Matthew 19 (BOYCB)
1 Lẹ́yìn tí Jesu ti parí ọ̀rọ̀ yìí, ó kúrò ní Galili. Ó sì yípo padà sí Judea, ó gba ìhà kejì odò Jordani. 2 Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì mú wọn láradá níbẹ̀. 3 Àwọn Farisi wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti dán an wò. Wọ́n bi í pé, “Ǹjẹ́ ó tọ̀nà fún ọkùnrin láti kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ nítorí ohunkóhun?” 4 Ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹyin kò ti kà á pé ‘ẹni tí ó dá wọn ní ìgbà àtètèkọ́ṣe, Ọlọ́run dá wọn ni ti akọ ti abo.’ 5 Ó sì wí fún un pé, ‘Nítorí ìdí èyí ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, òun yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan.’ 6 Wọn kì í túnṣe méjì mọ́, ṣùgbọ́n ara kan. Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run bá ti so ṣọ̀kan, kí ẹnikẹ́ni má ṣe yà wọ́n.” 7 Wọ́n bi í pé: “Kí ni ìdí tí Mose fi pàṣẹ pé, ọkùnrin kan lè kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ nípa fífún un ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀?” 8 Jesu dáhùn pé, “Nítorí líle àyà yín ni Mose ṣe gbà fún yín láti máa kọ aya yín sílẹ̀. Ṣùgbọ́n láti ìgbà àtètèkọ́ṣe wá, kò rí bẹ́ẹ̀. 9 Mo sọ èyí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, láìṣe pé nítorí àgbèrè, tí ó bá sì fẹ́ ẹlòmíràn, ó ṣe panṣágà.” 10 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Bí ọ̀rọ̀ bá rí báyìí láàrín ọkọ àti aya, kó ṣàǹfààní fún wa láti gbé ìyàwó.” 11 Jesu dáhùn pé, “Gbogbo ènìyàn kọ́ ló lé gba ọ̀rọ̀ yìí, bí kò ṣe iye àwọn tí a ti fún. 12 Àwọn mìíràn jẹ́ akúra nítorí bẹ́ẹ̀ ní a bí wọn, àwọn mìíràn ń bẹ tí ènìyàn sọ wọn di bẹ́ẹ̀; àwọn mìíràn kọ̀ láti gbé ìyàwó nítorí ìjọba ọ̀run. Ẹni tí ó bá lè gbà á kí ó gbà á.” 13 Lẹ́yìn náà a sì gbé àwọn ọmọ ọwọ́ wá sọ́dọ̀ Jesu, kí ó lè gbé ọwọ́ lé wọn, kí ó sì gbàdúrà fún wọn. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá àwọn tí ó gbé wọn wá wí. 14 Ṣùgbọ́n Jesu dáhùn pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọdé wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má ṣe dá wọn lẹ́kun, nítorí irú wọn ni ìjọba ọ̀run.” 15 Lẹ́yìn náà, ó gbé ọwọ́ lé wọn, ó sì kúrò níbẹ̀. 16 Ẹnìkan sì wá ó bí Jesu pé, “Olùkọ́, ohun rere kí ni èmi yóò ṣe, kí èmi kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun?” 17 Jesu dá a lóhùn pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń béèrè nípa ohun rere lọ́wọ́ mi. Ẹni kan ṣoṣo ni ó wà tí í ṣe ẹni rere. Bí ìwọ bá fẹ́ dé ibi ìyè, pa àwọn òfin mọ́.” 18 Ọkùnrin náà béèrè pé, “Àwọn wo ni òfin wọ̀nyí?”Jesu dáhùn pé, “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn; ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà; ìwọ kò gbọdọ̀ jalè; ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké’, 19 bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ. ‘Kí o sì fẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’ ” 20 Ọmọdékùnrin náà tún wí pé, “Gbogbo òfin wọ̀nyí ni èmi ti ń pamọ́, kí ni nǹkan mìíràn tí èmi ní láti ṣe?” 21 Jesu wí fún un pé, “Bí ìwọ bá fẹ́ di ẹni pípé, lọ ta ohun gbogbo tí ìwọ ní, kí o sì fi owó rẹ̀ tọrẹ fún àwọn aláìní. Ìwọ yóò ní ọrọ̀ ńlá ní ọ̀run. Lẹ́yìn náà, wá láti máa tọ̀ mi lẹ́yìn.” 22 Ṣùgbọ́n nígbà tí ọ̀dọ́mọkùnrin náà gbọ́ èyí, ó kúrò níbẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́, nítorí ó ní ọrọ̀ púpọ̀. 23 Nígbà náà, ní Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, ó ṣòro fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọ̀run.” 24 Mo tún wí fún yín pé, “Ó rọrùn fún ìbákasẹ láti wọ ojú abẹ́rẹ́ jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run.” 25 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbọ́ èyí, ẹnu sì yà wọn gidigidi, wọ́n béèrè pé, “Ǹjẹ́ ta ni ó ha le là?” 26 Ṣùgbọ́n Jesu wò wọ́n, ó sì wí fún wọn pé, “Ènìyàn ni èyí ṣòro fún; ṣùgbọ́n fún Ọlọ́run ohun gbogbo ni ṣíṣe.” 27 Peteru sì wí fún un pé, “Àwa ti fi ohun gbogbo sílẹ̀, a sì tẹ̀lé ọ, kí ni yóò jẹ́ èrè wa?” 28 Jesu dáhùn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, ‘Nígbà ìsọdọ̀tun ohun gbogbo, nígbà tí Ọmọ Ènìyàn yóò jókòó lórí ìtẹ́ tí ó lógo, dájúdájú, ẹ̀yin ọmọ-ẹ̀yìn mi yóò sì jókòó lórí ìtẹ́ méjìlá láti ṣe ìdájọ́ ẹ̀yà Israẹli méjìlá. 29 Àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ilé tàbí arákùnrin tàbí arábìnrin tàbí baba tàbí ìyá tàbí àwọn ọmọ, tàbí ohun ìní rẹ̀ sílẹ̀ nítorí orúkọ mí, yóò gba ọgọọgọ́rùn-ún èrè rẹ̀ láyé, wọn ó sì tún jogún ìyè àìnípẹ̀kun. 30 Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn tí ó síwájú nísinsin yìí ni yóò kẹ́yìn, àwọn tí ó kẹ́yìn ni yóò sì síwájú.’
In Other Versions
Matthew 19 in the ANGEFD
Matthew 19 in the ANTPNG2D
Matthew 19 in the AS21
Matthew 19 in the BAGH
Matthew 19 in the BBPNG
Matthew 19 in the BBT1E
Matthew 19 in the BDS
Matthew 19 in the BEV
Matthew 19 in the BHAD
Matthew 19 in the BIB
Matthew 19 in the BLPT
Matthew 19 in the BNT
Matthew 19 in the BNTABOOT
Matthew 19 in the BNTLV
Matthew 19 in the BOATCB
Matthew 19 in the BOATCB2
Matthew 19 in the BOBCV
Matthew 19 in the BOCNT
Matthew 19 in the BOECS
Matthew 19 in the BOGWICC
Matthew 19 in the BOHCB
Matthew 19 in the BOHCV
Matthew 19 in the BOHLNT
Matthew 19 in the BOHNTLTAL
Matthew 19 in the BOICB
Matthew 19 in the BOILNTAP
Matthew 19 in the BOITCV
Matthew 19 in the BOKCV
Matthew 19 in the BOKCV2
Matthew 19 in the BOKHWOG
Matthew 19 in the BOKSSV
Matthew 19 in the BOLCB
Matthew 19 in the BOLCB2
Matthew 19 in the BOMCV
Matthew 19 in the BONAV
Matthew 19 in the BONCB
Matthew 19 in the BONLT
Matthew 19 in the BONUT2
Matthew 19 in the BOPLNT
Matthew 19 in the BOSCB
Matthew 19 in the BOSNC
Matthew 19 in the BOTLNT
Matthew 19 in the BOVCB
Matthew 19 in the BPBB
Matthew 19 in the BPH
Matthew 19 in the BSB
Matthew 19 in the CCB
Matthew 19 in the CUV
Matthew 19 in the CUVS
Matthew 19 in the DBT
Matthew 19 in the DGDNT
Matthew 19 in the DHNT
Matthew 19 in the DNT
Matthew 19 in the ELBE
Matthew 19 in the EMTV
Matthew 19 in the ESV
Matthew 19 in the FBV
Matthew 19 in the FEB
Matthew 19 in the GGMNT
Matthew 19 in the GNT
Matthew 19 in the HARY
Matthew 19 in the HNT
Matthew 19 in the IRVA
Matthew 19 in the IRVB
Matthew 19 in the IRVG
Matthew 19 in the IRVH
Matthew 19 in the IRVK
Matthew 19 in the IRVM
Matthew 19 in the IRVM2
Matthew 19 in the IRVO
Matthew 19 in the IRVP
Matthew 19 in the IRVT
Matthew 19 in the IRVT2
Matthew 19 in the IRVU
Matthew 19 in the ISVN
Matthew 19 in the JSNT
Matthew 19 in the KAPI
Matthew 19 in the KBT1ETNIK
Matthew 19 in the KBV
Matthew 19 in the KJV
Matthew 19 in the KNFD
Matthew 19 in the LBA
Matthew 19 in the LBLA
Matthew 19 in the LNT
Matthew 19 in the LSV
Matthew 19 in the MAAL
Matthew 19 in the MBV
Matthew 19 in the MBV2
Matthew 19 in the MHNT
Matthew 19 in the MKNFD
Matthew 19 in the MNG
Matthew 19 in the MNT
Matthew 19 in the MNT2
Matthew 19 in the MRS1T
Matthew 19 in the NAA
Matthew 19 in the NASB
Matthew 19 in the NBLA
Matthew 19 in the NBS
Matthew 19 in the NBVTP
Matthew 19 in the NET2
Matthew 19 in the NIV11
Matthew 19 in the NNT
Matthew 19 in the NNT2
Matthew 19 in the NNT3
Matthew 19 in the PDDPT
Matthew 19 in the PFNT
Matthew 19 in the RMNT
Matthew 19 in the SBIAS
Matthew 19 in the SBIBS
Matthew 19 in the SBIBS2
Matthew 19 in the SBICS
Matthew 19 in the SBIDS
Matthew 19 in the SBIGS
Matthew 19 in the SBIHS
Matthew 19 in the SBIIS
Matthew 19 in the SBIIS2
Matthew 19 in the SBIIS3
Matthew 19 in the SBIKS
Matthew 19 in the SBIKS2
Matthew 19 in the SBIMS
Matthew 19 in the SBIOS
Matthew 19 in the SBIPS
Matthew 19 in the SBISS
Matthew 19 in the SBITS
Matthew 19 in the SBITS2
Matthew 19 in the SBITS3
Matthew 19 in the SBITS4
Matthew 19 in the SBIUS
Matthew 19 in the SBIVS
Matthew 19 in the SBT
Matthew 19 in the SBT1E
Matthew 19 in the SCHL
Matthew 19 in the SNT
Matthew 19 in the SUSU
Matthew 19 in the SUSU2
Matthew 19 in the SYNO
Matthew 19 in the TBIAOTANT
Matthew 19 in the TBT1E
Matthew 19 in the TBT1E2
Matthew 19 in the TFTIP
Matthew 19 in the TFTU
Matthew 19 in the TGNTATF3T
Matthew 19 in the THAI
Matthew 19 in the TNFD
Matthew 19 in the TNT
Matthew 19 in the TNTIK
Matthew 19 in the TNTIL
Matthew 19 in the TNTIN
Matthew 19 in the TNTIP
Matthew 19 in the TNTIZ
Matthew 19 in the TOMA
Matthew 19 in the TTENT
Matthew 19 in the UBG
Matthew 19 in the UGV
Matthew 19 in the UGV2
Matthew 19 in the UGV3
Matthew 19 in the VBL
Matthew 19 in the VDCC
Matthew 19 in the YALU
Matthew 19 in the YAPE
Matthew 19 in the YBVTP
Matthew 19 in the ZBP