Exodus 35 (BOYCB)
1 Mose pe gbogbo ìjọ Israẹli ó sì wí fún wọn pé, “Wọ̀nyí ni àwọn ohun ti OLÚWA ti pàṣẹ fún un yín láti ṣe. 2 Fún ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje yóò jẹ́ ọjọ́ mímọ́ fún yín, ọjọ́ ìsinmi ni sí OLÚWA. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kankan ni ọjọ́ náà ní a ó pa. 3 Ẹ má ṣe dáná kankan ní ibùgbé yín ní ọjọ́ ìsinmi.” 4 Mose sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli pé, “Èyí ni ohun tí OLÚWA pàṣẹ. 5 Láti inú ohun tí ẹ ni ni kí ẹ ti mú ọrẹ fún OLÚWA. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ ni kí ó mú ọrẹ fún OLÚWA ní ti: “wúrà, fàdákà àti idẹ; 6 aṣọ aláró, elése àlùkò, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára;àti irun ewúrẹ́; 7 awọ àgbò tí a kùn ní pupa àti awọ màlúù;odò igi kasia; 8 òróró olifi fún títan iná;olóòórùn fún òróró ìtasórí, àti fún tùràrí dídùn; 9 òkúta óníkìsì àti òkúta tí a tò sí ẹ̀wù efodu àti ìgbàyà. 10 “Gbogbo ẹni tí ó ní ọgbọ́n láàrín yín, kí ó wa, kí ó sì wá ṣe gbogbo ohun tí OLÚWA ti pàṣẹ: 11 “àgọ́ náà pẹ̀lú àgọ́ rẹ àti ìbòrí rẹ̀, kọ́kọ́rọ́ rẹ̀, pákó rẹ̀, ọ̀pá rẹ̀, ọ̀wọ́n rẹ̀ àti ihò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀; 12 Àpótí náà pẹ̀lú ọ̀pá rẹ̀, ìbò àánú àti aṣọ títa náà tí ó síji bò ó. 13 Tábìlì náà pẹ̀lú òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ àti àkàrà ìfihàn náà. 14 Ọ̀pá fìtílà tí ó wà fún títanná pẹ̀lú ohun èlò rẹ̀, fìtílà àti òróró fún títanná. 15 Pẹpẹ tùràrí náà pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀, òróró ìtasórí àti tùràrí dídùn;aṣọ títa fún ọ̀nà ìlẹ̀kùn ní ẹnu-ọ̀nà sí àgọ́ náà. 16 Pẹpẹ ẹbọ sísun pẹ̀lú ojú ààrò idẹ rẹ̀, òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀;agbada idẹ pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀. 17 Aṣọ títa ti àgbàlá pẹ̀lú, ọ̀wọ́n àti ihò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀ àti aṣọ títa fún ẹnu-ọ̀nà àgbàlá náà. 18 Èèkàn àgọ́ náà fún àgọ́ náà àti fún àgbàlá àti okùn wọn. 19 Aṣọ híhun láti ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́ aṣọ mímọ́ fún Aaroni àlùfáà àti aṣọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n sìn bí àlùfáà.” 20 Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli sì kúrò níwájú Mose, 21 olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ àti ẹni tí ọkàn rẹ̀ gbé sókè wá, wọ́n sì mú ọrẹ fún OLÚWA, fún iṣẹ́ àgọ́ àjọ, fún gbogbo ìsìn rẹ̀ àti fún aṣọ mímọ́ náà. 22 Gbogbo àwọn tí ó fẹ́, ọkùnrin àti obìnrin, wọ́n wá wọ́n sì mú onírúurú ìlẹ̀kẹ̀ wúrà: òrùka etí, òrùka àti ọ̀ṣọ́. Gbogbo wọn mú wúrà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ wá fún OLÚWA. 23 Olúkúlùkù ẹni tí ó ni aṣọ aláró elése àlùkò, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára, tàbí irun ewúrẹ́, awọ àgbò tí a rì ní pupa tàbí awọ màlúù odò, kí ó mú wọn wá. 24 Àwọn tí ó mú ọrẹ fàdákà tàbí idẹ wá, mú ọrẹ wá fún OLÚWA, àti olúkúlùkù ẹni tí ó ní igi ṣittimu fún ipa kankan nínú iṣẹ́ mú un wá. 25 Gbogbo àwọn obìnrin tí ó ní ọgbọ́n ríran owú pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀, kí ó mú èyí ti ó ti ran wá ti aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó tàbí ti ọ̀gbọ̀ dáradára. 26 Gbogbo àwọn obìnrin tí ó fẹ́, tí ó sì ní ọgbọ́n ń ran òwú irun ewúrẹ́. 27 Àwọn olórí mú òkúta óníkìsì wá láti tò ó lórí ẹ̀wù efodu àti ìgbàyà. 28 Wọ́n sì tún mú olóòórùn àti òróró olifi wá fún títanná àti fún òróró ìtasórí àti fún tùràrí dídùn. 29 Gbogbo àwọn ènìyàn Israẹli ọkùnrin àti obìnrin ẹni tí ó fẹ́ mú ọrẹ àtinúwá fún OLÚWA fún gbogbo iṣẹ́ tí OLÚWA ti pàṣẹ fún wọn láti ṣe nípasẹ̀ Mose. 30 Nígbà náà ni Mose wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Wò ó, OLÚWA ti yan Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀yà Juda, 31 Ó sì ti fi Ẹ̀mí Ọlọ́run kún un, pẹ̀lú ọgbọ́n, òye, ìmọ̀ àti gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà. 32 Láti máa ṣe aláràbarà iṣẹ́ ní ti wúrà, fàdákà àti idẹ, 33 láti gbẹ́ òkúta àti láti tò ó, láti fún igi àti láti ṣiṣẹ́ ni gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà. 34 Ó sì fún òun àti Oholiabu ọmọ Ahisamaki ti ẹ̀yà Dani, ni agbára láti kọ́ àwọn tókù. 35 Ó sì fi ọgbọ́n kún wọn láti ṣe gbogbo onírúurú iṣẹ́, ti oníṣọ̀nà, ti ayàwòrán, ti aránsọ, ti aláṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó àti ní ọ̀gbọ̀ dáradára àti ti ahunṣọ, gbogbo èyí tí ọ̀gá oníṣẹ́-ọnà àti ayàwòrán ń ṣe.
In Other Versions
Exodus 35 in the ANGEFD
Exodus 35 in the ANTPNG2D
Exodus 35 in the AS21
Exodus 35 in the BAGH
Exodus 35 in the BBPNG
Exodus 35 in the BBT1E
Exodus 35 in the BDS
Exodus 35 in the BEV
Exodus 35 in the BHAD
Exodus 35 in the BIB
Exodus 35 in the BLPT
Exodus 35 in the BNT
Exodus 35 in the BNTABOOT
Exodus 35 in the BNTLV
Exodus 35 in the BOATCB
Exodus 35 in the BOATCB2
Exodus 35 in the BOBCV
Exodus 35 in the BOCNT
Exodus 35 in the BOECS
Exodus 35 in the BOGWICC
Exodus 35 in the BOHCB
Exodus 35 in the BOHCV
Exodus 35 in the BOHLNT
Exodus 35 in the BOHNTLTAL
Exodus 35 in the BOICB
Exodus 35 in the BOILNTAP
Exodus 35 in the BOITCV
Exodus 35 in the BOKCV
Exodus 35 in the BOKCV2
Exodus 35 in the BOKHWOG
Exodus 35 in the BOKSSV
Exodus 35 in the BOLCB
Exodus 35 in the BOLCB2
Exodus 35 in the BOMCV
Exodus 35 in the BONAV
Exodus 35 in the BONCB
Exodus 35 in the BONLT
Exodus 35 in the BONUT2
Exodus 35 in the BOPLNT
Exodus 35 in the BOSCB
Exodus 35 in the BOSNC
Exodus 35 in the BOTLNT
Exodus 35 in the BOVCB
Exodus 35 in the BPBB
Exodus 35 in the BPH
Exodus 35 in the BSB
Exodus 35 in the CCB
Exodus 35 in the CUV
Exodus 35 in the CUVS
Exodus 35 in the DBT
Exodus 35 in the DGDNT
Exodus 35 in the DHNT
Exodus 35 in the DNT
Exodus 35 in the ELBE
Exodus 35 in the EMTV
Exodus 35 in the ESV
Exodus 35 in the FBV
Exodus 35 in the FEB
Exodus 35 in the GGMNT
Exodus 35 in the GNT
Exodus 35 in the HARY
Exodus 35 in the HNT
Exodus 35 in the IRVA
Exodus 35 in the IRVB
Exodus 35 in the IRVG
Exodus 35 in the IRVH
Exodus 35 in the IRVK
Exodus 35 in the IRVM
Exodus 35 in the IRVM2
Exodus 35 in the IRVO
Exodus 35 in the IRVP
Exodus 35 in the IRVT
Exodus 35 in the IRVT2
Exodus 35 in the IRVU
Exodus 35 in the ISVN
Exodus 35 in the JSNT
Exodus 35 in the KAPI
Exodus 35 in the KBT1ETNIK
Exodus 35 in the KBV
Exodus 35 in the KJV
Exodus 35 in the KNFD
Exodus 35 in the LBA
Exodus 35 in the LBLA
Exodus 35 in the LNT
Exodus 35 in the LSV
Exodus 35 in the MAAL
Exodus 35 in the MBV
Exodus 35 in the MBV2
Exodus 35 in the MHNT
Exodus 35 in the MKNFD
Exodus 35 in the MNG
Exodus 35 in the MNT
Exodus 35 in the MNT2
Exodus 35 in the MRS1T
Exodus 35 in the NAA
Exodus 35 in the NASB
Exodus 35 in the NBLA
Exodus 35 in the NBS
Exodus 35 in the NBVTP
Exodus 35 in the NET2
Exodus 35 in the NIV11
Exodus 35 in the NNT
Exodus 35 in the NNT2
Exodus 35 in the NNT3
Exodus 35 in the PDDPT
Exodus 35 in the PFNT
Exodus 35 in the RMNT
Exodus 35 in the SBIAS
Exodus 35 in the SBIBS
Exodus 35 in the SBIBS2
Exodus 35 in the SBICS
Exodus 35 in the SBIDS
Exodus 35 in the SBIGS
Exodus 35 in the SBIHS
Exodus 35 in the SBIIS
Exodus 35 in the SBIIS2
Exodus 35 in the SBIIS3
Exodus 35 in the SBIKS
Exodus 35 in the SBIKS2
Exodus 35 in the SBIMS
Exodus 35 in the SBIOS
Exodus 35 in the SBIPS
Exodus 35 in the SBISS
Exodus 35 in the SBITS
Exodus 35 in the SBITS2
Exodus 35 in the SBITS3
Exodus 35 in the SBITS4
Exodus 35 in the SBIUS
Exodus 35 in the SBIVS
Exodus 35 in the SBT
Exodus 35 in the SBT1E
Exodus 35 in the SCHL
Exodus 35 in the SNT
Exodus 35 in the SUSU
Exodus 35 in the SUSU2
Exodus 35 in the SYNO
Exodus 35 in the TBIAOTANT
Exodus 35 in the TBT1E
Exodus 35 in the TBT1E2
Exodus 35 in the TFTIP
Exodus 35 in the TFTU
Exodus 35 in the TGNTATF3T
Exodus 35 in the THAI
Exodus 35 in the TNFD
Exodus 35 in the TNT
Exodus 35 in the TNTIK
Exodus 35 in the TNTIL
Exodus 35 in the TNTIN
Exodus 35 in the TNTIP
Exodus 35 in the TNTIZ
Exodus 35 in the TOMA
Exodus 35 in the TTENT
Exodus 35 in the UBG
Exodus 35 in the UGV
Exodus 35 in the UGV2
Exodus 35 in the UGV3
Exodus 35 in the VBL
Exodus 35 in the VDCC
Exodus 35 in the YALU
Exodus 35 in the YAPE
Exodus 35 in the YBVTP
Exodus 35 in the ZBP