Amos 9 (BOYCB)
1 Mo rí Olúwa, ó dúró ní ẹ̀bá pẹpẹ, ó sì wí pé:“Lu orí àwọn àtẹ́rígbà ìlẹ̀kùnkí àwọn òpó kí ó lè mìfọ́ wọn sí orí àwọn gbogbo ènìyànàwọn tí ó ṣẹ́kù ni èmi yóò fi idà pa,ẹni tí ó sálọ nínú wọn kí yóò sá gbé,ẹni ti ó sá àsálà nínú wọn kí yóò gbàlà. 2 Bí wọ́n tilẹ̀ wa ilẹ̀ lọ sí ipò òkú,láti ibẹ̀ ni ọwọ́ mi yóò ti tẹ̀ wọ́n.Bí wọ́n tilẹ̀ gun òkè ọ̀run lọ,láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti mú wọn sọ̀kalẹ̀. 3 Bí wọ́n tilẹ̀ fi ara wọn pamọ́ ni orí òkè Karmeli,èmi yóò wá wọn rí, Èmi yóò si mú wọn kúrò níbẹ̀.Bí wọ́n tilẹ̀ fi ara pamọ́ fún mi sí ìsàlẹ̀ Òkun,láti ibẹ̀ ni Èmi yóò ti pàṣẹ fún ejò kí ó bù wọ́n ṣán. 4 Bí wọ́n tilẹ̀ lọ sí ìgbèkùn ní iwájú àwọn ọ̀tá wọnláti ibẹ̀ ni èmi yóò ti pàṣẹ fún idà kí ó ṣá wọn pa. “Èmi yóò sì tẹ ojú mi mọ́ wọn fún ìbí,kì í sì í ṣe fún rere.” 5 Olúwa, OLÚWA àwọn ọmọ-ogun,ẹni ti ó fi ọwọ́ kan ilẹ̀ náà tí ó sì yọ́, tí àwọn olùgbé inú rẹ̀ yóò sì ṣọ̀fọ̀;gbogbo orílẹ̀-èdè yóò si ru sókè bí ríru odò Nailitiwọn yóò sì tẹ̀rì bí odò Ejibiti. 6 Òun ni ẹni tí ó kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ nínú àwọn ọ̀runti ó sì fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ ní ilé ayé,Ẹni ti ó pe àwọn omi Òkunti ó sì tú wọn jáde si orí ilé ayé OLÚWA ni orúkọ rẹ̀. 7 “Àbá ẹ̀yin ọmọ Israẹlikò ha dàbí àwọn ọmọ Kuṣi sí mi?”ni OLÚWA wí.“Èmi kò ha ti mú Israẹli gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti jáde wáàti àwọn Filistini láti ilẹ̀ Kafitoriàti àwọn ará Aramu láti Kiri? 8 “Dájúdájú, ojú OLÚWA Olódùmarèń bẹ̀ lára ilẹ̀ ọba tó kún fún ẹ̀ṣẹ̀.Èmi yóò pa á run kúrò lórí ilẹ̀.Síbẹ̀, Èmi kò nípa ilé Jakọbu run pátápátá,”ni OLÚWA wí. 9 “Nítorí Èmi yóò pàṣẹ,Èmi yóò sì mi ilé Israẹliní àárín àwọn orílẹ̀-èdèbí a ti ń jọ nǹkan nínú ajọ̀tí hóró kín ń kín kì yóò bọ́ sórí ilẹ̀. 10 Gbogbo àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ láàrín àwọn ènìyàn mini yóò ti ipa idà kúgbogbo àwọn ti ń wí pé,‘Aburú kì yóò lé wa bá, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ká wa mọ́.’ 11 “Ní ọjọ́ náà níÈmi yóò gbé àgọ́ Dafidi tí ó wó ró,Èmi yóò dí odi rẹ̀ tí ó ya,Èmi yóò sì gbé ahoro rẹ̀ sókè,Èmi yóò sì kọ bí ti ọjọ́ ìgbàanì, 12 kí wọn le jogún ìyókù Edomuàti gbogbo àwọn kèfèrí, ti a ń pè nípa orúkọ mi,”ni OLÚWA, ẹni tí yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí wí. 13 “Ọjọ́ náà ń bọ,” ni OLÚWA wí,“tí ẹni tí ń tulẹ̀ yóò lé ẹni tí ń kórè bá.Tí ẹni tí ń fún èso àjàrà yóò lé ẹni tí ń gbìn bá.Àwọn òkè ńlá yóò sì kán ọtí wáìnì sílẹ̀,tí yóò sì sàn láti ara àwọn òkè kéékèèké. 14 Èmi yóò si tún mú ìgbèkùn Israẹli ènìyàn mi padà bọ̀. “Wọn yóò sì kọ́ ahoro ìlú, wọn yóò sì máa gbé inú wọn.Wọn yóò sì gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì mu ọtí wáìnì wọnwọn yóò sì ṣe ọgbà pẹ̀lú, wọn yóò sì jẹ èso inú wọn. 15 Èmi yóò gbin Israẹli sí orí ilẹ̀ rẹ̀.A kì yóò sì fà wọn tu mọ́ láéláékúrò ni orí ilẹ̀ ti mo fi fún wọn,”ni OLÚWA Ọlọ́run rẹ wí.
In Other Versions
Amos 9 in the ANGEFD
Amos 9 in the ANTPNG2D
Amos 9 in the AS21
Amos 9 in the BAGH
Amos 9 in the BBPNG
Amos 9 in the BBT1E
Amos 9 in the BDS
Amos 9 in the BEV
Amos 9 in the BHAD
Amos 9 in the BIB
Amos 9 in the BLPT
Amos 9 in the BNT
Amos 9 in the BNTABOOT
Amos 9 in the BNTLV
Amos 9 in the BOATCB
Amos 9 in the BOATCB2
Amos 9 in the BOBCV
Amos 9 in the BOCNT
Amos 9 in the BOECS
Amos 9 in the BOGWICC
Amos 9 in the BOHCB
Amos 9 in the BOHCV
Amos 9 in the BOHLNT
Amos 9 in the BOHNTLTAL
Amos 9 in the BOICB
Amos 9 in the BOILNTAP
Amos 9 in the BOITCV
Amos 9 in the BOKCV
Amos 9 in the BOKCV2
Amos 9 in the BOKHWOG
Amos 9 in the BOKSSV
Amos 9 in the BOLCB
Amos 9 in the BOLCB2
Amos 9 in the BOMCV
Amos 9 in the BONAV
Amos 9 in the BONCB
Amos 9 in the BONLT
Amos 9 in the BONUT2
Amos 9 in the BOPLNT
Amos 9 in the BOSCB
Amos 9 in the BOSNC
Amos 9 in the BOTLNT
Amos 9 in the BOVCB
Amos 9 in the BPBB
Amos 9 in the BPH
Amos 9 in the BSB
Amos 9 in the CCB
Amos 9 in the CUV
Amos 9 in the CUVS
Amos 9 in the DBT
Amos 9 in the DGDNT
Amos 9 in the DHNT
Amos 9 in the DNT
Amos 9 in the ELBE
Amos 9 in the EMTV
Amos 9 in the ESV
Amos 9 in the FBV
Amos 9 in the FEB
Amos 9 in the GGMNT
Amos 9 in the GNT
Amos 9 in the HARY
Amos 9 in the HNT
Amos 9 in the IRVA
Amos 9 in the IRVB
Amos 9 in the IRVG
Amos 9 in the IRVH
Amos 9 in the IRVK
Amos 9 in the IRVM
Amos 9 in the IRVM2
Amos 9 in the IRVO
Amos 9 in the IRVP
Amos 9 in the IRVT
Amos 9 in the IRVT2
Amos 9 in the IRVU
Amos 9 in the ISVN
Amos 9 in the JSNT
Amos 9 in the KAPI
Amos 9 in the KBT1ETNIK
Amos 9 in the KBV
Amos 9 in the KJV
Amos 9 in the KNFD
Amos 9 in the LBA
Amos 9 in the LBLA
Amos 9 in the LNT
Amos 9 in the LSV
Amos 9 in the MAAL
Amos 9 in the MBV
Amos 9 in the MBV2
Amos 9 in the MHNT
Amos 9 in the MKNFD
Amos 9 in the MNG
Amos 9 in the MNT
Amos 9 in the MNT2
Amos 9 in the MRS1T
Amos 9 in the NAA
Amos 9 in the NASB
Amos 9 in the NBLA
Amos 9 in the NBS
Amos 9 in the NBVTP
Amos 9 in the NET2
Amos 9 in the NIV11
Amos 9 in the NNT
Amos 9 in the NNT2
Amos 9 in the NNT3
Amos 9 in the PDDPT
Amos 9 in the PFNT
Amos 9 in the RMNT
Amos 9 in the SBIAS
Amos 9 in the SBIBS
Amos 9 in the SBIBS2
Amos 9 in the SBICS
Amos 9 in the SBIDS
Amos 9 in the SBIGS
Amos 9 in the SBIHS
Amos 9 in the SBIIS
Amos 9 in the SBIIS2
Amos 9 in the SBIIS3
Amos 9 in the SBIKS
Amos 9 in the SBIKS2
Amos 9 in the SBIMS
Amos 9 in the SBIOS
Amos 9 in the SBIPS
Amos 9 in the SBISS
Amos 9 in the SBITS
Amos 9 in the SBITS2
Amos 9 in the SBITS3
Amos 9 in the SBITS4
Amos 9 in the SBIUS
Amos 9 in the SBIVS
Amos 9 in the SBT
Amos 9 in the SBT1E
Amos 9 in the SCHL
Amos 9 in the SNT
Amos 9 in the SUSU
Amos 9 in the SUSU2
Amos 9 in the SYNO
Amos 9 in the TBIAOTANT
Amos 9 in the TBT1E
Amos 9 in the TBT1E2
Amos 9 in the TFTIP
Amos 9 in the TFTU
Amos 9 in the TGNTATF3T
Amos 9 in the THAI
Amos 9 in the TNFD
Amos 9 in the TNT
Amos 9 in the TNTIK
Amos 9 in the TNTIL
Amos 9 in the TNTIN
Amos 9 in the TNTIP
Amos 9 in the TNTIZ
Amos 9 in the TOMA
Amos 9 in the TTENT
Amos 9 in the UBG
Amos 9 in the UGV
Amos 9 in the UGV2
Amos 9 in the UGV3
Amos 9 in the VBL
Amos 9 in the VDCC
Amos 9 in the YALU
Amos 9 in the YAPE
Amos 9 in the YBVTP
Amos 9 in the ZBP