Philippians 2 (BOYCB)
1 Bí ìwọ bá ní ìmúlọ́kànle nítorí pé ìwọ wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi, bi ìtùnú kan bá wà nínú ìfẹ́ rẹ̀, bí ìdàpọ̀ Ẹ̀mí kan bá wà, bí ìyọ́nú àti ìṣeun bá wà, 2 síbẹ̀ ẹ mú ayọ̀ mi kún nínú ìṣọ̀kan yín, nípa ìfẹ́ kan náà, wíwà ní ẹ̀mí kan náà àti ète kan náà. 3 Ẹ má ṣe ohunkóhun nínú ìlépa ara tàbí ògo asán, ṣùgbọ́n ní ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn kí olúkúlùkù ro àwọn ẹlòmíràn sí ẹni ti ó sàn ju òun lọ. 4 Kí olúkúlùkù yín má ṣe ro ohun ti ara rẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n ti ẹlòmíràn pẹ̀lú. 5 Nínú ìbáṣepọ̀ yin pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, ẹ ni irú ìlépa ọkàn náà bí ti Kristi Jesu. 6 Ẹni tí, bí o tilẹ̀ jẹ́ ìrísí Ọlọ́run,kò kà á sí ohun tí ìbá fi ìwọra gbámú láti bá Ọlọ́run dọ́gba. 7 Ṣùgbọ́n ó bọ́ ògo rẹ̀ sílẹ̀,ó sì mú àwọ̀ ìránṣẹ́,a sì ṣe é ni àwòrán ènìyàn. 8 Ó sì wà ní àwòrán ènìyàn,ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀,o sì tẹríba títí de ojú ikú,àní ikú lórí àgbélébùú. 9 Nítorí náà, Ọlọ́run ti gbé e ga sí ipele tí ó ga jùlọ,ó sì ti fi orúkọ kan ti ó borí gbogbo orúkọ fún un, 10 pé ni orúkọ Jesu ni kí gbogbo eékún máa wólẹ̀,ní ọ̀run, àti ní orí ilẹ̀ ayé àti ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé, 11 àti pé kí gbogbo ahọ́n jẹ́wọ́ pé, Jesu Kristi ni Olúwa,fún ògo Ọlọ́run Baba. 12 Nítorí náà ẹ̀yin ará mi, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti ń gbọ́rọ̀ nígbà gbogbo, kì í ṣe nígbà ti mo wà lọ́dọ̀ yín nìkan, ṣùgbọ́n pàápàá nísinsin yìí tí èmi kò sí ni àárín yín, ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà yín yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì, 13 nítorí pé Ọlọ́run ni ó n ṣiṣẹ́ nínú yín, láti fẹ́ àti láti ṣiṣẹ́ fún ète rere rẹ̀. 14 Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láìsí ìkùnsínú àti ìjiyàn. 15 Kí ẹ̀yin lè jẹ́ aláìlẹ́gàn àti oníwà mímọ́, ọmọ Ọlọ́run, aláìlábàwọ́n, láàrín oníwà wíwọ́ àti alárékérekè orílẹ̀-èdè láàrín àwọn ẹni tí a ń rí yín bí ìmọ́lẹ̀ ní ayé. 16 Bí ẹ sì ṣe di ọ̀rọ̀ ìyè mú gírígírí, kí èmi lè ṣògo ni ọjọ́ Kristi pé èmi kò sáré lásán, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì ṣe làálàá lásán. 17 Ṣùgbọ́n, bí a tilẹ̀ ń dà mí bí ọtí-ìrúbọ sórí ẹbọ iṣẹ́ ìsìn ìgbàgbọ́ yín, inú mi dùn, mo sì ń bá gbogbo yín yọ̀ pẹ̀lú. 18 Bákan náà ni kí ẹ̀yin máa yọ̀, kí ẹ sì máa bá mi yọ̀ pẹ̀lú. 19 Mo ni ìrètí nínú Jesu Olúwa, láti rán Timotiu sí yín ni àìpẹ́ yìí, kí èmi pẹ̀lú lè ni ìfọ̀kànbalẹ̀ nígbà tí mo bá gbúròó yín. 20 Nítorí èmi kò ni ẹlòmíràn tí ó dàbí rẹ̀, tí yóò máa fi tinútinú ṣe àníyàn yín. 21 Nítorí gbogbo wọn ni ó tọ́jú nǹkan ti ara wọn, kì í ṣe àwọn nǹkan ti Jesu Kristi. 22 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin mọ̀ pé Timotiu pegedé, gẹ́gẹ́ bí ọmọ lọ́dọ̀ baba rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó sì ti ń bá mi ṣiṣẹ́ pọ̀, nínú iṣẹ́ ìyìnrere. 23 Nítorí náà, mo ní ìrètí láti rán sí yín ní àìpẹ́ tí mo bá wòye bí yóò ti rí fún mi. 24 Ṣùgbọ́n mo ní gbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa, pé èmi tìkára mi pẹ̀lú yóò wá ní àìpẹ́. 25 Mo kà á sí pé n kò lè ṣàìrán Epafiroditu arákùnrin mi sí yín, àti olùbáṣiṣẹ́ pọ̀ mi, àti ọmọ-ogun ẹlẹgbẹ́ mi, ìránṣẹ́ yín pẹ̀lú, tí ẹ rán láti ṣè ránṣẹ́ fún mi nínú àìní mi. 26 Nítorí tí ọkàn rẹ̀ fà sí gbogbo yín, ó sì kún fún ìbànújẹ́, nítorí tí ẹ̀yin gbọ́ pé ó ṣe àìsàn. 27 Nítòótọ́ ni ó ti ṣe àìsàn títí dé ojú ikú, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti ṣàánú fún un; kì í sì í ṣe fún òun nìkan, ṣùgbọ́n fún èmi pẹ̀lú kí èmi má ṣe ni ìbànújẹ́ lórí ìbànújẹ́. 28 Nítorí náà ni mo ṣe ní ìtara láti rán an, pé nígbà tí ẹ̀yin bá sì tún rí i, kí ẹ̀yin lè yọ̀ àti kí ìkáyà sókè mi lè dínkù. 29 Nítorí náà, ẹ fi ayọ̀ púpọ̀ gbà á nínú Olúwa; kí ẹ sì máa bu ọlá fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. 30 Nítorí iṣẹ́ Kristi ni ó ṣe súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ikú, tí ó sì fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wéwu, láti mu àìtó iṣẹ́ ìsìn yín sí mi kún.
In Other Versions
Philippians 2 in the ANGEFD
Philippians 2 in the ANTPNG2D
Philippians 2 in the AS21
Philippians 2 in the BAGH
Philippians 2 in the BBPNG
Philippians 2 in the BBT1E
Philippians 2 in the BDS
Philippians 2 in the BEV
Philippians 2 in the BHAD
Philippians 2 in the BIB
Philippians 2 in the BLPT
Philippians 2 in the BNT
Philippians 2 in the BNTABOOT
Philippians 2 in the BNTLV
Philippians 2 in the BOATCB
Philippians 2 in the BOATCB2
Philippians 2 in the BOBCV
Philippians 2 in the BOCNT
Philippians 2 in the BOECS
Philippians 2 in the BOGWICC
Philippians 2 in the BOHCB
Philippians 2 in the BOHCV
Philippians 2 in the BOHLNT
Philippians 2 in the BOHNTLTAL
Philippians 2 in the BOICB
Philippians 2 in the BOILNTAP
Philippians 2 in the BOITCV
Philippians 2 in the BOKCV
Philippians 2 in the BOKCV2
Philippians 2 in the BOKHWOG
Philippians 2 in the BOKSSV
Philippians 2 in the BOLCB
Philippians 2 in the BOLCB2
Philippians 2 in the BOMCV
Philippians 2 in the BONAV
Philippians 2 in the BONCB
Philippians 2 in the BONLT
Philippians 2 in the BONUT2
Philippians 2 in the BOPLNT
Philippians 2 in the BOSCB
Philippians 2 in the BOSNC
Philippians 2 in the BOTLNT
Philippians 2 in the BOVCB
Philippians 2 in the BPBB
Philippians 2 in the BPH
Philippians 2 in the BSB
Philippians 2 in the CCB
Philippians 2 in the CUV
Philippians 2 in the CUVS
Philippians 2 in the DBT
Philippians 2 in the DGDNT
Philippians 2 in the DHNT
Philippians 2 in the DNT
Philippians 2 in the ELBE
Philippians 2 in the EMTV
Philippians 2 in the ESV
Philippians 2 in the FBV
Philippians 2 in the FEB
Philippians 2 in the GGMNT
Philippians 2 in the GNT
Philippians 2 in the HARY
Philippians 2 in the HNT
Philippians 2 in the IRVA
Philippians 2 in the IRVB
Philippians 2 in the IRVG
Philippians 2 in the IRVH
Philippians 2 in the IRVK
Philippians 2 in the IRVM
Philippians 2 in the IRVM2
Philippians 2 in the IRVO
Philippians 2 in the IRVP
Philippians 2 in the IRVT
Philippians 2 in the IRVT2
Philippians 2 in the IRVU
Philippians 2 in the ISVN
Philippians 2 in the JSNT
Philippians 2 in the KAPI
Philippians 2 in the KBT1ETNIK
Philippians 2 in the KBV
Philippians 2 in the KJV
Philippians 2 in the KNFD
Philippians 2 in the LBA
Philippians 2 in the LBLA
Philippians 2 in the LNT
Philippians 2 in the LSV
Philippians 2 in the MAAL
Philippians 2 in the MBV
Philippians 2 in the MBV2
Philippians 2 in the MHNT
Philippians 2 in the MKNFD
Philippians 2 in the MNG
Philippians 2 in the MNT
Philippians 2 in the MNT2
Philippians 2 in the MRS1T
Philippians 2 in the NAA
Philippians 2 in the NASB
Philippians 2 in the NBLA
Philippians 2 in the NBS
Philippians 2 in the NBVTP
Philippians 2 in the NET2
Philippians 2 in the NIV11
Philippians 2 in the NNT
Philippians 2 in the NNT2
Philippians 2 in the NNT3
Philippians 2 in the PDDPT
Philippians 2 in the PFNT
Philippians 2 in the RMNT
Philippians 2 in the SBIAS
Philippians 2 in the SBIBS
Philippians 2 in the SBIBS2
Philippians 2 in the SBICS
Philippians 2 in the SBIDS
Philippians 2 in the SBIGS
Philippians 2 in the SBIHS
Philippians 2 in the SBIIS
Philippians 2 in the SBIIS2
Philippians 2 in the SBIIS3
Philippians 2 in the SBIKS
Philippians 2 in the SBIKS2
Philippians 2 in the SBIMS
Philippians 2 in the SBIOS
Philippians 2 in the SBIPS
Philippians 2 in the SBISS
Philippians 2 in the SBITS
Philippians 2 in the SBITS2
Philippians 2 in the SBITS3
Philippians 2 in the SBITS4
Philippians 2 in the SBIUS
Philippians 2 in the SBIVS
Philippians 2 in the SBT
Philippians 2 in the SBT1E
Philippians 2 in the SCHL
Philippians 2 in the SNT
Philippians 2 in the SUSU
Philippians 2 in the SUSU2
Philippians 2 in the SYNO
Philippians 2 in the TBIAOTANT
Philippians 2 in the TBT1E
Philippians 2 in the TBT1E2
Philippians 2 in the TFTIP
Philippians 2 in the TFTU
Philippians 2 in the TGNTATF3T
Philippians 2 in the THAI
Philippians 2 in the TNFD
Philippians 2 in the TNT
Philippians 2 in the TNTIK
Philippians 2 in the TNTIL
Philippians 2 in the TNTIN
Philippians 2 in the TNTIP
Philippians 2 in the TNTIZ
Philippians 2 in the TOMA
Philippians 2 in the TTENT
Philippians 2 in the UBG
Philippians 2 in the UGV
Philippians 2 in the UGV2
Philippians 2 in the UGV3
Philippians 2 in the VBL
Philippians 2 in the VDCC
Philippians 2 in the YALU
Philippians 2 in the YAPE
Philippians 2 in the YBVTP
Philippians 2 in the ZBP