Job 36 (BOYCB)
1 Elihu sì tún sọ̀rọ̀ wí pé, 2 “Fún mi láyè díẹ̀ èmi ó sì fihàn ọ́,nítorí ọ̀rọ̀ sísọ ní ó kún fún Ọlọ́run. 3 Èmi ó mú ìmọ̀ mi ti ọ̀nà jíjìn wá,èmi ó sì fi òdodo fún Ẹlẹ́dàá mi. 4 Rí i dájú pé ọ̀rọ̀ mi kì yóò ṣèké nítòótọ́;ẹni tí ó pé ní ìmọ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀. 5 “Kíyèsi i, Ọlọ́run ni alágbára, òun kò i sì gàn ènìyàn;ó ní agbára ní ipá àti òye. 6 Òun kì í dá ẹ̀mí ènìyàn búburú sí,ṣùgbọ́n ó fi òtítọ́ fún àwọn tálákà. 7 Òun kì í mú ojú rẹ̀ kúrò lára olódodo,ṣùgbọ́n àwọn ọba ni wọ́n wà lórí ìtẹ́;àní ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé, a sì gbé wọn lékè. 8 Bí ó bá sì dè wọ́n nínú àbà,tí a sì fi okùn ìpọ́njú dè wọ́n, 9 nígbà náà ni ó ń sọ àwọn ohun tí wọn ti ṣe fún wọn,wí pé wọ́n ti ṣẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga wọn. 10 Ó sí wọn létí pẹ̀lú sí ọ̀nà ẹ̀kọ́,ó sì pàṣẹ kí wọn kí ó padà kúrò nínú àìṣedédé. 11 Bí wọ́n bá gbàgbọ́ tí wọ́n sì sìn ín,wọn ó lo ọjọ́ wọn ní ìrọ̀rùn,àti ọdún wọn nínú afẹ́. 12 Ṣùgbọ́n, bí wọn kò bá gbàgbọ́,wọ́n ó ti ọwọ́ idà ṣègbé,wọ́n á sì kú láìní òye. 13 “Ṣùgbọ́n àwọn àgàbàgebè ní ayé kó ìbínú jọ;wọn kò kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nígbà tí ó bá wọ́n wí. 14 Nígbà náà ni ọkàn wọn yóò kú ní èwe,ní àárín àwọn ọkùnrin alágbèrè ojúbọ òrìṣà. 15 Òun gba òtòṣì nínú ìpọ́njú wọn,a sì sọ̀rọ̀ sí wọn ní etí nínú ìnira wọn. 16 “Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lúpẹ̀lú ó fa wọn yọ láti inú ìhágágá sí ibi gbòòrò,sí ibi tí ó ní ààyè tí kò ní wàhálà nínú rẹ̀,ohun tí a sì gbé kalẹ̀ ní tábìlì rẹ̀ jẹ́ kìkì ọ̀rá oúnjẹ tí ó fẹ́. 17 Ṣùgbọ́n ìwọ kún fún ìdájọ́ àwọn búburú;ìdájọ́ àti òtítọ́ dì ọ́ mú. 18 Nítorí ìbínú ń bẹ, ṣọ́ra kí òtítọ́ rẹ máa bá a tàn ọ;láti jẹ́ kí títóbi rẹ mú ọ ṣìnà. 19 Ọrọ̀ rẹ pọ̀ tó, tí wàhálà kì yóò fi dé bá ọ bí?Tàbí ipa agbára rẹ? 20 Má ṣe ìfẹ́ òru, nígbà tí a ń kéàwọn orílẹ̀-èdè kúrò ní ipò wọn. 21 Máa ṣọ́ra kí ìwọ ki ó má yí ara rẹ̀ padà sí búburú,nítorí èyí tí ìwọ rò pé ó dára jù ìpọ́njú lọ. 22 “Kíyèsi i, Ọlọ́run ni gbéga nípa agbára rẹ̀;ta ni jẹ́ olùkọ́ni bí rẹ̀? 23 Ta ni ó là ọ̀nà iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ fún un,tàbí ta ni ó lè wí pé ìwọ ti ń ṣe àìṣedéédéé? 24 Rántí kí ìwọ kí ó gbé iṣẹ́ rẹ̀ ga,ti ènìyàn ni yín nínú orin. 25 Olúkúlùkù ènìyàn a máa rí i;ẹni ikú a máa wò ó ní òkèrè. 26 Kíyèsi i, Ọlọ́run tóbi, àwa kò sì mọ̀ bí ó ti ní òye tó,bẹ́ẹ̀ ni a kò lè wádìí iye ọdún rẹ̀ rí. 27 “Nítorí pé òun ni ó fa ìkán omi òjò sílẹ̀,kí wọn kí ó kán bí òjò ní ìkùùkuu rẹ̀, 28 tí àwọsánmọ̀ ń rọ̀ ìrì rẹ̀ sílẹ̀,tí ó sì fi ń sẹ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ lórí ènìyàn. 29 Pẹ̀lúpẹ̀lú ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè ní ìmọ̀ ìtànká àwọsánmọ̀,tàbí ariwo àrá láti àgọ́ rẹ̀? 30 Kíyèsi i, ó tan ìmọ́lẹ̀ yí ara rẹ̀ káó sì bo ìsàlẹ̀ òkun mọ́lẹ̀. 31 Nítorí pé nípa wọn ní ń ṣe dájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ènìyàn;ó sí ń pèsè oúnjẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀. 32 Ó fi ìmọ́lẹ̀ bo ọwọ́ rẹ̀ méjèèjìó sì rán an sí ẹni olódì. 33 Ariwo àrá rẹ̀ fi ìjì hàn ní;ọ̀wọ́ ẹran pẹ̀lú wí pé, ó súnmọ́ etílé!
In Other Versions
Job 36 in the ANGEFD
Job 36 in the ANTPNG2D
Job 36 in the AS21
Job 36 in the BAGH
Job 36 in the BBPNG
Job 36 in the BBT1E
Job 36 in the BDS
Job 36 in the BEV
Job 36 in the BHAD
Job 36 in the BIB
Job 36 in the BLPT
Job 36 in the BNT
Job 36 in the BNTABOOT
Job 36 in the BNTLV
Job 36 in the BOATCB
Job 36 in the BOATCB2
Job 36 in the BOBCV
Job 36 in the BOCNT
Job 36 in the BOECS
Job 36 in the BOGWICC
Job 36 in the BOHCB
Job 36 in the BOHCV
Job 36 in the BOHLNT
Job 36 in the BOHNTLTAL
Job 36 in the BOICB
Job 36 in the BOILNTAP
Job 36 in the BOITCV
Job 36 in the BOKCV
Job 36 in the BOKCV2
Job 36 in the BOKHWOG
Job 36 in the BOKSSV
Job 36 in the BOLCB
Job 36 in the BOLCB2
Job 36 in the BOMCV
Job 36 in the BONAV
Job 36 in the BONCB
Job 36 in the BONLT
Job 36 in the BONUT2
Job 36 in the BOPLNT
Job 36 in the BOSCB
Job 36 in the BOSNC
Job 36 in the BOTLNT
Job 36 in the BOVCB
Job 36 in the BPBB
Job 36 in the BPH
Job 36 in the BSB
Job 36 in the CCB
Job 36 in the CUV
Job 36 in the CUVS
Job 36 in the DBT
Job 36 in the DGDNT
Job 36 in the DHNT
Job 36 in the DNT
Job 36 in the ELBE
Job 36 in the EMTV
Job 36 in the ESV
Job 36 in the FBV
Job 36 in the FEB
Job 36 in the GGMNT
Job 36 in the GNT
Job 36 in the HARY
Job 36 in the HNT
Job 36 in the IRVA
Job 36 in the IRVB
Job 36 in the IRVG
Job 36 in the IRVH
Job 36 in the IRVK
Job 36 in the IRVM
Job 36 in the IRVM2
Job 36 in the IRVO
Job 36 in the IRVP
Job 36 in the IRVT
Job 36 in the IRVT2
Job 36 in the IRVU
Job 36 in the ISVN
Job 36 in the JSNT
Job 36 in the KAPI
Job 36 in the KBT1ETNIK
Job 36 in the KBV
Job 36 in the KJV
Job 36 in the KNFD
Job 36 in the LBA
Job 36 in the LBLA
Job 36 in the LNT
Job 36 in the LSV
Job 36 in the MAAL
Job 36 in the MBV
Job 36 in the MBV2
Job 36 in the MHNT
Job 36 in the MKNFD
Job 36 in the MNG
Job 36 in the MNT
Job 36 in the MNT2
Job 36 in the MRS1T
Job 36 in the NAA
Job 36 in the NASB
Job 36 in the NBLA
Job 36 in the NBS
Job 36 in the NBVTP
Job 36 in the NET2
Job 36 in the NIV11
Job 36 in the NNT
Job 36 in the NNT2
Job 36 in the NNT3
Job 36 in the PDDPT
Job 36 in the PFNT
Job 36 in the RMNT
Job 36 in the SBIAS
Job 36 in the SBIBS
Job 36 in the SBIBS2
Job 36 in the SBICS
Job 36 in the SBIDS
Job 36 in the SBIGS
Job 36 in the SBIHS
Job 36 in the SBIIS
Job 36 in the SBIIS2
Job 36 in the SBIIS3
Job 36 in the SBIKS
Job 36 in the SBIKS2
Job 36 in the SBIMS
Job 36 in the SBIOS
Job 36 in the SBIPS
Job 36 in the SBISS
Job 36 in the SBITS
Job 36 in the SBITS2
Job 36 in the SBITS3
Job 36 in the SBITS4
Job 36 in the SBIUS
Job 36 in the SBIVS
Job 36 in the SBT
Job 36 in the SBT1E
Job 36 in the SCHL
Job 36 in the SNT
Job 36 in the SUSU
Job 36 in the SUSU2
Job 36 in the SYNO
Job 36 in the TBIAOTANT
Job 36 in the TBT1E
Job 36 in the TBT1E2
Job 36 in the TFTIP
Job 36 in the TFTU
Job 36 in the TGNTATF3T
Job 36 in the THAI
Job 36 in the TNFD
Job 36 in the TNT
Job 36 in the TNTIK
Job 36 in the TNTIL
Job 36 in the TNTIN
Job 36 in the TNTIP
Job 36 in the TNTIZ
Job 36 in the TOMA
Job 36 in the TTENT
Job 36 in the UBG
Job 36 in the UGV
Job 36 in the UGV2
Job 36 in the UGV3
Job 36 in the VBL
Job 36 in the VDCC
Job 36 in the YALU
Job 36 in the YAPE
Job 36 in the YBVTP
Job 36 in the ZBP