Numbers 20 (BOYCB)
1 Ní oṣù kìn-ín-ní, gbogbo àgbájọ ọmọ Israẹli gúnlẹ̀ sí pápá Sini, wọ́n sì dúró ní Kadeṣi. Níbẹ̀ ni Miriamu kú, wọ́n sì sin ín. 2 Omi kò sí fún ìjọ ènìyàn, àwọn ènìyàn sì kó ara wọn jọ pọ̀ sí Mose àti Aaroni, 3 wọ́n bá Mose jà wọ́n sì wí pé, “Ìbá kúkú sàn kí a kú nígbà tí àwọn arákùnrin ti kú níwájú OLÚWA! 4 Kí ni ó dé tí o sì kó gbogbo ìjọ ènìyàn OLÚWA wá sí aginjù yìí, kí àwa àti àwọn ẹran ọ̀sìn wa bá à kú síbí? 5 Kí ni ó dé tí o fi mú wa gòkè kúrò ní Ejibiti wá sí ibi búburú yìí? Ibi tí kò ní oúnjẹ tàbí igi ọ̀pọ̀tọ́, èso àjàrà tàbí pomegiranate. Bẹ́ẹ̀ ni kò sí omi tí a ó mu níhìn-ín!” 6 Mose àti Aaroni kúrò ní ibi àpéjọ, wọ́n sì lọ dojúbolẹ̀ sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, ògo OLÚWA sì farahàn wọ́n. 7 OLÚWA sọ fún Mose pé, 8 “Mú ọ̀pá, náà kí o sì pe ìjọ àwọn ènìyàn jọ, ìwọ àti Aaroni arákùnrin rẹ, kí ẹ sọ̀rọ̀ sí àpáta náà ní ojú wọn, yóò sì tú omi rẹ̀ jáde, ìwọ ó sì fún ìjọ àti ẹran wọn mu.” 9 Báyìí ni Mose mú ọ̀pá láti iwájú OLÚWA wá, gẹ́gẹ́ bí ó ti pàṣẹ fún un. 10 Òun àti Aaroni pe àwọn ènìyàn jọ sí ojú kan níwájú àpáta, Mose sì sọ fún wọn, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀, àwa kì yóò lè mú omi jáde láti inú àpáta yìí wá bí?” 11 Nígbà náà ni Mose gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ó sì fi ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ lu àpáta lẹ́ẹ̀méjì. Omi sì tú jáde, gbogbo ìjọ ènìyàn àti àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sì mu. 12 Ṣùgbọ́n OLÚWA sọ fún Mose àti Aaroni pé, “Nítorí pé ẹ̀yin kò gbà mí gbọ́ tó láti bu ọlá fún mi níwájú àwọn ọmọ Israẹli, ìwọ kò ní kó àwọn ìjọ ènìyàn yìí dé ilẹ̀ tí mo fún wọn.” 13 Èyí ni omi ti Meriba, níbi tí àwọn ọmọ Israẹli ti bá OLÚWA jà àti ibi tí O ti fi ara rẹ̀ hàn bí ẹni mímọ́ láàrín wọn. 14 Mose sì ránṣẹ́ láti Kadeṣi sí ọba Edomu, wí pé,“Èyí ni nǹkan tí arákùnrin rẹ Israẹli sọ, ìwọ ti mọ̀ nípa gbogbo ìnira, tí ó wá sí orí wa. 15 Àwọn baba ńlá wa sọ̀kalẹ̀ wá sí Ejibiti, a sì gbé ibẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àwọn ará Ejibiti ni wá lára àti àwọn baba wa, 16 ṣùgbọ́n nígbà tí a sọkún sí OLÚWA, ó gbọ́ ẹkún wa, ó sì rán angẹli kan sí wa, ó sì mú wa jáde láti Ejibiti.“Báyìí àwa wà ní Kadeṣi, ìlú tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ilẹ̀ rẹ. 17 Jọ̀wọ́ jẹ́ kí a gba orílẹ̀-èdè rẹ kọjá, àwa kì yóò gba inú oko tàbí ọgbà àjàrà rẹ kọjá, tàbí mu omi láti inú kànga. A ó ma kọjá ní òpópónà ọba, àwa kì yóò yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì títí àwa yóò fi kọjá ní ilẹ̀ rẹ.” 18 Ṣùgbọ́n Edomu dáhùn pé,“Ẹ̀yin kò le gba ibí kọjá; bí ẹ bá dán an wò, a ó dìde ogun sí yín, a ó sì bá yín jà pẹ̀lú idà.” 19 Àwọn ọmọ Israẹli dáhùn pé,“A ó gba ọ̀nà tóóró, bí àwa tàbí ẹran ọ̀sìn wa bá sì mú lára omi rẹ, a ó san owó rẹ̀. A kàn fẹ́ rìn kọjá lórí ilẹ̀ rẹ ni kò sí nǹkan kan mìíràn tí a fẹ́ ṣe.” 20 Wọ́n tún dáhùn wí pé,“Ẹ kò lè kọjá.”Nígbà náà ni Edomu jáde wá láti kọjú ìjà sí wọn pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àti alágbára ọmọ-ogun. 21 Nígbà tí Edomu sì kọ̀ jálẹ̀ láti jẹ́ kí wọn kọjá ní ilẹ̀ wọn, Israẹli yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn. 22 Gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli sì jáde láti Kadeṣi wọ́n sì wá sí orí òkè Hori. 23 Ní orí òkè Hori, ní ẹ̀gbẹ́ ààlà Edomu OLÚWA sọ fún Mose àti Aaroni pé, 24 “Aaroni yóò kú. Kò ní wọ ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn ọmọ Israẹli, nítorí ẹ̀yin méjèèjì ṣe àìgbọ́ràn sí òfin mi níbi omi Meriba. 25 Mú Aaroni àti ọmọ rẹ̀ Eleasari lọ sí orí òkè Hori. 26 Bọ́ aṣọ Aaroni kí o sì gbe wọ ọmọ rẹ̀ Eleasari, nítorí pé Aaroni yóò kú síbẹ̀.” 27 Mose sì ṣe gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ, wọ́n lọ sí orí òkè Hori ní ojú gbogbo ìjọ ènìyàn. 28 Mose bọ́ aṣọ Aaroni ó sì gbe wọ ọmọ rẹ̀ Eleasari, Aaroni sì kú sí orí òkè. Nígbà náà Mose àti Eleasari sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, 29 nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn sì gbọ́ pé Aaroni ti kú, gbogbo ilé Israẹli ṣe ìdárò rẹ̀ fún ọgbọ̀n ọjọ́.
In Other Versions
Numbers 20 in the ANGEFD
Numbers 20 in the ANTPNG2D
Numbers 20 in the AS21
Numbers 20 in the BAGH
Numbers 20 in the BBPNG
Numbers 20 in the BBT1E
Numbers 20 in the BDS
Numbers 20 in the BEV
Numbers 20 in the BHAD
Numbers 20 in the BIB
Numbers 20 in the BLPT
Numbers 20 in the BNT
Numbers 20 in the BNTABOOT
Numbers 20 in the BNTLV
Numbers 20 in the BOATCB
Numbers 20 in the BOATCB2
Numbers 20 in the BOBCV
Numbers 20 in the BOCNT
Numbers 20 in the BOECS
Numbers 20 in the BOGWICC
Numbers 20 in the BOHCB
Numbers 20 in the BOHCV
Numbers 20 in the BOHLNT
Numbers 20 in the BOHNTLTAL
Numbers 20 in the BOICB
Numbers 20 in the BOILNTAP
Numbers 20 in the BOITCV
Numbers 20 in the BOKCV
Numbers 20 in the BOKCV2
Numbers 20 in the BOKHWOG
Numbers 20 in the BOKSSV
Numbers 20 in the BOLCB
Numbers 20 in the BOLCB2
Numbers 20 in the BOMCV
Numbers 20 in the BONAV
Numbers 20 in the BONCB
Numbers 20 in the BONLT
Numbers 20 in the BONUT2
Numbers 20 in the BOPLNT
Numbers 20 in the BOSCB
Numbers 20 in the BOSNC
Numbers 20 in the BOTLNT
Numbers 20 in the BOVCB
Numbers 20 in the BPBB
Numbers 20 in the BPH
Numbers 20 in the BSB
Numbers 20 in the CCB
Numbers 20 in the CUV
Numbers 20 in the CUVS
Numbers 20 in the DBT
Numbers 20 in the DGDNT
Numbers 20 in the DHNT
Numbers 20 in the DNT
Numbers 20 in the ELBE
Numbers 20 in the EMTV
Numbers 20 in the ESV
Numbers 20 in the FBV
Numbers 20 in the FEB
Numbers 20 in the GGMNT
Numbers 20 in the GNT
Numbers 20 in the HARY
Numbers 20 in the HNT
Numbers 20 in the IRVA
Numbers 20 in the IRVB
Numbers 20 in the IRVG
Numbers 20 in the IRVH
Numbers 20 in the IRVK
Numbers 20 in the IRVM
Numbers 20 in the IRVM2
Numbers 20 in the IRVO
Numbers 20 in the IRVP
Numbers 20 in the IRVT
Numbers 20 in the IRVT2
Numbers 20 in the IRVU
Numbers 20 in the ISVN
Numbers 20 in the JSNT
Numbers 20 in the KAPI
Numbers 20 in the KBT1ETNIK
Numbers 20 in the KBV
Numbers 20 in the KJV
Numbers 20 in the KNFD
Numbers 20 in the LBA
Numbers 20 in the LBLA
Numbers 20 in the LNT
Numbers 20 in the LSV
Numbers 20 in the MAAL
Numbers 20 in the MBV
Numbers 20 in the MBV2
Numbers 20 in the MHNT
Numbers 20 in the MKNFD
Numbers 20 in the MNG
Numbers 20 in the MNT
Numbers 20 in the MNT2
Numbers 20 in the MRS1T
Numbers 20 in the NAA
Numbers 20 in the NASB
Numbers 20 in the NBLA
Numbers 20 in the NBS
Numbers 20 in the NBVTP
Numbers 20 in the NET2
Numbers 20 in the NIV11
Numbers 20 in the NNT
Numbers 20 in the NNT2
Numbers 20 in the NNT3
Numbers 20 in the PDDPT
Numbers 20 in the PFNT
Numbers 20 in the RMNT
Numbers 20 in the SBIAS
Numbers 20 in the SBIBS
Numbers 20 in the SBIBS2
Numbers 20 in the SBICS
Numbers 20 in the SBIDS
Numbers 20 in the SBIGS
Numbers 20 in the SBIHS
Numbers 20 in the SBIIS
Numbers 20 in the SBIIS2
Numbers 20 in the SBIIS3
Numbers 20 in the SBIKS
Numbers 20 in the SBIKS2
Numbers 20 in the SBIMS
Numbers 20 in the SBIOS
Numbers 20 in the SBIPS
Numbers 20 in the SBISS
Numbers 20 in the SBITS
Numbers 20 in the SBITS2
Numbers 20 in the SBITS3
Numbers 20 in the SBITS4
Numbers 20 in the SBIUS
Numbers 20 in the SBIVS
Numbers 20 in the SBT
Numbers 20 in the SBT1E
Numbers 20 in the SCHL
Numbers 20 in the SNT
Numbers 20 in the SUSU
Numbers 20 in the SUSU2
Numbers 20 in the SYNO
Numbers 20 in the TBIAOTANT
Numbers 20 in the TBT1E
Numbers 20 in the TBT1E2
Numbers 20 in the TFTIP
Numbers 20 in the TFTU
Numbers 20 in the TGNTATF3T
Numbers 20 in the THAI
Numbers 20 in the TNFD
Numbers 20 in the TNT
Numbers 20 in the TNTIK
Numbers 20 in the TNTIL
Numbers 20 in the TNTIN
Numbers 20 in the TNTIP
Numbers 20 in the TNTIZ
Numbers 20 in the TOMA
Numbers 20 in the TTENT
Numbers 20 in the UBG
Numbers 20 in the UGV
Numbers 20 in the UGV2
Numbers 20 in the UGV3
Numbers 20 in the VBL
Numbers 20 in the VDCC
Numbers 20 in the YALU
Numbers 20 in the YAPE
Numbers 20 in the YBVTP
Numbers 20 in the ZBP