Leviticus 10 (BOYCB)
1 Nadabu àti Abihu tí í ṣe ọmọ Aaroni sì mú àwo tùràrí kọ̀ọ̀kan, wọ́n fi iná àti tùràrí sínú rẹ̀, wọ́n sì rú iná àjèjì níwájú OLÚWA, èyí tó lòdì sí àṣẹ OLÚWA. 2 Torí èyí, iná jáde láti ọ̀dọ̀ OLÚWA, ó sì jó wọn pa, wọ́n sì kú níwájú OLÚWA. 3 Mose sì sọ fún Aaroni pé, “Ohun tí OLÚWA ń sọ nípa rẹ̀ nìyìí nígbà tó wí pé,“ ‘Ní àárín àwọn tó súnmọ́ mi,Èmi yóò fi ara mi hàn ní mímọ́ojú gbogbo ènìyànNí a ó ti bu ọlá fún mi.’ ”Aaroni sì dákẹ́. 4 Mose pe Miṣaeli àti Elsafani ọmọ Usieli tí í ṣe arákùnrin Aaroni, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ wá, kí ẹ sì gbé àwọn arákùnrin yín jáde kúrò níwájú ibi mímọ́ lọ sí ẹ̀yìn ibùdó.” 5 Wọ́n sì wá gbé wọn, pẹ̀lú ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọn ní ọrùn wọn lọ sí ẹ̀yìn ibùdó bí Mose ti sọ. 6 Mose sọ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù, Eleasari àti Itamari pé, “ẹ má ṣe ṣọ̀fọ̀ nípa ṣíṣe aláìtọ́jú irun yín tàbí kí ẹ ṣí orí yín sílẹ̀, ẹ kò sì gbọdọ̀ ya aṣọ, bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó kùú, OLÚWA yóò sì bínú sí gbogbo ìjọ ènìyàn. Ṣùgbọ́n àwọn ẹbí yín, àti gbogbo ilé Israẹli le è ṣọ̀fọ̀ lórí àwọn tí OLÚWA fi iná parun. 7 Ẹ má ṣe kúrò ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, bí ẹ bá kúrò níbẹ̀, ẹ ó kù ú, nítorí pé òróró ìtasórí OLÚWA wà lórí yín.” Wọ́n sì ṣe bí Mose ti wí. 8 OLÚWA sì sọ fún Aaroni pé. 9 “Ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ̀ kò gbọdọ̀ mu ọtí wáìnì tàbí ọtí líle mìíràn nígbàkígbà tí ẹ bá n lọ inú àgọ́ ìpàdé, bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó kù ú, èyí jẹ́ ìlànà títí láé fún un yín láti ìrandíran. 10 Ẹ gbọdọ̀ mọ ìyàtọ̀ láàrín mímọ́ àti àìmọ́, láàrín èérí àti àìléèérí. 11 Ẹ gbọdọ̀ kọ́ àwọn ara Israẹli ní gbogbo àṣẹ tí OLÚWA fún wọn láti ẹnu Mose.” 12 Mose sì sọ fún Aaroni, Eleasari àti Itamari àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù pé, “Ẹ mú ẹbọ ohun jíjẹ tó ṣẹ́kù láti inú ẹbọ àfinásun sí OLÚWA, kí ẹ jẹ ẹ́ láìní ìwúkàrà nínú, lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ nítorí ó jẹ́ mímọ́ jùlọ. 13 Ẹ jẹ́ ní ibi mímọ́, nítorí pé òun ni ìpín rẹ àti ti àwọn ọmọ rẹ nínú ẹbọ tí a finá sun sí OLÚWA nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe pa á láṣẹ. 14 Ṣùgbọ́n ìwọ àti àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin rẹ le jẹ igẹ̀ ẹran tí a fì níwájú OLÚWA àti itan tí wọ́n gbé síwájú OLÚWA, kí ẹ jẹ wọ́n ní ibi tí a kà sí mímọ́, èyí ni a ti fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpín yín nínú ẹbọ àlàáfíà àwọn ara Israẹli. 15 Itan tí wọ́n mú wá àti igẹ̀ ẹran tí ẹ fì ni ẹ gbọdọ̀ mú wá pẹ̀lú ọ̀rá ẹbọ tí a finá sun láti le è fì wọ́n níwájú OLÚWA bí ẹbọ fífì. Èyí yóò sì jẹ́ ìpín tìrẹ àti ti àwọn ọmọ rẹ nígbà gbogbo bí OLÚWA ṣe pàṣẹ.” 16 Nígbà tí Mose wádìí nípa ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tó sì rí i pé wọ́n ti sun ún, ó bínú sí Eleasari àti Itamari, àwọn ọmọ Aaroni yòókù, ó sì béèrè pé, 17 “Èéṣe tí ẹ kò jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà ní agbègbè ibi mímọ́? Ó jẹ́ mímọ́ jùlọ, a fi fún yín láti lè mú ẹ̀ṣẹ̀ ìjọ ènìyàn kúrò nípa fífi ṣe ètùtù fún wọn níwájú OLÚWA. 18 Níwọ́n ìgbà tí ẹ kò mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sí Ibi Mímọ́, ẹ̀ bá ti jẹ ewúrẹ́ náà ní agbègbè Ibi Mímọ́ bí mo ṣe pa á láṣẹ.” 19 Aaroni sì dá Mose lóhùn pé, “Lónìí tí wọ́n rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ sísun wọn níwájú OLÚWA ni irú èyí tún ṣẹlẹ̀ sí mi. Ǹjẹ́ inú OLÚWA yóò wá dùn bí mo bá jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ lónìí?” 20 Nígbà tí Mose gbọ́ èyí, ọkàn rẹ̀ balẹ̀.
In Other Versions
Leviticus 10 in the ANGEFD
Leviticus 10 in the ANTPNG2D
Leviticus 10 in the AS21
Leviticus 10 in the BAGH
Leviticus 10 in the BBPNG
Leviticus 10 in the BBT1E
Leviticus 10 in the BDS
Leviticus 10 in the BEV
Leviticus 10 in the BHAD
Leviticus 10 in the BIB
Leviticus 10 in the BLPT
Leviticus 10 in the BNT
Leviticus 10 in the BNTABOOT
Leviticus 10 in the BNTLV
Leviticus 10 in the BOATCB
Leviticus 10 in the BOATCB2
Leviticus 10 in the BOBCV
Leviticus 10 in the BOCNT
Leviticus 10 in the BOECS
Leviticus 10 in the BOGWICC
Leviticus 10 in the BOHCB
Leviticus 10 in the BOHCV
Leviticus 10 in the BOHLNT
Leviticus 10 in the BOHNTLTAL
Leviticus 10 in the BOICB
Leviticus 10 in the BOILNTAP
Leviticus 10 in the BOITCV
Leviticus 10 in the BOKCV
Leviticus 10 in the BOKCV2
Leviticus 10 in the BOKHWOG
Leviticus 10 in the BOKSSV
Leviticus 10 in the BOLCB
Leviticus 10 in the BOLCB2
Leviticus 10 in the BOMCV
Leviticus 10 in the BONAV
Leviticus 10 in the BONCB
Leviticus 10 in the BONLT
Leviticus 10 in the BONUT2
Leviticus 10 in the BOPLNT
Leviticus 10 in the BOSCB
Leviticus 10 in the BOSNC
Leviticus 10 in the BOTLNT
Leviticus 10 in the BOVCB
Leviticus 10 in the BPBB
Leviticus 10 in the BPH
Leviticus 10 in the BSB
Leviticus 10 in the CCB
Leviticus 10 in the CUV
Leviticus 10 in the CUVS
Leviticus 10 in the DBT
Leviticus 10 in the DGDNT
Leviticus 10 in the DHNT
Leviticus 10 in the DNT
Leviticus 10 in the ELBE
Leviticus 10 in the EMTV
Leviticus 10 in the ESV
Leviticus 10 in the FBV
Leviticus 10 in the FEB
Leviticus 10 in the GGMNT
Leviticus 10 in the GNT
Leviticus 10 in the HARY
Leviticus 10 in the HNT
Leviticus 10 in the IRVA
Leviticus 10 in the IRVB
Leviticus 10 in the IRVG
Leviticus 10 in the IRVH
Leviticus 10 in the IRVK
Leviticus 10 in the IRVM
Leviticus 10 in the IRVM2
Leviticus 10 in the IRVO
Leviticus 10 in the IRVP
Leviticus 10 in the IRVT
Leviticus 10 in the IRVT2
Leviticus 10 in the IRVU
Leviticus 10 in the ISVN
Leviticus 10 in the JSNT
Leviticus 10 in the KAPI
Leviticus 10 in the KBT1ETNIK
Leviticus 10 in the KBV
Leviticus 10 in the KJV
Leviticus 10 in the KNFD
Leviticus 10 in the LBA
Leviticus 10 in the LBLA
Leviticus 10 in the LNT
Leviticus 10 in the LSV
Leviticus 10 in the MAAL
Leviticus 10 in the MBV
Leviticus 10 in the MBV2
Leviticus 10 in the MHNT
Leviticus 10 in the MKNFD
Leviticus 10 in the MNG
Leviticus 10 in the MNT
Leviticus 10 in the MNT2
Leviticus 10 in the MRS1T
Leviticus 10 in the NAA
Leviticus 10 in the NASB
Leviticus 10 in the NBLA
Leviticus 10 in the NBS
Leviticus 10 in the NBVTP
Leviticus 10 in the NET2
Leviticus 10 in the NIV11
Leviticus 10 in the NNT
Leviticus 10 in the NNT2
Leviticus 10 in the NNT3
Leviticus 10 in the PDDPT
Leviticus 10 in the PFNT
Leviticus 10 in the RMNT
Leviticus 10 in the SBIAS
Leviticus 10 in the SBIBS
Leviticus 10 in the SBIBS2
Leviticus 10 in the SBICS
Leviticus 10 in the SBIDS
Leviticus 10 in the SBIGS
Leviticus 10 in the SBIHS
Leviticus 10 in the SBIIS
Leviticus 10 in the SBIIS2
Leviticus 10 in the SBIIS3
Leviticus 10 in the SBIKS
Leviticus 10 in the SBIKS2
Leviticus 10 in the SBIMS
Leviticus 10 in the SBIOS
Leviticus 10 in the SBIPS
Leviticus 10 in the SBISS
Leviticus 10 in the SBITS
Leviticus 10 in the SBITS2
Leviticus 10 in the SBITS3
Leviticus 10 in the SBITS4
Leviticus 10 in the SBIUS
Leviticus 10 in the SBIVS
Leviticus 10 in the SBT
Leviticus 10 in the SBT1E
Leviticus 10 in the SCHL
Leviticus 10 in the SNT
Leviticus 10 in the SUSU
Leviticus 10 in the SUSU2
Leviticus 10 in the SYNO
Leviticus 10 in the TBIAOTANT
Leviticus 10 in the TBT1E
Leviticus 10 in the TBT1E2
Leviticus 10 in the TFTIP
Leviticus 10 in the TFTU
Leviticus 10 in the TGNTATF3T
Leviticus 10 in the THAI
Leviticus 10 in the TNFD
Leviticus 10 in the TNT
Leviticus 10 in the TNTIK
Leviticus 10 in the TNTIL
Leviticus 10 in the TNTIN
Leviticus 10 in the TNTIP
Leviticus 10 in the TNTIZ
Leviticus 10 in the TOMA
Leviticus 10 in the TTENT
Leviticus 10 in the UBG
Leviticus 10 in the UGV
Leviticus 10 in the UGV2
Leviticus 10 in the UGV3
Leviticus 10 in the VBL
Leviticus 10 in the VDCC
Leviticus 10 in the YALU
Leviticus 10 in the YAPE
Leviticus 10 in the YBVTP
Leviticus 10 in the ZBP