Psalms 22 (BOYCB)

undefined Fún adarí orin. Tí ohùn orin “àgbọ̀nrín òwúrọ̀.” Saamu ti Dafidi. 1 Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?Èéṣe tí o fi jìnnà láti gbà mí là,àní sí igbe ìkérora mi? 2 Ọlọ́run mi, ní ọ̀sán gangan ni mo kígbe, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi ní ohùn:àti ní òru èmi kò dákẹ́. 3 Ṣùgbọ́n síbẹ̀ ẹni mímọ́ ni Ìwọ;ẹni tí ó tẹ ìyìn Israẹli dó. 4 Àwọn baba ńlá wa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ;wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé, ìwọ sì gbà wọ́n. 5 Ìwọ ni wọ́n sun ẹkún sí, wọ́n sì ní ìgbàlà;ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀lé, a kò sì dójútì wọ́n. 6 Ṣùgbọ́n kòkòrò ní mo jẹ́, kì í sì í ṣe ènìyàn;mo di ẹlẹ́gàn àwọn ènìyàn, ẹlẹ́yà àwọn ènìyàn. 7 Gbogbo àwọn tí ó rí mí fi mí ṣe ẹlẹ́yà;wọ́n yọ ètè ẹ̀gàn wọn sí mi, wọ́n sì ń mi orí wọn pé. 8 “Ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé OLÚWA;jẹ́ kí OLÚWA gbà á là.Jẹ́ kí ó gbà á là,nítorí pé, ó ní ayọ̀ nínú rẹ̀.” 9 Síbẹ̀ ìwọ ni ó ti mú mi wá láti inú;ìwọ ni ó mú mi wà láìléwu, nígbà tí mo rọ̀ mọ́ ọmú ìyá mi. 10 Ìwọ ni a fi mí lé lọ́wọ́ láti inú ìyá mi wá,nígbà tí ìyá mí sì ti bí mi, ìwọ ni Ọlọ́run mi. 11 Má ṣe jìnnà sí mi,nítorí pé ìyọnu súnmọ́ tòsíkò sì ṣí ẹnìkan tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́. 12 Ọ̀pọ̀ akọ màlúù yí mi ká;àwọn màlúù alágbára Baṣani rọ̀gbà yí mi ká. 13 Wọ́n ya ẹnu wọn sì mi bí i kìnnìún tí ń dọdẹ kiri,tí ń ké ramúramù. 14 A dà mí jáde gẹ́gẹ́ bí omi,gbogbo egungun mi ti yẹ̀ kúrò ní oríkèé rẹ̀.Ọkàn mi sì dàbí i ìda;tí ó yọ́ láàrín inú mi. 15 Agbára mí ti gbẹ bí àpáàdì,ahọ́n mí sì tilẹ̀ mọ́ párí ẹ̀rẹ̀kẹ́ ẹ mi;ìwọ ti tẹ́ mi sínú eruku ikú. 16 Àwọn ajá yí mi ká;ìjọ àwọn ènìyàn ibi ti ká mi mọ́,wọ́n gún mi lọ́wọ́, wọ́n sì gún mi lẹ́sẹ̀. 17 Mo lè ka gbogbo àwọn egungun mi;àwọn tìkára wọn ń wò, wọ́n dójú lé mi. 18 Wọ́n pín aṣọ mi láàrín ara wọnàní lórí aṣọ mi ni wọ́n ṣẹ́ gègé. 19 Ṣùgbọ́n ìwọ, OLÚWA, má ṣe jìnnà sí mi.Háà! Olùrànlọ́wọ́ ọ̀ mi, yára wá fún àtìlẹ́yìn mi! 20 Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ idà,àní ẹ̀mí mi lọ́wọ́ agbára àwọn ajá. 21 Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ kìnnìún;kí o sì gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ìwo àgbáǹréré. 22 Èmi yóò kéde orúkọ rẹ láàrín arákùnrin àti arábìnrin mi;nínú ìjọ ni èmi yóò máa yìn ọ́. 23 Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù OLÚWA, ẹ yìn ín!Gbogbo ẹ̀yin ìran Jakọbu, ẹ fi ògo fún un!Ẹ dìde fún un tẹ̀rù tẹ̀rù, ẹ̀yin irú-ọmọ Israẹli! 24 Nítorí pé òun kò ṣátá, bẹ́ẹ̀ ni kò sì kórìíraìpọ́njú àwọn tí a ni lára;kò sì fi ojú rẹ̀ pamọ́ fún miṣùgbọ́n ó gbọ́ nígbà tí mo ké pè é. 25 Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìyìn mi yóò ti wá nínú àjọ ńlá;ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò san níwájú àwọn tí o bẹ̀rù rẹ̀ 26 tálákà yóò jẹ yóò sì yó;àwọn tí n wá OLÚWA yóò yinjẹ́ kí ẹ̀mí rẹ̀ wà láààyè títí ayérayé! 27 Gbogbo òpin ayé ni yóò rántíwọn yóò sì yípadà sí OLÚWA,àti gbogbo ìdílé orílẹ̀-èdèni wọn yóò jọ́sìn níwájú rẹ̀, 28 nítorí ìjọba ni ti OLÚWA.Òun ni ó ń pàṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè. 29 Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn olówó ayé wọn yóò ṣe àsè, wọn yóò sì sìn;gbogbo àwọn tí ó wọ inú ilẹ̀ lọ yóò kúnlẹ̀ ní iwájú rẹ̀àti ẹni tí kò lè pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́ ni ààyè. 30 Irú-ọmọ rẹ̀ yóò sìn ín;a ó sọ fún àwọn ìran tí ń bọ̀ nípa OLÚWA. 31 Wọn yóò polongo òdodo rẹ̀sí àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí,wí pé, òun ni ó ṣe èyí.

In Other Versions

Psalms 22 in the ANGEFD

Psalms 22 in the ANTPNG2D

Psalms 22 in the AS21

Psalms 22 in the BAGH

Psalms 22 in the BBPNG

Psalms 22 in the BBT1E

Psalms 22 in the BDS

Psalms 22 in the BEV

Psalms 22 in the BHAD

Psalms 22 in the BIB

Psalms 22 in the BLPT

Psalms 22 in the BNT

Psalms 22 in the BNTABOOT

Psalms 22 in the BNTLV

Psalms 22 in the BOATCB

Psalms 22 in the BOATCB2

Psalms 22 in the BOBCV

Psalms 22 in the BOCNT

Psalms 22 in the BOECS

Psalms 22 in the BOGWICC

Psalms 22 in the BOHCB

Psalms 22 in the BOHCV

Psalms 22 in the BOHLNT

Psalms 22 in the BOHNTLTAL

Psalms 22 in the BOICB

Psalms 22 in the BOILNTAP

Psalms 22 in the BOITCV

Psalms 22 in the BOKCV

Psalms 22 in the BOKCV2

Psalms 22 in the BOKHWOG

Psalms 22 in the BOKSSV

Psalms 22 in the BOLCB

Psalms 22 in the BOLCB2

Psalms 22 in the BOMCV

Psalms 22 in the BONAV

Psalms 22 in the BONCB

Psalms 22 in the BONLT

Psalms 22 in the BONUT2

Psalms 22 in the BOPLNT

Psalms 22 in the BOSCB

Psalms 22 in the BOSNC

Psalms 22 in the BOTLNT

Psalms 22 in the BOVCB

Psalms 22 in the BPBB

Psalms 22 in the BPH

Psalms 22 in the BSB

Psalms 22 in the CCB

Psalms 22 in the CUV

Psalms 22 in the CUVS

Psalms 22 in the DBT

Psalms 22 in the DGDNT

Psalms 22 in the DHNT

Psalms 22 in the DNT

Psalms 22 in the ELBE

Psalms 22 in the EMTV

Psalms 22 in the ESV

Psalms 22 in the FBV

Psalms 22 in the FEB

Psalms 22 in the GGMNT

Psalms 22 in the GNT

Psalms 22 in the HARY

Psalms 22 in the HNT

Psalms 22 in the IRVA

Psalms 22 in the IRVB

Psalms 22 in the IRVG

Psalms 22 in the IRVH

Psalms 22 in the IRVK

Psalms 22 in the IRVM

Psalms 22 in the IRVM2

Psalms 22 in the IRVO

Psalms 22 in the IRVP

Psalms 22 in the IRVT

Psalms 22 in the IRVT2

Psalms 22 in the IRVU

Psalms 22 in the ISVN

Psalms 22 in the JSNT

Psalms 22 in the KAPI

Psalms 22 in the KBT1ETNIK

Psalms 22 in the KBV

Psalms 22 in the KJV

Psalms 22 in the KNFD

Psalms 22 in the LBA

Psalms 22 in the LBLA

Psalms 22 in the LNT

Psalms 22 in the LSV

Psalms 22 in the MAAL

Psalms 22 in the MBV

Psalms 22 in the MBV2

Psalms 22 in the MHNT

Psalms 22 in the MKNFD

Psalms 22 in the MNG

Psalms 22 in the MNT

Psalms 22 in the MNT2

Psalms 22 in the MRS1T

Psalms 22 in the NAA

Psalms 22 in the NASB

Psalms 22 in the NBLA

Psalms 22 in the NBS

Psalms 22 in the NBVTP

Psalms 22 in the NET2

Psalms 22 in the NIV11

Psalms 22 in the NNT

Psalms 22 in the NNT2

Psalms 22 in the NNT3

Psalms 22 in the PDDPT

Psalms 22 in the PFNT

Psalms 22 in the RMNT

Psalms 22 in the SBIAS

Psalms 22 in the SBIBS

Psalms 22 in the SBIBS2

Psalms 22 in the SBICS

Psalms 22 in the SBIDS

Psalms 22 in the SBIGS

Psalms 22 in the SBIHS

Psalms 22 in the SBIIS

Psalms 22 in the SBIIS2

Psalms 22 in the SBIIS3

Psalms 22 in the SBIKS

Psalms 22 in the SBIKS2

Psalms 22 in the SBIMS

Psalms 22 in the SBIOS

Psalms 22 in the SBIPS

Psalms 22 in the SBISS

Psalms 22 in the SBITS

Psalms 22 in the SBITS2

Psalms 22 in the SBITS3

Psalms 22 in the SBITS4

Psalms 22 in the SBIUS

Psalms 22 in the SBIVS

Psalms 22 in the SBT

Psalms 22 in the SBT1E

Psalms 22 in the SCHL

Psalms 22 in the SNT

Psalms 22 in the SUSU

Psalms 22 in the SUSU2

Psalms 22 in the SYNO

Psalms 22 in the TBIAOTANT

Psalms 22 in the TBT1E

Psalms 22 in the TBT1E2

Psalms 22 in the TFTIP

Psalms 22 in the TFTU

Psalms 22 in the TGNTATF3T

Psalms 22 in the THAI

Psalms 22 in the TNFD

Psalms 22 in the TNT

Psalms 22 in the TNTIK

Psalms 22 in the TNTIL

Psalms 22 in the TNTIN

Psalms 22 in the TNTIP

Psalms 22 in the TNTIZ

Psalms 22 in the TOMA

Psalms 22 in the TTENT

Psalms 22 in the UBG

Psalms 22 in the UGV

Psalms 22 in the UGV2

Psalms 22 in the UGV3

Psalms 22 in the VBL

Psalms 22 in the VDCC

Psalms 22 in the YALU

Psalms 22 in the YAPE

Psalms 22 in the YBVTP

Psalms 22 in the ZBP