Ezekiel 14 (BOYCB)
1 Díẹ̀ nínú àwọn àgbàgbà Israẹli wá sọ́dọ̀ mi, wọ́n sì jókòó níwájú mi. 2 Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ̀ mí wá, 3 “Ọmọ ènìyàn, àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ti gbé òrìṣà kalẹ̀ sínú ọkàn wọn, wọ́n sì gbé àwọn ohun tó lè mú wọn ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ síwájú wọn; Èmi yóò ha jẹ́ kí wọ́n béèrè lọ́wọ́ mi rárá bí? 4 Nítorí náà, sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni OLÚWA Olódùmarè wí: Bí ẹnikẹ́ni ní ilé Israẹli tó gbé òrìṣà sí ọkàn rẹ̀, tó tún gbé ohun ìkọ̀sẹ̀ síwájú rẹ̀, tí ó sì wá sọ́dọ̀ wòlíì, Èmi OLÚWA fúnra mi ni yóò dá ẹni tí ó wa lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà ìbọ̀rìṣà rẹ. 5 Èmi yóò ṣe èyí láti gba ọkàn àwọn ará Israẹli tó ti tẹ̀lé òrìṣà wọn lọ padà sí ọ̀dọ̀ mi.’ 6 “Nítorí náà sọ fún ilé Israẹli, ‘Èyí ni ohun tí OLÚWA Olódùmarè wí: Ẹ ronúpìwàdà! Ẹ yípadà kúrò lọ́dọ̀ òrìṣà yín, kí ẹ̀yin sì kọ gbogbo ìwà ìríra yín sílẹ̀! 7 “ ‘Bí ẹnikẹ́ni ní ilé Israẹli tàbí àlejò tó ń gbé ní ilẹ̀ Israẹli, bá ya ara rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi, tó gbé òrìṣà rẹ̀ sí ọkàn rẹ̀, tó tún gbé ohun tó mú ni ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ síwájú rẹ, lẹ́yìn èyí tó tún lọ sọ́dọ̀ wòlíì láti béèrè nǹkan lọ́wọ́ mi! Èmi OLÚWA fúnra ara mi ní èmi yóò dá a lóhùn. 8 Èmi yóò lòdì si irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ lọ́nà òdì, Èmi yóò sì fi i ṣe àmì àti òwe. Èmi yóò sì gé e kúrò láàrín àwọn ènìyàn mi. Nígbà náà, ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni OLÚWA. 9 “ ‘Bí wọ́n bá sì tan wòlíì náà láti sọtẹ́lẹ̀, Èmi OLÚWA ló tan wòlíì náà, Èmi yóò nawọ́ sí i, èmi yóò sì pa á run kúrò láàrín àwọn ènìyàn mi Israẹli. 10 Wọn yóò ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wọn—ìjìyà kan náà là ó fún wòlíì àti ẹni tó lọ béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀. 11 Kí ilé Israẹli má ba à ṣáko kúrò lọ́dọ̀ mi mọ, kí wọ́n má ba à fi gbogbo ìrékọjá ba ara wọn jẹ́ mọ́. Ṣùgbọ́n kí wọ́n le jẹ́ ènìyàn mi, kí Èmi náà sì le jẹ́ Ọlọ́run wọn, ni OLÚWA Olódùmarè wí.’ ” 12 Ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ̀ mí wá wí pé: 13 “Ọmọ ènìyàn bí orílẹ̀-èdè kan bá dẹ́ṣẹ̀ sí mi nípa ìwà àìṣòdodo, èmi yóò nawọ́ mi jáde sí wọn, láti gé ìpèsè oúnjẹ wọn, èmi yóò rán ìyàn sí wọn, èmi yóò sì pa ènìyàn àti ẹranko inú rẹ̀, 14 bí àwọn ọkùnrin mẹ́ta yìí. Noa, Daniẹli àti Jobu tilẹ̀ wà nínú rẹ, kìkì ẹ̀mí ara wọn nìkan ni wọ́n lé fi òdodo wọn gbàlà, OLÚWA Olódùmarè wí. 15 “Tàbí bí mo bá jẹ́ kí ẹranko búburú gba orílẹ̀-èdè náà kọjá, tí wọn sì bà á jẹ́ tó bẹ́ẹ̀ tí ó di ahoro, tí kò sí ẹni tó le gba ibẹ̀ kọjá torí ẹranko búburú yìí, 16 bí àwọn ọkùnrin mẹ́ta wọ̀nyí tilẹ̀ wà nínú rẹ̀, OLÚWA Olódùmarè wí pé, wọn kì yóò gba ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin là: àwọn nìkan ni a ó gbàlà, ṣùgbọ́n ilẹ̀ náà yóò di ahoro. 17 “Tàbí tí mo bá mú idà kọjá láàrín orílẹ̀-èdè náà tí mo wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí idà kọjá láàrín ilẹ̀ náà,’ tí mo sì tú ìbínú gbígbóná lé wọn lórí nípa ìtàjẹ̀ sílẹ̀, tí mo pa ènìyàn àti ẹranko inú rẹ. 18 Bí àwọn ọkùnrin mẹ́ta yìí tilẹ̀ wà nínú rẹ̀, OLÚWA Olódùmarè wí pé, bí mo ti wà, wọn ki yóò gba ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin là, ṣùgbọ́n àwọn tìkára wọn nìkan ni a ó gbàlà. 19 “Tàbí bí mo rán àjàkálẹ̀-ààrùn si ilẹ̀ náà, ti mo si da ìrunú mi lé e lórí pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀, láti gé ènìyàn àti ẹranko kúrò nínú rẹ̀, 20 bó tilẹ̀ jẹ́ pé Noa, Daniẹli àti Jobu wà nínú rẹ, bí mo ti wà láààyè ni OLÚWA Olódùmarè wí, wọn kò le gba ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin wọn lá. Ara wọn nìkan ni ìwà òdodo wọn lè gbàlà. 21 “Nítorí báyìí ni OLÚWA Olódùmarè wí, báwo ni yóò ti burú tó nígbà tí mo bá rán ìdájọ́ kíkan mi mẹ́rin sórí Jerusalẹmu, èyí ni idà àti ìyàn, ẹranko búburú àti àjàkálẹ̀-ààrùn láti pa àwọn ènìyàn àti ẹranko inú rẹ̀! 22 Síbẹ̀, yóò ṣẹ́kù àwọn díẹ̀, àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin tí a ó kó jáde nínú rẹ̀. Wọn yóò wá bá yin, ẹ̀yin yóò rí ìwà àti ìṣe wọn, nígbà náà ni ẹ̀yin yóò rí ìtùnú nípa àjálù tí mo mú wá sórí Jerusalẹmu—àní gbogbo àjálù ní mo ti mú wá sórí rẹ̀. 23 Nígbà tí ẹ̀yin bá rí ìwà àti ìṣe wọn, a ó tù yín nínú, nítorí pé ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi kò ṣe nǹkan kan láìnídìí, ni OLÚWA Olódùmarè wí.”
In Other Versions
Ezekiel 14 in the ANGEFD
Ezekiel 14 in the ANTPNG2D
Ezekiel 14 in the AS21
Ezekiel 14 in the BAGH
Ezekiel 14 in the BBPNG
Ezekiel 14 in the BBT1E
Ezekiel 14 in the BDS
Ezekiel 14 in the BEV
Ezekiel 14 in the BHAD
Ezekiel 14 in the BIB
Ezekiel 14 in the BLPT
Ezekiel 14 in the BNT
Ezekiel 14 in the BNTABOOT
Ezekiel 14 in the BNTLV
Ezekiel 14 in the BOATCB
Ezekiel 14 in the BOATCB2
Ezekiel 14 in the BOBCV
Ezekiel 14 in the BOCNT
Ezekiel 14 in the BOECS
Ezekiel 14 in the BOGWICC
Ezekiel 14 in the BOHCB
Ezekiel 14 in the BOHCV
Ezekiel 14 in the BOHLNT
Ezekiel 14 in the BOHNTLTAL
Ezekiel 14 in the BOICB
Ezekiel 14 in the BOILNTAP
Ezekiel 14 in the BOITCV
Ezekiel 14 in the BOKCV
Ezekiel 14 in the BOKCV2
Ezekiel 14 in the BOKHWOG
Ezekiel 14 in the BOKSSV
Ezekiel 14 in the BOLCB
Ezekiel 14 in the BOLCB2
Ezekiel 14 in the BOMCV
Ezekiel 14 in the BONAV
Ezekiel 14 in the BONCB
Ezekiel 14 in the BONLT
Ezekiel 14 in the BONUT2
Ezekiel 14 in the BOPLNT
Ezekiel 14 in the BOSCB
Ezekiel 14 in the BOSNC
Ezekiel 14 in the BOTLNT
Ezekiel 14 in the BOVCB
Ezekiel 14 in the BPBB
Ezekiel 14 in the BPH
Ezekiel 14 in the BSB
Ezekiel 14 in the CCB
Ezekiel 14 in the CUV
Ezekiel 14 in the CUVS
Ezekiel 14 in the DBT
Ezekiel 14 in the DGDNT
Ezekiel 14 in the DHNT
Ezekiel 14 in the DNT
Ezekiel 14 in the ELBE
Ezekiel 14 in the EMTV
Ezekiel 14 in the ESV
Ezekiel 14 in the FBV
Ezekiel 14 in the FEB
Ezekiel 14 in the GGMNT
Ezekiel 14 in the GNT
Ezekiel 14 in the HARY
Ezekiel 14 in the HNT
Ezekiel 14 in the IRVA
Ezekiel 14 in the IRVB
Ezekiel 14 in the IRVG
Ezekiel 14 in the IRVH
Ezekiel 14 in the IRVK
Ezekiel 14 in the IRVM
Ezekiel 14 in the IRVM2
Ezekiel 14 in the IRVO
Ezekiel 14 in the IRVP
Ezekiel 14 in the IRVT
Ezekiel 14 in the IRVT2
Ezekiel 14 in the IRVU
Ezekiel 14 in the ISVN
Ezekiel 14 in the JSNT
Ezekiel 14 in the KAPI
Ezekiel 14 in the KBT1ETNIK
Ezekiel 14 in the KBV
Ezekiel 14 in the KJV
Ezekiel 14 in the KNFD
Ezekiel 14 in the LBA
Ezekiel 14 in the LBLA
Ezekiel 14 in the LNT
Ezekiel 14 in the LSV
Ezekiel 14 in the MAAL
Ezekiel 14 in the MBV
Ezekiel 14 in the MBV2
Ezekiel 14 in the MHNT
Ezekiel 14 in the MKNFD
Ezekiel 14 in the MNG
Ezekiel 14 in the MNT
Ezekiel 14 in the MNT2
Ezekiel 14 in the MRS1T
Ezekiel 14 in the NAA
Ezekiel 14 in the NASB
Ezekiel 14 in the NBLA
Ezekiel 14 in the NBS
Ezekiel 14 in the NBVTP
Ezekiel 14 in the NET2
Ezekiel 14 in the NIV11
Ezekiel 14 in the NNT
Ezekiel 14 in the NNT2
Ezekiel 14 in the NNT3
Ezekiel 14 in the PDDPT
Ezekiel 14 in the PFNT
Ezekiel 14 in the RMNT
Ezekiel 14 in the SBIAS
Ezekiel 14 in the SBIBS
Ezekiel 14 in the SBIBS2
Ezekiel 14 in the SBICS
Ezekiel 14 in the SBIDS
Ezekiel 14 in the SBIGS
Ezekiel 14 in the SBIHS
Ezekiel 14 in the SBIIS
Ezekiel 14 in the SBIIS2
Ezekiel 14 in the SBIIS3
Ezekiel 14 in the SBIKS
Ezekiel 14 in the SBIKS2
Ezekiel 14 in the SBIMS
Ezekiel 14 in the SBIOS
Ezekiel 14 in the SBIPS
Ezekiel 14 in the SBISS
Ezekiel 14 in the SBITS
Ezekiel 14 in the SBITS2
Ezekiel 14 in the SBITS3
Ezekiel 14 in the SBITS4
Ezekiel 14 in the SBIUS
Ezekiel 14 in the SBIVS
Ezekiel 14 in the SBT
Ezekiel 14 in the SBT1E
Ezekiel 14 in the SCHL
Ezekiel 14 in the SNT
Ezekiel 14 in the SUSU
Ezekiel 14 in the SUSU2
Ezekiel 14 in the SYNO
Ezekiel 14 in the TBIAOTANT
Ezekiel 14 in the TBT1E
Ezekiel 14 in the TBT1E2
Ezekiel 14 in the TFTIP
Ezekiel 14 in the TFTU
Ezekiel 14 in the TGNTATF3T
Ezekiel 14 in the THAI
Ezekiel 14 in the TNFD
Ezekiel 14 in the TNT
Ezekiel 14 in the TNTIK
Ezekiel 14 in the TNTIL
Ezekiel 14 in the TNTIN
Ezekiel 14 in the TNTIP
Ezekiel 14 in the TNTIZ
Ezekiel 14 in the TOMA
Ezekiel 14 in the TTENT
Ezekiel 14 in the UBG
Ezekiel 14 in the UGV
Ezekiel 14 in the UGV2
Ezekiel 14 in the UGV3
Ezekiel 14 in the VBL
Ezekiel 14 in the VDCC
Ezekiel 14 in the YALU
Ezekiel 14 in the YAPE
Ezekiel 14 in the YBVTP
Ezekiel 14 in the ZBP