Psalms 13 (BOYCB)
undefined Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. 1 Yóò ti pẹ́ tó, OLÚWA? Ìwọ o ha gbàgbé mi títí láé?Yóò tí pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa fi ojú rẹ pamọ́ fún mi? 2 Yóò ti pẹ́ tó tí èmi ó máa bá èrò mi jà,àti ní ojoojúmọ́ ni èmi ń ní ìbànújẹ́ ní ọkàn mi?Yóò ti pẹ́ tó tí àwọn ọ̀tá mi yóò máa borí mi? 3 Wò mí kí o sì dá mi lóhùn, OLÚWA Ọlọ́run mi.Fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú mi, kí èmi ó má sún oorun ikú. 4 Ọ̀tá mi wí pé, “Èmi ti ṣẹ́gun rẹ̀,”àwọn ọ̀tá mi yóò yọ̀ tí mo bá ṣubú. 5 Ṣùgbọ́n mo gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà;ọkàn mi ń yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ. 6 Èmi ó máa kọrin sí OLÚWA,nítorí ó dára sí mi.