John 14 (BOYCB)

1 “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín kí ó dàrú, ẹ gba Ọlọ́run gbọ́, kí ẹ sì gbà mí gbọ́ pẹ̀lú. 2 Nínú ilé Baba mi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibùgbé ni ó wà, ìbá má ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ìbá tí sọ fún yín. Èmi ń lọ láti pèsè ààyè sílẹ̀ fún yín. 3 Bí mo bá sì lọ láti pèsè ààyè sílẹ̀ fún un yín, èmi ó tún padà wá, èmi ó sì mú yín lọ sọ́dọ̀ èmi tìkára mi; pé níbi tí èmi gbé wà, kí ẹ̀yin lè wà níbẹ̀ pẹ̀lú. 4 Ẹ̀yin mọ ibi tí èmi gbé ń lọ, ẹ sì mọ ọ̀nà náà.” 5 Tomasi wí fún un pé, “Olúwa, a kò mọ ibi tí ìwọ ń lọ, a ó ha ti ṣe mọ ọ̀nà náà?” 6 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi ni ọ̀nà, òtítọ́ àti ìyè, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè wá sọ́dọ̀ Baba, bí kò ṣe nípasẹ̀ mi. 7 Ìbá ṣe pé ẹ̀yin ti mọ̀ mí, ẹ̀yin ìbá ti mọ Baba mi pẹ̀lú, láti ìsinsin yìí lọ ẹ̀yin mọ̀ ọ́n, ẹ sì ti rí i.” 8 Filipi wí fún un pé, “Olúwa, fi Baba náà hàn wá, yóò sì tó fún wa.” 9 Jesu wí fún un pé, “Bí àkókò tí mo bá yín gbé ti tó yìí, ìwọ, kò sì tí ì mọ̀ mí síbẹ̀ Filipi? Ẹni tí ó bá ti rí mi, ó ti rí Baba. Ìwọ ha ti ṣe wí pé, ‘Fi Baba hàn wá!’ 10 Ìwọ kò ha gbàgbọ́ pé, èmi wà nínú Baba, àti pé Baba wà nínú mi? Ọ̀rọ̀ tí èmi ń sọ fún yín, èmi kò dá a sọ; ṣùgbọ́n Baba ti ó wà nínú mi, òun ní ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀. 11 Ẹ gbà mí gbọ́ pé, èmi wà nínú Baba, Baba sì wà nínú mi, bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ gbà mí gbọ́ nítorí àwọn ẹ̀rí iṣẹ́ náà pàápàá! 12 Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, iṣẹ́ tí èmi ń ṣe ni òun yóò ṣe pẹ̀lú; iṣẹ́ tí ó tóbi ju wọ̀nyí lọ ni yóò sì ṣe; nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba. 13 Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá sì béèrè ní orúkọ mi, òun náà ni èmi ó ṣe, kí a lè yin Baba lógo nínú Ọmọ. 14 Bí ẹ̀yin bá béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi, èmi ó ṣe é. 15 “Bí ẹ̀yin bá fẹ́ràn mi, ẹ ó pa òfin mi mọ́. 16 Nígbà náà èmi yóò wá béèrè lọ́wọ́ Baba. Òun yóò sì fún yín ní olùtùnú mìíràn. Olùtùnú náà yóò máa bá yín gbé títí láé. 17 Òun ni Ẹ̀mí òtítọ́. Ayé kò le gbà á. Nítorí ayé kò mọ̀ ọ́n, bẹ́ẹ̀ ni kò rí i rí. Ẹ̀yin mọ̀ ọn nítorí láti ìgbà tí ẹ ti wà pẹ̀lú mí. Òun náà ti wà pẹ̀lú yín. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kan yóò wọ inú yín láti máa gbé ibẹ̀. 18 Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ láìní Olùtùnú, kí ẹ ma dàbí ọmọ tí kò ní òbí. Rárá o! Mo tún ń tọ̀ yín bọ̀. 19 Nígbà díẹ̀ sí i, ayé kì yóò rí mi mọ́; ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò rí mi, nítorí tí èmi wà láààyè, ẹ̀yin yóò wà láààyè pẹ̀lú. 20 Ní ọjọ́ náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi wà nínú Baba mi, àti ẹ̀yin nínú mi, àti èmi nínú yín. 21 Ẹni tí ó bá ní òfin mi, tí ó bá sì ń pa wọ́n mọ́, òun ni ẹni tí ó fẹ́ràn mi, ẹni tí ó bá sì fẹ́ràn mi, a ó fẹ́ràn rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba mi, èmi ó sì fẹ́ràn rẹ̀, èmi ó sì fi ara mi hàn fún un.” 22 Judasi (kì í ṣe Judasi Iskariotu) wí fún un pé, “Olúwa, èéha ti ṣe tí ìwọ ó fi ara rẹ hàn fún àwa, tí kì yóò sì ṣe fún aráyé?” 23 Jesu dáhùn ó sì wí fún un pé, “Bí ẹnìkan bá fẹ́ràn mi, yóò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́. Baba mi yóò sì fẹ́ràn rẹ̀, àwa ó sì tọ̀ ọ́ wá, a ó sì ṣe ibùgbé wa pẹ̀lú rẹ̀. 24 Ẹni tí kò fẹ́ràn mi ni kò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́. Ọ̀rọ̀ tí ẹ̀yin ń gbọ́ kì í ṣe ti èmi, ṣùgbọ́n ti Baba tí ó rán mi. 25 “Nǹkan wọ̀nyí ni èmi ti sọ fún yín, nígbà tí mo ń bá yín gbé. 26 Ṣùgbọ́n Olùtùnú náà, Ẹ̀mí Mímọ́, ẹni tí Baba yóò rán ní orúkọ mi, òun ni yóò kọ́ yín ní ohun gbogbo, yóò sì rán yín létí ohun gbogbo tí mo ti sọ fún yín. 27 Àlàáfíà ni mo fi sílẹ̀ fún yín pé, àlàáfíà mi ni mo fi fún yin, kì í ṣe bí ayé ti fi fún ni. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín dàrú, ẹ má sì jẹ́ kí ó wárìrì. 28 “Ẹ̀yin sá ti gbọ́ bí mo ti wí fún yín pé, ‘Èmi ń lọ, èmi ó sì tọ̀ yín wá.’ Ìbá ṣe pé ẹ̀yin fẹ́ràn mi, ẹ̀yin ìbá yọ̀ nítorí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba; nítorí Baba mi tóbi jù mí lọ. 29 Èmi sì ti sọ fún yín nísinsin yìí kí ó tó ṣẹ, pé nígbà tí ó bá ṣẹ, kí ẹ lè gbàgbọ́. 30 Èmi kì yóò bá yín sọ̀rọ̀ púpọ̀, nítorí ọmọ-aládé ayé yí wá, kò sì ní nǹkan kan lòdì sí mi. 31 Ṣùgbọ́n nítorí kí ayé lè mọ̀ pé èmi fẹ́ràn Baba; gẹ́gẹ́ bí Baba sì ti fi àṣẹ fún mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi ń ṣe. “Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a lọ kúrò níhìn-ín yìí.

In Other Versions

John 14 in the ANGEFD

John 14 in the ANTPNG2D

John 14 in the AS21

John 14 in the BAGH

John 14 in the BBPNG

John 14 in the BBT1E

John 14 in the BDS

John 14 in the BEV

John 14 in the BHAD

John 14 in the BIB

John 14 in the BLPT

John 14 in the BNT

John 14 in the BNTABOOT

John 14 in the BNTLV

John 14 in the BOATCB

John 14 in the BOATCB2

John 14 in the BOBCV

John 14 in the BOCNT

John 14 in the BOECS

John 14 in the BOGWICC

John 14 in the BOHCB

John 14 in the BOHCV

John 14 in the BOHLNT

John 14 in the BOHNTLTAL

John 14 in the BOICB

John 14 in the BOILNTAP

John 14 in the BOITCV

John 14 in the BOKCV

John 14 in the BOKCV2

John 14 in the BOKHWOG

John 14 in the BOKSSV

John 14 in the BOLCB

John 14 in the BOLCB2

John 14 in the BOMCV

John 14 in the BONAV

John 14 in the BONCB

John 14 in the BONLT

John 14 in the BONUT2

John 14 in the BOPLNT

John 14 in the BOSCB

John 14 in the BOSNC

John 14 in the BOTLNT

John 14 in the BOVCB

John 14 in the BPBB

John 14 in the BPH

John 14 in the BSB

John 14 in the CCB

John 14 in the CUV

John 14 in the CUVS

John 14 in the DBT

John 14 in the DGDNT

John 14 in the DHNT

John 14 in the DNT

John 14 in the ELBE

John 14 in the EMTV

John 14 in the ESV

John 14 in the FBV

John 14 in the FEB

John 14 in the GGMNT

John 14 in the GNT

John 14 in the HARY

John 14 in the HNT

John 14 in the IRVA

John 14 in the IRVB

John 14 in the IRVG

John 14 in the IRVH

John 14 in the IRVK

John 14 in the IRVM

John 14 in the IRVM2

John 14 in the IRVO

John 14 in the IRVP

John 14 in the IRVT

John 14 in the IRVT2

John 14 in the IRVU

John 14 in the ISVN

John 14 in the JSNT

John 14 in the KAPI

John 14 in the KBT1ETNIK

John 14 in the KBV

John 14 in the KJV

John 14 in the KNFD

John 14 in the LBA

John 14 in the LBLA

John 14 in the LNT

John 14 in the LSV

John 14 in the MAAL

John 14 in the MBV

John 14 in the MBV2

John 14 in the MHNT

John 14 in the MKNFD

John 14 in the MNG

John 14 in the MNT

John 14 in the MNT2

John 14 in the MRS1T

John 14 in the NAA

John 14 in the NASB

John 14 in the NBLA

John 14 in the NBS

John 14 in the NBVTP

John 14 in the NET2

John 14 in the NIV11

John 14 in the NNT

John 14 in the NNT2

John 14 in the NNT3

John 14 in the PDDPT

John 14 in the PFNT

John 14 in the RMNT

John 14 in the SBIAS

John 14 in the SBIBS

John 14 in the SBIBS2

John 14 in the SBICS

John 14 in the SBIDS

John 14 in the SBIGS

John 14 in the SBIHS

John 14 in the SBIIS

John 14 in the SBIIS2

John 14 in the SBIIS3

John 14 in the SBIKS

John 14 in the SBIKS2

John 14 in the SBIMS

John 14 in the SBIOS

John 14 in the SBIPS

John 14 in the SBISS

John 14 in the SBITS

John 14 in the SBITS2

John 14 in the SBITS3

John 14 in the SBITS4

John 14 in the SBIUS

John 14 in the SBIVS

John 14 in the SBT

John 14 in the SBT1E

John 14 in the SCHL

John 14 in the SNT

John 14 in the SUSU

John 14 in the SUSU2

John 14 in the SYNO

John 14 in the TBIAOTANT

John 14 in the TBT1E

John 14 in the TBT1E2

John 14 in the TFTIP

John 14 in the TFTU

John 14 in the TGNTATF3T

John 14 in the THAI

John 14 in the TNFD

John 14 in the TNT

John 14 in the TNTIK

John 14 in the TNTIL

John 14 in the TNTIN

John 14 in the TNTIP

John 14 in the TNTIZ

John 14 in the TOMA

John 14 in the TTENT

John 14 in the UBG

John 14 in the UGV

John 14 in the UGV2

John 14 in the UGV3

John 14 in the VBL

John 14 in the VDCC

John 14 in the YALU

John 14 in the YAPE

John 14 in the YBVTP

John 14 in the ZBP