Psalms 126 (BOYCB)
undefined Orin fún ìgòkè. 1 Nígbà tí OLÚWA mú ìkólọ Sioni padà,àwa dàbí ẹni tí ó ń lá àlá. 2 Nígbà náà ni ẹnu wa kún fún ẹ̀rín,àti ahọ́n wa kọ orin;nígbà náà ni wọ́n wí nínú àwọn kèfèrí pé, OLÚWA ṣe ohun ńlá fún wọn. 3 OLÚWA ṣe ohun ńlá fún wa;nítorí náà àwa ń yọ̀. 4 OLÚWA mú ìkólọ wa padà,bí ìṣàn omi ní gúúsù. 5 Àwọn tí ń fi omijé fún irúgbìnyóò fi ayọ̀ ka. 6 Ẹni tí ń fi ẹkún rìn lọ,tí ó sì gbé irúgbìn lọ́wọ́,lóòtítọ́, yóò fi ayọ̀ padà wá,yóò sì ru ìtí rẹ̀.