Jeremiah 6 (BOYCB)

1 “Ẹ̀yin ènìyàn Benjamini, sá sí ibi ààbò!Ẹ sá kúrò ní Jerusalẹmu.Ẹ fọn fèrè ní Tekoa!Kí ẹ gbé àmì sókè lórí Beti-Hakeremu!Nítorí àjálù farahàn láti àríwá,àní ìparun tí ó lágbára. 2 Èmi yóò pa ọmọbìnrin Sioni run,tí ó jẹ́ arẹwà àti ẹlẹgẹ́. 3 Olùṣọ́-àgùntàn pẹ̀lú agbo wọn yóò gbóguntì wọ́n.Wọn yóò pa àgọ́ yí wọn ká,olúkúlùkù yóò máa jẹ ní ilé rẹ̀.” 4 “Ẹ ya ará yín sí mímọ́ láti bá a jagun!Dìde, kí a kọlù ú ní ìgbà ọ̀sán!Ṣùgbọ́n ó ṣe, nítorí ọjọ́ lọ tán,ọjọ́ alẹ́ náà sì gùn sí i. 5 Nítorí náà, ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a kọlù ú ní àṣálẹ́kí a sì ba odi alágbára rẹ̀ jẹ́.” 6 Èyí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run Àwọn ọmọ-ogun wí:“Ẹ ké àwọn igi náà lulẹ̀kí ẹ sì mọ odi ààbò yí Jerusalẹmu ká.Èyí ni ìlú títóbi tí a ó bẹ̀wò,nítorí pé ó kún fún ìninilára. 7 Gẹ́gẹ́ bí kànga ṣe ń da omi inú rẹ̀ sílẹ̀,náà ni ó ń tú ìwà búburú rẹ̀ jáde.Ìwà ipá àti ìparun ń tún pariwo nínú rẹ̀;nígbà gbogbo ni àìsàn àti ọgbẹ́ rẹ̀ ń wà níwájú mi. 8 Ìwọ Jerusalẹmu, gba ìkìlọ̀,kí Èmi kí ó má ba à lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ,kí n sì sọ ilẹ̀ rẹ di ahoro,tí kò ní ní olùgbé.” 9 Èyí ni ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí:“Jẹ́ kí wọn pèsè ìyókù Israẹliní tónítóní bí àjàrà;na ọwọ́ rẹ sí àwọn ẹ̀ka nì lẹ́ẹ̀kan sí igẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ti í kó èso àjàrà jọ.” 10 Ta ni ẹni tí mo lè bá sọ̀rọ̀ àti tí mo lè fún ní ìmọ̀ràn?Ta ni yóò tẹ́tí sílẹ̀ sí mi?Etí wọn ti di,nítorí náà wọn kò lè gbọ́.Ọ̀rọ̀ OLÚWA, jẹ́ ohun búburú sí wọn,wọn kò sì ní inú dídùn nínú rẹ̀. 11 Èmi kún fún ìbínú OLÚWA,èmi kò sì le è pa á mọ́ra. “Tú u sí orí àwọn ọmọ ńigboro,àti sórí àwọn ọmọkùnrin tí wọn kó ra wọn jọ pọ̀,àti ọkọ àti aya ni a ò mú sínú rẹ̀,àti àwọn arúgbó tí ó ní ọjọ́ kíkún lórí. 12 Ilé wọn o sì di ti ẹlòmíràn,oko wọn àti àwọn aya wọn,nígbà tí èmi bá na ọwọ́ misí àwọn olùgbé ilẹ̀ náà,”ni OLÚWA wí. 13 “Láti orí ẹni tí ó kéré sí orí ẹni tí ó tóbi ju,gbogbo wọn ni ó sì ní ojúkòkòrò fún èrè,àwọn wòlíì àti àlùfáà lápapọ̀sì kún fún ẹ̀tàn. 14 Wọ́n sì ń wo ọgbẹ́ àwọn ènìyànmi bí ẹni pé kò tó nǹkan.Wọ́n ń wí pé, ‘Àlàáfíà, Àlàáfíà,’nígbà tí kò sì sí àlàáfíà. 15 Ojú ha a tì wọ́n nítorí ìwà ìríra wọn bí?Rárá, wọn kò ní ìtìjú mọ́,wọn kò tilẹ̀ ní oorun ìtìjú.Nítorí náà, wọn ó ṣubú láàrín àwọn tó ṣubú,a ó sì ké wọn lulẹ̀ nígbà tí mo bá bẹ̀ wọ́n wò,”ni OLÚWA wí. 16 Èyí ni ohun tí OLÚWA wí:“Ẹ dúró sí ìkóríta, kí ẹ sì wò,ẹ béèrè fún ọ̀nà àtijọ́,ẹ béèrè ọ̀nà dáradára nì, kí ẹ rìn nínú rẹ,ẹ̀yin yóò sì rí ìsinmi fún ọkàn yín.Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa kì yóò rìn nínú rẹ̀.’ 17 Èmi yan olùṣọ́ fún un yín,mo sì wí pé:‘Tẹ́tí sí dídún fèrè náà,’ẹ̀yìn wí pé, ‘Àwa kì yóò tẹ́tí sílẹ̀.’ 18 Nítorí náà, gbọ́ ẹ̀yin orílẹ̀-èdè;kíyèsi, kí ẹ sì jẹ́ ẹlẹ́rìí,ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí wọn. 19 Gbọ́, ìwọ ayé!Mò ń mú ìparun bọ̀ sórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí,èso ìrò inú wọn,nítorí wọn kò fi etí sí ọ̀rọ̀ mi,wọ́n sì ti kọ òfin mi sílẹ̀. 20 Èrè wo ni ó wà fún mi nínú tùràrí láti Ṣeba wá,tàbí èso dáradára láti ilẹ̀ jíjìn réré?Ẹbọ sísun yín kò ṣe ìtẹ́wọ́gbà,ọrẹ yín kò sì wù mí.” 21 Nítorí náà, èyí ni ohun tí OLÚWA wí:“Èmi yóò gbé ohun ìdènà síwájú àwọn ènìyàn wọ̀nyí.Àwọn baba àti ọmọ yóò jùmọ̀ ṣubú lù wọ́n,àwọn aládùúgbò àti ọ̀rẹ́ yóò ṣègbé.” 22 Báyìí ni OLÚWA wí:“Wò ó, àwọn ọmọ-ogun ń bọ̀ wá láti ilẹ̀ àríwá,a ó sì gbé orílẹ̀-èdè ńlá dìdeláti òpin ayé wá. 23 Wọ́n sì dìmọ́ra pẹ̀lú ọrun àti ọ̀kọ̀,wọ́n jẹ́ ẹni ibi, wọn kò sì ní àánú.Wọ́n ń hó bí omi Òkun,bí wọ́n ti ṣe ń gun àwọn ẹṣin wọn lọ;wọ́n sì wá bí ọkùnrin tí yóò jà ọ́ lógun,ìwọ ọmọbìnrin Sioni.” 24 Àwa ti gbọ́ ìròyìn nípa wọn,ọwọ́ wa sì di rírọ, ìrora sì mú wabí obìnrin tí ń rọbí. 25 Má ṣe jáde lọ sí orí pápátàbí kí o máa rìn ní àwọn ojú ọ̀nà,nítorí ọ̀tá náà ní idà,ìpayà sì wà níbi gbogbo. 26 Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbé aṣọ ọ̀fọ̀ wọ̀,kí ẹ sì sùn nínú eérú,ẹ ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú ìpohùnréré ẹkúngẹ́gẹ́ bí i lórí ọmọkùnrin yín kan ṣoṣonítorí pé lójijì ni àwọn apanirun yóò kọlù wá. 27 “Èmi ti fi ẹ́ ṣe ẹni tí yóò máa yọ́irú àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bi irin tútù,kí wọn kí ó lè ṣe àkíyèsí,kí ó sì dán ọ̀nà wọn wò. 28 Ọlọ́tẹ̀ tí ọkàn rẹ̀ le ní gbogbo wọn.Wọ́n ń lọ káàkiri láti sọ̀rọ̀-òdì.Wọ́n jẹ́ idẹ àti irin,wọ́n sì kún fún ìwà ìbàjẹ́. 29 Ewìrì a fẹ́ná kíkankíkan,kí ó lè yọ́ òjé,ẹni tí ń yọ́ ọ ń yọ́ ọ lásán;a kò si ya ènìyàn búburú kúrò. 30 A pè wọ́n ní fàdákà tí a kọ̀sílẹ̀,nítorí OLÚWA ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀.”

In Other Versions

Jeremiah 6 in the ANGEFD

Jeremiah 6 in the ANTPNG2D

Jeremiah 6 in the AS21

Jeremiah 6 in the BAGH

Jeremiah 6 in the BBPNG

Jeremiah 6 in the BBT1E

Jeremiah 6 in the BDS

Jeremiah 6 in the BEV

Jeremiah 6 in the BHAD

Jeremiah 6 in the BIB

Jeremiah 6 in the BLPT

Jeremiah 6 in the BNT

Jeremiah 6 in the BNTABOOT

Jeremiah 6 in the BNTLV

Jeremiah 6 in the BOATCB

Jeremiah 6 in the BOATCB2

Jeremiah 6 in the BOBCV

Jeremiah 6 in the BOCNT

Jeremiah 6 in the BOECS

Jeremiah 6 in the BOGWICC

Jeremiah 6 in the BOHCB

Jeremiah 6 in the BOHCV

Jeremiah 6 in the BOHLNT

Jeremiah 6 in the BOHNTLTAL

Jeremiah 6 in the BOICB

Jeremiah 6 in the BOILNTAP

Jeremiah 6 in the BOITCV

Jeremiah 6 in the BOKCV

Jeremiah 6 in the BOKCV2

Jeremiah 6 in the BOKHWOG

Jeremiah 6 in the BOKSSV

Jeremiah 6 in the BOLCB

Jeremiah 6 in the BOLCB2

Jeremiah 6 in the BOMCV

Jeremiah 6 in the BONAV

Jeremiah 6 in the BONCB

Jeremiah 6 in the BONLT

Jeremiah 6 in the BONUT2

Jeremiah 6 in the BOPLNT

Jeremiah 6 in the BOSCB

Jeremiah 6 in the BOSNC

Jeremiah 6 in the BOTLNT

Jeremiah 6 in the BOVCB

Jeremiah 6 in the BPBB

Jeremiah 6 in the BPH

Jeremiah 6 in the BSB

Jeremiah 6 in the CCB

Jeremiah 6 in the CUV

Jeremiah 6 in the CUVS

Jeremiah 6 in the DBT

Jeremiah 6 in the DGDNT

Jeremiah 6 in the DHNT

Jeremiah 6 in the DNT

Jeremiah 6 in the ELBE

Jeremiah 6 in the EMTV

Jeremiah 6 in the ESV

Jeremiah 6 in the FBV

Jeremiah 6 in the FEB

Jeremiah 6 in the GGMNT

Jeremiah 6 in the GNT

Jeremiah 6 in the HARY

Jeremiah 6 in the HNT

Jeremiah 6 in the IRVA

Jeremiah 6 in the IRVB

Jeremiah 6 in the IRVG

Jeremiah 6 in the IRVH

Jeremiah 6 in the IRVK

Jeremiah 6 in the IRVM

Jeremiah 6 in the IRVM2

Jeremiah 6 in the IRVO

Jeremiah 6 in the IRVP

Jeremiah 6 in the IRVT

Jeremiah 6 in the IRVT2

Jeremiah 6 in the IRVU

Jeremiah 6 in the ISVN

Jeremiah 6 in the JSNT

Jeremiah 6 in the KAPI

Jeremiah 6 in the KBT1ETNIK

Jeremiah 6 in the KBV

Jeremiah 6 in the KJV

Jeremiah 6 in the KNFD

Jeremiah 6 in the LBA

Jeremiah 6 in the LBLA

Jeremiah 6 in the LNT

Jeremiah 6 in the LSV

Jeremiah 6 in the MAAL

Jeremiah 6 in the MBV

Jeremiah 6 in the MBV2

Jeremiah 6 in the MHNT

Jeremiah 6 in the MKNFD

Jeremiah 6 in the MNG

Jeremiah 6 in the MNT

Jeremiah 6 in the MNT2

Jeremiah 6 in the MRS1T

Jeremiah 6 in the NAA

Jeremiah 6 in the NASB

Jeremiah 6 in the NBLA

Jeremiah 6 in the NBS

Jeremiah 6 in the NBVTP

Jeremiah 6 in the NET2

Jeremiah 6 in the NIV11

Jeremiah 6 in the NNT

Jeremiah 6 in the NNT2

Jeremiah 6 in the NNT3

Jeremiah 6 in the PDDPT

Jeremiah 6 in the PFNT

Jeremiah 6 in the RMNT

Jeremiah 6 in the SBIAS

Jeremiah 6 in the SBIBS

Jeremiah 6 in the SBIBS2

Jeremiah 6 in the SBICS

Jeremiah 6 in the SBIDS

Jeremiah 6 in the SBIGS

Jeremiah 6 in the SBIHS

Jeremiah 6 in the SBIIS

Jeremiah 6 in the SBIIS2

Jeremiah 6 in the SBIIS3

Jeremiah 6 in the SBIKS

Jeremiah 6 in the SBIKS2

Jeremiah 6 in the SBIMS

Jeremiah 6 in the SBIOS

Jeremiah 6 in the SBIPS

Jeremiah 6 in the SBISS

Jeremiah 6 in the SBITS

Jeremiah 6 in the SBITS2

Jeremiah 6 in the SBITS3

Jeremiah 6 in the SBITS4

Jeremiah 6 in the SBIUS

Jeremiah 6 in the SBIVS

Jeremiah 6 in the SBT

Jeremiah 6 in the SBT1E

Jeremiah 6 in the SCHL

Jeremiah 6 in the SNT

Jeremiah 6 in the SUSU

Jeremiah 6 in the SUSU2

Jeremiah 6 in the SYNO

Jeremiah 6 in the TBIAOTANT

Jeremiah 6 in the TBT1E

Jeremiah 6 in the TBT1E2

Jeremiah 6 in the TFTIP

Jeremiah 6 in the TFTU

Jeremiah 6 in the TGNTATF3T

Jeremiah 6 in the THAI

Jeremiah 6 in the TNFD

Jeremiah 6 in the TNT

Jeremiah 6 in the TNTIK

Jeremiah 6 in the TNTIL

Jeremiah 6 in the TNTIN

Jeremiah 6 in the TNTIP

Jeremiah 6 in the TNTIZ

Jeremiah 6 in the TOMA

Jeremiah 6 in the TTENT

Jeremiah 6 in the UBG

Jeremiah 6 in the UGV

Jeremiah 6 in the UGV2

Jeremiah 6 in the UGV3

Jeremiah 6 in the VBL

Jeremiah 6 in the VDCC

Jeremiah 6 in the YALU

Jeremiah 6 in the YAPE

Jeremiah 6 in the YBVTP

Jeremiah 6 in the ZBP