1 Chronicles 16 (BOYCB)

1 Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, wá sínú àgọ́ ti Dafidi ti pèsè fún un, wọ́n sì gbé ẹbọ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀ kalẹ̀ níwájú Ọlọ́run. 2 Lẹ́yìn tí Dafidi parí ẹbọ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀, ó bùkún àwọn ènìyàn ní orúkọ OLÚWA. 3 Nígbà náà ó fún olúkúlùkù ọkùnrin àti obìnrin ọmọ Israẹli ní ìṣù àkàrà kan, àkàrà dídùn ti àkókò kan àti àkàrà dídùn ti èso àjàrà kan. 4 Ó yan díẹ̀ lára àwọn ará Lefi láti máa jọ́sìn níwájú àpótí ẹ̀rí OLÚWA, àti láti ṣe ìrántí àti dúpẹ́ àti láti yin OLÚWA, Ọlọ́run Israẹli. 5 Asafu ni olóyè, àtẹ̀lé rẹ ni Sekariah, Jehieli, Ṣemiramotu, Asieli, Mattitiah, Eliabu, Benaiah, Obedi-Edomu àti Jeieli, àwọn ni yóò lu ohun èlò orin olókùn àti dùùrù haapu. Asafu ni yóò lu símbálì kíkan. 6 Àti Benaiah àti Jahasieli àwọn àlùfáà ni yóò fọn ìpè nígbà gbogbo níwájú àpótí ẹ̀rí májẹ̀mú ti Ọlọ́run. 7 Ní ọjọ́ náà Dafidi kọ́kọ́ fi lé Asafu àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ orin Dafidi ti ọpẹ́ sí OLÚWA. 8 Ẹ fi ọpẹ́ fún OLÚWA, ẹ pe orúkọ rẹ̀,ẹ fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn nínú àwọn ènìyàn fún ohun tí ó ṣe 9 Ẹ kọrin sí i, ẹ kọrin ìyìn, sí i,ẹ sọ ti gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀. 10 Ìyìn nínú orúkọ rẹ̀ mímọ́;jẹ kí ọkàn àwọn tí ó yin OLÚWA kí ó yọ̀. 11 Ẹ wá OLÚWA àti agbára rẹ̀;e wá ojú rẹ̀ nígbà gbogbo. 12 Rántí àwọn ìyanu tí Ó ti ṣe,iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àti ìdájọ́ tí Ó ti sọ. 13 A! ẹ̀yin ìran ọmọ Israẹli ìránṣẹ́ rẹ̀,àwọn ọmọ Jakọbu, ẹ̀yin tí ó ti yàn. 14 Òun ni OLÚWA Ọlọ́run wa;ìdájọ́ rẹ̀ wà ní gbogbo ayé. 15 Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ láéláé,ọ̀rọ̀ tí ó pàṣẹ, fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìran, 16 májẹ̀mú tí ó dá pẹ̀lú Abrahamu,ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú fún Isaaki. 17 Ó ṣe ìdánilójú u rẹ̀ fún Jakọbu,gẹ́gẹ́ bí àṣẹ sí Israẹli, gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú ayérayé: 18 “Sí ọ, ni èmi yóò fún ní ilẹ̀ Kenaani.Gẹ́gẹ́ bí ààyè tí ìwọ yóò jogún.” 19 Nígbà tí wọn kéré ní iye,wọ́n kéré gidigidi, wọ́n sì jẹ́ àlejò níbẹ̀, 20 wọ́n rìn kiri láti orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdèláti ìjọba kan sí èkejì. 21 Kò gba ọkùnrin kankan láyè láti pọ́n wọn lójú;nítorí tiwọn, ó bá àwọn ọba wí. 22 “Má ṣe fọwọ́ kan àwọn ẹni àmì òróró mi;má ṣe pa àwọn wòlíì mi lára.” 23 Kọrin sí OLÚWA gbogbo ayé;ẹ máa fi ìgbàlà rẹ̀ hàn láti ọjọ́ dé ọjọ́. 24 Kéde ògo à rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,ohun ìyàlẹ́nu tí ó ṣe láàrín gbogbo ènìyàn. 25 Nítorí títóbi ni OLÚWA òun sì ni ìyìn yẹ jùlọ;òun ni kí a bẹ̀rù ju gbogbo àwọn Ọlọ́run lọ. 26 Nítorí gbogbo àwọn ọlọ́run orílẹ̀-èdè jẹ́ àwọn òrìṣà,ṣùgbọ́n OLÚWA dá àwọn ọ̀run. 27 Dídán àti ọláńlá ni ó wà níwájú rẹ̀;agbára àti ayọ̀ ni ó wà ní ibi ibùgbé rẹ̀. 28 Fi fún OLÚWA, ẹ̀yin ìdílé àwọn orílẹ̀-èdè,ẹ fi ògo àti ipá fún OLÚWA. 29 Fún OLÚWA ní ìyìn nítorí orúkọ rẹ̀;gbé ọrẹ kí ẹ sì wá síwájú rẹ̀.Sìn OLÚWA nínú inú dídùn ìwà mímọ́ rẹ̀. 30 Wárìrì níwájú rẹ̀, gbogbo ayé!Ayé sì fi ìdí múlẹ̀; a kò sì le è ṣí i. 31 Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, jẹ́ kí ayé kí ó ṣe inú dídùn;lẹ́ kí wọn kí ó sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, pé “OLÚWA jẹ ọba!” 32 Jẹ́ kí ọ̀run kí ó tún dún padà, àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀;Jẹ́ kí àwọn pápá kí ó hó fún ayọ̀, àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀! 33 Nígbà náà ni igi igbó yóò kọrin,wọn yóò kọrin fún ayọ̀ níwájú OLÚWA,nítorí tí ó wá láti ṣèdájọ́ ayé. 34 Fi ọpẹ́ fún OLÚWA, nítorí tí ó dára;ìfẹ́ ẹ rẹ̀ dúró títí láé. 35 Ké lóhùn rara, “Gbà wá, Ọlọ́run olùgbàlà a wa;kó wa jọ kí o sì gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè,kí àwa kí ó lè fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ,kí àwa kí ó lè yọ̀ nínú ìyìn rẹ̀.” 36 Olùbùkún ni OLÚWA, Ọlọ́run Israẹli,láé àti láéláé.Lẹ́yìn náà gbogbo àwọn ènìyàn wí pé, “Àmín,” wọ́n “Yin OLÚWA.” 37 Dafidi fi Asafu àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí OLÚWA láti jíṣẹ́ níbẹ̀ déédé, gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ṣe gbà. 38 Ó fi Obedi-Edomu àti méjìdínláàádọ́rin ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú wọn. Obedi-Edomu mọ Jedutuni, àti Hosa pẹ̀lú jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà. 39 Dafidi fi Sadoku àlùfáà àti àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níwájú Àgọ́ OLÚWA ní ibi gíga ní Gibeoni. 40 Láti gbé pẹpẹ ẹbọ sísun déédé, àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí a kọ sínú òfin OLÚWA, tí ó ti fún Israẹli. 41 Pẹ̀lú wọn ni Hemani àti Jedutuni àti ìyókù tí a mú àti yàn nípasẹ̀ orúkọ láti fi ọpẹ́ fún OLÚWA, nítorí tí ìfẹ́ rẹ̀ dúró títí láéláé 42 Hemani àti Jedutuni ni wọ́n dúró fún fífọn ìpè àti Kimbali àti fún lílo ohun èlò yòókù fún orin Ọlọ́run. Àwọn ọmọ Jedutuni wà ní ipò dídúró ní ẹnu-ọ̀nà. 43 Nígbà náà gbogbo àwọn ènìyàn kúrò, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀: Dafidi yípadà láti súre fún ìdílé rẹ̀.

In Other Versions

1 Chronicles 16 in the ANGEFD

1 Chronicles 16 in the ANTPNG2D

1 Chronicles 16 in the AS21

1 Chronicles 16 in the BAGH

1 Chronicles 16 in the BBPNG

1 Chronicles 16 in the BBT1E

1 Chronicles 16 in the BDS

1 Chronicles 16 in the BEV

1 Chronicles 16 in the BHAD

1 Chronicles 16 in the BIB

1 Chronicles 16 in the BLPT

1 Chronicles 16 in the BNT

1 Chronicles 16 in the BNTABOOT

1 Chronicles 16 in the BNTLV

1 Chronicles 16 in the BOATCB

1 Chronicles 16 in the BOATCB2

1 Chronicles 16 in the BOBCV

1 Chronicles 16 in the BOCNT

1 Chronicles 16 in the BOECS

1 Chronicles 16 in the BOGWICC

1 Chronicles 16 in the BOHCB

1 Chronicles 16 in the BOHCV

1 Chronicles 16 in the BOHLNT

1 Chronicles 16 in the BOHNTLTAL

1 Chronicles 16 in the BOICB

1 Chronicles 16 in the BOILNTAP

1 Chronicles 16 in the BOITCV

1 Chronicles 16 in the BOKCV

1 Chronicles 16 in the BOKCV2

1 Chronicles 16 in the BOKHWOG

1 Chronicles 16 in the BOKSSV

1 Chronicles 16 in the BOLCB

1 Chronicles 16 in the BOLCB2

1 Chronicles 16 in the BOMCV

1 Chronicles 16 in the BONAV

1 Chronicles 16 in the BONCB

1 Chronicles 16 in the BONLT

1 Chronicles 16 in the BONUT2

1 Chronicles 16 in the BOPLNT

1 Chronicles 16 in the BOSCB

1 Chronicles 16 in the BOSNC

1 Chronicles 16 in the BOTLNT

1 Chronicles 16 in the BOVCB

1 Chronicles 16 in the BPBB

1 Chronicles 16 in the BPH

1 Chronicles 16 in the BSB

1 Chronicles 16 in the CCB

1 Chronicles 16 in the CUV

1 Chronicles 16 in the CUVS

1 Chronicles 16 in the DBT

1 Chronicles 16 in the DGDNT

1 Chronicles 16 in the DHNT

1 Chronicles 16 in the DNT

1 Chronicles 16 in the ELBE

1 Chronicles 16 in the EMTV

1 Chronicles 16 in the ESV

1 Chronicles 16 in the FBV

1 Chronicles 16 in the FEB

1 Chronicles 16 in the GGMNT

1 Chronicles 16 in the GNT

1 Chronicles 16 in the HARY

1 Chronicles 16 in the HNT

1 Chronicles 16 in the IRVA

1 Chronicles 16 in the IRVB

1 Chronicles 16 in the IRVG

1 Chronicles 16 in the IRVH

1 Chronicles 16 in the IRVK

1 Chronicles 16 in the IRVM

1 Chronicles 16 in the IRVM2

1 Chronicles 16 in the IRVO

1 Chronicles 16 in the IRVP

1 Chronicles 16 in the IRVT

1 Chronicles 16 in the IRVT2

1 Chronicles 16 in the IRVU

1 Chronicles 16 in the ISVN

1 Chronicles 16 in the JSNT

1 Chronicles 16 in the KAPI

1 Chronicles 16 in the KBT1ETNIK

1 Chronicles 16 in the KBV

1 Chronicles 16 in the KJV

1 Chronicles 16 in the KNFD

1 Chronicles 16 in the LBA

1 Chronicles 16 in the LBLA

1 Chronicles 16 in the LNT

1 Chronicles 16 in the LSV

1 Chronicles 16 in the MAAL

1 Chronicles 16 in the MBV

1 Chronicles 16 in the MBV2

1 Chronicles 16 in the MHNT

1 Chronicles 16 in the MKNFD

1 Chronicles 16 in the MNG

1 Chronicles 16 in the MNT

1 Chronicles 16 in the MNT2

1 Chronicles 16 in the MRS1T

1 Chronicles 16 in the NAA

1 Chronicles 16 in the NASB

1 Chronicles 16 in the NBLA

1 Chronicles 16 in the NBS

1 Chronicles 16 in the NBVTP

1 Chronicles 16 in the NET2

1 Chronicles 16 in the NIV11

1 Chronicles 16 in the NNT

1 Chronicles 16 in the NNT2

1 Chronicles 16 in the NNT3

1 Chronicles 16 in the PDDPT

1 Chronicles 16 in the PFNT

1 Chronicles 16 in the RMNT

1 Chronicles 16 in the SBIAS

1 Chronicles 16 in the SBIBS

1 Chronicles 16 in the SBIBS2

1 Chronicles 16 in the SBICS

1 Chronicles 16 in the SBIDS

1 Chronicles 16 in the SBIGS

1 Chronicles 16 in the SBIHS

1 Chronicles 16 in the SBIIS

1 Chronicles 16 in the SBIIS2

1 Chronicles 16 in the SBIIS3

1 Chronicles 16 in the SBIKS

1 Chronicles 16 in the SBIKS2

1 Chronicles 16 in the SBIMS

1 Chronicles 16 in the SBIOS

1 Chronicles 16 in the SBIPS

1 Chronicles 16 in the SBISS

1 Chronicles 16 in the SBITS

1 Chronicles 16 in the SBITS2

1 Chronicles 16 in the SBITS3

1 Chronicles 16 in the SBITS4

1 Chronicles 16 in the SBIUS

1 Chronicles 16 in the SBIVS

1 Chronicles 16 in the SBT

1 Chronicles 16 in the SBT1E

1 Chronicles 16 in the SCHL

1 Chronicles 16 in the SNT

1 Chronicles 16 in the SUSU

1 Chronicles 16 in the SUSU2

1 Chronicles 16 in the SYNO

1 Chronicles 16 in the TBIAOTANT

1 Chronicles 16 in the TBT1E

1 Chronicles 16 in the TBT1E2

1 Chronicles 16 in the TFTIP

1 Chronicles 16 in the TFTU

1 Chronicles 16 in the TGNTATF3T

1 Chronicles 16 in the THAI

1 Chronicles 16 in the TNFD

1 Chronicles 16 in the TNT

1 Chronicles 16 in the TNTIK

1 Chronicles 16 in the TNTIL

1 Chronicles 16 in the TNTIN

1 Chronicles 16 in the TNTIP

1 Chronicles 16 in the TNTIZ

1 Chronicles 16 in the TOMA

1 Chronicles 16 in the TTENT

1 Chronicles 16 in the UBG

1 Chronicles 16 in the UGV

1 Chronicles 16 in the UGV2

1 Chronicles 16 in the UGV3

1 Chronicles 16 in the VBL

1 Chronicles 16 in the VDCC

1 Chronicles 16 in the YALU

1 Chronicles 16 in the YAPE

1 Chronicles 16 in the YBVTP

1 Chronicles 16 in the ZBP