Jeremiah 48 (BOYCB)

1 Nípa Moabu. Báyìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí:“Ègbé ni fún Nebo nítorí a ó parun.A dójútì Kiriataimu, a sì mú un,ojú yóò ti alágbára, a ó sì fọ́nká. 2 Moabu kò ní ní ìyìn mọ́,ní Heṣboni ni wọn ó pète ìparun rẹ̀,‘Wá, kí a pa orílẹ̀-èdè náà run.’Àti ẹ̀yin òmùgọ̀ ọkùnrin pàápàá ni a ó pa lẹ́nu mọ́,a ó fi idà lé e yín. 3 Gbọ́ igbe ní Horonaimu,igbe ìrora àti ìparun ńlá. 4 Moabu yóò di wíwó palẹ̀;àwọn ọmọdé rẹ̀ yóò kígbe síta. 5 Wọ́n gòkè lọ sí Luhiti,wọ́n ń sọkún kíkorò bí wọ́n ti ń lọ;ní ojú ọ̀nà sí Horonaimuigbe ìrora ìparun ni à ń gbọ́ lọ. 6 Sá! Àsálà fún ẹ̀mí yín;kí ẹ sì dàbí aláìní ní aginjù. 7 Níwọ́n ìgbà tí o gbẹ́kẹ̀lé agbára àti ọrọ̀ rẹ,a ó kó ìwọ náà ní ìgbèkùn,Kemoṣi náà yóò lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùnpẹ̀lú àlùfáà àti àwọn aláṣẹ rẹ̀. 8 Gbogbo ìlú rẹ ni apanirun yóò dojúkọ,ìlú kan kò sì ní le là.Àfonífojì yóò di ahoroàti ilẹ̀ títẹ́ ni a ó run,nítorí tí OLÚWA ti sọ̀rọ̀. 9 Fi iyọ̀ sí Moabu,nítorí yóò ṣègbé,àwọn ìlú rẹ yóò sì di ahoroláìsí ẹni tí yóò gbé inú rẹ̀. 10 “Ìfibú ni fún ẹni tí ó fi ìmẹ́lẹ́ ṣe iṣẹ́ OLÚWA,ìfibú ni fún ẹni tí ó pa idà mọ́ fún ìtàjẹ̀ sílẹ̀. 11 “Moabu ti wà ní ìsinmi láti ìgbà èwe rẹ̀ wábí i ọtí wáìnì lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ rẹ̀,tí a kò dà láti ìgò kan sí èkejìkò tí ì lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn rí.Ó dùn lẹ́nu bí ó ti yẹ,òórùn rẹ̀ kò yí padà. 12 Ṣùgbọ́n ọjọ́ ń bọ̀,” ni OLÚWA wí,“nígbà tí n ó rán àwọn tí ó n da ọtí láti inú àwọn ìgòtí wọ́n ó sì dà á síta;wọn ó sọ àwọn ìgò rẹ̀ di òfo,wọn ó sì fọ́ àwọn ife rẹ̀. 13 Nígbà náà Moabu yóò sì tú u nítorí Kemoṣi,bí ojú ti í ti ilé Israẹlinígbà tí ó gbẹ́kẹ̀lé Beteli. 14 “Báwo ni o ṣe lè sọ pé, ‘Ajagun ni wá,alágbára ní ogun jíjà’? 15 A ó pa Moabu run, a ó sì gba àwọn ìlú rẹ̀;a ó sì dúńbú àwọn arẹwà ọkùnrin rẹ̀,”ni ọba wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLÚWA àwọn ọmọ-ogun. 16 “Ìṣubú Moabu súnmọ́;ìpọ́njú yóò dé kánkán. 17 Ẹ dárò fún, gbogbo ẹ̀yin tí ó yí i kágbogbo ẹ̀yin tí ẹ mọ bí ó ti ní òkìkí tó.Ẹ sọ pé, ‘Báwo ni ọ̀pá agbára rẹtítóbi tí ó sì lógo ṣe fọ́!’ 18 “Sọ̀kalẹ̀ níbi ògo rẹ,kí o sì jókòó ní ilẹ̀ gbígbẹ,ẹ̀yin olùgbé ọmọbìnrin Diboni,nítorí tí ẹni tí ó pa Moabu runyóò dojúkọ ọ́yóò sì pa àwọn ìlú olódi rẹ run. 19 Dúró lẹ́bàá ọ̀nà kí o sì wòran,ìwọ tí ń gbé ní Aroeri.Bí ọkùnrin tí ó sálọ àti obìnrin tí ó ń sá àsálà‘Kí ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀?’ 20 Ojú ti Moabu nítorí tí a wó o lulẹ̀.Ẹ hu, kí ẹ sì kígbe!Ẹ kéde rẹ̀ ní Arnoni pé,a pa Moabu run. 21 Ìdájọ́ ti dé sí àwọn òkè pẹrẹsẹ,sórí Holoni, Jahisa àti Mefaati, 22 sórí Diboni, Nebo àti Beti-Diblataimu, 23 sórí Kiriataimu, Beti-Gamu àti Beti-Meoni, 24 sórí Kerioti àti Bosra,sórí gbogbo ìlú Moabu, nítòsí àti ní ọ̀nà jíjìn. 25 A gé ìwo Moabu kúrò,apá rẹ̀ dá,”ni OLÚWA wí. 26 “Ẹ jẹ́ kí a mú u mutínítorí ó kó ìdọ̀tí bá OLÚWA,jẹ́ kí Moabu lúwẹ̀ẹ́ nínú èébì rẹ̀,kí ó di ẹni ẹ̀gàn. 27 Ǹjẹ́ Israẹli kò di ẹni ẹ̀gàn rẹ?Ǹjẹ́ a kó o pẹ̀lú àwọn olètó bẹ́ẹ̀ tí o ń gbọn orí rẹ̀ pẹ̀lú yẹ̀yẹ́nígbàkígbà bí a bá sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? 28 Kúrò ní àwọn ìlú rẹ, kí o sì máa gbé láàrín àwọn òkúta,ẹ̀yin tí ó ti ń gbé inú ìlú Moabu.Ẹ dàbí i àdàbà tí ó kọ́ ìtẹ́ rẹ̀sí ẹnu ihò. 29 “A ti gbọ́ nípa ìgbéraga Moabu:àti ìwà mo gbọ́n tan rẹ̀àti ìgbéraga ọkàn rẹ̀. 30 Mo mọ àfojúdi rẹ̀, ṣùgbọ́n òfo ni,” ni OLÚWA wí,“ìfọ́nnu rẹ̀ kò lè ṣe nǹkan kan. 31 Nítorí náà, mo pohùnréré ẹkún lórí Moabufún àwọn ará Moabu ni mo kígbe lóhùn rara,mo kẹ́dùn fún àwọn ọkùnrin Kiri-Hareseti. 32 Mo sọkún fún ọ bí Jaseri ṣe sọkúnìwọ àjàrà Sibma.Ẹ̀ka rẹ tẹ̀ títí dé Òkun,wọn dé Òkun Jaseri.Ajẹnirun ti kọlu èso rẹ,ìkórè èso àjàrà rẹ. 33 Ayọ̀ àti ìdùnnú ti kúrònínú ọgbà àjàrà àti oko Moabu.Mo dá ọwọ́ ṣíṣàn ọtí wáìnì dúró lọ́dọ̀ olùfúntí;kò sí ẹni tí ó ń tẹ̀ wọ́n pẹ̀lú igbe ayọ̀.Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igbe wà,wọn kì í ṣe igbe ti ayọ̀. 34 “Ohùn igbe wọn gòkèláti Heṣboni dé Eleale àti Jahasi,láti Soari títí dé Horonaimu àti Eglati-Ṣeliṣi,nítorí àwọn omi Nimrimu pẹ̀lú yóò gbẹ. 35 Ní ti Moabu ni èmi yóò ti fi òpin síẹni tí ó rú ẹbọ ní ibí gígaàti ẹni tí ń sun tùràrí fún òrìṣà rẹ̀,”ni OLÚWA wí. 36 “Nítorí náà ọkàn mi ró fún Moabu bí fèrè,ọkàn mi ró bí fèrè fún àwọn ọkùnrin Kiri-Hareseti.Nítorí ìṣúra tí ó kójọ ṣègbé. 37 Gbogbo orí ni yóò pá,gbogbo irùngbọ̀n ni a ó gé kúrò,gbogbo ọwọ́ ni a sá lọ́gbẹ́,àti aṣọ ọ̀fọ̀ ní gbogbo ẹ̀gbẹ́. 38 Ẹkún ńlá ní yóò wà lórí gbogbo òrùlé Moabu,àti ní ìta rẹ̀,nítorí èmi ti fọ́ Moabubí a ti ń fọ́ ohun èlò tí kò wu ni,”ni OLÚWA wí. 39 “Èéṣe tí ẹ fi fọ́ túútúú,tí ẹ sì fi ń pohùnréré ẹkún!Báwo ni Moabu ṣe yíẹ̀yìn padà ní ìtìjú!Moabu ti di ẹni ìtìjú àti ẹ̀gàn àtiìdààmú sí gbogbo àwọn tí ó yìí ká.” 40 Báyìí ni OLÚWA wí:“Wò ó ẹyẹ idì náà ń fò bọ̀ nílẹ̀ó sì na ìyẹ́ rẹ̀ lórí Moabu. 41 Kerioti ni a ó kó lẹ́rú àti ilé agbára ni ó gbà.Ní ọjọ́ náà ọkàn àwọn akọni Moabuyóò dàbí ọkàn obìnrin tí ó ń rọbí. 42 A ó pa Moabu run gẹ́gẹ́ bíorílẹ̀-èdè nítorí pé ó gbéraga sí OLÚWA. 43 Ẹ̀rù àti ọ̀fìn àti okùn dídèń dúró dè yín, ẹ̀yin ènìyàn Moabu,”ní OLÚWA wí. 44 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá fúnẹ̀rù yóò ṣubú sínú ọ̀fìnẹnikẹ́ni tí o bá jáde sítanínú ọ̀fìn ní à ó múnínú okùn dídè nítorí tíèmi yóò mú wá sóríMoabu àní ọdún ìjìyà rẹ,”ní OLÚWA wí. 45 “Ní abẹ́ òjìji Heṣboniàwọn tí ó sá dúró láìní agbára,nítorí iná ti jáde wá láti Heṣboni,àti ọwọ́ iná láti àárín Sihoni,yóò sì jó iwájú orí Moabu run,àti agbárí àwọn ọmọ aláriwo. 46 Ègbé ní fún ọ Moabu!Àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè Kemoṣi ṣègbéa kó àwọn ọmọkùnrin rẹ lọ sí ilẹ̀ àjèjìàti àwọn ọmọbìnrin rẹ lọ sí ìgbèkùn. 47 “Síbẹ̀, èmi yóò dá ìkólọMoabu padà ní ọjọ́ ìkẹyìn,”ni OLÚWA wí.Eléyìí ní ìdájọ́ ìkẹyìn lórí Moabu.

In Other Versions

Jeremiah 48 in the ANGEFD

Jeremiah 48 in the ANTPNG2D

Jeremiah 48 in the AS21

Jeremiah 48 in the BAGH

Jeremiah 48 in the BBPNG

Jeremiah 48 in the BBT1E

Jeremiah 48 in the BDS

Jeremiah 48 in the BEV

Jeremiah 48 in the BHAD

Jeremiah 48 in the BIB

Jeremiah 48 in the BLPT

Jeremiah 48 in the BNT

Jeremiah 48 in the BNTABOOT

Jeremiah 48 in the BNTLV

Jeremiah 48 in the BOATCB

Jeremiah 48 in the BOATCB2

Jeremiah 48 in the BOBCV

Jeremiah 48 in the BOCNT

Jeremiah 48 in the BOECS

Jeremiah 48 in the BOGWICC

Jeremiah 48 in the BOHCB

Jeremiah 48 in the BOHCV

Jeremiah 48 in the BOHLNT

Jeremiah 48 in the BOHNTLTAL

Jeremiah 48 in the BOICB

Jeremiah 48 in the BOILNTAP

Jeremiah 48 in the BOITCV

Jeremiah 48 in the BOKCV

Jeremiah 48 in the BOKCV2

Jeremiah 48 in the BOKHWOG

Jeremiah 48 in the BOKSSV

Jeremiah 48 in the BOLCB

Jeremiah 48 in the BOLCB2

Jeremiah 48 in the BOMCV

Jeremiah 48 in the BONAV

Jeremiah 48 in the BONCB

Jeremiah 48 in the BONLT

Jeremiah 48 in the BONUT2

Jeremiah 48 in the BOPLNT

Jeremiah 48 in the BOSCB

Jeremiah 48 in the BOSNC

Jeremiah 48 in the BOTLNT

Jeremiah 48 in the BOVCB

Jeremiah 48 in the BPBB

Jeremiah 48 in the BPH

Jeremiah 48 in the BSB

Jeremiah 48 in the CCB

Jeremiah 48 in the CUV

Jeremiah 48 in the CUVS

Jeremiah 48 in the DBT

Jeremiah 48 in the DGDNT

Jeremiah 48 in the DHNT

Jeremiah 48 in the DNT

Jeremiah 48 in the ELBE

Jeremiah 48 in the EMTV

Jeremiah 48 in the ESV

Jeremiah 48 in the FBV

Jeremiah 48 in the FEB

Jeremiah 48 in the GGMNT

Jeremiah 48 in the GNT

Jeremiah 48 in the HARY

Jeremiah 48 in the HNT

Jeremiah 48 in the IRVA

Jeremiah 48 in the IRVB

Jeremiah 48 in the IRVG

Jeremiah 48 in the IRVH

Jeremiah 48 in the IRVK

Jeremiah 48 in the IRVM

Jeremiah 48 in the IRVM2

Jeremiah 48 in the IRVO

Jeremiah 48 in the IRVP

Jeremiah 48 in the IRVT

Jeremiah 48 in the IRVT2

Jeremiah 48 in the IRVU

Jeremiah 48 in the ISVN

Jeremiah 48 in the JSNT

Jeremiah 48 in the KAPI

Jeremiah 48 in the KBT1ETNIK

Jeremiah 48 in the KBV

Jeremiah 48 in the KJV

Jeremiah 48 in the KNFD

Jeremiah 48 in the LBA

Jeremiah 48 in the LBLA

Jeremiah 48 in the LNT

Jeremiah 48 in the LSV

Jeremiah 48 in the MAAL

Jeremiah 48 in the MBV

Jeremiah 48 in the MBV2

Jeremiah 48 in the MHNT

Jeremiah 48 in the MKNFD

Jeremiah 48 in the MNG

Jeremiah 48 in the MNT

Jeremiah 48 in the MNT2

Jeremiah 48 in the MRS1T

Jeremiah 48 in the NAA

Jeremiah 48 in the NASB

Jeremiah 48 in the NBLA

Jeremiah 48 in the NBS

Jeremiah 48 in the NBVTP

Jeremiah 48 in the NET2

Jeremiah 48 in the NIV11

Jeremiah 48 in the NNT

Jeremiah 48 in the NNT2

Jeremiah 48 in the NNT3

Jeremiah 48 in the PDDPT

Jeremiah 48 in the PFNT

Jeremiah 48 in the RMNT

Jeremiah 48 in the SBIAS

Jeremiah 48 in the SBIBS

Jeremiah 48 in the SBIBS2

Jeremiah 48 in the SBICS

Jeremiah 48 in the SBIDS

Jeremiah 48 in the SBIGS

Jeremiah 48 in the SBIHS

Jeremiah 48 in the SBIIS

Jeremiah 48 in the SBIIS2

Jeremiah 48 in the SBIIS3

Jeremiah 48 in the SBIKS

Jeremiah 48 in the SBIKS2

Jeremiah 48 in the SBIMS

Jeremiah 48 in the SBIOS

Jeremiah 48 in the SBIPS

Jeremiah 48 in the SBISS

Jeremiah 48 in the SBITS

Jeremiah 48 in the SBITS2

Jeremiah 48 in the SBITS3

Jeremiah 48 in the SBITS4

Jeremiah 48 in the SBIUS

Jeremiah 48 in the SBIVS

Jeremiah 48 in the SBT

Jeremiah 48 in the SBT1E

Jeremiah 48 in the SCHL

Jeremiah 48 in the SNT

Jeremiah 48 in the SUSU

Jeremiah 48 in the SUSU2

Jeremiah 48 in the SYNO

Jeremiah 48 in the TBIAOTANT

Jeremiah 48 in the TBT1E

Jeremiah 48 in the TBT1E2

Jeremiah 48 in the TFTIP

Jeremiah 48 in the TFTU

Jeremiah 48 in the TGNTATF3T

Jeremiah 48 in the THAI

Jeremiah 48 in the TNFD

Jeremiah 48 in the TNT

Jeremiah 48 in the TNTIK

Jeremiah 48 in the TNTIL

Jeremiah 48 in the TNTIN

Jeremiah 48 in the TNTIP

Jeremiah 48 in the TNTIZ

Jeremiah 48 in the TOMA

Jeremiah 48 in the TTENT

Jeremiah 48 in the UBG

Jeremiah 48 in the UGV

Jeremiah 48 in the UGV2

Jeremiah 48 in the UGV3

Jeremiah 48 in the VBL

Jeremiah 48 in the VDCC

Jeremiah 48 in the YALU

Jeremiah 48 in the YAPE

Jeremiah 48 in the YBVTP

Jeremiah 48 in the ZBP