Jeremiah 26 (BOYCB)
1 Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìjọba ọba Jehoiakimu ọmọ Josiah tí ń ṣe ọba Juda, ọ̀rọ̀ yìí wá láti ọ̀dọ̀ OLÚWA: 2 “Èyí ni ohun tí OLÚWA wí, Dúró ní àgbàlá ilé OLÚWA, kí o sì sọ fún gbogbo ènìyàn ilẹ̀ Juda tí ó ti wá láti wá jọ́sìn ní ilé OLÚWA, sọ fún gbogbo ohun tí mo pàṣẹ fún ọ; má ṣaláìsọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà. 3 Bóyá gbogbo wọn máa gbọ́ ọ̀rọ̀ náà tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yóò kúrò nínú ìwà búburú wọn. Èmi ó yí ọkàn padà, n kò sì ní fi ibi tí mo ti rò sí wọn ṣe wọ́n. 4 Sọ fún wọn wí pé, ‘Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: Tí ẹ kò bá fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, tí ẹ kò sì gbọ́ òfin mi, ti mo gbé kalẹ̀ níwájú yín, 5 àti tí ẹ kò bá gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ mi, àwọn wòlíì tí mo rán sí i yín léraléra (ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọ́), 6 nígbà náà ni èmi yóò ṣe ilé yìí bí Ṣilo, èmi yóò sì ṣe ìlú yìí ní ìfibú sí gbogbo orílẹ̀-èdè ayé.’ ” 7 Àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì àti gbogbo ènìyàn ni ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Jeremiah tí ó sọ ní ilé OLÚWA. 8 Ṣùgbọ́n ní kété tí Jeremiah ti parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí OLÚWA pàṣẹ láti sọ; àwọn àlùfáà, àti gbogbo ènìyàn dìímú, wọ́n sì wí pé, “Kíkú ni ìwọ yóò kú! 9 Kí ló dé tí ìwọ ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ OLÚWA pé, ilé yìí yóò dàbí Ṣilo, orílẹ̀-èdè yìí yóò sì di ahoro tí kì yóò ní olùgbé.” Gbogbo àwọn ènìyàn sì kójọpọ̀ pẹ̀lú Jeremiah nínú ilé OLÚWA. 10 Nígbà tí àwọn aláṣẹ Juda gbọ́ nípa nǹkan wọ̀nyí, wọ́n lọ láti ààfin ọba sí ilé OLÚWA, wọ́n sì mú ààyè wọn, wọ́n jókòó ní ẹnu-ọ̀nà tuntun ilé OLÚWA. 11 Àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì sọ fún àwọn aláṣẹ àti gbogbo ènìyàn pé, “Arákùnrin yìí gbọdọ̀ gba ìdájọ́ ikú nítorí pé ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ lórí ìlú yìí: bí ẹ̀yin ti fi etí yín gbọ́!” 12 Nígbà náà ni Jeremiah sọ fún gbogbo àwọn aláṣẹ àti gbogbo àwọn ènìyàn wí pé: “OLÚWA rán mi láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ilé yìí àti ìlú yìí, gbogbo ohun tí ẹ ti gbọ́. 13 Nísinsin yìí, tún ọ̀nà rẹ ṣe àti ìṣe rẹ, kí ẹ sì gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA Ọlọ́run yín. OLÚWA yóò yí ọkàn rẹ̀ padà, kò sì ní mú ohun gbogbo tí ó ti sọ jáde ní búburú ṣẹ lórí yín. 14 Bí ó bá ṣe tèmi ni, èmi wà ní ọwọ́ yín, ẹ ṣe ohun tí ẹ̀yin bá rò pé ó dára, tí ó sì tọ́ lójú yín fún mi. 15 Ẹ mọ̀ dájú pé tí ẹ bá pa mí, ẹ ó mú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ wá sórí ara yín, sórí ìlú yìí àti àwọn olùgbé inú rẹ̀; nítorí pé nítòótọ́ ni OLÚWA ti rán mi láti sọ ọ̀rọ̀ yìí fún un yín.” 16 Nígbà náà ni àwọn aláṣẹ àti gbogbo àwọn ènìyàn sọ fún àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì pé, “Ẹ má ṣe pa ọkùnrin yìí nítorí ó ti bá wa sọ̀rọ̀ ní orúkọ OLÚWA àwọn ọmọ-ogun.” 17 Lára àwọn àgbàgbà ilẹ̀ náà sì sún síwájú, wọ́n sì sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn náà wí pé, 18 “Mika ti Moreṣeti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ọjọ́ Hesekiah ọba Juda. Ó sọ fún gbogbo ènìyàn Juda pé, ‘Èyí ni ohun tí OLÚWA wí:“ ‘A ó sì fa Sioni tu bí okoJerusalẹmu yóò di òkìtìàlàpà àti òkè ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bíibi gíga igbó.’ 19 Ǹjẹ́ Hesekiah ọba Juda tàbí ẹnikẹ́ni ní Juda pa á bí? Ǹjẹ́ Hesekiah kò bẹ̀rù OLÚWA tí ó sì wá ojúrere rẹ̀? Ǹjẹ́ OLÚWA kò ha a sì yí ìpinnu rẹ̀ padà, tí kò sì mú ibi tí ó ti sọtẹ́lẹ̀ yẹ̀ kúrò lórí wọn? Ibi ni a fẹ́ mú wá sórí ara wa yìí.” 20 (Bákan náà Uriah ọmọ Ṣemaiah láti Kiriati-Jearimu jẹ́ ọkùnrin mìíràn tí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan náà ní orúkọ OLÚWA. Ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan náà sí ìlú náà àti ilẹ̀ yín bí Jeremiah ti ṣe. 21 Nígbà tí ọba Jehoiakimu àti gbogbo àwọn aláṣẹ gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀, ọba ń wá láti pa á: ṣùgbọ́n Uriah gbọ́ èyí, ẹ̀rù bà á, ó sì sálọ sí Ejibiti. 22 Ọba Jehoiakimu rán Elnatani ọmọ Akbori lọ sí Ejibiti pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mìíràn. 23 Wọ́n sì mú Uriah láti Ejibiti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Jehoiakimu; ẹni tí ó fi idà pa, ó sì sọ òkú rẹ̀ sí inú isà òkú àwọn ènìyàn lásán.) 24 Ahikamu ọmọ Ṣafani ń bẹ pẹ̀lú Jeremiah, wọn kò sì fi í lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti pa á.
In Other Versions
Jeremiah 26 in the ANGEFD
Jeremiah 26 in the ANTPNG2D
Jeremiah 26 in the AS21
Jeremiah 26 in the BAGH
Jeremiah 26 in the BBPNG
Jeremiah 26 in the BBT1E
Jeremiah 26 in the BDS
Jeremiah 26 in the BEV
Jeremiah 26 in the BHAD
Jeremiah 26 in the BIB
Jeremiah 26 in the BLPT
Jeremiah 26 in the BNT
Jeremiah 26 in the BNTABOOT
Jeremiah 26 in the BNTLV
Jeremiah 26 in the BOATCB
Jeremiah 26 in the BOATCB2
Jeremiah 26 in the BOBCV
Jeremiah 26 in the BOCNT
Jeremiah 26 in the BOECS
Jeremiah 26 in the BOGWICC
Jeremiah 26 in the BOHCB
Jeremiah 26 in the BOHCV
Jeremiah 26 in the BOHLNT
Jeremiah 26 in the BOHNTLTAL
Jeremiah 26 in the BOICB
Jeremiah 26 in the BOILNTAP
Jeremiah 26 in the BOITCV
Jeremiah 26 in the BOKCV
Jeremiah 26 in the BOKCV2
Jeremiah 26 in the BOKHWOG
Jeremiah 26 in the BOKSSV
Jeremiah 26 in the BOLCB
Jeremiah 26 in the BOLCB2
Jeremiah 26 in the BOMCV
Jeremiah 26 in the BONAV
Jeremiah 26 in the BONCB
Jeremiah 26 in the BONLT
Jeremiah 26 in the BONUT2
Jeremiah 26 in the BOPLNT
Jeremiah 26 in the BOSCB
Jeremiah 26 in the BOSNC
Jeremiah 26 in the BOTLNT
Jeremiah 26 in the BOVCB
Jeremiah 26 in the BPBB
Jeremiah 26 in the BPH
Jeremiah 26 in the BSB
Jeremiah 26 in the CCB
Jeremiah 26 in the CUV
Jeremiah 26 in the CUVS
Jeremiah 26 in the DBT
Jeremiah 26 in the DGDNT
Jeremiah 26 in the DHNT
Jeremiah 26 in the DNT
Jeremiah 26 in the ELBE
Jeremiah 26 in the EMTV
Jeremiah 26 in the ESV
Jeremiah 26 in the FBV
Jeremiah 26 in the FEB
Jeremiah 26 in the GGMNT
Jeremiah 26 in the GNT
Jeremiah 26 in the HARY
Jeremiah 26 in the HNT
Jeremiah 26 in the IRVA
Jeremiah 26 in the IRVB
Jeremiah 26 in the IRVG
Jeremiah 26 in the IRVH
Jeremiah 26 in the IRVK
Jeremiah 26 in the IRVM
Jeremiah 26 in the IRVM2
Jeremiah 26 in the IRVO
Jeremiah 26 in the IRVP
Jeremiah 26 in the IRVT
Jeremiah 26 in the IRVT2
Jeremiah 26 in the IRVU
Jeremiah 26 in the ISVN
Jeremiah 26 in the JSNT
Jeremiah 26 in the KAPI
Jeremiah 26 in the KBT1ETNIK
Jeremiah 26 in the KBV
Jeremiah 26 in the KJV
Jeremiah 26 in the KNFD
Jeremiah 26 in the LBA
Jeremiah 26 in the LBLA
Jeremiah 26 in the LNT
Jeremiah 26 in the LSV
Jeremiah 26 in the MAAL
Jeremiah 26 in the MBV
Jeremiah 26 in the MBV2
Jeremiah 26 in the MHNT
Jeremiah 26 in the MKNFD
Jeremiah 26 in the MNG
Jeremiah 26 in the MNT
Jeremiah 26 in the MNT2
Jeremiah 26 in the MRS1T
Jeremiah 26 in the NAA
Jeremiah 26 in the NASB
Jeremiah 26 in the NBLA
Jeremiah 26 in the NBS
Jeremiah 26 in the NBVTP
Jeremiah 26 in the NET2
Jeremiah 26 in the NIV11
Jeremiah 26 in the NNT
Jeremiah 26 in the NNT2
Jeremiah 26 in the NNT3
Jeremiah 26 in the PDDPT
Jeremiah 26 in the PFNT
Jeremiah 26 in the RMNT
Jeremiah 26 in the SBIAS
Jeremiah 26 in the SBIBS
Jeremiah 26 in the SBIBS2
Jeremiah 26 in the SBICS
Jeremiah 26 in the SBIDS
Jeremiah 26 in the SBIGS
Jeremiah 26 in the SBIHS
Jeremiah 26 in the SBIIS
Jeremiah 26 in the SBIIS2
Jeremiah 26 in the SBIIS3
Jeremiah 26 in the SBIKS
Jeremiah 26 in the SBIKS2
Jeremiah 26 in the SBIMS
Jeremiah 26 in the SBIOS
Jeremiah 26 in the SBIPS
Jeremiah 26 in the SBISS
Jeremiah 26 in the SBITS
Jeremiah 26 in the SBITS2
Jeremiah 26 in the SBITS3
Jeremiah 26 in the SBITS4
Jeremiah 26 in the SBIUS
Jeremiah 26 in the SBIVS
Jeremiah 26 in the SBT
Jeremiah 26 in the SBT1E
Jeremiah 26 in the SCHL
Jeremiah 26 in the SNT
Jeremiah 26 in the SUSU
Jeremiah 26 in the SUSU2
Jeremiah 26 in the SYNO
Jeremiah 26 in the TBIAOTANT
Jeremiah 26 in the TBT1E
Jeremiah 26 in the TBT1E2
Jeremiah 26 in the TFTIP
Jeremiah 26 in the TFTU
Jeremiah 26 in the TGNTATF3T
Jeremiah 26 in the THAI
Jeremiah 26 in the TNFD
Jeremiah 26 in the TNT
Jeremiah 26 in the TNTIK
Jeremiah 26 in the TNTIL
Jeremiah 26 in the TNTIN
Jeremiah 26 in the TNTIP
Jeremiah 26 in the TNTIZ
Jeremiah 26 in the TOMA
Jeremiah 26 in the TTENT
Jeremiah 26 in the UBG
Jeremiah 26 in the UGV
Jeremiah 26 in the UGV2
Jeremiah 26 in the UGV3
Jeremiah 26 in the VBL
Jeremiah 26 in the VDCC
Jeremiah 26 in the YALU
Jeremiah 26 in the YAPE
Jeremiah 26 in the YBVTP
Jeremiah 26 in the ZBP