Ezekiel 30 (BOYCB)
1 Ọ̀rọ̀ OLÚWA tún tọ̀ mí wá: wí pé: 2 “Ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ kí o sì wí pé: ‘Báyìí ní OLÚWA Olódùmarè wí:“ ‘Hu, kí o sì wí pé,“Ó ṣe fún ọjọ́ náà!” 3 Nítorí ọjọ́ náà súnmọ́ tòsíàní ọjọ́ OLÚWA súnmọ́ tòsí,ọjọ́ tí ọjọ́ ìkùùkuu ṣú dúdú,àsìkò ìparun fún àwọn kèfèrí. 4 Idà yóò wá sórí Ejibitiìrora ńlá yóò sì wá sórí Kuṣi.Nígbà tí àwọn tí a pa yóò ṣubú ní Ejibitiwọn yóò kò ọrọ̀ rẹ̀ lọìpìlẹ̀ rẹ̀ yóò sì wó lulẹ̀. 5 Kuṣi àti Puti, Libia, Ludi àti gbogbo Arabia, Kubu àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà tí ó mulẹ̀ yóò ṣubú nípa idà pẹ̀lú Ejibiti. 6 “ ‘Èyí yìí ní OLÚWA wí:“ ‘Àwọn àlejò Ejibiti yóò ṣubúagbára ìgbéraga rẹ yóò kùnàláti Migdoli títí dé Siene,wọn yóò ti ipa idà ṣubú nínú rẹ;ní OLÚWA Olódùmarè wí. 7 Wọn yóò sì wàlára àwọn ilẹ̀ tí ó di ahoro,ìlú rẹ yóò sì wàní ara àwọn ìlú tí ó di ahoro. 8 Lẹ́yìn náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ní OLÚWA,nígbà tí mo bá gbé iná kalẹ̀ ní Ejibitití gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ bá parun. 9 “ ‘Ní ọjọ́ náà oníṣẹ́ yóò ti ọ̀dọ̀ mi jáde nínú ọkọ̀ ojú omi láti dẹ́rùbà Kuṣi tí ó wà nínú àlàáfíà. Ìrora yóò wá sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ti ọjọ́ ìparun Ejibiti. Kíyèsi i, ó dé. 10 “ ‘Báyìí ni OLÚWA Olódùmarè wí:“ ‘Èmi yóò mú òpin bá ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọnènìyàn Ejibiti láti ọwọ́ Nebukadnessari ọba Babeli. 11 Òun àti àwọn ológun rẹ̀ẹ̀rù àwọn orílẹ̀-èdèní a o mú wá láti pa ilẹ̀ náà run.Wọn yóò fa idà wọn yọ sí Ejibitiilẹ̀ náà yóò sì kún fún àwọn tí a pa. 12 Èmi yóò mú kí àwọn odò Naili gbẹ,Èmi yóò sì ta ilẹ̀ náà fún àwọn ènìyàn búburú:láti ọwọ́ àwọn àjèjì ènìyàn,Èmi yóò jẹ́ kí ilẹ̀ náà àti gbogbo ohun tí ó wá nínú rẹ ṣòfò.Èmi OLÚWA ni ó ti sọ ọ́. 13 “ ‘Báyìí ní OLÚWA Olódùmarè wí:“ ‘Èmi yóò pa àwọn òrìṣà run,Èmi yóò sì mú kí òpin dé bá ère gbígbẹ́ ni Memfisi.Kò ní sí ọmọ-aládé mọ́ ní Ejibiti,Èmi yóò mú kí ìbẹ̀rù gba gbogbo ilẹ̀ náà. 14 Èmi yóò sì mú kí Paturosi di ahoro,èmi yóò fi iná sí Ṣoani,èmi yóò sì fi ìyà jẹ Tebesi. 15 Èmi yóò tú ìbínú mi jáde sórí Pelusiumuìlú odi Ejibitièmi yóò sì ké àkójọpọ̀ Tebesi kúrò. 16 Èmi yóò ti iná bọ EjibitiPelusiumu yóò japoró ní ìrora.Ìjì líle yóò jà ní TebesiMemfisi yóò wà ìpọ́njú ní ìgbà gbogbo. 17 Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ní Heliopolisi àti Bubasitiyóò ti ipa idà ṣubúwọn yóò sì kó àwọn ìlú wọn ní ìgbèkùn. 18 Ojú ọjọ́ yóò ṣókùnkùn ní Tafanesinígbà tí mo bá já àjàgà Ejibiti kúrò;níbẹ̀ agbára iyì rẹ̀ yóò dópinwọn yóò fi ìkùùkuu bò óàwọn abúlé rẹ ní wọn yóò lọ sí ìgbèkùn. 19 Nítorí náà, Èmi yóò mú ki ìjìyà wá sórí Ejibiti,wọn yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni OLÚWA.’ ” 20 Ní ọjọ́ keje oṣù kìn-ín-ní ọdún kọkànlá ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ̀ mí wá, 21 “Ọmọ ènìyàn, Èmi ti ṣẹ́ apá Farao ọba Ejibiti. A kò ì tí ì di apá náà papọ̀ láti mu kí ó san, a kò sì ti di i si àárín igi pẹlẹbẹ kí o lè ni agbára tó láti di idà mú. 22 Nítorí náà, báyìí ní OLÚWA Olódùmarè wí: Èmi lòdì sí Farao ọba Ejibiti. Èmi yóò sẹ́ apá rẹ̀ méjèèjì, èyí tí ó dára àti èyí tí a ti ṣẹ́ pẹ̀lú, yóò sì mú kí idà bọ́ sọnù ní ọwọ́ rẹ̀. 23 Èmi yóò sì fọ́n àwọn ènìyàn Ejibiti ká sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì tú wọn ká gbogbo ilẹ̀. 24 Èmi yóò mú kí apá ọba Babeli ní agbára, èmi yóò sì fi idà mi sí ọwọ́ rẹ, ṣùgbọ́n èmi yóò ṣẹ́ apá Farao, yóò sì kérora níwájú rẹ̀ bí ọkùnrin tí a sá ní àṣápa. 25 Èmi yóò mú kí apá ọba Babeli lé, ṣùgbọ́n apá Farao yóò sì rọ. Nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé, Èmi ni OLÚWA, nígbà tí mo bá mú idà mi sí ọwọ́ ọba Babeli yóò sì fi idà náà kọlu Ejibiti. 26 Èmi yóò fọ́n àwọn ara Ejibiti ká sí àárín orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sí àárín orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sí gbogbo ilẹ̀. Nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ni OLÚWA.”
In Other Versions
Ezekiel 30 in the ANGEFD
Ezekiel 30 in the ANTPNG2D
Ezekiel 30 in the AS21
Ezekiel 30 in the BAGH
Ezekiel 30 in the BBPNG
Ezekiel 30 in the BBT1E
Ezekiel 30 in the BDS
Ezekiel 30 in the BEV
Ezekiel 30 in the BHAD
Ezekiel 30 in the BIB
Ezekiel 30 in the BLPT
Ezekiel 30 in the BNT
Ezekiel 30 in the BNTABOOT
Ezekiel 30 in the BNTLV
Ezekiel 30 in the BOATCB
Ezekiel 30 in the BOATCB2
Ezekiel 30 in the BOBCV
Ezekiel 30 in the BOCNT
Ezekiel 30 in the BOECS
Ezekiel 30 in the BOGWICC
Ezekiel 30 in the BOHCB
Ezekiel 30 in the BOHCV
Ezekiel 30 in the BOHLNT
Ezekiel 30 in the BOHNTLTAL
Ezekiel 30 in the BOICB
Ezekiel 30 in the BOILNTAP
Ezekiel 30 in the BOITCV
Ezekiel 30 in the BOKCV
Ezekiel 30 in the BOKCV2
Ezekiel 30 in the BOKHWOG
Ezekiel 30 in the BOKSSV
Ezekiel 30 in the BOLCB
Ezekiel 30 in the BOLCB2
Ezekiel 30 in the BOMCV
Ezekiel 30 in the BONAV
Ezekiel 30 in the BONCB
Ezekiel 30 in the BONLT
Ezekiel 30 in the BONUT2
Ezekiel 30 in the BOPLNT
Ezekiel 30 in the BOSCB
Ezekiel 30 in the BOSNC
Ezekiel 30 in the BOTLNT
Ezekiel 30 in the BOVCB
Ezekiel 30 in the BPBB
Ezekiel 30 in the BPH
Ezekiel 30 in the BSB
Ezekiel 30 in the CCB
Ezekiel 30 in the CUV
Ezekiel 30 in the CUVS
Ezekiel 30 in the DBT
Ezekiel 30 in the DGDNT
Ezekiel 30 in the DHNT
Ezekiel 30 in the DNT
Ezekiel 30 in the ELBE
Ezekiel 30 in the EMTV
Ezekiel 30 in the ESV
Ezekiel 30 in the FBV
Ezekiel 30 in the FEB
Ezekiel 30 in the GGMNT
Ezekiel 30 in the GNT
Ezekiel 30 in the HARY
Ezekiel 30 in the HNT
Ezekiel 30 in the IRVA
Ezekiel 30 in the IRVB
Ezekiel 30 in the IRVG
Ezekiel 30 in the IRVH
Ezekiel 30 in the IRVK
Ezekiel 30 in the IRVM
Ezekiel 30 in the IRVM2
Ezekiel 30 in the IRVO
Ezekiel 30 in the IRVP
Ezekiel 30 in the IRVT
Ezekiel 30 in the IRVT2
Ezekiel 30 in the IRVU
Ezekiel 30 in the ISVN
Ezekiel 30 in the JSNT
Ezekiel 30 in the KAPI
Ezekiel 30 in the KBT1ETNIK
Ezekiel 30 in the KBV
Ezekiel 30 in the KJV
Ezekiel 30 in the KNFD
Ezekiel 30 in the LBA
Ezekiel 30 in the LBLA
Ezekiel 30 in the LNT
Ezekiel 30 in the LSV
Ezekiel 30 in the MAAL
Ezekiel 30 in the MBV
Ezekiel 30 in the MBV2
Ezekiel 30 in the MHNT
Ezekiel 30 in the MKNFD
Ezekiel 30 in the MNG
Ezekiel 30 in the MNT
Ezekiel 30 in the MNT2
Ezekiel 30 in the MRS1T
Ezekiel 30 in the NAA
Ezekiel 30 in the NASB
Ezekiel 30 in the NBLA
Ezekiel 30 in the NBS
Ezekiel 30 in the NBVTP
Ezekiel 30 in the NET2
Ezekiel 30 in the NIV11
Ezekiel 30 in the NNT
Ezekiel 30 in the NNT2
Ezekiel 30 in the NNT3
Ezekiel 30 in the PDDPT
Ezekiel 30 in the PFNT
Ezekiel 30 in the RMNT
Ezekiel 30 in the SBIAS
Ezekiel 30 in the SBIBS
Ezekiel 30 in the SBIBS2
Ezekiel 30 in the SBICS
Ezekiel 30 in the SBIDS
Ezekiel 30 in the SBIGS
Ezekiel 30 in the SBIHS
Ezekiel 30 in the SBIIS
Ezekiel 30 in the SBIIS2
Ezekiel 30 in the SBIIS3
Ezekiel 30 in the SBIKS
Ezekiel 30 in the SBIKS2
Ezekiel 30 in the SBIMS
Ezekiel 30 in the SBIOS
Ezekiel 30 in the SBIPS
Ezekiel 30 in the SBISS
Ezekiel 30 in the SBITS
Ezekiel 30 in the SBITS2
Ezekiel 30 in the SBITS3
Ezekiel 30 in the SBITS4
Ezekiel 30 in the SBIUS
Ezekiel 30 in the SBIVS
Ezekiel 30 in the SBT
Ezekiel 30 in the SBT1E
Ezekiel 30 in the SCHL
Ezekiel 30 in the SNT
Ezekiel 30 in the SUSU
Ezekiel 30 in the SUSU2
Ezekiel 30 in the SYNO
Ezekiel 30 in the TBIAOTANT
Ezekiel 30 in the TBT1E
Ezekiel 30 in the TBT1E2
Ezekiel 30 in the TFTIP
Ezekiel 30 in the TFTU
Ezekiel 30 in the TGNTATF3T
Ezekiel 30 in the THAI
Ezekiel 30 in the TNFD
Ezekiel 30 in the TNT
Ezekiel 30 in the TNTIK
Ezekiel 30 in the TNTIL
Ezekiel 30 in the TNTIN
Ezekiel 30 in the TNTIP
Ezekiel 30 in the TNTIZ
Ezekiel 30 in the TOMA
Ezekiel 30 in the TTENT
Ezekiel 30 in the UBG
Ezekiel 30 in the UGV
Ezekiel 30 in the UGV2
Ezekiel 30 in the UGV3
Ezekiel 30 in the VBL
Ezekiel 30 in the VDCC
Ezekiel 30 in the YALU
Ezekiel 30 in the YAPE
Ezekiel 30 in the YBVTP
Ezekiel 30 in the ZBP