Psalms 109 (BOYCB)
undefined Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu. 1 Ọlọ́run, ti èmi ń fi ìyìn fún,má ṣe dákẹ́, 2 nítorí àwọn ènìyàn búburú àti ẹlẹ́tànti ya ẹnu wọn sí miwọ́n ti fi ahọ́n èké sọ̀rọ̀ sí mi. 3 Wọ́n fi ọ̀rọ̀ ìríra yí mi káàkiri;wọ́n bá mi jà láìnídìí 4 Nípò ìfẹ́ mi, wọn ń ṣe ọ̀tá mi,ṣùgbọ́n èmi ń gba àdúrà. 5 Wọ́n sì fi ibi san ìre fún miàti ìríra fún ìfẹ́ mi. 6 Yan àwọn ènìyàn búburú láti dojúkọjẹ́ kí àwọn olùfisùndúró ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀. 7 Kí a dá a lẹ́bi nígbà tí a bá ṣe ìdájọ́kí àdúrà rẹ̀ kí ó lè di ìkọ̀sílẹ̀. 8 Kí ọjọ́ rẹ̀ kí ó kúrú;kí ẹlòmíràn kí ó rọ́pò iṣẹ́ rẹ̀. 9 Kí àwọn ọmọ rẹ̀ di aláìní babakí aya rẹ̀ sì di opó. 10 Jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe kirikí wọn máa tọrọ oúnjẹ jìnnà sí ibi ahoro wọn. 11 Jẹ́ kí alọ́nilọ́wọ́gbà kí ó mú ohun gbogbo tí ó níjẹ́ kí àlejò kí o kó èrè iṣẹ́ rẹ̀ lọ. 12 Má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan ṣe àánú fún untàbí kí wọn káàánú lóríàwọn ọmọ rẹ̀ aláìní baba. 13 Kí a gé àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ kúròkí orúkọ wọn kí ó parẹ́ ní ìran tí ń bọ̀. 14 Kí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba rẹ̀ kíó wà ní ìrántí ní ọ̀dọ̀ OLÚWA.Má ṣe jẹ́ kí a yọ ẹ̀ṣẹ̀ ìyá wọn kúrò. 15 Jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ wọn kí ó wà ní ìrántí níwájú OLÚWAkí ó lè gé ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀. 16 Nítorí kò rántí láti ṣàánú,ṣùgbọ́n ó ṣe inúnibíni sí ọkùnrin tálákà àti olùpọ́njú,kí ó lè pa oníròbìnújẹ́ ọkàn. 17 Ó fẹ́ràn láti máa mú ègún wá sí orí rẹ̀:bi inú rẹ̀ kò ti dùn si ìre, bẹ́ẹ̀ ni kí ó jìnnà sí. 18 Bí ó ti fi ègún wọ ará rẹ̀ láṣọ bí ẹ̀wùbẹ́ẹ̀ ni kí ó wá sí inú rẹ̀ bí omi. 19 Jẹ́ kí ó rí fún un bí aṣọ tí a dà bò ó ní ara,àti fún àmùrè tí ó fi gba ọ̀já nígbà gbogbo. 20 Èyí ni èrè àwọn ọ̀tá mi láti ọwọ́ OLÚWA wá;àti ti àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọkàn mi. 21 Ṣùgbọ́n ìwọ, ìwọ ṣe fún mi OLÚWA Olódùmarè,ṣe rere fún mi nítorí orúkọ rẹ.Nítorí tí àánú rẹ dára, ìwọ gbà mí. 22 Nítorí pé tálákà àti aláìní ni mí,àyà mi sì gbọgbẹ́ nínú mi. 23 Èmi ń kọjá lọ bí òjìji tí àṣálẹ́,mo ń gbọ̀n sókè bí eṣú. 24 Eékún mi di aláìlera nítorí àwẹ̀ gbígbàẹran-ara mi sì gbẹ nítorí àìlera mi. 25 Mo dàbí ẹ̀gàn fún àwọn olùfisùn mi;nígbà tí wọn wò mí, wọ́n gbọn orí wọn. 26 Ràn mí lọ́wọ́, OLÚWA Ọlọ́run mi;gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìṣeun ìfẹ́ rẹ. 27 Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ọwọ́ rẹ ni èyíwí pé ìwọ, OLÚWA, ni ó ṣe é. 28 Wọ́n ó máa gégùn ún, ṣùgbọ́n ìwọ máa súre,nígbà tí wọn bá dìde kí ojú kí ó tì wọ́n,ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ rẹ yóò yọ̀. 29 Jẹ́ kí a wọ àwọn ọ̀tá mi ní aṣọ ìtìjúkí á sì fi ìdàrúdàpọ̀ bọ̀ wọ́n lára bí ẹ̀wù. 30 Pẹ̀lú ẹnu mi èmi yóò máa yin OLÚWA gidigidiní àárín ọ̀pọ̀ ènìyàn èmi yóò máa yìn ín. 31 Nítorí ó dúró ní apá ọ̀tún aláìníláti gbà á lọ́wọ́ àwọn tí ń dá ọkàn rẹ̀ lẹ́bi.
In Other Versions
Psalms 109 in the ANGEFD
Psalms 109 in the ANTPNG2D
Psalms 109 in the AS21
Psalms 109 in the BAGH
Psalms 109 in the BBPNG
Psalms 109 in the BBT1E
Psalms 109 in the BDS
Psalms 109 in the BEV
Psalms 109 in the BHAD
Psalms 109 in the BIB
Psalms 109 in the BLPT
Psalms 109 in the BNT
Psalms 109 in the BNTABOOT
Psalms 109 in the BNTLV
Psalms 109 in the BOATCB
Psalms 109 in the BOATCB2
Psalms 109 in the BOBCV
Psalms 109 in the BOCNT
Psalms 109 in the BOECS
Psalms 109 in the BOGWICC
Psalms 109 in the BOHCB
Psalms 109 in the BOHCV
Psalms 109 in the BOHLNT
Psalms 109 in the BOHNTLTAL
Psalms 109 in the BOICB
Psalms 109 in the BOILNTAP
Psalms 109 in the BOITCV
Psalms 109 in the BOKCV
Psalms 109 in the BOKCV2
Psalms 109 in the BOKHWOG
Psalms 109 in the BOKSSV
Psalms 109 in the BOLCB
Psalms 109 in the BOLCB2
Psalms 109 in the BOMCV
Psalms 109 in the BONAV
Psalms 109 in the BONCB
Psalms 109 in the BONLT
Psalms 109 in the BONUT2
Psalms 109 in the BOPLNT
Psalms 109 in the BOSCB
Psalms 109 in the BOSNC
Psalms 109 in the BOTLNT
Psalms 109 in the BOVCB
Psalms 109 in the BPBB
Psalms 109 in the BPH
Psalms 109 in the BSB
Psalms 109 in the CCB
Psalms 109 in the CUV
Psalms 109 in the CUVS
Psalms 109 in the DBT
Psalms 109 in the DGDNT
Psalms 109 in the DHNT
Psalms 109 in the DNT
Psalms 109 in the ELBE
Psalms 109 in the EMTV
Psalms 109 in the ESV
Psalms 109 in the FBV
Psalms 109 in the FEB
Psalms 109 in the GGMNT
Psalms 109 in the GNT
Psalms 109 in the HARY
Psalms 109 in the HNT
Psalms 109 in the IRVA
Psalms 109 in the IRVB
Psalms 109 in the IRVG
Psalms 109 in the IRVH
Psalms 109 in the IRVK
Psalms 109 in the IRVM
Psalms 109 in the IRVM2
Psalms 109 in the IRVO
Psalms 109 in the IRVP
Psalms 109 in the IRVT
Psalms 109 in the IRVT2
Psalms 109 in the IRVU
Psalms 109 in the ISVN
Psalms 109 in the JSNT
Psalms 109 in the KAPI
Psalms 109 in the KBT1ETNIK
Psalms 109 in the KBV
Psalms 109 in the KJV
Psalms 109 in the KNFD
Psalms 109 in the LBA
Psalms 109 in the LBLA
Psalms 109 in the LNT
Psalms 109 in the LSV
Psalms 109 in the MAAL
Psalms 109 in the MBV
Psalms 109 in the MBV2
Psalms 109 in the MHNT
Psalms 109 in the MKNFD
Psalms 109 in the MNG
Psalms 109 in the MNT
Psalms 109 in the MNT2
Psalms 109 in the MRS1T
Psalms 109 in the NAA
Psalms 109 in the NASB
Psalms 109 in the NBLA
Psalms 109 in the NBS
Psalms 109 in the NBVTP
Psalms 109 in the NET2
Psalms 109 in the NIV11
Psalms 109 in the NNT
Psalms 109 in the NNT2
Psalms 109 in the NNT3
Psalms 109 in the PDDPT
Psalms 109 in the PFNT
Psalms 109 in the RMNT
Psalms 109 in the SBIAS
Psalms 109 in the SBIBS
Psalms 109 in the SBIBS2
Psalms 109 in the SBICS
Psalms 109 in the SBIDS
Psalms 109 in the SBIGS
Psalms 109 in the SBIHS
Psalms 109 in the SBIIS
Psalms 109 in the SBIIS2
Psalms 109 in the SBIIS3
Psalms 109 in the SBIKS
Psalms 109 in the SBIKS2
Psalms 109 in the SBIMS
Psalms 109 in the SBIOS
Psalms 109 in the SBIPS
Psalms 109 in the SBISS
Psalms 109 in the SBITS
Psalms 109 in the SBITS2
Psalms 109 in the SBITS3
Psalms 109 in the SBITS4
Psalms 109 in the SBIUS
Psalms 109 in the SBIVS
Psalms 109 in the SBT
Psalms 109 in the SBT1E
Psalms 109 in the SCHL
Psalms 109 in the SNT
Psalms 109 in the SUSU
Psalms 109 in the SUSU2
Psalms 109 in the SYNO
Psalms 109 in the TBIAOTANT
Psalms 109 in the TBT1E
Psalms 109 in the TBT1E2
Psalms 109 in the TFTIP
Psalms 109 in the TFTU
Psalms 109 in the TGNTATF3T
Psalms 109 in the THAI
Psalms 109 in the TNFD
Psalms 109 in the TNT
Psalms 109 in the TNTIK
Psalms 109 in the TNTIL
Psalms 109 in the TNTIN
Psalms 109 in the TNTIP
Psalms 109 in the TNTIZ
Psalms 109 in the TOMA
Psalms 109 in the TTENT
Psalms 109 in the UBG
Psalms 109 in the UGV
Psalms 109 in the UGV2
Psalms 109 in the UGV3
Psalms 109 in the VBL
Psalms 109 in the VDCC
Psalms 109 in the YALU
Psalms 109 in the YAPE
Psalms 109 in the YBVTP
Psalms 109 in the ZBP