Joshua 18 (BOYCB)
1 Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli péjọ ní Ṣilo, wọ́n si kọ́ àgọ́ ìpàdé ní ibẹ̀. Gbogbo ilẹ̀ náà sì wà ní abẹ́ àkóso wọn, 2 ṣùgbọ́n ó ku ẹ̀yà méje nínú àwọn ọmọ Israẹli tí kò tí ì gba ogún ìní wọn. 3 Báyìí ni Joṣua sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, “Báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe dúró pẹ́ tó, kí ẹ tó gba ilẹ̀ ìní tí OLÚWA Ọlọ́run àwọn baba yín ti fi fún yín? 4 Ẹ yan àwọn ọkùnrin mẹ́ta nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Èmi yóò rán wọn jáde láti lọ bojú wo ilẹ̀ náà káàkiri, wọn yóò sì ṣe àpèjúwe rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìní ẹni kọ̀ọ̀kan. Nígbà náà ni wọn yóò padà tọ̀ mí wá. 5 Ẹ̀yin yóò sì pín ilẹ̀ náà sí ọ̀nà méje kí Juda dúró sí ilẹ̀ rẹ̀ ni ìhà gúúsù àti ilé Josẹfu ní ilẹ̀ rẹ̀ ní ìhà àríwá. 6 Lẹ́yìn ìgbà tí ẹ bá kọ àpèjúwe ọ̀nà méjèèje ilẹ̀ náà, ẹ mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi ní ibí, èmi ó sì ṣẹ́ kèké fún yín ní iwájú OLÚWA Ọlọ́run wa. 7 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Lefi kò ní ìpín ní àárín yín, nítorí iṣẹ́ àlùfáà. OLÚWA ni ìní wọ́n. Gadi, Reubeni àti ìdajì ẹ̀yà Manase, ti gba ìní wọn ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani. Mose ìránṣẹ́ OLÚWA ti fi fún wọn.” 8 Bí àwọn ọkùnrin náà ti bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn láti fojú díwọ̀n ilẹ̀ náà, Joṣua pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ lọ kí ẹ sì fojú díwọ̀n ilẹ̀ náà káàkiri, kí ẹ sì kọ àpèjúwe rẹ̀. Lẹ́yìn náà kí ẹ padà tọ̀ mí wá, kí èmi kí ò lè ṣẹ́ kèké fún yin ní ibí ní Ṣilo ní iwájú OLÚWA.” 9 Báyìí ni àwọn ọkùnrin náà lọ, wọ́n sì la ilẹ̀ náà já. Wọ́n sì kọ àpèjúwe rẹ̀ sí orí ìwé kíká ní ìlú, ní ọ̀nà méje, wọ́n sì padà tọ Joṣua lọ ní ibùdó ní Ṣilo. 10 Joṣua sì ṣẹ́ gègé fún wọn ní Ṣilo ní iwájú OLÚWA, Joṣua sì pín ilẹ̀ náà fún àwọn Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà wọn ní ibẹ̀. 11 Ìbò náà sì wá sórí ẹ̀yà Benjamini, ní agbo ilé, agbo ilé. Ilẹ̀ ìpín wọn sì wà láàrín ti ẹ̀yà Juda àti Josẹfu. 12 Ní ìhà àríwá ààlà wọn bẹ̀rẹ̀ ní Jordani, ó kọjá lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Jeriko ní ìhà àríwá, ó sì forí lé ìwọ̀-oòrùn sí ìlú òkè, jáde sí aginjù Beti-Afeni. 13 Láti ibẹ̀ ààlà náà tún kọjá lọ sí ìhà gúúsù ní ọ̀nà Lusi (tí í ṣe Beteli) ó sì dé Atarotu-Addari, ní orí òkè tí ó wà ní gúúsù Beti-Horoni. 14 Láti òkè tí ó kọjú sí Beti-Horoni ní gúúsù ààlà náà yà sí gúúsù ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, ó sì jáde sí Kiriati-Baali (tí í ṣe Kiriati-Jearimu), ìlú àwọn ènìyàn Juda. Èyí ni ìhà ìwọ̀-oòrùn. 15 Ìhà gúúsù bẹ̀rẹ̀ ní ìpẹ̀kun Kiriati-Jearimu ní ìwọ̀-oòrùn, ààlà náà wà ní ibi ìsun omi Nefitoa. 16 Ààlà náà lọ sí ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ òkè tí ó kọjú sí àfonífojì Beni-Hinnomu, àríwá àfonífojì Refaimu. O sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí àfonífojì Hinnomu sí apá gúúsù gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ìlú Jebusi, ó sì lọ bẹ́ẹ̀ títí dé En-Rogeli. 17 Nígbà náà ni ó yípo sí ìhà àríwá, ó sì lọ sí Ẹni-Ṣemeṣi, ó tẹ̀síwájú dé Geliloti tí ó kọjú sí òkè Adummimu, ó sì sọ̀kalẹ̀ sí ibi Òkúta Bohani ọmọ Reubeni. 18 Ó tẹ̀síwájú títí dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Beti-Araba, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí aginjù. 19 Nígbà náà ni ó lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Beti-Hogla, ó sì jáde ní àríwá etí bèbè Òkun Iyọ̀, ní ẹnu odò Jordani ní gúúsù. Èyí ni ààlà ti gúúsù. 20 Odò Jordani sí jẹ́ ààlà ní ìhà ìlà-oòrùn.Ìwọ̀nyí ní àwọn ààlà ti ó sàmì sí ìní àwọn ìdílé Benjamini ní gbogbo àwọn àyíká wọn. 21 Ẹ̀yà Benjamini ní agbo ilé, agbo ilé ni àwọn ìlú wọ̀nyí:Jeriko, Beti-Hogla, Emeki-Keṣiṣi, 22 Beti-Araba, Semaraimu, Beteli, 23 Affimu, Para, Ofira 24 Kefari, Ammoni, Ofini àti Geba; àwọn ìlú méjìlá àti ìletò wọn. 25 Gibeoni, Rama, Beeroti, 26 Mispa, Kefira, Mosa, 27 Rekemu, Irpeeli, Tarala, 28 Ṣela, Haelefi, ìlú Jebusi (tí í ṣe Jerusalẹmu), Gibeah àti Kiriati, àwọn ìlú mẹ́rìnlá àti ìletò wọn.Èyí ni ìní Benjamini fún ìdílé rẹ̀.
In Other Versions
Joshua 18 in the ANGEFD
Joshua 18 in the ANTPNG2D
Joshua 18 in the AS21
Joshua 18 in the BAGH
Joshua 18 in the BBPNG
Joshua 18 in the BBT1E
Joshua 18 in the BDS
Joshua 18 in the BEV
Joshua 18 in the BHAD
Joshua 18 in the BIB
Joshua 18 in the BLPT
Joshua 18 in the BNT
Joshua 18 in the BNTABOOT
Joshua 18 in the BNTLV
Joshua 18 in the BOATCB
Joshua 18 in the BOATCB2
Joshua 18 in the BOBCV
Joshua 18 in the BOCNT
Joshua 18 in the BOECS
Joshua 18 in the BOGWICC
Joshua 18 in the BOHCB
Joshua 18 in the BOHCV
Joshua 18 in the BOHLNT
Joshua 18 in the BOHNTLTAL
Joshua 18 in the BOICB
Joshua 18 in the BOILNTAP
Joshua 18 in the BOITCV
Joshua 18 in the BOKCV
Joshua 18 in the BOKCV2
Joshua 18 in the BOKHWOG
Joshua 18 in the BOKSSV
Joshua 18 in the BOLCB
Joshua 18 in the BOLCB2
Joshua 18 in the BOMCV
Joshua 18 in the BONAV
Joshua 18 in the BONCB
Joshua 18 in the BONLT
Joshua 18 in the BONUT2
Joshua 18 in the BOPLNT
Joshua 18 in the BOSCB
Joshua 18 in the BOSNC
Joshua 18 in the BOTLNT
Joshua 18 in the BOVCB
Joshua 18 in the BPBB
Joshua 18 in the BPH
Joshua 18 in the BSB
Joshua 18 in the CCB
Joshua 18 in the CUV
Joshua 18 in the CUVS
Joshua 18 in the DBT
Joshua 18 in the DGDNT
Joshua 18 in the DHNT
Joshua 18 in the DNT
Joshua 18 in the ELBE
Joshua 18 in the EMTV
Joshua 18 in the ESV
Joshua 18 in the FBV
Joshua 18 in the FEB
Joshua 18 in the GGMNT
Joshua 18 in the GNT
Joshua 18 in the HARY
Joshua 18 in the HNT
Joshua 18 in the IRVA
Joshua 18 in the IRVB
Joshua 18 in the IRVG
Joshua 18 in the IRVH
Joshua 18 in the IRVK
Joshua 18 in the IRVM
Joshua 18 in the IRVM2
Joshua 18 in the IRVO
Joshua 18 in the IRVP
Joshua 18 in the IRVT
Joshua 18 in the IRVT2
Joshua 18 in the IRVU
Joshua 18 in the ISVN
Joshua 18 in the JSNT
Joshua 18 in the KAPI
Joshua 18 in the KBT1ETNIK
Joshua 18 in the KBV
Joshua 18 in the KJV
Joshua 18 in the KNFD
Joshua 18 in the LBA
Joshua 18 in the LBLA
Joshua 18 in the LNT
Joshua 18 in the LSV
Joshua 18 in the MAAL
Joshua 18 in the MBV
Joshua 18 in the MBV2
Joshua 18 in the MHNT
Joshua 18 in the MKNFD
Joshua 18 in the MNG
Joshua 18 in the MNT
Joshua 18 in the MNT2
Joshua 18 in the MRS1T
Joshua 18 in the NAA
Joshua 18 in the NASB
Joshua 18 in the NBLA
Joshua 18 in the NBS
Joshua 18 in the NBVTP
Joshua 18 in the NET2
Joshua 18 in the NIV11
Joshua 18 in the NNT
Joshua 18 in the NNT2
Joshua 18 in the NNT3
Joshua 18 in the PDDPT
Joshua 18 in the PFNT
Joshua 18 in the RMNT
Joshua 18 in the SBIAS
Joshua 18 in the SBIBS
Joshua 18 in the SBIBS2
Joshua 18 in the SBICS
Joshua 18 in the SBIDS
Joshua 18 in the SBIGS
Joshua 18 in the SBIHS
Joshua 18 in the SBIIS
Joshua 18 in the SBIIS2
Joshua 18 in the SBIIS3
Joshua 18 in the SBIKS
Joshua 18 in the SBIKS2
Joshua 18 in the SBIMS
Joshua 18 in the SBIOS
Joshua 18 in the SBIPS
Joshua 18 in the SBISS
Joshua 18 in the SBITS
Joshua 18 in the SBITS2
Joshua 18 in the SBITS3
Joshua 18 in the SBITS4
Joshua 18 in the SBIUS
Joshua 18 in the SBIVS
Joshua 18 in the SBT
Joshua 18 in the SBT1E
Joshua 18 in the SCHL
Joshua 18 in the SNT
Joshua 18 in the SUSU
Joshua 18 in the SUSU2
Joshua 18 in the SYNO
Joshua 18 in the TBIAOTANT
Joshua 18 in the TBT1E
Joshua 18 in the TBT1E2
Joshua 18 in the TFTIP
Joshua 18 in the TFTU
Joshua 18 in the TGNTATF3T
Joshua 18 in the THAI
Joshua 18 in the TNFD
Joshua 18 in the TNT
Joshua 18 in the TNTIK
Joshua 18 in the TNTIL
Joshua 18 in the TNTIN
Joshua 18 in the TNTIP
Joshua 18 in the TNTIZ
Joshua 18 in the TOMA
Joshua 18 in the TTENT
Joshua 18 in the UBG
Joshua 18 in the UGV
Joshua 18 in the UGV2
Joshua 18 in the UGV3
Joshua 18 in the VBL
Joshua 18 in the VDCC
Joshua 18 in the YALU
Joshua 18 in the YAPE
Joshua 18 in the YBVTP
Joshua 18 in the ZBP