Joel 3 (BOYCB)

1 “Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àti ní àkókò náà,nígbà tí èmi tún mú ìgbèkùn Juda àti Jerusalẹmu padà bọ̀. 2 Èmi yóò kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọpẹ̀lú èmi yóò sì mú wọn wá sí àfonífojì Jehoṣafati.Èmi yóò sì bá wọn wíjọ́ níbẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn mi,àti nítorí Israẹli ìní mi,tí wọ́n fọ́nká sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè,wọ́n sì pín ilẹ̀ mi. 3 Wọ́n si ti di ìbò fún àwọn ènìyàn mi;wọ́n sì ti fi ọmọdékùnrin kan fún panṣágà obìnrin kan,wọ́n sì ta ọmọdébìnrin kan fún ọtí wáìnì, kí wọ́n kí ó lè mu. 4 “Nísinsin yìí, kí ni ẹ̀yin ní fi mí ṣe Tire àti Sidoni, àti gbogbo ẹ̀yin ẹkún Filistia? Ẹ̀yin yóò ha sàn ẹ̀san fún mi? Bí ẹ̀yin bá sì san ẹ̀san fún mi, ní kánkán àti ní kíákíá ní èmi yóò san ẹ̀san ohun ti ẹ̀yin ṣe padà sórí ara yín. 5 Nítorí tí ẹ̀yin tí mú fàdákà mi àti wúrà mi, ẹ̀yin si tí mú ohun rere dáradára mi lọ sínú tẹmpili yín. 6 Àti àwọn ọmọ Juda, àti àwọn ọmọ Jerusalẹmu ní ẹ̀yin ti tà fún àwọn ará Giriki, kí ẹ̀yin bá à lè sí wọn jìnnà kúrò ní agbègbè ilẹ̀ ìní wọn. 7 “Kíyèsi í, èmi yóò gbé wọ́n dìde kúrò níbi tì ẹ̀yin ti tà wọ́n sí, èmi yóò sì san ẹ̀san ohun ti ẹ ṣe padà sórí ara yín. 8 Èmi yóò si tà àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín sí ọwọ́ àwọn ọmọ Juda, wọ́n yóò sì tà wọ́n fún àwọn ara Sabeani, fún orílẹ̀-èdè kan tí ó jìnnà réré.” Nítorí OLÚWA ní o ti sọ ọ. 9 Ẹ kéde èyí ní àárín àwọn kèfèrí;ẹ dira ogun,ẹ jí àwọn alágbára.Jẹ kí àwọn ajagun kí wọn bẹ̀rẹ̀ ogun. 10 Ẹ fi irin ìtulẹ̀ yín rọ idà,àti dòjé yín rọ ọ̀kọ̀.Jẹ́ kí aláìlera wí pé,“Ara mi le koko.” 11 Ẹ wá kánkán, gbogbo ẹ̀yin kèfèrí láti gbogbo àyíká,kí ẹ sì gbá ara yín jọ yí káàkiri. Níbẹ̀ ní kí o mú àwọn alágbára rẹ sọ̀kalẹ̀, OLÚWA. 12 “Ẹ jí, ẹ sì gòkè wá sí àfonífojìJehoṣafati ẹ̀yin kèfèrí:nítorí níbẹ̀ ní èmi yóò jókòó láti ṣeìdájọ́ àwọn kèfèrí yí káàkiri. 13 Ẹ tẹ dòjé bọ̀ ọ́,nítorí ìkórè pọ́n.Ẹ wá, ẹ sọ̀kalẹ̀,nítorí ìfúntí kún,nítorí àwọn ọpọ́n kún àkúnwọ́sílẹ̀,nítorí ìwà búburú wọn pọ̀!” 14 Ọ̀pọ̀lọpọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ní àfonífojì ìpinnu!Nítorí ọjọ́ OLÚWA kù si dẹ̀dẹ̀ní àfonífojì ìdájọ́. 15 Oòrùn àti òṣùpá yóò ṣú òkùnkùn,àti àwọn ìràwọ̀ kí yóò tan ìmọ́lẹ̀ wọn mọ́. 16 OLÚWA yóò sí ké ramúramù láti Sioni wá,yóò sì fọ ohùn rẹ̀ jáde láti Jerusalẹmu wá;àwọn ọ̀run àti ayé yóò sì mì tìtì.Ṣùgbọ́n OLÚWA yóò ṣe ààbò àwọn ènìyàn rẹ̀,àti agbára àwọn ọmọ Israẹli. 17 “Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ni OLÚWA Ọlọ́run yín,tí ń gbé Sioni òkè mímọ́ mi.Ìgbà náà ni Jerusalẹmu yóò jẹ́ mímọ́;àwọn àjèjì kì yóò sì kó o mọ́. 18 “Ní ọjọ́ náà, àwọn òkè ńlá yóò máa kán ọtí wáìnì tuntun sílẹ̀,àwọn òkè kéékèèké yóò máa sàn fún wàrà;gbogbo odò Juda tí ó gbẹ́ yóò máa sàn fún omi.Orísun kan yóò sì ṣàn jáde láti inú ilé OLÚWA wá,yóò sì rin omi sí àfonífojì Ṣittimu. 19 Ṣùgbọ́n Ejibiti yóò di ahoro,Edomu yóò sì di aṣálẹ̀ ahoro,nítorí ìwà ipá tí a hù sì àwọn ọmọ Juda,ní ilẹ̀ ẹni tí wọ́n ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀. 20 Ṣùgbọ́n Juda yóò jẹ́ ibùgbé títí láé,àti Jerusalẹmu láti ìran dé ìran. 21 Nítorí èmi yóò wẹ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wọn nù, tí èmi kò tí ì wẹ̀nù. Nítorí OLÚWA ń gbé Sioni.”

In Other Versions

Joel 3 in the ANGEFD

Joel 3 in the ANTPNG2D

Joel 3 in the AS21

Joel 3 in the BAGH

Joel 3 in the BBPNG

Joel 3 in the BBT1E

Joel 3 in the BDS

Joel 3 in the BEV

Joel 3 in the BHAD

Joel 3 in the BIB

Joel 3 in the BLPT

Joel 3 in the BNT

Joel 3 in the BNTABOOT

Joel 3 in the BNTLV

Joel 3 in the BOATCB

Joel 3 in the BOATCB2

Joel 3 in the BOBCV

Joel 3 in the BOCNT

Joel 3 in the BOECS

Joel 3 in the BOGWICC

Joel 3 in the BOHCB

Joel 3 in the BOHCV

Joel 3 in the BOHLNT

Joel 3 in the BOHNTLTAL

Joel 3 in the BOICB

Joel 3 in the BOILNTAP

Joel 3 in the BOITCV

Joel 3 in the BOKCV

Joel 3 in the BOKCV2

Joel 3 in the BOKHWOG

Joel 3 in the BOKSSV

Joel 3 in the BOLCB

Joel 3 in the BOLCB2

Joel 3 in the BOMCV

Joel 3 in the BONAV

Joel 3 in the BONCB

Joel 3 in the BONLT

Joel 3 in the BONUT2

Joel 3 in the BOPLNT

Joel 3 in the BOSCB

Joel 3 in the BOSNC

Joel 3 in the BOTLNT

Joel 3 in the BOVCB

Joel 3 in the BPBB

Joel 3 in the BPH

Joel 3 in the BSB

Joel 3 in the CCB

Joel 3 in the CUV

Joel 3 in the CUVS

Joel 3 in the DBT

Joel 3 in the DGDNT

Joel 3 in the DHNT

Joel 3 in the DNT

Joel 3 in the ELBE

Joel 3 in the EMTV

Joel 3 in the ESV

Joel 3 in the FBV

Joel 3 in the FEB

Joel 3 in the GGMNT

Joel 3 in the GNT

Joel 3 in the HARY

Joel 3 in the HNT

Joel 3 in the IRVA

Joel 3 in the IRVB

Joel 3 in the IRVG

Joel 3 in the IRVH

Joel 3 in the IRVK

Joel 3 in the IRVM

Joel 3 in the IRVM2

Joel 3 in the IRVO

Joel 3 in the IRVP

Joel 3 in the IRVT

Joel 3 in the IRVT2

Joel 3 in the IRVU

Joel 3 in the ISVN

Joel 3 in the JSNT

Joel 3 in the KAPI

Joel 3 in the KBT1ETNIK

Joel 3 in the KBV

Joel 3 in the KJV

Joel 3 in the KNFD

Joel 3 in the LBA

Joel 3 in the LBLA

Joel 3 in the LNT

Joel 3 in the LSV

Joel 3 in the MAAL

Joel 3 in the MBV

Joel 3 in the MBV2

Joel 3 in the MHNT

Joel 3 in the MKNFD

Joel 3 in the MNG

Joel 3 in the MNT

Joel 3 in the MNT2

Joel 3 in the MRS1T

Joel 3 in the NAA

Joel 3 in the NASB

Joel 3 in the NBLA

Joel 3 in the NBS

Joel 3 in the NBVTP

Joel 3 in the NET2

Joel 3 in the NIV11

Joel 3 in the NNT

Joel 3 in the NNT2

Joel 3 in the NNT3

Joel 3 in the PDDPT

Joel 3 in the PFNT

Joel 3 in the RMNT

Joel 3 in the SBIAS

Joel 3 in the SBIBS

Joel 3 in the SBIBS2

Joel 3 in the SBICS

Joel 3 in the SBIDS

Joel 3 in the SBIGS

Joel 3 in the SBIHS

Joel 3 in the SBIIS

Joel 3 in the SBIIS2

Joel 3 in the SBIIS3

Joel 3 in the SBIKS

Joel 3 in the SBIKS2

Joel 3 in the SBIMS

Joel 3 in the SBIOS

Joel 3 in the SBIPS

Joel 3 in the SBISS

Joel 3 in the SBITS

Joel 3 in the SBITS2

Joel 3 in the SBITS3

Joel 3 in the SBITS4

Joel 3 in the SBIUS

Joel 3 in the SBIVS

Joel 3 in the SBT

Joel 3 in the SBT1E

Joel 3 in the SCHL

Joel 3 in the SNT

Joel 3 in the SUSU

Joel 3 in the SUSU2

Joel 3 in the SYNO

Joel 3 in the TBIAOTANT

Joel 3 in the TBT1E

Joel 3 in the TBT1E2

Joel 3 in the TFTIP

Joel 3 in the TFTU

Joel 3 in the TGNTATF3T

Joel 3 in the THAI

Joel 3 in the TNFD

Joel 3 in the TNT

Joel 3 in the TNTIK

Joel 3 in the TNTIL

Joel 3 in the TNTIN

Joel 3 in the TNTIP

Joel 3 in the TNTIZ

Joel 3 in the TOMA

Joel 3 in the TTENT

Joel 3 in the UBG

Joel 3 in the UGV

Joel 3 in the UGV2

Joel 3 in the UGV3

Joel 3 in the VBL

Joel 3 in the VDCC

Joel 3 in the YALU

Joel 3 in the YAPE

Joel 3 in the YBVTP

Joel 3 in the ZBP