Psalms 129 (BOYCB)
undefined Orin fún ìgòkè. 1 “Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójúláti ìgbà èwe mi wá,”jẹ́ kí Israẹli kí ó wí nísinsin yìí; 2 “Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójúláti ìgbà èwe mi wá;síbẹ̀ wọn kò tí ì borí mi. 3 Àwọn awalẹ̀ walẹ̀ sí ẹ̀yìn mi:wọ́n sì la aporo wọn gígùn. 4 Olódodo ni OLÚWA:ó ti ké okùn àwọn ènìyàn búburú kúrò.” 5 Kí gbogbo àwọn tí ó kórìíra Sioni kí ó dààmú,kí wọn kí ó sì yí ẹ̀yìn padà. 6 Kí wọn kí ó dàbí koríko orí ilẹ̀tí ó gbẹ dànù kí ó tó dàgbàsókè, 7 èyí tí olóko pípa kó kún ọwọ́ rẹ̀:bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń di ìtí, kó kún apá rẹ̀. 8 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ń kọjá lọ kò wí pé,ìbùkún OLÚWA kí ó pẹ̀lú yín:àwa ń súre fún yin ní orúkọ OLÚWA.