Genesis 46 (BOYCB)

1 Báyìí ni Israẹli mú ìrìnàjò rẹ̀ pọ̀n pẹ̀lú ohun gbogbo tí ó ní, nígbà tí ó sì dé Beerṣeba, ó rú ẹbọ sí Ọlọ́run Isaaki baba rẹ̀. 2 Ọlọ́run sì bá Israẹli sọ̀rọ̀ ní ojú ìran ní òru pé, “Jakọbu! Jakọbu!”Ó sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.” 3 Ọlọ́run sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run, Ọlọ́run baba rẹ, má ṣe bẹ̀rù láti sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Ejibiti nítorí, èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá níbẹ̀. 4 Èmi yóò sì sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú rẹ lọ sí Ejibiti, èmi yóò sì tún mú ọ padà wá. Ọwọ́ Josẹfu fúnra rẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí.” 5 Nígbà náà ni Jakọbu kúrò ní Beerṣeba, àwọn ọmọ Israẹli sì mú Jakọbu baba wọn àti àwọn aya wọn àti àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì kó wọn sí inú kẹ̀kẹ́ ẹrù tí Farao fi ránṣẹ́ fún ìrìnàjò rẹ̀. 6 Wọ́n tún kó àwọn ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo ohun ìní tí wọ́n ti ní láti ilẹ̀ Kenaani, Jakọbu àti gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti. 7 Ó kó àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin pẹ̀lú àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin pẹ̀lú àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ obìnrin, gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ lọ sí Ejibiti. 8 Èyí ni orúkọ àwọn ọmọ Israẹli (Jakọbu àti ìran rẹ̀) tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ Ejibiti: Reubeni àkọ́bí Jakọbu. 9 Àwọn ọmọkùnrin Reubeni:Hanoku, Pallu, Hesroni àti Karmi. 10 Àwọn ọmọkùnrin Simeoni:Jemueli, Jamini, Ohadi, Jakini, Sohari àti Saulu, tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọbìnrin ará Kenaani. 11 Àwọn ọmọkùnrin Lefi:Gerṣoni, Kohati àti Merari. 12 Àwọn ọmọkùnrin Juda:Eri, Onani, Ṣela, Peresi àti Sera (ṣùgbọ́n Ẹri àti Onani ti kú ní ilẹ̀ Kenaani).Àwọn ọmọ Peresi:Hesroni àti Hamulu. 13 Àwọn ọmọkùnrin: Isakari!Tola, Pua, Jaṣibu àti Ṣimroni. 14 Àwọn ọmọkùnrin Sebuluni:Seredi, Eloni àti Jahaleli. 15 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Lea tí ó bí fún Jakọbu ní Padani-Aramu yàtọ̀ fún Dina ọmọbìnrin rẹ̀. Àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti ọmọbìnrin rẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) lápapọ̀. 16 Àwọn ọmọkùnrin Gadi:Sefoni, Haggi, Ṣuni, Esboni, Eri, Arodi, àti Areli. 17 Àwọn ọmọkùnrin Aṣeri:Imina, Iṣifa, Iṣfi àti Beriah. Arábìnrin wọn ni Sera.Àwọn ọmọkùnrin Beriah:Heberi àti Malkieli. 18 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ tí Jakọbu bí nípasẹ̀ Silipa, ẹni tí Labani fi fún Lea ọmọbìnrin rẹ̀. Gbogbo wọn jẹ́ mẹ́rìndínlógún lápapọ̀. 19 Àwọn ọmọkùnrin Rakeli aya Jakọbu:Josẹfu àti Benjamini. 20 Ní Ejibiti, Asenati ọmọbìnrin Potifẹra, alábojútó àti àlùfáà Oni, bí Manase àti Efraimu fún Josẹfu. 21 Àwọn ọmọ Benjamini:Bela, Bekeri, Aṣbeli, Gera, Naamani, Ehi, Roṣi, Mupimu, Huppimu àti Ardi. 22 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin tí Rakeli bí fún Jakọbu. Wọ́n jẹ́ mẹ́rìnlá lápapọ̀. 23 Àwọn ọmọ Dani:Huṣimu. 24 Àwọn ọmọ Naftali:Jasieli, Guni, Jeseri, àti Ṣillemu. 25 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ tí Biliha ẹni tí Labani fi fún Rakeli ọmọ rẹ̀ bí fún Jakọbu. Wọ́n jẹ́ méje lápapọ̀. 26 Gbogbo àwọn tí ó lọ pẹ̀lú Jakọbu sí Ejibiti, àwọn tí ó jẹ́ ìran rẹ̀ tààrà láìka àwọn aya ọmọ rẹ̀, jẹ́ ènìyàn mẹ́rìndínláàádọ́rin. 27 Pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin méjì tí a bí fún Josẹfu ní Ejibiti àwọn ará ilé Jakọbu tí ó lọ sí Ejibiti jẹ́ àádọ́rin lápapọ̀. 28 Jakọbu sì rán Juda ṣáájú rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Josẹfu, kí wọn bá à le mọ ọ̀nà Goṣeni. Nígbà tí wọ́n dé agbègbè Goṣeni, 29 Josẹfu tọ́jú kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀ ó sì lọ sí Goṣeni láti pàdé Israẹli baba rẹ̀. Bí Josẹfu ti dé iwájú baba rẹ̀, ó dì mọ́ baba rẹ̀ ó sì sọkún fún ìgbà pípẹ́. 30 Israẹli wí fún Josẹfu pé, “Wàyí o, mo le kú, níwọ̀n bí mo ti rí i fún ara mi pé, o wà láààyè síbẹ̀.” 31 Nígbà náà ni Josẹfu wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ àti fún àwọn ará ilé baba rẹ̀ pé, “Èmi yóò gòkè lọ, èmi yóò sì bá Farao sọ̀rọ̀, èmi yóò sì wí fún un pé, ‘Àwọn arákùnrin mi àti ìdílé baba mi tí ń gbé ní Kenaani ti tọ̀ mí wá. 32 Darandaran ni àwọn ènìyàn náà, wọ́n ń tọ́jú ẹran ọ̀sìn, wọ́n sì kó agbo ẹran wọn àti agbo màlúù wọn àti gbogbo ohun tí wọ́n ní pẹ̀lú wá.’ 33 Nígbà tí Farao bá pè yín wọlé tí ó sí béèrè irú iṣẹ́ tí ẹ ń ṣe, 34 ẹ fún un lésì pé, ‘Àwọn ìránṣẹ́ rẹ ń tọ́jú ẹran ọ̀sìn ni láti ìgbà èwe wa wá gẹ́gẹ́ bí a ṣe ba a lọ́wọ́ àwọn baba wa.’ Nígbà náà ni wọn yóò fún un yín láààyè láti tẹ̀dó sí ilẹ̀ Goṣeni, nítorí pé àwọn ará Ejibiti kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ darandaran.”

In Other Versions

Genesis 46 in the ANGEFD

Genesis 46 in the ANTPNG2D

Genesis 46 in the AS21

Genesis 46 in the BAGH

Genesis 46 in the BBPNG

Genesis 46 in the BBT1E

Genesis 46 in the BDS

Genesis 46 in the BEV

Genesis 46 in the BHAD

Genesis 46 in the BIB

Genesis 46 in the BLPT

Genesis 46 in the BNT

Genesis 46 in the BNTABOOT

Genesis 46 in the BNTLV

Genesis 46 in the BOATCB

Genesis 46 in the BOATCB2

Genesis 46 in the BOBCV

Genesis 46 in the BOCNT

Genesis 46 in the BOECS

Genesis 46 in the BOGWICC

Genesis 46 in the BOHCB

Genesis 46 in the BOHCV

Genesis 46 in the BOHLNT

Genesis 46 in the BOHNTLTAL

Genesis 46 in the BOICB

Genesis 46 in the BOILNTAP

Genesis 46 in the BOITCV

Genesis 46 in the BOKCV

Genesis 46 in the BOKCV2

Genesis 46 in the BOKHWOG

Genesis 46 in the BOKSSV

Genesis 46 in the BOLCB

Genesis 46 in the BOLCB2

Genesis 46 in the BOMCV

Genesis 46 in the BONAV

Genesis 46 in the BONCB

Genesis 46 in the BONLT

Genesis 46 in the BONUT2

Genesis 46 in the BOPLNT

Genesis 46 in the BOSCB

Genesis 46 in the BOSNC

Genesis 46 in the BOTLNT

Genesis 46 in the BOVCB

Genesis 46 in the BPBB

Genesis 46 in the BPH

Genesis 46 in the BSB

Genesis 46 in the CCB

Genesis 46 in the CUV

Genesis 46 in the CUVS

Genesis 46 in the DBT

Genesis 46 in the DGDNT

Genesis 46 in the DHNT

Genesis 46 in the DNT

Genesis 46 in the ELBE

Genesis 46 in the EMTV

Genesis 46 in the ESV

Genesis 46 in the FBV

Genesis 46 in the FEB

Genesis 46 in the GGMNT

Genesis 46 in the GNT

Genesis 46 in the HARY

Genesis 46 in the HNT

Genesis 46 in the IRVA

Genesis 46 in the IRVB

Genesis 46 in the IRVG

Genesis 46 in the IRVH

Genesis 46 in the IRVK

Genesis 46 in the IRVM

Genesis 46 in the IRVM2

Genesis 46 in the IRVO

Genesis 46 in the IRVP

Genesis 46 in the IRVT

Genesis 46 in the IRVT2

Genesis 46 in the IRVU

Genesis 46 in the ISVN

Genesis 46 in the JSNT

Genesis 46 in the KAPI

Genesis 46 in the KBT1ETNIK

Genesis 46 in the KBV

Genesis 46 in the KJV

Genesis 46 in the KNFD

Genesis 46 in the LBA

Genesis 46 in the LBLA

Genesis 46 in the LNT

Genesis 46 in the LSV

Genesis 46 in the MAAL

Genesis 46 in the MBV

Genesis 46 in the MBV2

Genesis 46 in the MHNT

Genesis 46 in the MKNFD

Genesis 46 in the MNG

Genesis 46 in the MNT

Genesis 46 in the MNT2

Genesis 46 in the MRS1T

Genesis 46 in the NAA

Genesis 46 in the NASB

Genesis 46 in the NBLA

Genesis 46 in the NBS

Genesis 46 in the NBVTP

Genesis 46 in the NET2

Genesis 46 in the NIV11

Genesis 46 in the NNT

Genesis 46 in the NNT2

Genesis 46 in the NNT3

Genesis 46 in the PDDPT

Genesis 46 in the PFNT

Genesis 46 in the RMNT

Genesis 46 in the SBIAS

Genesis 46 in the SBIBS

Genesis 46 in the SBIBS2

Genesis 46 in the SBICS

Genesis 46 in the SBIDS

Genesis 46 in the SBIGS

Genesis 46 in the SBIHS

Genesis 46 in the SBIIS

Genesis 46 in the SBIIS2

Genesis 46 in the SBIIS3

Genesis 46 in the SBIKS

Genesis 46 in the SBIKS2

Genesis 46 in the SBIMS

Genesis 46 in the SBIOS

Genesis 46 in the SBIPS

Genesis 46 in the SBISS

Genesis 46 in the SBITS

Genesis 46 in the SBITS2

Genesis 46 in the SBITS3

Genesis 46 in the SBITS4

Genesis 46 in the SBIUS

Genesis 46 in the SBIVS

Genesis 46 in the SBT

Genesis 46 in the SBT1E

Genesis 46 in the SCHL

Genesis 46 in the SNT

Genesis 46 in the SUSU

Genesis 46 in the SUSU2

Genesis 46 in the SYNO

Genesis 46 in the TBIAOTANT

Genesis 46 in the TBT1E

Genesis 46 in the TBT1E2

Genesis 46 in the TFTIP

Genesis 46 in the TFTU

Genesis 46 in the TGNTATF3T

Genesis 46 in the THAI

Genesis 46 in the TNFD

Genesis 46 in the TNT

Genesis 46 in the TNTIK

Genesis 46 in the TNTIL

Genesis 46 in the TNTIN

Genesis 46 in the TNTIP

Genesis 46 in the TNTIZ

Genesis 46 in the TOMA

Genesis 46 in the TTENT

Genesis 46 in the UBG

Genesis 46 in the UGV

Genesis 46 in the UGV2

Genesis 46 in the UGV3

Genesis 46 in the VBL

Genesis 46 in the VDCC

Genesis 46 in the YALU

Genesis 46 in the YAPE

Genesis 46 in the YBVTP

Genesis 46 in the ZBP