Job 25 (BOYCB)
1 Nígbà náà ní Bilidadi, ará Ṣuhi, dáhùn wí pé, 2 “Ìjọba àti ẹ̀rù ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀,òun ní i ṣe ìlàjà ní ibi gíga gíga ọ̀run. 3 Àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ha ní ìyè bí,tàbí ara ta ni ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kò tàn sí? 4 Èéha ti ṣe tí a ó fi dá ènìyàn láre lọ́dọ̀ Ọlọ́run?Tàbí ẹni tí a bí láti inú obìnrin wá yóò ha ṣe mọ́? 5 Kíyèsi i, òṣùpá kò sì lè tàn ìmọ́lẹ̀,àní àwọn ìràwọ̀ kò mọ́lẹ̀ ní ojú rẹ̀, 6 kí a má sọ ènìyàn tí i ṣe ìdin,àti ọmọ ènìyàn tí í ṣe kòkòrò!”