Philippians 4 (BOYCB)
1 Nítorí náà ẹ̀yin ará mi olùfẹ́, ti mo sì ń ṣàfẹ́rí gidigidi, ayọ̀ àti adé mi, ẹ dúró ṣinṣin bẹ́ẹ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin olùfẹ́ mi. 2 Èmi ń bẹ̀ Euodia, mo sì ń bẹ Sintike, kí wọn ní inú kan náà nínú Olúwa. 3 Mo sì bẹ̀ yin pẹ̀lú bí alájọru àjàgà mi tòótọ́, ran àwọn obìnrin wọ̀nyí lọ́wọ́, nítorí wọn bá mi ṣiṣẹ́ pọ̀ ní ìfẹ̀gbẹ́-kẹ̀gbẹ́ nínú ìyìnrere, àti Klementi pẹ̀lú, àti àwọn olùbáṣiṣẹ́ mi yòókù pẹ̀lú, orúkọ àwọn tí ń bẹ nínú ìwé ìyè. 4 Ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa nígbà gbogbo: mo sì tún wí pé. Ẹ máa yọ̀. 5 Ẹ jẹ́ ki ìpamọ́ra yín di mímọ́ fún gbogbo ènìyàn, Olúwa ń bẹ nítòsí. 6 Ẹ má ṣe ṣe àníyàn ohunkóhun; ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo, nípa àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa fi ìbéèrè yín hàn fún Ọlọ́run. 7 Àti àlàáfíà Ọlọ́run, tí ó ju ìmòye gbogbo lọ, yóò pa ọkàn àti èrò yín mọ nínú Kristi Jesu. 8 Ní àkótán, ará, ohunkóhun tí í ṣe òtítọ́, ohunkóhun tí í ṣe ọ̀wọ̀, ohunkóhun tí í ṣe títọ́ ohunkóhun tí í ṣe mímọ́, ohunkóhun tí í ṣe fífẹ́, ohunkóhun tí ó ni ìròyìn rere, bí ìwà títọ́ kan bá wà, bí ìyìn kan bá sì wà, ẹ máa gba nǹkan wọ̀nyí rò. 9 Àwọn nǹkan tí ẹ̀yin ti kọ́, tí ẹ̀yin sì ti gbà, tí ẹ̀yin sì ti gbọ́, tí ẹ̀yin sì ti rí lọ́wọ́ mi, ẹ máa ṣe wọ́n: Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì wà pẹ̀lú yín. 10 Èmi yọ̀ gidigidi nínú Olúwa pé, nísinsin yìí, ẹ̀yin tún ti sọjí nínú àníyàn ọkàn yín sí mi, nítòótọ́ ọkàn yín ń fàmọ́ mi ṣùgbọ́n ẹ kò ní àǹfààní tó. 11 Kì í ṣe pé èmi ń sọ nítorí àìní: nítorí pé ni ipòkípò tí mo bá wà, mo tí kọ́ láti ní ìtẹ́lọ́rùn nínú rẹ̀. 12 Mo mọ̀ ohun tí o jẹ láti wa nínú àìní, mo sì mọ ohun tí ó jẹ láti ni lọ́pọ̀lọ́pọ̀. Nínú ohunkóhun àti nínú ohun gbogbo mo ti kọ́ àṣírí láti máa jẹ́ àjẹyó tàbí láti wà ni àìjẹun, láti máa ni ànító àti láti ṣe aláìní. 13 Èmi le ṣe ohun gbogbo nínú Kristi ẹni ti ń fi agbára fún mi. 14 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ṣeun gidigidi ní ti pé ẹ̀yin ṣe alábápín nínú ìpọ́njú mi. 15 Ẹ̀yin pàápàá sì mọ̀ pẹ̀lú, ẹ̀yin ará Filipi, pé ni ìbẹ̀rẹ̀ ìyìnrere, nígbà tí mo kúrò ni Makedonia, kò sí ìjọ kan ti ó bá mi ń ṣe alábápín ní ti gbígbà àti fífún ni, bí kò ṣe ẹ̀yin nìkan ṣoṣo. 16 Nítorí ní Tẹsalonika ẹ̀yin fi nǹkan ránṣẹ́, lẹ́ẹ̀kan fún àìní mi. 17 Kì í ṣe nítorí ti èmi ń fẹ́ ẹ̀bùn náà, ṣùgbọ́n èmi ń fẹ́ èso ti yóò máa di púpọ̀ nítorí yín. 18 Ṣùgbọ́n mo ní ohun gbogbo, mo sì ti di púpọ̀, mo sì tún ni lọ́pọ̀lọ́pọ̀ nígbà ti mo tí gba nǹkan wọ̀nyí lọ́wọ́ Epafiroditu tí a ti rán wá láti lọ́dọ̀ yín, ọrẹ olóòórùn dídùn, ẹbọ ìtẹ́wọ́gbà, tì í ṣe inú dídùn gidigidi sí Ọlọ́run. 19 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run mi yóò pèsè ní kíkún fún gbogbo àìní yín, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú ògo nínú Kristi Jesu. 20 Ṣùgbọ́n ògo ni fún Ọlọ́run àti Baba wa láé àti láéláé. Àmín. 21 Ẹ kí olúkúlùkù ènìyàn mímọ́ nínú Kristi Jesu.Àwọn ará tí ó wà pẹ̀lú mi kí yín. 22 Gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ kí yín, pàápàá àwọn tí ń ṣe ti agbo ilé Kesari. 23 Oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa, kí ó wà pẹ̀lú ẹ̀mí yín. Àmín.
In Other Versions
Philippians 4 in the ANGEFD
Philippians 4 in the ANTPNG2D
Philippians 4 in the AS21
Philippians 4 in the BAGH
Philippians 4 in the BBPNG
Philippians 4 in the BBT1E
Philippians 4 in the BDS
Philippians 4 in the BEV
Philippians 4 in the BHAD
Philippians 4 in the BIB
Philippians 4 in the BLPT
Philippians 4 in the BNT
Philippians 4 in the BNTABOOT
Philippians 4 in the BNTLV
Philippians 4 in the BOATCB
Philippians 4 in the BOATCB2
Philippians 4 in the BOBCV
Philippians 4 in the BOCNT
Philippians 4 in the BOECS
Philippians 4 in the BOGWICC
Philippians 4 in the BOHCB
Philippians 4 in the BOHCV
Philippians 4 in the BOHLNT
Philippians 4 in the BOHNTLTAL
Philippians 4 in the BOICB
Philippians 4 in the BOILNTAP
Philippians 4 in the BOITCV
Philippians 4 in the BOKCV
Philippians 4 in the BOKCV2
Philippians 4 in the BOKHWOG
Philippians 4 in the BOKSSV
Philippians 4 in the BOLCB
Philippians 4 in the BOLCB2
Philippians 4 in the BOMCV
Philippians 4 in the BONAV
Philippians 4 in the BONCB
Philippians 4 in the BONLT
Philippians 4 in the BONUT2
Philippians 4 in the BOPLNT
Philippians 4 in the BOSCB
Philippians 4 in the BOSNC
Philippians 4 in the BOTLNT
Philippians 4 in the BOVCB
Philippians 4 in the BPBB
Philippians 4 in the BPH
Philippians 4 in the BSB
Philippians 4 in the CCB
Philippians 4 in the CUV
Philippians 4 in the CUVS
Philippians 4 in the DBT
Philippians 4 in the DGDNT
Philippians 4 in the DHNT
Philippians 4 in the DNT
Philippians 4 in the ELBE
Philippians 4 in the EMTV
Philippians 4 in the ESV
Philippians 4 in the FBV
Philippians 4 in the FEB
Philippians 4 in the GGMNT
Philippians 4 in the GNT
Philippians 4 in the HARY
Philippians 4 in the HNT
Philippians 4 in the IRVA
Philippians 4 in the IRVB
Philippians 4 in the IRVG
Philippians 4 in the IRVH
Philippians 4 in the IRVK
Philippians 4 in the IRVM
Philippians 4 in the IRVM2
Philippians 4 in the IRVO
Philippians 4 in the IRVP
Philippians 4 in the IRVT
Philippians 4 in the IRVT2
Philippians 4 in the IRVU
Philippians 4 in the ISVN
Philippians 4 in the JSNT
Philippians 4 in the KAPI
Philippians 4 in the KBT1ETNIK
Philippians 4 in the KBV
Philippians 4 in the KJV
Philippians 4 in the KNFD
Philippians 4 in the LBA
Philippians 4 in the LBLA
Philippians 4 in the LNT
Philippians 4 in the LSV
Philippians 4 in the MAAL
Philippians 4 in the MBV
Philippians 4 in the MBV2
Philippians 4 in the MHNT
Philippians 4 in the MKNFD
Philippians 4 in the MNG
Philippians 4 in the MNT
Philippians 4 in the MNT2
Philippians 4 in the MRS1T
Philippians 4 in the NAA
Philippians 4 in the NASB
Philippians 4 in the NBLA
Philippians 4 in the NBS
Philippians 4 in the NBVTP
Philippians 4 in the NET2
Philippians 4 in the NIV11
Philippians 4 in the NNT
Philippians 4 in the NNT2
Philippians 4 in the NNT3
Philippians 4 in the PDDPT
Philippians 4 in the PFNT
Philippians 4 in the RMNT
Philippians 4 in the SBIAS
Philippians 4 in the SBIBS
Philippians 4 in the SBIBS2
Philippians 4 in the SBICS
Philippians 4 in the SBIDS
Philippians 4 in the SBIGS
Philippians 4 in the SBIHS
Philippians 4 in the SBIIS
Philippians 4 in the SBIIS2
Philippians 4 in the SBIIS3
Philippians 4 in the SBIKS
Philippians 4 in the SBIKS2
Philippians 4 in the SBIMS
Philippians 4 in the SBIOS
Philippians 4 in the SBIPS
Philippians 4 in the SBISS
Philippians 4 in the SBITS
Philippians 4 in the SBITS2
Philippians 4 in the SBITS3
Philippians 4 in the SBITS4
Philippians 4 in the SBIUS
Philippians 4 in the SBIVS
Philippians 4 in the SBT
Philippians 4 in the SBT1E
Philippians 4 in the SCHL
Philippians 4 in the SNT
Philippians 4 in the SUSU
Philippians 4 in the SUSU2
Philippians 4 in the SYNO
Philippians 4 in the TBIAOTANT
Philippians 4 in the TBT1E
Philippians 4 in the TBT1E2
Philippians 4 in the TFTIP
Philippians 4 in the TFTU
Philippians 4 in the TGNTATF3T
Philippians 4 in the THAI
Philippians 4 in the TNFD
Philippians 4 in the TNT
Philippians 4 in the TNTIK
Philippians 4 in the TNTIL
Philippians 4 in the TNTIN
Philippians 4 in the TNTIP
Philippians 4 in the TNTIZ
Philippians 4 in the TOMA
Philippians 4 in the TTENT
Philippians 4 in the UBG
Philippians 4 in the UGV
Philippians 4 in the UGV2
Philippians 4 in the UGV3
Philippians 4 in the VBL
Philippians 4 in the VDCC
Philippians 4 in the YALU
Philippians 4 in the YAPE
Philippians 4 in the YBVTP
Philippians 4 in the ZBP