Ezekiel 26 (BOYCB)
1 Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kọ́kànlá, ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ̀ mí wá wí pé: 2 “Ọmọ ènìyàn, nítorí pé Tire sọ nípa Jerusalẹmu pé, ‘Háà! A fọ́ èyí tí í ṣe bodè àwọn orílẹ̀-èdè, a yí i padà sí mi, èmi yóò di kíkún, òun yóò sì di ahoro,’ 3 nítorí náà, báyìí ní OLÚWA Olódùmarè wí, kíyèsi i, èmí dojúkọ ọ́ ìwọ tire, Èmi yóò sì jẹ́ kí Orílẹ̀-èdè púpọ̀ dìde sí ọ, gẹ́gẹ́ bí Òkun tí ru sókè. 4 Wọn yóò wó odi tire lulẹ̀, wọn yóò sì wo ilé ìṣọ́ rẹ̀ lulẹ̀, Èmi yóò sì ha erùpẹ̀ rẹ̀ kúrò, Èmi yóò sì sọ ọ́ di orí àpáta. 5 Yóò sì jẹ́ ibi nína àwọ̀n tí wọn fi ń pẹja sí láàrín Òkun, ní OLÚWA Olódùmarè wí. Yóò di ìkógun fún àwọn orílẹ̀-èdè. 6 Ìlú tí ó tẹ̀dó sí, ní àárín gbùngbùn ilẹ̀ rẹ̀ ni a ó fi idà sọ ọ́ di ahoro. Nígbà náà ní wọn yóò mọ̀ pé, Èmi ni OLÚWA. 7 “Nítorí báyìí ní OLÚWA Olódùmarè wí: Kíyèsi i, láti ìhà àríwá ni èmi yóò ti mú Nebukadnessari ọba Babeli, ọba àwọn ọba, dìde sí Tire pẹ̀lú ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣin àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ológun. 8 Yóò sì fi idà sá àwọn ọmọbìnrin rẹ ní oko, yóò sì kọ́ odi tì ọ́, yóò sì mọ òkìtì tì ọ́, yóò sì gbé àpáta sókè sí ọ. 9 Yóò sì gbé ẹ̀rọ ogun tí odi rẹ, yóò sì fi ohun èlò ogun wó ilé ìṣọ́ rẹ palẹ̀. 10 Àwọn ẹṣin rẹ̀ yóò pọ̀ dé bí pé wọn yóò fi eruku bò ọ́ mọ́lẹ̀. Àwọn ògiri rẹ yóò mì tìtì fún igbe àwọn ẹṣin ogun kẹ̀kẹ́ ẹrù àti kẹ̀kẹ́ ogun nígbà tí ó bá wọ ẹnu-ọ̀nà odi gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ń wọ ìlú láti inú àwọn ògiri rẹ̀ ti ó di fífọ́ pátápátá. 11 Pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin rẹ̀ ni yóò fi tẹ gbogbo òpópónà rẹ mọ́lẹ̀; yóò fi idà pa àwọn ènìyàn rẹ, àwọn ọ̀wọ́n rẹ ti o lágbára yóò wó palẹ̀. 12 Wọn yóò kó ọrọ̀ rẹ, wọn yóò sì fi òwò rẹ ṣe ìjẹ ogun; wọn yóò sì wó odi rẹ lulẹ̀, wọn yóò sì ba àwọn ilé rẹ dídára jẹ́, wọn yóò sì kó àwọn òkúta rẹ̀, àti igi ìtì ìkọ́lé rẹ̀, àti erùpẹ̀ rẹ̀, dà sí inú Òkun. 13 Èmi yóò sì mú ariwo orin rẹ̀ dákẹ́ àti ìró dùùrù orin rẹ̀ ni a kì yóò gbọ́ mọ́. 14 Èmi yóò sọ ọ di àpáta lásán, ìwọ yóò sì di ibi tí a ń sá àwọ̀n ẹja sí. A kì yóò sì tún ọ mọ nítorí Èmi OLÚWA ti sọ ọ̀rọ̀ ní OLÚWA Olódùmarè wí. 15 “Báyìí ni OLÚWA Olódùmarè wí sí Tire: Ǹjẹ́ àwọn erékùṣù kì yóò ha wárìrì nípa ìṣubú rẹ, nígbà tí ìkórìíra ìpalára àti rírẹ́ni lọ́run bá ń ṣẹlẹ̀ ní inú rẹ? 16 Nígbà náà ni gbogbo àwọn ọmọ-aládé etí Òkun yóò sọ̀kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ wọn, wọn yóò sì pa àwọn aṣọ ìgúnwà wọn da, tì wọn yóò sì bọ́ àwọn aṣọ iṣẹ́ ọnà abẹ́rẹ́ kúrò. Ẹ̀rù yóò bò wọ́n, wọn yóò sì jókòó lórí ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀, wọn yóò sì máa wárìrì ní gbogbo ìgbà, ẹnu yóò sì yà wọ́n sí ọ́. 17 Nígbà náà wọn yóò gbóhùn ẹkún sókè nítorí rẹ, wọn yóò sì wí fún ọ pé:“ ‘Báwo ni a ṣe pa ọ́ run, ìwọ ìlú olókìkíìwọ tí àwọn èrò okun ti gbé inú rẹ̀!Ìwọ jẹ alágbára lórí okun gbogboòun àti àwọn olùgbé inú rẹ̀;ìwọ gbé ẹ̀rù rẹlórí gbogbo olùgbé ibẹ̀. 18 Nísinsin yìí erékùṣù wárìrìní ọjọ́ ìṣubú rẹ;erékùṣù tí ó wà nínú Òkunni ẹ̀rù bà torí ìṣubú rẹ.’ 19 “Èyí yìí ní OLÚWA Olódùmarè wí: Nígbà tí mo bá sọ ọ́ di ìlú ahoro, gẹ́gẹ́ bi àwọn ìlú tí a kò gbé inú wọn mọ́, àti nígbà tí èmi yóò mú ibú agbami Òkun wá sí orí rẹ, omi ńlá yóò sì bò ọ́, 20 nígbà tí èmi yóò mú ọ wálẹ̀ pẹ̀lú àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ihò, pẹ̀lú àwọn ènìyàn àtijọ́. Èmi yóò sì gbé ọ lọ si bi ìsàlẹ̀, ní ibi ahoro àtijọ́, pẹ̀lú àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ihò, ìwọ kì yóò sì padà gbé inú rẹ̀ mọ́, èmi yóò sì gbé ògo kalẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn alààyè. 21 Èmi yóò ṣe ọ ní ẹ̀rù, ìwọ kì yóò sì ṣí mọ́. Bí a tilẹ̀ wá ọ, síbẹ̀ a kì yóò tún rí ọ mọ́, ní OLÚWA Olódùmarè wí.”
In Other Versions
Ezekiel 26 in the ANGEFD
Ezekiel 26 in the ANTPNG2D
Ezekiel 26 in the AS21
Ezekiel 26 in the BAGH
Ezekiel 26 in the BBPNG
Ezekiel 26 in the BBT1E
Ezekiel 26 in the BDS
Ezekiel 26 in the BEV
Ezekiel 26 in the BHAD
Ezekiel 26 in the BIB
Ezekiel 26 in the BLPT
Ezekiel 26 in the BNT
Ezekiel 26 in the BNTABOOT
Ezekiel 26 in the BNTLV
Ezekiel 26 in the BOATCB
Ezekiel 26 in the BOATCB2
Ezekiel 26 in the BOBCV
Ezekiel 26 in the BOCNT
Ezekiel 26 in the BOECS
Ezekiel 26 in the BOGWICC
Ezekiel 26 in the BOHCB
Ezekiel 26 in the BOHCV
Ezekiel 26 in the BOHLNT
Ezekiel 26 in the BOHNTLTAL
Ezekiel 26 in the BOICB
Ezekiel 26 in the BOILNTAP
Ezekiel 26 in the BOITCV
Ezekiel 26 in the BOKCV
Ezekiel 26 in the BOKCV2
Ezekiel 26 in the BOKHWOG
Ezekiel 26 in the BOKSSV
Ezekiel 26 in the BOLCB
Ezekiel 26 in the BOLCB2
Ezekiel 26 in the BOMCV
Ezekiel 26 in the BONAV
Ezekiel 26 in the BONCB
Ezekiel 26 in the BONLT
Ezekiel 26 in the BONUT2
Ezekiel 26 in the BOPLNT
Ezekiel 26 in the BOSCB
Ezekiel 26 in the BOSNC
Ezekiel 26 in the BOTLNT
Ezekiel 26 in the BOVCB
Ezekiel 26 in the BPBB
Ezekiel 26 in the BPH
Ezekiel 26 in the BSB
Ezekiel 26 in the CCB
Ezekiel 26 in the CUV
Ezekiel 26 in the CUVS
Ezekiel 26 in the DBT
Ezekiel 26 in the DGDNT
Ezekiel 26 in the DHNT
Ezekiel 26 in the DNT
Ezekiel 26 in the ELBE
Ezekiel 26 in the EMTV
Ezekiel 26 in the ESV
Ezekiel 26 in the FBV
Ezekiel 26 in the FEB
Ezekiel 26 in the GGMNT
Ezekiel 26 in the GNT
Ezekiel 26 in the HARY
Ezekiel 26 in the HNT
Ezekiel 26 in the IRVA
Ezekiel 26 in the IRVB
Ezekiel 26 in the IRVG
Ezekiel 26 in the IRVH
Ezekiel 26 in the IRVK
Ezekiel 26 in the IRVM
Ezekiel 26 in the IRVM2
Ezekiel 26 in the IRVO
Ezekiel 26 in the IRVP
Ezekiel 26 in the IRVT
Ezekiel 26 in the IRVT2
Ezekiel 26 in the IRVU
Ezekiel 26 in the ISVN
Ezekiel 26 in the JSNT
Ezekiel 26 in the KAPI
Ezekiel 26 in the KBT1ETNIK
Ezekiel 26 in the KBV
Ezekiel 26 in the KJV
Ezekiel 26 in the KNFD
Ezekiel 26 in the LBA
Ezekiel 26 in the LBLA
Ezekiel 26 in the LNT
Ezekiel 26 in the LSV
Ezekiel 26 in the MAAL
Ezekiel 26 in the MBV
Ezekiel 26 in the MBV2
Ezekiel 26 in the MHNT
Ezekiel 26 in the MKNFD
Ezekiel 26 in the MNG
Ezekiel 26 in the MNT
Ezekiel 26 in the MNT2
Ezekiel 26 in the MRS1T
Ezekiel 26 in the NAA
Ezekiel 26 in the NASB
Ezekiel 26 in the NBLA
Ezekiel 26 in the NBS
Ezekiel 26 in the NBVTP
Ezekiel 26 in the NET2
Ezekiel 26 in the NIV11
Ezekiel 26 in the NNT
Ezekiel 26 in the NNT2
Ezekiel 26 in the NNT3
Ezekiel 26 in the PDDPT
Ezekiel 26 in the PFNT
Ezekiel 26 in the RMNT
Ezekiel 26 in the SBIAS
Ezekiel 26 in the SBIBS
Ezekiel 26 in the SBIBS2
Ezekiel 26 in the SBICS
Ezekiel 26 in the SBIDS
Ezekiel 26 in the SBIGS
Ezekiel 26 in the SBIHS
Ezekiel 26 in the SBIIS
Ezekiel 26 in the SBIIS2
Ezekiel 26 in the SBIIS3
Ezekiel 26 in the SBIKS
Ezekiel 26 in the SBIKS2
Ezekiel 26 in the SBIMS
Ezekiel 26 in the SBIOS
Ezekiel 26 in the SBIPS
Ezekiel 26 in the SBISS
Ezekiel 26 in the SBITS
Ezekiel 26 in the SBITS2
Ezekiel 26 in the SBITS3
Ezekiel 26 in the SBITS4
Ezekiel 26 in the SBIUS
Ezekiel 26 in the SBIVS
Ezekiel 26 in the SBT
Ezekiel 26 in the SBT1E
Ezekiel 26 in the SCHL
Ezekiel 26 in the SNT
Ezekiel 26 in the SUSU
Ezekiel 26 in the SUSU2
Ezekiel 26 in the SYNO
Ezekiel 26 in the TBIAOTANT
Ezekiel 26 in the TBT1E
Ezekiel 26 in the TBT1E2
Ezekiel 26 in the TFTIP
Ezekiel 26 in the TFTU
Ezekiel 26 in the TGNTATF3T
Ezekiel 26 in the THAI
Ezekiel 26 in the TNFD
Ezekiel 26 in the TNT
Ezekiel 26 in the TNTIK
Ezekiel 26 in the TNTIL
Ezekiel 26 in the TNTIN
Ezekiel 26 in the TNTIP
Ezekiel 26 in the TNTIZ
Ezekiel 26 in the TOMA
Ezekiel 26 in the TTENT
Ezekiel 26 in the UBG
Ezekiel 26 in the UGV
Ezekiel 26 in the UGV2
Ezekiel 26 in the UGV3
Ezekiel 26 in the VBL
Ezekiel 26 in the VDCC
Ezekiel 26 in the YALU
Ezekiel 26 in the YAPE
Ezekiel 26 in the YBVTP
Ezekiel 26 in the ZBP