Isaiah 13 (BOYCB)
1 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Babeli èyí tí Isaiah ọmọ Amosi rí. 2 Gbé àsíá sókè ní orí òkè gbẹrẹfu,kígbe sí wọn,pè wọ́nláti wọlé sí ẹnu-ọ̀nà àwọn ọlọ́lá. 3 Mo ti pàṣẹ fún àwọn ẹni mímọ́ mi,mo ti pe àwọn jagunjagun miláti gbé ìbínú mi jádeàwọn tí ń yọ̀ nínú ìṣẹ́gun mi. 4 Gbọ́ ohùn kan ní àwọn orí òkè,gẹ́gẹ́ bí i ti ogunlọ́gọ̀ ènìyàn.Gbọ́ ìdàrúdàpọ̀ láàrín àwọn ìjọba,gẹ́gẹ́ bí i ti ìkórajọ àwọn orílẹ̀-èdè! OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ti kó ogun rẹ̀ jọàwọn jagunjagun fún ogun. 5 Wọ́n wá láti ọ̀nà jíjìn réré,láti ìpẹ̀kun ọ̀run wá OLÚWA pẹ̀lú àwọn ohun ìjà ìbínú rẹ̀,láti pa gbogbo orílẹ̀-èdè náà run. 6 Ẹ hu, nítorí ọjọ́ OLÚWA súnmọ́ tòsí,yóò sì wá gẹ́gẹ́ bí ìparun láti ọ̀dọ̀ Alágbára jùlọ. 7 Nítorí èyí, gbogbo ọwọ́ ni yóò rọ,ọkàn ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò rẹ̀wẹ̀sì. 8 Ẹ̀rù yóò gbá wọn mú,ìrora àti ìpayínkeke yóò dìwọ́n mú,wọn yóò kérora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó ń rọbí.Ẹnìkínní yóò wo ẹnìkejì rẹ̀ pẹ̀lú ìpayàojú wọn á sì gbinájẹ. 9 Kíyèsi i, ọjọ́ OLÚWA ń bọ̀ọjọ́ búburú, pẹ̀lú ìbínú àti ìrunú gbígbóná—láti sọ ilẹ̀ náà dahoro,àti láti pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ inú rẹ̀ run. 10 Àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti ìkójọpọ̀ wọnkò sì ní fi ìmọ́lẹ̀ wọn hàn.Àṣẹ̀ṣẹ̀yọ oòrùn yóò di òkùnkùnàti òṣùpá kò ní fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn. 11 Èmi yóò jẹ ayé ní ìyà nítorí ibi rẹ̀,àwọn ìkà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.Èmi yóò fi òpin sí gààrù àwọn agbéragaèmi ó sì rẹ ìgbéraga àwọn aláìláàánú sílẹ̀. 12 Èmi yóò jẹ́ kí ọkùnrin kí ó wọnju ojúlówó wúrà lọ,yóò sì ṣọ̀wọ́n ju wúrà Ofiri lọ. 13 Nítorí náà èmi yóò jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó wárìrì;ayé yóò sì mì tìtì ní ibùjókòó rẹ̀láti ọwọ́ ìbínú OLÚWA àwọn ọmọ-ogun,ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná rẹ. 14 Gẹ́gẹ́ bí egbin tí à ń dọdẹ rẹ̀,gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́,ọ̀kọ̀ọ̀kan yóò padà tọ àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ,ọ̀kọ̀ọ̀kan yóò sá padà sí ilẹ̀ abínibí i rẹ̀. 15 Ẹnikẹ́ni tí a bá gbámú ni a ó wọ́ nílẹ̀ tuurutu,gbogbo àwọn tí ọwọ́ bá tẹ̀ ni yóò ti ipa idà kú. 16 Àwọn ọ̀dọ́mọdé wọn ni a ó fọ́ sí wẹ́wẹ́ níṣojú wọn,gbogbo ilẹ̀ wọn ni a ó kóàwọn aya wọn ni a ó sì bá dàpọ̀. 17 Kíyèsi i, èmi yóò ru àwọn Media sókè sí wọn,àwọn tí kò bìkítà fún fàdákàtí kò sì ní inú dídùn sí wúrà. 18 Ọrùn wọn yóò ré àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin lulẹ̀;wọn kò ní ṣàánú àwọn ọ̀dọ́mọdétàbí kí wọn síjú àánú wo àwọn ọmọdé. 19 Babeli, ohun ọ̀ṣọ́ àwọn ìjọbaògo ìgbéraga àwọn ará Babelini Ọlọ́run yóò da ojú rẹ̀ bolẹ̀gẹ́gẹ́ bí Sodomu àti Gomorra. 20 A kì yóò tẹ̀ ibẹ̀ dó mọ́tàbí kí á gbé inú rẹ̀ láti ìrandíran;ará Arabia kì yóò pa àgọ́ níbẹ̀ mọ́,olùṣọ́-àgùntàn kan kì yóò kó ẹran rẹ̀ sinmi níbẹ̀. 21 Ṣùgbọ́n àwọn ẹranko igbó ni yóò dùbúlẹ̀ níbẹ̀,àwọn ajáko yóò kún inú ilé wọn,níbẹ̀ ni àwọn òwìwí yóò máa gbéníbẹ̀ ni àwọn ewúrẹ́ igbó yóò ti máa bẹ́ kiri. 22 Ìkookò yóò máa gbó ní ibùba wọn,àwọn ajáko nínú arẹwà ààfin wọn.
In Other Versions
Isaiah 13 in the ANGEFD
Isaiah 13 in the ANTPNG2D
Isaiah 13 in the AS21
Isaiah 13 in the BAGH
Isaiah 13 in the BBPNG
Isaiah 13 in the BBT1E
Isaiah 13 in the BDS
Isaiah 13 in the BEV
Isaiah 13 in the BHAD
Isaiah 13 in the BIB
Isaiah 13 in the BLPT
Isaiah 13 in the BNT
Isaiah 13 in the BNTABOOT
Isaiah 13 in the BNTLV
Isaiah 13 in the BOATCB
Isaiah 13 in the BOATCB2
Isaiah 13 in the BOBCV
Isaiah 13 in the BOCNT
Isaiah 13 in the BOECS
Isaiah 13 in the BOGWICC
Isaiah 13 in the BOHCB
Isaiah 13 in the BOHCV
Isaiah 13 in the BOHLNT
Isaiah 13 in the BOHNTLTAL
Isaiah 13 in the BOICB
Isaiah 13 in the BOILNTAP
Isaiah 13 in the BOITCV
Isaiah 13 in the BOKCV
Isaiah 13 in the BOKCV2
Isaiah 13 in the BOKHWOG
Isaiah 13 in the BOKSSV
Isaiah 13 in the BOLCB
Isaiah 13 in the BOLCB2
Isaiah 13 in the BOMCV
Isaiah 13 in the BONAV
Isaiah 13 in the BONCB
Isaiah 13 in the BONLT
Isaiah 13 in the BONUT2
Isaiah 13 in the BOPLNT
Isaiah 13 in the BOSCB
Isaiah 13 in the BOSNC
Isaiah 13 in the BOTLNT
Isaiah 13 in the BOVCB
Isaiah 13 in the BPBB
Isaiah 13 in the BPH
Isaiah 13 in the BSB
Isaiah 13 in the CCB
Isaiah 13 in the CUV
Isaiah 13 in the CUVS
Isaiah 13 in the DBT
Isaiah 13 in the DGDNT
Isaiah 13 in the DHNT
Isaiah 13 in the DNT
Isaiah 13 in the ELBE
Isaiah 13 in the EMTV
Isaiah 13 in the ESV
Isaiah 13 in the FBV
Isaiah 13 in the FEB
Isaiah 13 in the GGMNT
Isaiah 13 in the GNT
Isaiah 13 in the HARY
Isaiah 13 in the HNT
Isaiah 13 in the IRVA
Isaiah 13 in the IRVB
Isaiah 13 in the IRVG
Isaiah 13 in the IRVH
Isaiah 13 in the IRVK
Isaiah 13 in the IRVM
Isaiah 13 in the IRVM2
Isaiah 13 in the IRVO
Isaiah 13 in the IRVP
Isaiah 13 in the IRVT
Isaiah 13 in the IRVT2
Isaiah 13 in the IRVU
Isaiah 13 in the ISVN
Isaiah 13 in the JSNT
Isaiah 13 in the KAPI
Isaiah 13 in the KBT1ETNIK
Isaiah 13 in the KBV
Isaiah 13 in the KJV
Isaiah 13 in the KNFD
Isaiah 13 in the LBA
Isaiah 13 in the LBLA
Isaiah 13 in the LNT
Isaiah 13 in the LSV
Isaiah 13 in the MAAL
Isaiah 13 in the MBV
Isaiah 13 in the MBV2
Isaiah 13 in the MHNT
Isaiah 13 in the MKNFD
Isaiah 13 in the MNG
Isaiah 13 in the MNT
Isaiah 13 in the MNT2
Isaiah 13 in the MRS1T
Isaiah 13 in the NAA
Isaiah 13 in the NASB
Isaiah 13 in the NBLA
Isaiah 13 in the NBS
Isaiah 13 in the NBVTP
Isaiah 13 in the NET2
Isaiah 13 in the NIV11
Isaiah 13 in the NNT
Isaiah 13 in the NNT2
Isaiah 13 in the NNT3
Isaiah 13 in the PDDPT
Isaiah 13 in the PFNT
Isaiah 13 in the RMNT
Isaiah 13 in the SBIAS
Isaiah 13 in the SBIBS
Isaiah 13 in the SBIBS2
Isaiah 13 in the SBICS
Isaiah 13 in the SBIDS
Isaiah 13 in the SBIGS
Isaiah 13 in the SBIHS
Isaiah 13 in the SBIIS
Isaiah 13 in the SBIIS2
Isaiah 13 in the SBIIS3
Isaiah 13 in the SBIKS
Isaiah 13 in the SBIKS2
Isaiah 13 in the SBIMS
Isaiah 13 in the SBIOS
Isaiah 13 in the SBIPS
Isaiah 13 in the SBISS
Isaiah 13 in the SBITS
Isaiah 13 in the SBITS2
Isaiah 13 in the SBITS3
Isaiah 13 in the SBITS4
Isaiah 13 in the SBIUS
Isaiah 13 in the SBIVS
Isaiah 13 in the SBT
Isaiah 13 in the SBT1E
Isaiah 13 in the SCHL
Isaiah 13 in the SNT
Isaiah 13 in the SUSU
Isaiah 13 in the SUSU2
Isaiah 13 in the SYNO
Isaiah 13 in the TBIAOTANT
Isaiah 13 in the TBT1E
Isaiah 13 in the TBT1E2
Isaiah 13 in the TFTIP
Isaiah 13 in the TFTU
Isaiah 13 in the TGNTATF3T
Isaiah 13 in the THAI
Isaiah 13 in the TNFD
Isaiah 13 in the TNT
Isaiah 13 in the TNTIK
Isaiah 13 in the TNTIL
Isaiah 13 in the TNTIN
Isaiah 13 in the TNTIP
Isaiah 13 in the TNTIZ
Isaiah 13 in the TOMA
Isaiah 13 in the TTENT
Isaiah 13 in the UBG
Isaiah 13 in the UGV
Isaiah 13 in the UGV2
Isaiah 13 in the UGV3
Isaiah 13 in the VBL
Isaiah 13 in the VDCC
Isaiah 13 in the YALU
Isaiah 13 in the YAPE
Isaiah 13 in the YBVTP
Isaiah 13 in the ZBP