Leviticus 15 (BOYCB)

1 OLÚWA sọ fún Mose àti Aaroni pé, 2 “Ẹ bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀, kí ẹ wí fún wọn pé, ‘Bí ìsunjáde bá ń jáde lára ọkùnrin kan lójú ara, ìsunjáde náà jẹ́ àìmọ́. 3 Yálà ó ń jáde léraléra tàbí ó dúró, èyí yóò sọ ọ́ di aláìmọ́. Báyìí ni ìsunjáde rẹ̀ ṣe le è sọ ọ́ di aláìmọ́: 4 “ ‘Gbogbo ibùsùn tí irú ẹni tí ó ní ìsunjáde náà bá sùn di àìmọ́. 5 Bí ẹnikẹ́ni bá fi ara kan ibùsùn rẹ̀, ó gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀. Yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. 6 Ẹnikẹ́ni tí ó bá jókòó lórí ohunkóhun tí ọkùnrin tí ó ní ìsunjáde bá jókòó le gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, kí ó sì wà láìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. 7 “ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ọkùnrin náà tí ó ní ìsunjáde gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóò sì di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. 8 “ ‘Bí ẹni tí ó ní ìsunjáde bá tu itọ́ sí ẹni tí ó mọ́ lára, ẹni tí ó mọ́ náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀, yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. 9 “ ‘Gàárì ẹranko tí ẹni náà bá gùn yóò di àìmọ́. 10 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ohunkóhun tí ó wà lábẹ́ ọkùnrin náà di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú irú nǹkan bẹ́ẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó wẹ ara rẹ̀. Yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. 11 “ ‘Ẹnikẹ́ni tí ọkùnrin tí ó ní ìsunjáde ní ara rẹ̀ bá fi ara kàn láìfi omi fọ ọwọ́ rẹ̀, gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀. Yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. 12 “ ‘Ìkòkò amọ̀ tí ọkùnrin náà bá fọwọ́ kàn ni kí ẹ fọ́, gbogbo ohun èlò igi tí ó fọwọ́ kàn ni kí ẹ fi omi sàn. 13 “ ‘Ẹnikẹ́ni tí a bá wẹ̀nù kúrò nínú ìsunjáde rẹ̀ gbọdọ̀ ka ọjọ́ méje fún àwọn ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́: kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì fi omi wẹ ara rẹ̀, yóò sì di mímọ́. 14 Ní ọjọ́ kẹjọ kí ó mú àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì, kí ó sì wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé níwájú OLÚWA, kí ó sì kó wọn fún àlùfáà. 15 Kí àlùfáà fi wọ́n rú ẹbọ: ọ̀kan fún ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ọrẹ ẹbọ sísun níwájú OLÚWA ní ipò ọkùnrin náà nítorí ìsunjáde rẹ̀. 16 “ ‘Bí nǹkan ọkùnrin kan bá tú jáde, kí ó wẹ gbogbo ara rẹ̀, kí ó wà ní ipò àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. 17 Yálà àwọ̀ tàbí aṣọ tí nǹkan ọkùnrin bá dà sí lórí ni kí ẹ fọ̀, yóò sì wà ní ipò àìmọ́ di ìrọ̀lẹ́. 18 Bí ọkùnrin kan bá bá obìnrin lòpọ̀ tí nǹkan ọkùnrin sì tú jáde lára rẹ̀. Àwọn méjèèjì gbọdọ̀ fi omi wẹ̀, kí wọ́n sì wà ní ipò àìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. 19 “ ‘Bí obìnrin bá ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀, obìnrin yìí wà ní àìmọ́ títí di ọjọ́ méje. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kàn án yóò wà ní ipò àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. 20 “ ‘Gbogbo ohun tí ó bá sùn lé ní àkókò nǹkan oṣù rẹ̀ di àìmọ́. 21 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ibùsùn rẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀, yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. 22 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ohunkóhun tí ó bá jókòó lé gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. 23 Ìbá à ṣe ibùsùn tàbí ohunkóhun tí ó jókòó lé. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kàn án yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. 24 “ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá a lòpọ̀, tí nǹkan oṣù rẹ̀ sì kàn án lára, yóò jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje, gbogbo ibùsùn tí ọkùnrin náà bá sùn yóò jẹ́ aláìmọ́. 25 “ ‘Bí obìnrin bá ní ìsun ẹ̀jẹ̀ fún ọjọ́ púpọ̀ yálà sí àkókò nǹkan oṣù rẹ̀ tàbí tí nǹkan oṣù rẹ̀ bá kọjá ìgbà tí ó yẹ. Gbogbo ìgbà tí ó bá fi ń ní ìsun ẹ̀jẹ̀ náà ni yóò fi wà ní àìmọ́ gẹ́gẹ́ bí àkókò nǹkan oṣù rẹ̀. 26 Ibùsùn tí ó wù kí ó sùn sí ní gbogbo ìgbà tí ẹ̀jẹ̀ náà ń wá yóò jẹ́ àìmọ́ bí ibùsùn rẹ̀ ṣe jẹ́ ní àkókò nǹkan oṣù rẹ̀. Gbogbo ohun tí ó bá jókòó lé yóò wà ní àìmọ́, gẹ́gẹ́ bí àkókò nǹkan oṣù rẹ̀. 27 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kàn wọ́n yóò wà ní àìmọ́. Ó gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀ kí ó sì wà ní àìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. 28 “ ‘Nígbà tí ó bá di mímọ́ kúrò nínú ìsun rẹ̀, kí ó ka ọjọ́ méje lẹ́yìn náà, a ó kà á sí mímọ́. 29 Ní ọjọ́ kẹjọ kí ó mú àdàbà méjì àti ọmọ ẹyẹlé wá síwájú àlùfáà ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 30 Kí àlùfáà fi ọ̀kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun. Báyìí ni yóò ṣe ètùtù fún un, níwájú OLÚWA fún àìmọ́ ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. 31 “ ‘Ẹ ya ará Israẹli sọ́tọ̀ kúrò nínú ohun tí ó ń sọ wọ́n di aláìmọ́, kí wọ́n má bá a kú nínú àìmọ́ wọn nípa bíba ibùgbé mímọ́ mi jẹ́, èyí tí ó wà láàrín wọn.’ ” 32 Ìwọ̀nyí ni àwọn òfin fún ọkùnrin tí ó ni ìsunjáde fún ẹnikẹ́ni tí a sọ di àìmọ́ nípa ìsunjáde nǹkan ọkùnrin rẹ̀. 33 Fún obìnrin ní nǹkan oṣù rẹ̀, fún ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó ní ìsunjáde, àti fún ọkùnrin tí ó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin tí ó jẹ́ aláìmọ́.

In Other Versions

Leviticus 15 in the ANGEFD

Leviticus 15 in the ANTPNG2D

Leviticus 15 in the AS21

Leviticus 15 in the BAGH

Leviticus 15 in the BBPNG

Leviticus 15 in the BBT1E

Leviticus 15 in the BDS

Leviticus 15 in the BEV

Leviticus 15 in the BHAD

Leviticus 15 in the BIB

Leviticus 15 in the BLPT

Leviticus 15 in the BNT

Leviticus 15 in the BNTABOOT

Leviticus 15 in the BNTLV

Leviticus 15 in the BOATCB

Leviticus 15 in the BOATCB2

Leviticus 15 in the BOBCV

Leviticus 15 in the BOCNT

Leviticus 15 in the BOECS

Leviticus 15 in the BOGWICC

Leviticus 15 in the BOHCB

Leviticus 15 in the BOHCV

Leviticus 15 in the BOHLNT

Leviticus 15 in the BOHNTLTAL

Leviticus 15 in the BOICB

Leviticus 15 in the BOILNTAP

Leviticus 15 in the BOITCV

Leviticus 15 in the BOKCV

Leviticus 15 in the BOKCV2

Leviticus 15 in the BOKHWOG

Leviticus 15 in the BOKSSV

Leviticus 15 in the BOLCB

Leviticus 15 in the BOLCB2

Leviticus 15 in the BOMCV

Leviticus 15 in the BONAV

Leviticus 15 in the BONCB

Leviticus 15 in the BONLT

Leviticus 15 in the BONUT2

Leviticus 15 in the BOPLNT

Leviticus 15 in the BOSCB

Leviticus 15 in the BOSNC

Leviticus 15 in the BOTLNT

Leviticus 15 in the BOVCB

Leviticus 15 in the BPBB

Leviticus 15 in the BPH

Leviticus 15 in the BSB

Leviticus 15 in the CCB

Leviticus 15 in the CUV

Leviticus 15 in the CUVS

Leviticus 15 in the DBT

Leviticus 15 in the DGDNT

Leviticus 15 in the DHNT

Leviticus 15 in the DNT

Leviticus 15 in the ELBE

Leviticus 15 in the EMTV

Leviticus 15 in the ESV

Leviticus 15 in the FBV

Leviticus 15 in the FEB

Leviticus 15 in the GGMNT

Leviticus 15 in the GNT

Leviticus 15 in the HARY

Leviticus 15 in the HNT

Leviticus 15 in the IRVA

Leviticus 15 in the IRVB

Leviticus 15 in the IRVG

Leviticus 15 in the IRVH

Leviticus 15 in the IRVK

Leviticus 15 in the IRVM

Leviticus 15 in the IRVM2

Leviticus 15 in the IRVO

Leviticus 15 in the IRVP

Leviticus 15 in the IRVT

Leviticus 15 in the IRVT2

Leviticus 15 in the IRVU

Leviticus 15 in the ISVN

Leviticus 15 in the JSNT

Leviticus 15 in the KAPI

Leviticus 15 in the KBT1ETNIK

Leviticus 15 in the KBV

Leviticus 15 in the KJV

Leviticus 15 in the KNFD

Leviticus 15 in the LBA

Leviticus 15 in the LBLA

Leviticus 15 in the LNT

Leviticus 15 in the LSV

Leviticus 15 in the MAAL

Leviticus 15 in the MBV

Leviticus 15 in the MBV2

Leviticus 15 in the MHNT

Leviticus 15 in the MKNFD

Leviticus 15 in the MNG

Leviticus 15 in the MNT

Leviticus 15 in the MNT2

Leviticus 15 in the MRS1T

Leviticus 15 in the NAA

Leviticus 15 in the NASB

Leviticus 15 in the NBLA

Leviticus 15 in the NBS

Leviticus 15 in the NBVTP

Leviticus 15 in the NET2

Leviticus 15 in the NIV11

Leviticus 15 in the NNT

Leviticus 15 in the NNT2

Leviticus 15 in the NNT3

Leviticus 15 in the PDDPT

Leviticus 15 in the PFNT

Leviticus 15 in the RMNT

Leviticus 15 in the SBIAS

Leviticus 15 in the SBIBS

Leviticus 15 in the SBIBS2

Leviticus 15 in the SBICS

Leviticus 15 in the SBIDS

Leviticus 15 in the SBIGS

Leviticus 15 in the SBIHS

Leviticus 15 in the SBIIS

Leviticus 15 in the SBIIS2

Leviticus 15 in the SBIIS3

Leviticus 15 in the SBIKS

Leviticus 15 in the SBIKS2

Leviticus 15 in the SBIMS

Leviticus 15 in the SBIOS

Leviticus 15 in the SBIPS

Leviticus 15 in the SBISS

Leviticus 15 in the SBITS

Leviticus 15 in the SBITS2

Leviticus 15 in the SBITS3

Leviticus 15 in the SBITS4

Leviticus 15 in the SBIUS

Leviticus 15 in the SBIVS

Leviticus 15 in the SBT

Leviticus 15 in the SBT1E

Leviticus 15 in the SCHL

Leviticus 15 in the SNT

Leviticus 15 in the SUSU

Leviticus 15 in the SUSU2

Leviticus 15 in the SYNO

Leviticus 15 in the TBIAOTANT

Leviticus 15 in the TBT1E

Leviticus 15 in the TBT1E2

Leviticus 15 in the TFTIP

Leviticus 15 in the TFTU

Leviticus 15 in the TGNTATF3T

Leviticus 15 in the THAI

Leviticus 15 in the TNFD

Leviticus 15 in the TNT

Leviticus 15 in the TNTIK

Leviticus 15 in the TNTIL

Leviticus 15 in the TNTIN

Leviticus 15 in the TNTIP

Leviticus 15 in the TNTIZ

Leviticus 15 in the TOMA

Leviticus 15 in the TTENT

Leviticus 15 in the UBG

Leviticus 15 in the UGV

Leviticus 15 in the UGV2

Leviticus 15 in the UGV3

Leviticus 15 in the VBL

Leviticus 15 in the VDCC

Leviticus 15 in the YALU

Leviticus 15 in the YAPE

Leviticus 15 in the YBVTP

Leviticus 15 in the ZBP