 2 in the PDDPT

Jeremiah 2 in the PFNT

Jeremiah 2 in the RMNT

Jeremiah 2 in the SBIAS

Jeremiah 2 in the SBIBS

Jeremiah 2 in the SBIBS2

Jeremiah 2 in the SBICS

Jeremiah 2 in the SBIDS

Jeremiah 2 in the SBIGS

Jeremiah 2 in the SBIHS

Jeremiah 2 in the SBIIS

Jeremiah 2 in the SBIIS2

Jeremiah 2 in the SBIIS3

Jeremiah 2 in the SBIKS

Jeremiah 2 in the SBIKS2

Jeremiah 2 in the SBIMS

Jeremiah 2 in the SBIOS

Jeremiah 2 in the SBIPS

Jeremiah 2 in the SBISS

Jeremiah 2 in the SBITS

Jeremiah 2 in the SBITS2

Jeremiah 2 in the SBITS3

Jeremiah 2 in the SBITS4

Jeremiah 2 in the SBIUS

Jeremiah 2 in the SBIVS

Jeremiah 2 in the SBT

Jeremiah 2 in the SBT1E

Jeremiah 2 in the SCHL

Jeremiah 2 in the SNT

Jeremiah 2 in the SUSU

Jeremiah 2 in the SUSU2

Jeremiah 2 in the SYNO

Jeremiah 2 in the TBIAOTANT

Jeremiah 2 in the TBT1E

Jeremiah 2 in the TBT1E2

Jeremiah 2 in the TFTIP

Jeremiah 2 in the TFTU

Jeremiah 2 in the TGNTATF3T

Jeremiah 2 in the THAI

Jeremiah 2 in the TNFD

Jeremiah 2 in the TNT

Jeremiah 2 in the TNTIK

Jeremiah 2 in the TNTIL

Jeremiah 2 in the TNTIN

Jeremiah 2 in the TNTIP

Jeremiah 2 in the TNTIZ

Jeremiah 2 in the TOMA

Jeremiah 2 in the TTENT

Jeremiah 2 in the UBG

Jeremiah 2 in the UGV

Jeremiah 2 in the UGV2

Jeremiah 2 in the UGV3

Jeremiah 2 in the VBL

Jeremiah 2 in the VDCC

Jeremiah 2 in the YALU

Jeremiah 2 in the YAPE

Jeremiah 2 in the YBVTP

Jeremiah 2 in the ZBP