Job 21 (BOYCB)
1 Jobu wá dáhùn, ó sì wí pé, 2 “Ẹ tẹ́tí sílẹ̀ dáradára sì àwọn ọ̀rọ̀ mi,kí èyí kí ó jásí ìtùnú fún mi. 3 Ẹ jọ̀wọ́ mi ki èmi sọ̀rọ̀;lẹ́yìn ìgbà ìwọ le máa fi mi ṣẹ̀sín ń ṣo. 4 “Àròyé mi ha ṣe sí ènìyàn bí?Èétise tí ọkàn mi kì yóò fi ṣe àìbalẹ̀? 5 Ẹ wò mí fín, kí ẹnu kí ó sì yà yín,kí ẹ sì fi ọwọ́ lé ẹnu yín. 6 Àní nígbà tí mo rántí, ẹ̀rù bà mí,ìwárìrì sì mú mi lára. 7 Nítorí kí ní ènìyàn búburú fi wà ní ayé,tí wọ́n gbó, àní tí wọ́n di alágbára ní ipa? 8 Irú-ọmọ wọn fi ìdí kalẹ̀ ní ojúwọn pẹ̀lú wọn, àti ọmọ ọmọ wọn ní ojú wọn. 9 Ilé wọn wà láìní ewu àti ẹ̀rù,bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá ìbínú Ọlọ́run kò sí lára wọn. 10 Akọ màlúù wọn a máa gùn, kì í sì tàsé;abo màlúù wọn a máa bí, kì í sì í ṣẹ́yun. 11 Wọn a máa rán àwọn ọmọ wọnwẹ́wẹ́ jáde bí agbo ẹran, àwọn ọmọ wọn a sì máa jo kiri. 12 Wọ́n mú ohun ọ̀nà orin, ìlù àti haapu;wọ́n sì ń yọ̀ sí ohùn fèrè. 13 Wọ́n n lo ọjọ́ wọn nínú ọrọ̀;wọn sì lọ sí ipò òkú ní àlàáfíà. 14 Nítorí náà ni wọ́n ṣe wí fún Ọlọ́run pé, ‘Lọ kúrò lọ́dọ̀ wa!’Nítorí pé wọn kò fẹ́ ìmọ̀ ipa ọ̀nà rẹ. 15 Kí ni Olódùmarè tí àwa ó fi máa sìn in?Èrè kí ni a ó sì jẹ bí àwa ba gbàdúrà sí i? 16 Kíyèsi i, àlàáfíà wọn kò sí nípa ọwọ́ wọn;ìmọ̀ ènìyàn búburú jìnnà sí mi réré. 17 “Ìgbà mélòó mélòó ní a ń pa fìtílà ènìyàn búburú kú?Ìgbà mélòó mélòó ní ìparun wọn dé bá wọn,tí Ọlọ́run sì í máa pín ìbìnújẹ́ nínú ìbínú rẹ̀? 18 Wọ́n dàbí àgékù koríko níwájú afẹ́fẹ́,àti bí ìyàngbò, tí ẹ̀fúùfù ńlá fẹ́ lọ. 19 Ẹ̀yin wí pé, ‘Ọlọ́run to ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jọ fún àwọn ọmọ rẹ̀.’Jẹ́ kí ó san án fún un, yóò sì mọ̀ ọ́n. 20 Ojú rẹ̀ yóò rí ìparun ara rẹ̀,yóò sì máa mu nínú ríru ìbínú Olódùmarè. 21 Nítorí pé àlàáfíà kí ni ó ní nínú ilé rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀,nígbà tí a bá ké iye oṣù rẹ̀ kúrò ní agbede-méjì? 22 “Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni le kọ Ọlọ́run ní ìmọ̀?Òun ní í sá à ń ṣe ìdájọ́ ẹni ibi gíga. 23 Ẹnìkan a kú nínú pípé agbára rẹ̀,ó wà nínú ìrora àti ìdákẹ́ pátápátá. 24 Ọpọ́n rẹ̀ kún fún omi ọmú,egungun rẹ̀ sì tutù fún ọ̀rá. 25 Ẹlòmíràn a sì kú nínú kíkorò ọkàn rẹ̀,tí kò sì fi inú dídùn jẹun. 26 Wọ́n o dùbúlẹ̀ bákan náà nínú erùpẹ̀,kòkòrò yóò sì ṣùbò wọ́n. 27 “Kíyèsi i, èmi mọ̀ èrò inú yín àtiàrékérekè ọkàn yín láti ṣe ìlòdì sí mi. 28 Nítorí tí ẹ̀yin wí pé, ‘Níbo ní ilé ọmọ-aládé,àti níbo ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú nì gbé wà?’ 29 Ẹ̀yin kò béèrè lọ́wọ́ àwọn tí ń kọjá lọ ní ọ̀nà?Ẹ̀yin kò mọ̀ àmì wọn, 30 pé ènìyàn búburú ní a fi pamọ́ fún ọjọ́ ìparun.A ó sì mú wọn jáde ní ọjọ́ ríru ìbínú. 31 Ta ni yóò tako ipa ọ̀nà rẹ̀ lójúkojú,ta ni yóò sì san án padà fún un ní èyí tí ó ti ṣe? 32 Síbẹ̀ a ó sì sin ín ní ọ̀nà ipò òkú,a ó sì máa ṣọ́ ibojì òkú. 33 Ògúlùtu àfonífojì yóò dùn mọ́ ọn.Gbogbo ènìyàn yóò sì máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn,bí ènìyàn àìníye ti lọ síwájú rẹ̀. 34 “Èéha ti ṣe tí ẹ̀yin fi ń tù mí nínú lásán,bí ò ṣe pé ní ìdáhùn yín, àrékérekè wa níbẹ̀!”
In Other Versions
Job 21 in the ANGEFD
Job 21 in the ANTPNG2D
Job 21 in the AS21
Job 21 in the BAGH
Job 21 in the BBPNG
Job 21 in the BBT1E
Job 21 in the BDS
Job 21 in the BEV
Job 21 in the BHAD
Job 21 in the BIB
Job 21 in the BLPT
Job 21 in the BNT
Job 21 in the BNTABOOT
Job 21 in the BNTLV
Job 21 in the BOATCB
Job 21 in the BOATCB2
Job 21 in the BOBCV
Job 21 in the BOCNT
Job 21 in the BOECS
Job 21 in the BOGWICC
Job 21 in the BOHCB
Job 21 in the BOHCV
Job 21 in the BOHLNT
Job 21 in the BOHNTLTAL
Job 21 in the BOICB
Job 21 in the BOILNTAP
Job 21 in the BOITCV
Job 21 in the BOKCV
Job 21 in the BOKCV2
Job 21 in the BOKHWOG
Job 21 in the BOKSSV
Job 21 in the BOLCB
Job 21 in the BOLCB2
Job 21 in the BOMCV
Job 21 in the BONAV
Job 21 in the BONCB
Job 21 in the BONLT
Job 21 in the BONUT2
Job 21 in the BOPLNT
Job 21 in the BOSCB
Job 21 in the BOSNC
Job 21 in the BOTLNT
Job 21 in the BOVCB
Job 21 in the BPBB
Job 21 in the BPH
Job 21 in the BSB
Job 21 in the CCB
Job 21 in the CUV
Job 21 in the CUVS
Job 21 in the DBT
Job 21 in the DGDNT
Job 21 in the DHNT
Job 21 in the DNT
Job 21 in the ELBE
Job 21 in the EMTV
Job 21 in the ESV
Job 21 in the FBV
Job 21 in the FEB
Job 21 in the GGMNT
Job 21 in the GNT
Job 21 in the HARY
Job 21 in the HNT
Job 21 in the IRVA
Job 21 in the IRVB
Job 21 in the IRVG
Job 21 in the IRVH
Job 21 in the IRVK
Job 21 in the IRVM
Job 21 in the IRVM2
Job 21 in the IRVO
Job 21 in the IRVP
Job 21 in the IRVT
Job 21 in the IRVT2
Job 21 in the IRVU
Job 21 in the ISVN
Job 21 in the JSNT
Job 21 in the KAPI
Job 21 in the KBT1ETNIK
Job 21 in the KBV
Job 21 in the KJV
Job 21 in the KNFD
Job 21 in the LBA
Job 21 in the LBLA
Job 21 in the LNT
Job 21 in the LSV
Job 21 in the MAAL
Job 21 in the MBV
Job 21 in the MBV2
Job 21 in the MHNT
Job 21 in the MKNFD
Job 21 in the MNG
Job 21 in the MNT
Job 21 in the MNT2
Job 21 in the MRS1T
Job 21 in the NAA
Job 21 in the NASB
Job 21 in the NBLA
Job 21 in the NBS
Job 21 in the NBVTP
Job 21 in the NET2
Job 21 in the NIV11
Job 21 in the NNT
Job 21 in the NNT2
Job 21 in the NNT3
Job 21 in the PDDPT
Job 21 in the PFNT
Job 21 in the RMNT
Job 21 in the SBIAS
Job 21 in the SBIBS
Job 21 in the SBIBS2
Job 21 in the SBICS
Job 21 in the SBIDS
Job 21 in the SBIGS
Job 21 in the SBIHS
Job 21 in the SBIIS
Job 21 in the SBIIS2
Job 21 in the SBIIS3
Job 21 in the SBIKS
Job 21 in the SBIKS2
Job 21 in the SBIMS
Job 21 in the SBIOS
Job 21 in the SBIPS
Job 21 in the SBISS
Job 21 in the SBITS
Job 21 in the SBITS2
Job 21 in the SBITS3
Job 21 in the SBITS4
Job 21 in the SBIUS
Job 21 in the SBIVS
Job 21 in the SBT
Job 21 in the SBT1E
Job 21 in the SCHL
Job 21 in the SNT
Job 21 in the SUSU
Job 21 in the SUSU2
Job 21 in the SYNO
Job 21 in the TBIAOTANT
Job 21 in the TBT1E
Job 21 in the TBT1E2
Job 21 in the TFTIP
Job 21 in the TFTU
Job 21 in the TGNTATF3T
Job 21 in the THAI
Job 21 in the TNFD
Job 21 in the TNT
Job 21 in the TNTIK
Job 21 in the TNTIL
Job 21 in the TNTIN
Job 21 in the TNTIP
Job 21 in the TNTIZ
Job 21 in the TOMA
Job 21 in the TTENT
Job 21 in the UBG
Job 21 in the UGV
Job 21 in the UGV2
Job 21 in the UGV3
Job 21 in the VBL
Job 21 in the VDCC
Job 21 in the YALU
Job 21 in the YAPE
Job 21 in the YBVTP
Job 21 in the ZBP