Proverbs 3 (BOYCB)
1 Ọmọ mi, má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ mi.Ṣùgbọ́n pa òfin mi mọ́ sí ọkàn rẹ. 2 Nítorí ọjọ́ gígùn, ẹ̀mí gígùn, àti àlàáfíà,ni wọn yóò fi kùn un fún ọ. 3 Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ àti òtítọ́ ṣíṣe fi ọ́ sílẹ̀ láéláéso wọ́n mọ́ ọrùn rẹ,kọ wọ́n sí wàláà àyà rẹ. 4 Nígbà náà ni ìwọ yóò rí ojúrere àti orúkọ rerení ojú Ọlọ́run àti lójú ènìyàn. 5 Gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹmá ṣe sinmi lé òye ara à rẹ. 6 Mọ̀ ọ́n ní gbogbo ọ̀nà rẹòun yóò sì máa tọ́ ipa ọ̀nà rẹ. 7 Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara à rẹbẹ̀rù OLÚWA kí o sì kórìíra ibi. 8 Èyí yóò mú ìlera fún ara rẹàti okun fún àwọn egungun rẹ. 9 Fi ọrọ̀ rẹ bọ̀wọ̀ fún OLÚWA,pẹ̀lú àkọ́so oko rẹ, 10 nígbà náà ni àká rẹ yóò kún àkúnyaàgbá rẹ yóò kún àkúnwọ́sílẹ̀ fún wáìnì tuntun. 11 Ọmọ mi, má ṣe kẹ́gàn ìbáwí OLÚWAmá sì ṣe bínú nígbà tí ó bá ń bá ọ wí, 12 nítorí OLÚWA a máa bá àwọn tí ó fẹ́ràn wíbí baba ti í bá ọmọ tí ó bá nínú dídùn sí wí. 13 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ní ìmọ̀,ẹni tí ó tún ní òye sí i, 14 nítorí ó ṣe èrè ju fàdákà lọó sì ní èrè lórí ju wúrà lọ. 15 Ó ṣe iyebíye ju iyùn lọ;kò sí ohunkóhun tí a lè fiwé e nínú ohun gbogbo tí ìwọ fẹ́. 16 Ẹ̀mí gígùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀;ní ọwọ́ òsì rẹ sì ni ọrọ̀ àti ọlá. 17 Àwọn ọ̀nà rẹ jẹ́ ọ̀nà ìtura,òpópónà rẹ sì jẹ́ ti àlàáfíà. 18 Igi ìyè ni ó jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó bá gbà á;àwọn tí ó bá sì dìímú yóò rí ìbùkún gbà. 19 Nípa ọgbọ́n, OLÚWA fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀; nípa òye, ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn; 20 nípa ìmọ̀ rẹ̀ ó pín ibú omi ní yà,àwọsánmọ̀ sì ń sẹ ìrì. 21 Ọmọ mi, pa ọgbọ́n tí ó yè kooro àti ìmòye mọ́,má jẹ́ kí wọn lọ kúrò ní ibi tí ojú rẹ ti le tó wọn. 22 Wọn yóò jẹ́ ìyè fún ọ,àti ẹ̀ṣọ́ fún ọrùn rẹ. 23 Nígbà náà ni ìwọ yóò bá ọ̀nà rẹ lọ ní àìléwu,ìwọ kì yóò sì kọsẹ̀. 24 Nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, ìwọ kì yóò bẹ̀rù,nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, oorun rẹ yóò jẹ́ oorun ayọ̀. 25 Má ṣe bẹ̀rù ìdààmú òjijì,tàbí ti ìparun tí ó ń dé bá àwọn ènìyàn búburú. 26 Nítorí OLÚWA yóò jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ,kì yóò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ bọ́ sínú pàkúté. 27 Má ṣe fa ọwọ́ ìre sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ṣe tìrẹ,nígbà tí ó bá wà ní ìkápá rẹ láti ṣe ohun kan. 28 Má ṣe wí fún aládùúgbò rẹ pé,“Padà wá nígbà tó ṣe díẹ̀; èmi yóò fi fún ọ ní ọ̀la,”nígbà tí o ní i pẹ̀lú rẹ nísinsin yìí. 29 Má ṣe pète ohun búburú fún aládùúgbò rẹ,ti o gbé nítòsí rẹ, tí ó sì fọkàn tán ọ. 30 Má ṣe fẹ̀sùn kan ènìyàn láìnídìí,nígbà tí kò ṣe ọ́ ní ibi kankan rárá. 31 Má ṣe ṣe ìlara ènìyàn jàgídíjàgantàbí kí o yàn láti rìn ní ọ̀nà rẹ̀. 32 Nítorí OLÚWA kórìíra ènìyàn aláyídáyidàṣùgbọ́n a máa fọkàn tán ẹni dídúró ṣinṣin. 33 Ègún OLÚWA ń bẹ lórí ilé ènìyàn búburú,ṣùgbọ́n ó bùkún fún ilé olódodo. 34 Ó fi àwọn ẹlẹ́yà ṣe yẹ̀yẹ́,ṣùgbọ́n ó fi oore-ọ̀fẹ́ fún onírẹ̀lẹ̀. 35 Ọlọ́gbọ́n jogún iyì,ṣùgbọ́n àwọn aṣiwèrè ni yóò ru ìtìjú wọn.
In Other Versions
Proverbs 3 in the ANGEFD
Proverbs 3 in the ANTPNG2D
Proverbs 3 in the AS21
Proverbs 3 in the BAGH
Proverbs 3 in the BBPNG
Proverbs 3 in the BBT1E
Proverbs 3 in the BDS
Proverbs 3 in the BEV
Proverbs 3 in the BHAD
Proverbs 3 in the BIB
Proverbs 3 in the BLPT
Proverbs 3 in the BNT
Proverbs 3 in the BNTABOOT
Proverbs 3 in the BNTLV
Proverbs 3 in the BOATCB
Proverbs 3 in the BOATCB2
Proverbs 3 in the BOBCV
Proverbs 3 in the BOCNT
Proverbs 3 in the BOECS
Proverbs 3 in the BOGWICC
Proverbs 3 in the BOHCB
Proverbs 3 in the BOHCV
Proverbs 3 in the BOHLNT
Proverbs 3 in the BOHNTLTAL
Proverbs 3 in the BOICB
Proverbs 3 in the BOILNTAP
Proverbs 3 in the BOITCV
Proverbs 3 in the BOKCV
Proverbs 3 in the BOKCV2
Proverbs 3 in the BOKHWOG
Proverbs 3 in the BOKSSV
Proverbs 3 in the BOLCB
Proverbs 3 in the BOLCB2
Proverbs 3 in the BOMCV
Proverbs 3 in the BONAV
Proverbs 3 in the BONCB
Proverbs 3 in the BONLT
Proverbs 3 in the BONUT2
Proverbs 3 in the BOPLNT
Proverbs 3 in the BOSCB
Proverbs 3 in the BOSNC
Proverbs 3 in the BOTLNT
Proverbs 3 in the BOVCB
Proverbs 3 in the BPBB
Proverbs 3 in the BPH
Proverbs 3 in the BSB
Proverbs 3 in the CCB
Proverbs 3 in the CUV
Proverbs 3 in the CUVS
Proverbs 3 in the DBT
Proverbs 3 in the DGDNT
Proverbs 3 in the DHNT
Proverbs 3 in the DNT
Proverbs 3 in the ELBE
Proverbs 3 in the EMTV
Proverbs 3 in the ESV
Proverbs 3 in the FBV
Proverbs 3 in the FEB
Proverbs 3 in the GGMNT
Proverbs 3 in the GNT
Proverbs 3 in the HARY
Proverbs 3 in the HNT
Proverbs 3 in the IRVA
Proverbs 3 in the IRVB
Proverbs 3 in the IRVG
Proverbs 3 in the IRVH
Proverbs 3 in the IRVK
Proverbs 3 in the IRVM
Proverbs 3 in the IRVM2
Proverbs 3 in the IRVO
Proverbs 3 in the IRVP
Proverbs 3 in the IRVT
Proverbs 3 in the IRVT2
Proverbs 3 in the IRVU
Proverbs 3 in the ISVN
Proverbs 3 in the JSNT
Proverbs 3 in the KAPI
Proverbs 3 in the KBT1ETNIK
Proverbs 3 in the KBV
Proverbs 3 in the KJV
Proverbs 3 in the KNFD
Proverbs 3 in the LBA
Proverbs 3 in the LBLA
Proverbs 3 in the LNT
Proverbs 3 in the LSV
Proverbs 3 in the MAAL
Proverbs 3 in the MBV
Proverbs 3 in the MBV2
Proverbs 3 in the MHNT
Proverbs 3 in the MKNFD
Proverbs 3 in the MNG
Proverbs 3 in the MNT
Proverbs 3 in the MNT2
Proverbs 3 in the MRS1T
Proverbs 3 in the NAA
Proverbs 3 in the NASB
Proverbs 3 in the NBLA
Proverbs 3 in the NBS
Proverbs 3 in the NBVTP
Proverbs 3 in the NET2
Proverbs 3 in the NIV11
Proverbs 3 in the NNT
Proverbs 3 in the NNT2
Proverbs 3 in the NNT3
Proverbs 3 in the PDDPT
Proverbs 3 in the PFNT
Proverbs 3 in the RMNT
Proverbs 3 in the SBIAS
Proverbs 3 in the SBIBS
Proverbs 3 in the SBIBS2
Proverbs 3 in the SBICS
Proverbs 3 in the SBIDS
Proverbs 3 in the SBIGS
Proverbs 3 in the SBIHS
Proverbs 3 in the SBIIS
Proverbs 3 in the SBIIS2
Proverbs 3 in the SBIIS3
Proverbs 3 in the SBIKS
Proverbs 3 in the SBIKS2
Proverbs 3 in the SBIMS
Proverbs 3 in the SBIOS
Proverbs 3 in the SBIPS
Proverbs 3 in the SBISS
Proverbs 3 in the SBITS
Proverbs 3 in the SBITS2
Proverbs 3 in the SBITS3
Proverbs 3 in the SBITS4
Proverbs 3 in the SBIUS
Proverbs 3 in the SBIVS
Proverbs 3 in the SBT
Proverbs 3 in the SBT1E
Proverbs 3 in the SCHL
Proverbs 3 in the SNT
Proverbs 3 in the SUSU
Proverbs 3 in the SUSU2
Proverbs 3 in the SYNO
Proverbs 3 in the TBIAOTANT
Proverbs 3 in the TBT1E
Proverbs 3 in the TBT1E2
Proverbs 3 in the TFTIP
Proverbs 3 in the TFTU
Proverbs 3 in the TGNTATF3T
Proverbs 3 in the THAI
Proverbs 3 in the TNFD
Proverbs 3 in the TNT
Proverbs 3 in the TNTIK
Proverbs 3 in the TNTIL
Proverbs 3 in the TNTIN
Proverbs 3 in the TNTIP
Proverbs 3 in the TNTIZ
Proverbs 3 in the TOMA
Proverbs 3 in the TTENT
Proverbs 3 in the UBG
Proverbs 3 in the UGV
Proverbs 3 in the UGV2
Proverbs 3 in the UGV3
Proverbs 3 in the VBL
Proverbs 3 in the VDCC
Proverbs 3 in the YALU
Proverbs 3 in the YAPE
Proverbs 3 in the YBVTP
Proverbs 3 in the ZBP