Isaiah 40 (BOYCB)

1 Ẹ tù ú nínú, ẹ tu ènìyàn mi nínú,ni Ọlọ́run yín wí. 2 Sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ fún Jerusalẹmukí o sì kéde fún unpé iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ ti parí,pé à ti san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,pé ó ti rí i gbà láti ọwọ́ OLÚWAìlọ́po méjì fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. 3 Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù:“Ẹ tún ọ̀nà OLÚWA ṣe,ṣe òpópó tí ó tọ́ ní aginjù fún Ọlọ́run wa. 4 Gbogbo àfonífojì ni a ó gbé sókè,gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀;wíwọ́ ni a ó sọ di títọ́ àtiọ̀nà pálapàla ni a óò sọ di títẹ́jú pẹrẹsẹ. 5 Ògo OLÚWA yóò sì di mí mọ̀,gbogbo ènìyàn lápapọ̀ ni yóò sì rí i.Nítorí ẹnu OLÚWA ni ó ti sọ ọ́.” 6 Ohùn kan wí pé, “Kígbe sókè.”Èmi sì sọ pé, “Igbe kí ni èmi ó ké?” “Gbogbo ènìyàn dàbí i koríko,àti gbogbo ògo wọn dàbí ìtànná igbó. 7 Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀,nítorí èémí OLÚWA ń fẹ́ lù wọ́n.Nítòótọ́ koríko ni àwọn ènìyàn. 8 Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀,ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa dúró títí láé.” 9 Ìwọ tí o mú ìyìn ayọ̀ wá sí Sioni,lọ sí orí òkè gíga.Ìwọ tí ó mú ìyìn ayọ̀ wá sí Jerusalẹmu,gbé ohùn rẹ sókè pẹ̀lú ariwo,gbé e sókè, má ṣe bẹ̀rù;sọ fún àwọn ìlú u Juda,“Ọlọ́run rẹ nìyìí!” 10 Wò ó, OLÚWA Olódùmarè náà ń bọ̀ wá pẹ̀lú agbára,apá rẹ̀ sì ń jẹ ọba fún un.Wò ó, èrè rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀,àti ìdápadà rẹ̀ tí ń bá a bọ̀ wá. 11 Ó ń tọ́ àwọn agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn:Ó kó àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn ní apá rẹ̀.Ó sì gbé wọn súnmọ́ oókan àyà rẹ̀;ó sì fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ darí àwọn tí ó ní. 12 Ta ni ó tiwọn omi nínú kòtò ọwọ́ rẹ̀,tàbí pẹ̀lú ìbú ọwọ́ rẹ̀tí ó wọn àwọn ọ̀run?Ta ni ó ti kó erùpẹ̀ ilẹ̀ ayé jọ nínú apẹ̀rẹ̀,tàbí kí ó wọn àwọn òkè ńlá lórí ìwọ̀nàti òkè kéékèèké nínú òsùwọ̀n? 13 Ta ni ó ti mọ ọkàn OLÚWA,tàbí tí ó ti tọ́ ọ ṣọ́nà gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn rẹ̀? 14 Ta ni OLÚWA ké sí kí ó là á lọ́yẹàti ta ni ó kọ́ òun ní ọ̀nà tí ó tọ́?Ta ni ẹni náà tí ó kọ́ ọ ní ọgbọ́ntàbí tí ó fi ipa ọ̀nà òye hàn án? 15 Nítòótọ́ àwọn orílẹ̀-èdè dàbí i ẹ̀kún omi nínú garawa;a kà wọ́n sí gẹ́gẹ́ bí eruku lórí ìwọ̀n;ó wọn àwọn erékùṣù àfi bí eruku múnúmúnú ni wọ́n. 16 Lebanoni kò tó fún pẹpẹ iná,tàbí kí àwọn ẹranko rẹ̀ kí ó tó fún ẹbọ sísun. 17 Níwájú rẹ̀ ni gbogbo orílẹ̀-èdè dàbí ohun tí kò sí;gbogbo wọn ló kà sí ohun tí kò wúlòtí kò tó ohun tí kò sí. 18 Ta ni nígbà náà tí ìwọ yóò fi Ọlọ́run wé?Ère wo ni ìwọ yóò fi ṣe àkàwé rẹ̀? 19 Ní ti ère, oníṣọ̀nà ni ó dà á,ti alágbẹ̀dẹ wúrà sì fi wúrà bò ótí a sì ṣe ẹ̀wọ̀n ọ̀nà sílífà fún un. 20 Ọkùnrin kan tí ó tálákà jù kí ó lè múirú ọrẹ bẹ́ẹ̀ wá,wá igi tí kò le è rà.Ó wá oníṣọ̀nà tí óláti ṣe àgbékalẹ̀ ère tí kì yóò le è ṣubú. 21 Ǹjẹ́ o kò tí ì mọ̀ìwọ kò tí ì gbọ́?A kò tí ì sọ fún ọ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá?Ìwọ kò tí ì mọ láti ìgbà ìpìlẹ̀ ayé? 22 Òun jókòó lórí ìtẹ́ ní òkè òbírí ilẹ̀ ayé,àwọn ènìyàn rẹ̀ sì dàbí i láńtata.Ó ta àwọn ọ̀run bí ìbòrí ìgúnwà,ó sì nà wọ́n jáde gẹ́gẹ́ bí àgọ́ láti gbé. 23 Ó sọ àwọn ọmọ ọba di asánàti àwọn aláṣẹ ayé yìí ni ó ti sọ dòfo. 24 Gẹ́rẹ́ tí a ti gbìn wọ́n,kété tí a gbìn wọ́n,kété tí wọ́n fi gbòǹgbò múlẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni ó fẹ́ atẹ́gùn lù wọ́n gbogbo wọn sì gbẹ,bẹ́ ni ìjì líle sì gbá wọn lọ gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò. 25 “Ta ni ẹ ó fi mi wé?Tàbí ta ni ó bá mi dọ́gba?” ni Ẹni Mímọ́ wí. 26 Gbé ojú rẹ sókè kí o sì wo àwọn ọ̀run.Ta ni ó dá àwọn wọ̀nyí?Ẹni tí ó mú àkójọpọ̀ àwọn ìràwọ̀ jáde wá ní ọ̀kọ̀ọ̀kantí ó sì pè wọ́n ní orúkọ lọ́kọ̀ọ̀kan.Nítorí agbára ńlá àti ipá rẹ̀,ọ̀kan ṣoṣo nínú wọn kò sọnù. 27 Èéṣe tí o fi sọ, ìwọ Jakọbu?Àti tí o ṣàròyé, ìwọ Israẹli,“Ọ̀nà mi pamọ́ níwájú OLÚWA;ìṣe mi ni a kò kọbi ara sí láti ọwọ́ Ọlọ́run mi”? 28 Ìwọ kò tí ì mọ̀?Ìwọ kò tí ì gbọ́? OLÚWA òun ni Ọlọ́run ayérayé,Ẹlẹ́dàá gbogbo ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé.Agara kì yóò da bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣàárẹ̀,àti òye rẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò le ṣe òdínwọ̀n rẹ̀. 29 Ó ń fi agbára fún àwọn aláàárẹ̀ó sì fi kún agbára àwọn tí agara dá. 30 Àní, ó ń rẹ̀ wọ́n àwọn ọ̀dọ́, wọ́n ń rẹ̀wẹ̀sì,àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì ń kọsẹ̀ wọ́n ṣubú; 31 ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLÚWAyóò sọ agbára wọn di ọ̀tun.Wọn yóò fìyẹ́ fò lókè bí idì;wọn yóò sáré àárẹ̀ kò ní mú wọn,wọn yóò rìn òòyì kò ní kọ́ wọn.

In Other Versions

Isaiah 40 in the ANGEFD

Isaiah 40 in the ANTPNG2D

Isaiah 40 in the AS21

Isaiah 40 in the BAGH

Isaiah 40 in the BBPNG

Isaiah 40 in the BBT1E

Isaiah 40 in the BDS

Isaiah 40 in the BEV

Isaiah 40 in the BHAD

Isaiah 40 in the BIB

Isaiah 40 in the BLPT

Isaiah 40 in the BNT

Isaiah 40 in the BNTABOOT

Isaiah 40 in the BNTLV

Isaiah 40 in the BOATCB

Isaiah 40 in the BOATCB2

Isaiah 40 in the BOBCV

Isaiah 40 in the BOCNT

Isaiah 40 in the BOECS

Isaiah 40 in the BOGWICC

Isaiah 40 in the BOHCB

Isaiah 40 in the BOHCV

Isaiah 40 in the BOHLNT

Isaiah 40 in the BOHNTLTAL

Isaiah 40 in the BOICB

Isaiah 40 in the BOILNTAP

Isaiah 40 in the BOITCV

Isaiah 40 in the BOKCV

Isaiah 40 in the BOKCV2

Isaiah 40 in the BOKHWOG

Isaiah 40 in the BOKSSV

Isaiah 40 in the BOLCB

Isaiah 40 in the BOLCB2

Isaiah 40 in the BOMCV

Isaiah 40 in the BONAV

Isaiah 40 in the BONCB

Isaiah 40 in the BONLT

Isaiah 40 in the BONUT2

Isaiah 40 in the BOPLNT

Isaiah 40 in the BOSCB

Isaiah 40 in the BOSNC

Isaiah 40 in the BOTLNT

Isaiah 40 in the BOVCB

Isaiah 40 in the BPBB

Isaiah 40 in the BPH

Isaiah 40 in the BSB

Isaiah 40 in the CCB

Isaiah 40 in the CUV

Isaiah 40 in the CUVS

Isaiah 40 in the DBT

Isaiah 40 in the DGDNT

Isaiah 40 in the DHNT

Isaiah 40 in the DNT

Isaiah 40 in the ELBE

Isaiah 40 in the EMTV

Isaiah 40 in the ESV

Isaiah 40 in the FBV

Isaiah 40 in the FEB

Isaiah 40 in the GGMNT

Isaiah 40 in the GNT

Isaiah 40 in the HARY

Isaiah 40 in the HNT

Isaiah 40 in the IRVA

Isaiah 40 in the IRVB

Isaiah 40 in the IRVG

Isaiah 40 in the IRVH

Isaiah 40 in the IRVK

Isaiah 40 in the IRVM

Isaiah 40 in the IRVM2

Isaiah 40 in the IRVO

Isaiah 40 in the IRVP

Isaiah 40 in the IRVT

Isaiah 40 in the IRVT2

Isaiah 40 in the IRVU

Isaiah 40 in the ISVN

Isaiah 40 in the JSNT

Isaiah 40 in the KAPI

Isaiah 40 in the KBT1ETNIK

Isaiah 40 in the KBV

Isaiah 40 in the KJV

Isaiah 40 in the KNFD

Isaiah 40 in the LBA

Isaiah 40 in the LBLA

Isaiah 40 in the LNT

Isaiah 40 in the LSV

Isaiah 40 in the MAAL

Isaiah 40 in the MBV

Isaiah 40 in the MBV2

Isaiah 40 in the MHNT

Isaiah 40 in the MKNFD

Isaiah 40 in the MNG

Isaiah 40 in the MNT

Isaiah 40 in the MNT2

Isaiah 40 in the MRS1T

Isaiah 40 in the NAA

Isaiah 40 in the NASB

Isaiah 40 in the NBLA

Isaiah 40 in the NBS

Isaiah 40 in the NBVTP

Isaiah 40 in the NET2

Isaiah 40 in the NIV11

Isaiah 40 in the NNT

Isaiah 40 in the NNT2

Isaiah 40 in the NNT3

Isaiah 40 in the PDDPT

Isaiah 40 in the PFNT

Isaiah 40 in the RMNT

Isaiah 40 in the SBIAS

Isaiah 40 in the SBIBS

Isaiah 40 in the SBIBS2

Isaiah 40 in the SBICS

Isaiah 40 in the SBIDS

Isaiah 40 in the SBIGS

Isaiah 40 in the SBIHS

Isaiah 40 in the SBIIS

Isaiah 40 in the SBIIS2

Isaiah 40 in the SBIIS3

Isaiah 40 in the SBIKS

Isaiah 40 in the SBIKS2

Isaiah 40 in the SBIMS

Isaiah 40 in the SBIOS

Isaiah 40 in the SBIPS

Isaiah 40 in the SBISS

Isaiah 40 in the SBITS

Isaiah 40 in the SBITS2

Isaiah 40 in the SBITS3

Isaiah 40 in the SBITS4

Isaiah 40 in the SBIUS

Isaiah 40 in the SBIVS

Isaiah 40 in the SBT

Isaiah 40 in the SBT1E

Isaiah 40 in the SCHL

Isaiah 40 in the SNT

Isaiah 40 in the SUSU

Isaiah 40 in the SUSU2

Isaiah 40 in the SYNO

Isaiah 40 in the TBIAOTANT

Isaiah 40 in the TBT1E

Isaiah 40 in the TBT1E2

Isaiah 40 in the TFTIP

Isaiah 40 in the TFTU

Isaiah 40 in the TGNTATF3T

Isaiah 40 in the THAI

Isaiah 40 in the TNFD

Isaiah 40 in the TNT

Isaiah 40 in the TNTIK

Isaiah 40 in the TNTIL

Isaiah 40 in the TNTIN

Isaiah 40 in the TNTIP

Isaiah 40 in the TNTIZ

Isaiah 40 in the TOMA

Isaiah 40 in the TTENT

Isaiah 40 in the UBG

Isaiah 40 in the UGV

Isaiah 40 in the UGV2

Isaiah 40 in the UGV3

Isaiah 40 in the VBL

Isaiah 40 in the VDCC

Isaiah 40 in the YALU

Isaiah 40 in the YAPE

Isaiah 40 in the YBVTP

Isaiah 40 in the ZBP