Deuteronomy 32 (BOYCB)

1 Fetísílẹ̀, ẹ̀yin ọ̀run, èmi yóò sọ̀rọ̀;ẹ gbọ́, ìwọ ayé, ọ̀rọ̀ ẹnu mi. 2 Jẹ́ kí ẹ̀kọ́ ọ̀ mi máa rọ̀ bí òjò,kí àwọn ọ̀rọ̀ mi máa sọ̀kalẹ̀ bí ìrì,bí òjò wíníwíní sára ewéko tuntun,bí ọ̀wààrà òjò sára ohun ọ̀gbìn. 3 Èmi yóò kókìkí orúkọ OLÚWA.Ẹyin títóbi Ọlọ́run wa! 4 Òun ni àpáta, iṣẹ́ ẹ rẹ̀ jẹ́ pípé,gbogbo ọ̀nà an rẹ̀ jẹ́ òdodo.Ọlọ́run olóòtítọ́ tí kò ṣe àṣìṣe kan,Ó dúró ṣinṣin, òdodo àti òtítọ́ ni òun. 5 Wọ́n ti ṣe iṣẹ́ ìbàjẹ́ sọ́dọ̀ ọ rẹ̀;fún ìtìjú u wọn, wọn kì í ṣe ọmọ rẹ̀ mọ́,ṣùgbọ́n ìran tí ó yí sí apá kan tí ó sì dorí kodò. 6 Ṣé báyìí ni ẹ̀yin yóò ṣe san an fún OLÚWA,ẹ̀yin aṣiwèrè àti aláìgbọ́n ènìyàn?Ǹjẹ́ òun kọ́ ni baba yín, Ẹlẹ́dàá yín,tí ó dá a yín tí ó sì mọ yín? 7 Rántí ìgbà láéláé;wádìí àwọn ìran tí ó ti kọjá.Béèrè lọ́wọ́ baba à rẹ yóò sì sọ fún ọ,àwọn àgbàgbà rẹ, wọn yóò sì ṣàlàyé fún ọ. 8 Nígbà tí Ọ̀gá-ògo fi ogún àwọn orílẹ̀-èdè fún wọn,nígbà tí ó pín onírúurú ènìyàn,ó sì gbé ààlà kalẹ̀ fún àwọn ènìyàngẹ́gẹ́ bí iye ọmọkùnrin Israẹli. 9 Nítorí ìpín OLÚWA ni àwọn ènìyàn an rẹ̀,Jakọbu ni ìpín ìní i rẹ̀. 10 Ní aginjù ni ó ti rí i,ní aginjù níbi tí ẹranko kò sí.Ó yíká, ó sì tọ́jú rẹ̀,ó pa á mọ́ bí ẹyin ojú u rẹ̀. 11 Bí idì ti í ru ìtẹ́ rẹ̀ ti ó sì ńrábàbà sórí ọmọ rẹ̀,tí ó na ìyẹ́ apá rẹ̀ láti gbé wọn ki ó sìgbé wọn sórí ìyẹ́ apá rẹ̀. 12 OLÚWA ṣamọ̀nà;kò sì sí ọlọ́run àjèjì pẹ̀lú rẹ̀. 13 Ó mú gun ibi gíga ayéó sì fi èso oko bọ́ ọ.Ó sì jẹ́ kí ó mú oyin láti inú àpáta wá,àti òróró láti inú akọ òkúta wá. 14 Pẹ̀lú u wàràǹkàṣì àti wàrà àgùntànàti ti àgbò ẹranàti pẹ̀lú ọ̀rá ọ̀dọ́-àgùntàn àti ewúrẹ́,pẹ̀lú àgbò irú u ti Baṣanití ó sì mu ẹ̀jẹ̀ èso àjàrà, àní àti wáìnì. 15 Jeṣuruni sanra tán ó sì tàpá;ìwọ sanra tán, ìwọ ki tan, ọ̀rá sì bò ọ́ tán.O kọ Ọlọ́run tí ó dá ọo sì kọ àpáta ìgbàlà rẹ. 16 Wọ́n sì fi òrìṣà mú un jowú,ohun ìríra ni wọ́n fi mú un bínú. 17 Wọ́n rú ẹbọ sí iwin búburú, tí kì í ṣe Ọlọ́run,ọlọ́run tí wọn kò mọ̀ rí,ọlọ́run tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ farahàn láìpẹ́,ọlọ́run tí àwọn baba yín kò bẹ̀rù. 18 Ìwọ kò rántí àpáta, tí ó bí ọ;o sì gbàgbé Ọlọ́run tí ó dá ọ. 19 OLÚWA sì rí èyí ó sì kọ̀ wọ́n,nítorí tí ó ti bínú nítorí ìwà ìmúnibínú àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ. 20 Ó sì wí pé, “Èmi yóò pa ojú mi mọ́ kúrò lára wọn,èmi yóò sì wò ó bí ìgbẹ̀yìn in wọn yóò ti rí;nítorí wọ́n jẹ́ ìran alágídí,àwọn ọmọ tí kò sí ìgbàgbọ́ nínú wọn. 21 Wọ́n fi mí jowú nípa ohun tí kì í ṣe Ọlọ́run,wọ́n sì fi ohun asán an wọn mú mi bínú.Èmi yóò mú wọn kún fún ìlara láti ọ̀dọ̀ àwọn tí kì í ṣe ènìyàn;èmi yóò sì mú wọn bínú láti ọ̀dọ̀ aṣiwèrè orílẹ̀-èdè. 22 Nítorí pé iná kan ràn nínú ìbínú mi,yóò sì jó dé ipò ikú ní ìsàlẹ̀.Yóò sì run ayé àti ìkórè e rẹ̀yóò sì tiná bọ ìpìlẹ̀ àwọn òkè ńlá. 23 “Èmi yóò kó àwọn ohun búburú lé wọn lóríèmi ó sì na ọfà mi tán sí wọn lára. 24 Èmi yóò mú wọn gbẹ,ooru gbígbóná àti ìparun kíkorò ni a ó fi run wọ́n.Pẹ̀lú oró ohun tí ń rákò nínú erùpẹ̀. 25 Idà ní òde, àti ẹ̀rù nínú ìyẹ̀wù,ni yóò run ọmọkùnrin àti wúńdíá.Ọmọ ẹnu ọmú àti arúgbó eléwú irun pẹ̀lú. 26 Mo ní èmi yóò tú wọn káèmi yóò sì mú ìrántí i wọn dà kúrò nínú àwọn ènìyàn, 27 nítorí bí mo ti bẹ̀rù ìbínú ọ̀tá,kí àwọn ọ̀tá a wọn kí ó mába à wí pé, ‘Ọwọ́ wa lékè ni;kì í sì í ṣe OLÚWA ni ó ṣe gbogbo èyí.’ ” 28 Wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè tí kò ní ìmọ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò sí òye nínú wọn. 29 Bí ó ṣe pé wọ́n gbọ́n, kí òye yìí sì yé wọnkí wọn ro bí ìgbẹ̀yìn wọn yóò ti rí! 30 Báwo ni ẹnìkan ṣe lè lé ẹgbẹ̀rún (1,000),tàbí tí ẹni méjì sì lè lé ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) sá,bí kò ṣe pé àpáta wọn ti tà wọ́n,bí kò ṣe pé OLÚWA wọn ti fi wọ́n tọrẹ? 31 Nítorí pé àpáta wọn kò dàbí àpáta wa,àní àwọn ọ̀tá wa tìkára wọn ń ṣe onídàájọ́. 32 Igi àjàrà a wọn wá láti igi àjàrà Sodomuàti ti ìgbẹ́ ẹ Gomorra.Èso àjàrà wọn kún fún oró,ìdì wọn korò. 33 Ọtí wáìnì wọn ìwọ ti dragoni ni,àti oró mímú ti ejò paramọ́lẹ̀. 34 “Èmi kò to èyí jọ ní ìpamọ́èmi kò sì fi èdìdì dì í ní ìṣúra mi? 35 Ti èmi ni láti gbẹ̀san. Èmi yóò san án fún wọnní àkókò tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn yóò yọ;ọjọ́ ìdààmú wọn súnmọ́ etíléohun tí ó sì ń bọ̀ wá bá wọn yára bọ̀.” 36 OLÚWA yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn an rẹ̀yóò sì ṣàánú fún àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀nígbà tí ó bá rí i pé agbára wọn lọ tántí kò sì sí ẹnìkan tí ó kù, ẹrú tàbí ọmọ. 37 Yóò wí pé, “Òrìṣà wọn dà báyìí,àpáta tí wọ́n fi ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé e wọn, 38 ọlọ́run tí ó jẹ ọ̀rá ẹran ẹbọ wọntí ó ti mu ọtí i wáìnì ẹbọ ohun mímu wọn?Jẹ́ kí wọn dìde láti gbà wọ́n!Jẹ́ kí wọn ṣe ààbò fún un yín! 39 “Wò ó báyìí pé, Èmi fúnra à mi, Èmi ni!Kò sí ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi.Mo sọ di kíkú mo sì tún sọ di ààyè.Mo ti ṣá lọ́gbẹ́ Èmi yóò sì mu jiná,kò sí ẹni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ ọ̀ mi. 40 Mo gbé ọwọ́ mi sókè ọ̀run mo sì wí pé,Èmi ti wà láààyè títí láé, 41 nígbà tí mo bá pọ́n idà dídán miàti tí mo bá sì fi ọwọ́ mi lé ìdájọ́,Èmi yóò san ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá miÈmi ó sì san fún àwọn tí ó kórìíra à mi. 42 Èmi yóò mú ọfà mu ẹ̀jẹ̀,nígbà tí idà mi bá jẹ ẹran:ẹ̀jẹ̀ ẹni pípa àti ẹni ìgbèkùn,láti orí àwọn aṣáájú ọ̀tá.” 43 Ẹ yọ̀ ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀nítorí òun yóò gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀;yóò sì gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá a rẹ̀yóò sì ṣe ètùtù fún ilẹ̀ àti ènìyàn rẹ̀. 44 Mose sì wá ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí ní etí àwọn ènìyàn náà, òun, àti Hosea ọmọ Nuni. 45 Nígbà tí Mose parí i kíka gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí Israẹli. 46 Ó sọ fún un pé, “Ẹ gbé ọkàn an yín lé gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ láàrín yín lónìí, kí ẹ̀yin lè pàṣẹ fún àwọn ọmọ yín láti gbọ́rọ̀ àti láti ṣe gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí. 47 Wọn kì í ṣe ọ̀rọ̀ asán fún ọ, ìyè e yín ni wọ́n. Nípa wọn ni ẹ̀yin yóò gbé pẹ́ lórí ilẹ̀ tí ẹ̀yin ń gòkè e Jordani lọ láti gbà.” 48 Ní ọjọ́ kan náà, OLÚWA sọ fún Mose pé, 49 “Gòkè lọ sí Abarimu sí òkè Nebo ní Moabu, tí ó kọjú sí Jeriko, kí o sì wo ilẹ̀ Kenaani, ilẹ̀ tí mo ń fi fún àwọn ọmọ Israẹli, bí ìní i wọn. 50 Ní orí òkè tí ìwọ ń gùn lọ ìwọ yóò kùú níbẹ̀, kí a sì sin ọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ, gẹ́gẹ́ bí arákùnrin in rẹ Aaroni ti kú ní orí òkè Hori tí a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn an rẹ̀. 51 Ìdí ni pé ẹ̀yin méjèèjì ṣẹ̀ sí mi láàrín àwọn ọmọ Israẹli ní ibi omi Meriba Kadeṣi ní aginjù Sini àti nítorí ẹ̀yin kò yà mí sí mímọ́ láàrín àwọn ọmọ Israẹli. 52 Nítorí náà, ìwọ yóò rí ilẹ̀ náà ní ọ̀kánkán, o kì yóò wọ inú rẹ̀ ilẹ̀ ti mo ti fi fún àwọn ọmọ Israẹli.”

In Other Versions

Deuteronomy 32 in the ANGEFD

Deuteronomy 32 in the ANTPNG2D

Deuteronomy 32 in the AS21

Deuteronomy 32 in the BAGH

Deuteronomy 32 in the BBPNG

Deuteronomy 32 in the BBT1E

Deuteronomy 32 in the BDS

Deuteronomy 32 in the BEV

Deuteronomy 32 in the BHAD

Deuteronomy 32 in the BIB

Deuteronomy 32 in the BLPT

Deuteronomy 32 in the BNT

Deuteronomy 32 in the BNTABOOT

Deuteronomy 32 in the BNTLV

Deuteronomy 32 in the BOATCB

Deuteronomy 32 in the BOATCB2

Deuteronomy 32 in the BOBCV

Deuteronomy 32 in the BOCNT

Deuteronomy 32 in the BOECS

Deuteronomy 32 in the BOGWICC

Deuteronomy 32 in the BOHCB

Deuteronomy 32 in the BOHCV

Deuteronomy 32 in the BOHLNT

Deuteronomy 32 in the BOHNTLTAL

Deuteronomy 32 in the BOICB

Deuteronomy 32 in the BOILNTAP

Deuteronomy 32 in the BOITCV

Deuteronomy 32 in the BOKCV

Deuteronomy 32 in the BOKCV2

Deuteronomy 32 in the BOKHWOG

Deuteronomy 32 in the BOKSSV

Deuteronomy 32 in the BOLCB

Deuteronomy 32 in the BOLCB2

Deuteronomy 32 in the BOMCV

Deuteronomy 32 in the BONAV

Deuteronomy 32 in the BONCB

Deuteronomy 32 in the BONLT

Deuteronomy 32 in the BONUT2

Deuteronomy 32 in the BOPLNT

Deuteronomy 32 in the BOSCB

Deuteronomy 32 in the BOSNC

Deuteronomy 32 in the BOTLNT

Deuteronomy 32 in the BOVCB

Deuteronomy 32 in the BPBB

Deuteronomy 32 in the BPH

Deuteronomy 32 in the BSB

Deuteronomy 32 in the CCB

Deuteronomy 32 in the CUV

Deuteronomy 32 in the CUVS

Deuteronomy 32 in the DBT

Deuteronomy 32 in the DGDNT

Deuteronomy 32 in the DHNT

Deuteronomy 32 in the DNT

Deuteronomy 32 in the ELBE

Deuteronomy 32 in the EMTV

Deuteronomy 32 in the ESV

Deuteronomy 32 in the FBV

Deuteronomy 32 in the FEB

Deuteronomy 32 in the GGMNT

Deuteronomy 32 in the GNT

Deuteronomy 32 in the HARY

Deuteronomy 32 in the HNT

Deuteronomy 32 in the IRVA

Deuteronomy 32 in the IRVB

Deuteronomy 32 in the IRVG

Deuteronomy 32 in the IRVH

Deuteronomy 32 in the IRVK

Deuteronomy 32 in the IRVM

Deuteronomy 32 in the IRVM2

Deuteronomy 32 in the IRVO

Deuteronomy 32 in the IRVP

Deuteronomy 32 in the IRVT

Deuteronomy 32 in the IRVT2

Deuteronomy 32 in the IRVU

Deuteronomy 32 in the ISVN

Deuteronomy 32 in the JSNT

Deuteronomy 32 in the KAPI

Deuteronomy 32 in the KBT1ETNIK

Deuteronomy 32 in the KBV

Deuteronomy 32 in the KJV

Deuteronomy 32 in the KNFD

Deuteronomy 32 in the LBA

Deuteronomy 32 in the LBLA

Deuteronomy 32 in the LNT

Deuteronomy 32 in the LSV

Deuteronomy 32 in the MAAL

Deuteronomy 32 in the MBV

Deuteronomy 32 in the MBV2

Deuteronomy 32 in the MHNT

Deuteronomy 32 in the MKNFD

Deuteronomy 32 in the MNG

Deuteronomy 32 in the MNT

Deuteronomy 32 in the MNT2

Deuteronomy 32 in the MRS1T

Deuteronomy 32 in the NAA

Deuteronomy 32 in the NASB

Deuteronomy 32 in the NBLA

Deuteronomy 32 in the NBS

Deuteronomy 32 in the NBVTP

Deuteronomy 32 in the NET2

Deuteronomy 32 in the NIV11

Deuteronomy 32 in the NNT

Deuteronomy 32 in the NNT2

Deuteronomy 32 in the NNT3

Deuteronomy 32 in the PDDPT

Deuteronomy 32 in the PFNT

Deuteronomy 32 in the RMNT

Deuteronomy 32 in the SBIAS

Deuteronomy 32 in the SBIBS

Deuteronomy 32 in the SBIBS2

Deuteronomy 32 in the SBICS

Deuteronomy 32 in the SBIDS

Deuteronomy 32 in the SBIGS

Deuteronomy 32 in the SBIHS

Deuteronomy 32 in the SBIIS

Deuteronomy 32 in the SBIIS2

Deuteronomy 32 in the SBIIS3

Deuteronomy 32 in the SBIKS

Deuteronomy 32 in the SBIKS2

Deuteronomy 32 in the SBIMS

Deuteronomy 32 in the SBIOS

Deuteronomy 32 in the SBIPS

Deuteronomy 32 in the SBISS

Deuteronomy 32 in the SBITS

Deuteronomy 32 in the SBITS2

Deuteronomy 32 in the SBITS3

Deuteronomy 32 in the SBITS4

Deuteronomy 32 in the SBIUS

Deuteronomy 32 in the SBIVS

Deuteronomy 32 in the SBT

Deuteronomy 32 in the SBT1E

Deuteronomy 32 in the SCHL

Deuteronomy 32 in the SNT

Deuteronomy 32 in the SUSU

Deuteronomy 32 in the SUSU2

Deuteronomy 32 in the SYNO

Deuteronomy 32 in the TBIAOTANT

Deuteronomy 32 in the TBT1E

Deuteronomy 32 in the TBT1E2

Deuteronomy 32 in the TFTIP

Deuteronomy 32 in the TFTU

Deuteronomy 32 in the TGNTATF3T

Deuteronomy 32 in the THAI

Deuteronomy 32 in the TNFD

Deuteronomy 32 in the TNT

Deuteronomy 32 in the TNTIK

Deuteronomy 32 in the TNTIL

Deuteronomy 32 in the TNTIN

Deuteronomy 32 in the TNTIP

Deuteronomy 32 in the TNTIZ

Deuteronomy 32 in the TOMA

Deuteronomy 32 in the TTENT

Deuteronomy 32 in the UBG

Deuteronomy 32 in the UGV

Deuteronomy 32 in the UGV2

Deuteronomy 32 in the UGV3

Deuteronomy 32 in the VBL

Deuteronomy 32 in the VDCC

Deuteronomy 32 in the YALU

Deuteronomy 32 in the YAPE

Deuteronomy 32 in the YBVTP

Deuteronomy 32 in the ZBP