Job 34 (BOYCB)

1 Nígbà náà ni Elihu dáhùn, ó sì wí pé, 2 “Ẹ̀yin ọlọ́gbọ́n ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi,kí ẹ sì fi etí sílẹ̀ sí mi ẹ̀yin tí ẹ ní ìmòye. 3 Nítorí pé etí a máa dán ọ̀rọ̀ wò,bí adùn ẹnu ti ń tọ́ oúnjẹ wò. 4 Ẹ jẹ́ kí a mọ òye ohun tí o tọ́ fún ara wa;ẹ jẹ́ kí a mọ ohun tí ó dára láàrín wa. 5 “Nítorí pé Jobu wí pé, ‘Aláìlẹ́ṣẹ̀ ni èmi;Ọlọ́run sì ti gba ìdájọ́ mi lọ. 6 Èmi ha purọ́ sí ẹ̀tọ́ mi bí,bí mo tilẹ̀ jẹ́ aláìjẹ̀bi,ọfà rẹ̀ kò ní àwòtán ọgbẹ́.’ 7 Ọkùnrin wo ni ó dàbí Jobu,tí ń mu ẹ̀gàn bí ẹní mú omi? 8 Tí ń bá àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kẹ́gbẹ́ tí ósì ń bá àwọn ènìyàn búburú rìn. 9 Nítorí ó sá ti wí pé, ‘Èrè kan kò sí fún ènìyàn,tí yóò fi máa ṣe inú dídùn sí Ọlọ́run.’ 10 “Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ fetísílẹ̀ sí mi,ẹ fi etí sí mi ẹ̀yin ènìyàn amòye:Ó di èèwọ̀ fún Ọlọ́run ti ìbá fi hùwà búburú,àti fún Olódùmarè, tí yóò fi ṣe àìṣedéédéé! 11 Nítorí pé ó ń sán fún ènìyàn fún gẹ́gẹ́ bi ohun tí a bá ṣe,yóò sì mú olúkúlùkù kí ó rí gẹ́gẹ́ bí ipa ọ̀nà rẹ̀. 12 Nítòótọ́ Ọlọ́run kì yóò hùwàkiwà;bẹ́ẹ̀ ni Olódùmarè kì yóò yí ìdájọ́ po. 13 Ta ni ó fi ìtọ́jú ayé lé e lọ́wọ́,tàbí ta ni ó fi gbogbo ayé lé e lọ́wọ́? 14 Bí ó bá gbé ayé rẹ̀ lé kìkì ara rẹ̀tí ó sì gba ọkàn rẹ̀ àti ẹ̀mí rẹ̀ sọ́dọ̀ ara rẹ̀, 15 gbogbo ènìyàn ni yóò parun pọ̀,ènìyàn a sì tún padà di erùpẹ̀. 16 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, bí ìwọ bá ní òye,gbọ́ èyí; fetísí ohùn ẹnu mi. 17 Ẹni tí ó kórìíra òtítọ́ ha le ṣe olórí bí?Ìwọ ó ha sì dá olóòótọ́ àti ẹni ńlá lẹ́bi? 18 O ha tọ́ láti wí fún ọba pé, ‘Ènìyàn búburú ní ìwọ,’tàbí fún àwọn ọmọ-aládé pé, ‘Ìkà ni ẹ̀yin,’ 19 mélòó mélòó fún ẹni tí kì í ṣe ojúsàájú àwọn ọmọ-aládétàbí tí kò kà ọlọ́rọ̀ sí ju tálákà lọ,nítorí pé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọn í ṣe? 20 Ní ìṣẹ́jú kan ni wọn ó kú,àwọn ènìyàn á sì di yíyọ́ lẹ́nu láàrín ọ̀gànjọ́, wọn a sì kọjá lọ;a sì mú àwọn alágbára kúrò láìsí ọwọ́ ènìyàn níbẹ̀. 21 “Nítorí pé ojú rẹ̀ ń bẹ ní ipa ọ̀nà ènìyàn,òun sì rí ìrìn rẹ̀ gbogbo. 22 Kò sí ibi òkùnkùn, tàbí òjìji ikú,níbi tí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ yóò gbé sá pamọ́ sí. 23 Nítorí pé òun kò pẹ́ àti kíyèsi ẹnìkan,kí òun kí ó sì mú lọ sínú ìdájọ́ níwájú Ọlọ́run. 24 Òun ó sì fọ́ àwọn alágbára túútúú láìní ìwádìí,a sì fi ẹlòmíràn dípò wọn, 25 nítorí pé ó mọ iṣẹ́ wọn,ó sì yí wọn po ní òru, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n di ìtẹ̀mọ́lẹ̀. 26 Ó kọlù wọ́n nítorí ìwà búburú wọnníbi tí àwọn ẹlòmíràn ti lè rí i, 27 nítorí pé wọ́n padà pẹ̀yìndà sí i,wọn kò sì fiyèsí ipa ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, 28 kí wọn kí ó sì mú igbe ẹkún àwọn tálákà lọ dé ọ̀dọ̀ rẹ̀,òun sì gbọ́ igbe ẹkún aláìní. 29 Ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá dákẹ́ síbẹ̀, ta ni yóò dá lẹ́bi?Nígbà tí ó bá pa ojú rẹ̀ mọ́, ta ni yóò lè rí i?Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe si orílẹ̀-èdè tàbí sí ènìyàn kan ṣoṣo; 30 kí aláìwà bi Ọlọ́run kí ó má bá à jẹ ọbakí wọn kí ó má di ìdẹwò fún ènìyàn. 31 “Nítorí pé ẹnìkan ha lè wí fún Ọlọ́run pé,èmi jẹ̀bi, èmi kò sì ní ṣẹ̀ mọ́? 32 Èyí tí èmi kò rí ìwọ fi kọ́ mibi mo bá sì dẹ́ṣẹ̀ èmi kì yóò ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́. 33 Ǹjẹ́ bí ti inú rẹ̀ ni ki òun ó san ẹ̀ṣẹ̀ padà?Ǹjẹ́ òun yóò san án padà bí ìwọ bá kọ̀ ọ́ láti jẹ́wọ́,ìwọ gbọdọ̀ yan, kì í ṣe èmi.Nítorí náà sọ ohun tí o mọ̀,pẹ̀lúpẹ̀lú ohun tí ìwọ mọ̀, sọ ọ́! 34 “Àwọn ènìyàn amòye yóò wí fún mi,àti pẹ̀lúpẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí í ṣe ọlọ́gbọ́n tí ó sì gbọ́ mi pé, 35 ‘Jobu ti fi àìmọ̀ sọ̀rọ̀,ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ṣe aláìgbọ́n.’ 36 Ìfẹ́ mi ni kí a dán Jobu wò dé òpin,nítorí ìdáhùn rẹ̀ dàbí i ti ènìyàn búburú. 37 Nítorí pe ó fi ìṣọ̀tẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀;ó pàtẹ́wọ́ ní àárín wa,ó sì sọ ọ̀rọ̀ odi púpọ̀ sí Ọlọ́run.”

In Other Versions

Job 34 in the ANGEFD

Job 34 in the ANTPNG2D

Job 34 in the AS21

Job 34 in the BAGH

Job 34 in the BBPNG

Job 34 in the BBT1E

Job 34 in the BDS

Job 34 in the BEV

Job 34 in the BHAD

Job 34 in the BIB

Job 34 in the BLPT

Job 34 in the BNT

Job 34 in the BNTABOOT

Job 34 in the BNTLV

Job 34 in the BOATCB

Job 34 in the BOATCB2

Job 34 in the BOBCV

Job 34 in the BOCNT

Job 34 in the BOECS

Job 34 in the BOGWICC

Job 34 in the BOHCB

Job 34 in the BOHCV

Job 34 in the BOHLNT

Job 34 in the BOHNTLTAL

Job 34 in the BOICB

Job 34 in the BOILNTAP

Job 34 in the BOITCV

Job 34 in the BOKCV

Job 34 in the BOKCV2

Job 34 in the BOKHWOG

Job 34 in the BOKSSV

Job 34 in the BOLCB

Job 34 in the BOLCB2

Job 34 in the BOMCV

Job 34 in the BONAV

Job 34 in the BONCB

Job 34 in the BONLT

Job 34 in the BONUT2

Job 34 in the BOPLNT

Job 34 in the BOSCB

Job 34 in the BOSNC

Job 34 in the BOTLNT

Job 34 in the BOVCB

Job 34 in the BPBB

Job 34 in the BPH

Job 34 in the BSB

Job 34 in the CCB

Job 34 in the CUV

Job 34 in the CUVS

Job 34 in the DBT

Job 34 in the DGDNT

Job 34 in the DHNT

Job 34 in the DNT

Job 34 in the ELBE

Job 34 in the EMTV

Job 34 in the ESV

Job 34 in the FBV

Job 34 in the FEB

Job 34 in the GGMNT

Job 34 in the GNT

Job 34 in the HARY

Job 34 in the HNT

Job 34 in the IRVA

Job 34 in the IRVB

Job 34 in the IRVG

Job 34 in the IRVH

Job 34 in the IRVK

Job 34 in the IRVM

Job 34 in the IRVM2

Job 34 in the IRVO

Job 34 in the IRVP

Job 34 in the IRVT

Job 34 in the IRVT2

Job 34 in the IRVU

Job 34 in the ISVN

Job 34 in the JSNT

Job 34 in the KAPI

Job 34 in the KBT1ETNIK

Job 34 in the KBV

Job 34 in the KJV

Job 34 in the KNFD

Job 34 in the LBA

Job 34 in the LBLA

Job 34 in the LNT

Job 34 in the LSV

Job 34 in the MAAL

Job 34 in the MBV

Job 34 in the MBV2

Job 34 in the MHNT

Job 34 in the MKNFD

Job 34 in the MNG

Job 34 in the MNT

Job 34 in the MNT2

Job 34 in the MRS1T

Job 34 in the NAA

Job 34 in the NASB

Job 34 in the NBLA

Job 34 in the NBS

Job 34 in the NBVTP

Job 34 in the NET2

Job 34 in the NIV11

Job 34 in the NNT

Job 34 in the NNT2

Job 34 in the NNT3

Job 34 in the PDDPT

Job 34 in the PFNT

Job 34 in the RMNT

Job 34 in the SBIAS

Job 34 in the SBIBS

Job 34 in the SBIBS2

Job 34 in the SBICS

Job 34 in the SBIDS

Job 34 in the SBIGS

Job 34 in the SBIHS

Job 34 in the SBIIS

Job 34 in the SBIIS2

Job 34 in the SBIIS3

Job 34 in the SBIKS

Job 34 in the SBIKS2

Job 34 in the SBIMS

Job 34 in the SBIOS

Job 34 in the SBIPS

Job 34 in the SBISS

Job 34 in the SBITS

Job 34 in the SBITS2

Job 34 in the SBITS3

Job 34 in the SBITS4

Job 34 in the SBIUS

Job 34 in the SBIVS

Job 34 in the SBT

Job 34 in the SBT1E

Job 34 in the SCHL

Job 34 in the SNT

Job 34 in the SUSU

Job 34 in the SUSU2

Job 34 in the SYNO

Job 34 in the TBIAOTANT

Job 34 in the TBT1E

Job 34 in the TBT1E2

Job 34 in the TFTIP

Job 34 in the TFTU

Job 34 in the TGNTATF3T

Job 34 in the THAI

Job 34 in the TNFD

Job 34 in the TNT

Job 34 in the TNTIK

Job 34 in the TNTIL

Job 34 in the TNTIN

Job 34 in the TNTIP

Job 34 in the TNTIZ

Job 34 in the TOMA

Job 34 in the TTENT

Job 34 in the UBG

Job 34 in the UGV

Job 34 in the UGV2

Job 34 in the UGV3

Job 34 in the VBL

Job 34 in the VDCC

Job 34 in the YALU

Job 34 in the YAPE

Job 34 in the YBVTP

Job 34 in the ZBP