Psalms 125 (BOYCB)
undefined Orin fún ìgòkè. 1 Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA yóò dàbí òkè Sioni,tí a kò lè ṣí ní ìdí, bí kò ṣe pé ó dúró láéláé. 2 Bí òkè ńlá ti yí Jerusalẹmu ká,bẹ́ẹ̀ ni OLÚWA yí ènìyàn káláti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé. 3 Nítorí tí ọ̀pá àwọn ènìyàn búburúkì yóò bà lé ìpín àwọn olódodo;kí àwọn olódodo kí ó máa ba àfi ọwọ́ wọn lé ẹ̀ṣẹ̀. 4 OLÚWA ṣe rere fún àwọn ẹni rere,àti fún àwọn tí àyà wọn dúró ṣinṣin. 5 Bí ó ṣe ti irú àwọn tí wọn yà sí ipa ọ̀nà wíwọ́ wọn; OLÚWA yóò jẹ́ kí wọn lọ pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n àlàáfíà yóò wà lórí Israẹli.