Obadiah 1 (BOYCB)
1 Ìran ti Obadiah. Èyí ni OLÚWA Olódùmarè wí nípa Edomu.Àwa ti gbọ́ ohùn kan láti ọ̀dọ̀ OLÚWA wá,a sì ti rán ikọ̀ kan sí gbogbo kèfèrí láti sọ pé,“Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a dìde ogun sí i.” 2 “Kíyèsi i, Èmi yóò sọ ọ́ di kékeré láàrín àwọn kèfèrí;ìwọ yóò sì di gígàn lọ́pọ̀lọ́pọ̀. 3 Ìgbéraga àyà rẹ ti tàn ọ́ jẹ,ìwọ tí ń gbé inú pálapàla àpáta,tí o sì kọ́ ibùgbé rẹ sí ibi gíga,ìwọ wí nínú ọkàn rẹ pé,‘Ta ni yóò mú mi sọ̀kalẹ̀?’ 4 Bí ìwọ tilẹ̀ gbé ara rẹ ga bí ẹyẹ idì,bí ìwọ tilẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ rẹ sí àárín àwọn ìràwọ̀,láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti sọ̀ ọ kalẹ̀,”ni OLÚWA wí. 5 “Bí àwọn olè tọ̀ ọ́ wá,bí àwọn ọlọ́ṣà ní òru,Háà! Irú ìparun wo ló dúró dè ọ́,wọn kò ha jalè tó bí wọ́n ti fẹ́?Bí àwọn tí ń ká èso àjàrà tọ̀ ọ́ wá,wọn kò ha ni fi èso àjàrà díẹ̀ sílẹ̀? 6 Báwo ni a ṣe ṣe àwárí nǹkan Esau,tí a sì wá ohun ìní ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ jáde. 7 Gbogbo àwọn ẹni ìmùlẹ̀ rẹti mú ọ dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ rẹ,àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ti tàn ọ́ jẹ, wọ́n sì ti borí rẹ;àwọn tó jẹ oúnjẹ rẹ dẹ pàkúté dè ọ́,ṣùgbọ́n ìwọ kò ní ní òye rẹ̀.” 8 OLÚWA wí pé, “Ní ọjọ́ náà,Èmi kì yóò ha pa àwọn ọlọ́gbọ́n Edomu run,àti àwọn amòye run kúrò ní òkè Esau? 9 A ó ṣe ẹ̀rù ba àwọn jagunjagun rẹ, ìwọ Temani,gbogbo àwọn tó wà ní orí òkè Esauní a ó gé kúrò nínú ìpànìyàn náà. 10 Nítorí ìwà ipá sí Jakọbu arákùnrin rẹ,ìtìjú yóò bò ọ,a ó sì pa ọ run títí láé. 11 Ní ọjọ́ tí ìwọ dúró ní apá kan,ní ọjọ́ tí àlejò kó ogún rẹ lọ,tí àwọn àjèjì sì wọ ibodè rẹ,tí wọ́n sì sẹ́ kèké lórí Jerusalẹmu,ìwọ náà wà bí ọ̀kan nínú wọn. 12 Ìwọ kì bá tí fi ojú kéré arákùnrin rẹ,ní àkókò ìbànújẹ́ rẹ̀ìwọ kì bá tí yọ̀ lórí àwọn ọmọ Juda,ní ọjọ́ ìparun wọnìwọ kì bá tí gbéraga púpọ̀ní ọjọ́ wàhálà wọn. 13 Ìwọ kì bá tí wọ inú ibodè àwọn ènìyàn mi lọ,ní ọjọ́ àjálù wọn.Ìwọ kì bá tí fojú kó wọn mọ́lẹ̀nínú ìdààmú wọn, ní ọjọ́ àjálù wọn.Ìwọ kì bá tí jí ẹrù wọn kó,ní ọjọ́ ìpọ́njú wọn. 14 Ìwọ kì bá tí dúró ní ìkóríta ọ̀nàláti ké àwọn tirẹ̀ tó ti sálà kúrò.Ìwọ kì bá tí fa àwọn tó ṣẹ́kù nínúwọn lélẹ̀ ní ọjọ́ wàhálà wọn. 15 “Nítorí ọjọ́ OLÚWA súnmọ́ etílélórí gbogbo àwọn kèfèrí.Bí ìwọ ti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe sí ìwọ náà;ẹ̀san rẹ yóò sì yípadà sí orí ara rẹ. 16 Gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀ ṣe mu lórí òkè mímọ́ mi,bẹ́ẹ̀ ni gbogbo kèfèrí yóò máa mu títí;wọn yóò mu ún ní àmutẹ́rùnwọn yóò sì wà bí ẹni pé wọn kò mu ún rí. 17 Ṣùgbọ́n ìgbàlà yóò wà lórí òkè Sioni,wọn yóò sì jẹ́ mímọ́,àti ilé Jakọbu yóò sì ní ìní wọn. 18 Ilé Jakọbu yóò sì jẹ́ ináàti ilé Josẹfu ọwọ́ ináilé Esau yóò jẹ àgékù koríkowọn yóò fi iná sí i,wọn yóò jo run.Kì yóò sí ẹni tí yóò kù ní ilé Esau.”Nítorí OLÚWA ti sọ̀rọ̀. 19 Àwọn ará gúúsù yóò ni òkè Esau,àwọn ará ẹsẹ̀ òkè yóò niilẹ̀ àwọn ará Filistini ní ìní.Wọn yóò sì ni oko Efraimu àti Samaria;Benjamini yóò ní Gileadi ní ìní. 20 Àwọn ìgbèkùn Israẹli tí ó wà ní Kenaaniyóò ni ilẹ̀ títí dé Sarefati;àwọn ìgbèkùn láti Jerusalẹmu tí ó wà ní Sefarediyóò ni àwọn ìlú gúúsù ní ìní. 21 Àwọn tó ń gba ni là yóò sì gòkè Sioni wáláti jẹ ọba lé orí àwọn òkè Esau.Ìjọba náà yóò sì jẹ́ ti OLÚWA.
In Other Versions
Obadiah 1 in the ANGEFD
Obadiah 1 in the ANTPNG2D
Obadiah 1 in the AS21
Obadiah 1 in the BAGH
Obadiah 1 in the BBPNG
Obadiah 1 in the BBT1E
Obadiah 1 in the BDS
Obadiah 1 in the BEV
Obadiah 1 in the BHAD
Obadiah 1 in the BIB
Obadiah 1 in the BLPT
Obadiah 1 in the BNT
Obadiah 1 in the BNTABOOT
Obadiah 1 in the BNTLV
Obadiah 1 in the BOATCB
Obadiah 1 in the BOATCB2
Obadiah 1 in the BOBCV
Obadiah 1 in the BOCNT
Obadiah 1 in the BOECS
Obadiah 1 in the BOGWICC
Obadiah 1 in the BOHCB
Obadiah 1 in the BOHCV
Obadiah 1 in the BOHLNT
Obadiah 1 in the BOHNTLTAL
Obadiah 1 in the BOICB
Obadiah 1 in the BOILNTAP
Obadiah 1 in the BOITCV
Obadiah 1 in the BOKCV
Obadiah 1 in the BOKCV2
Obadiah 1 in the BOKHWOG
Obadiah 1 in the BOKSSV
Obadiah 1 in the BOLCB
Obadiah 1 in the BOLCB2
Obadiah 1 in the BOMCV
Obadiah 1 in the BONAV
Obadiah 1 in the BONCB
Obadiah 1 in the BONLT
Obadiah 1 in the BONUT2
Obadiah 1 in the BOPLNT
Obadiah 1 in the BOSCB
Obadiah 1 in the BOSNC
Obadiah 1 in the BOTLNT
Obadiah 1 in the BOVCB
Obadiah 1 in the BPBB
Obadiah 1 in the BPH
Obadiah 1 in the BSB
Obadiah 1 in the CCB
Obadiah 1 in the CUV
Obadiah 1 in the CUVS
Obadiah 1 in the DBT
Obadiah 1 in the DGDNT
Obadiah 1 in the DHNT
Obadiah 1 in the DNT
Obadiah 1 in the ELBE
Obadiah 1 in the EMTV
Obadiah 1 in the ESV
Obadiah 1 in the FBV
Obadiah 1 in the FEB
Obadiah 1 in the GGMNT
Obadiah 1 in the GNT
Obadiah 1 in the HARY
Obadiah 1 in the HNT
Obadiah 1 in the IRVA
Obadiah 1 in the IRVB
Obadiah 1 in the IRVG
Obadiah 1 in the IRVH
Obadiah 1 in the IRVK
Obadiah 1 in the IRVM
Obadiah 1 in the IRVM2
Obadiah 1 in the IRVO
Obadiah 1 in the IRVP
Obadiah 1 in the IRVT
Obadiah 1 in the IRVT2
Obadiah 1 in the IRVU
Obadiah 1 in the ISVN
Obadiah 1 in the JSNT
Obadiah 1 in the KAPI
Obadiah 1 in the KBT1ETNIK
Obadiah 1 in the KBV
Obadiah 1 in the KJV
Obadiah 1 in the KNFD
Obadiah 1 in the LBA
Obadiah 1 in the LBLA
Obadiah 1 in the LNT
Obadiah 1 in the LSV
Obadiah 1 in the MAAL
Obadiah 1 in the MBV
Obadiah 1 in the MBV2
Obadiah 1 in the MHNT
Obadiah 1 in the MKNFD
Obadiah 1 in the MNG
Obadiah 1 in the MNT
Obadiah 1 in the MNT2
Obadiah 1 in the MRS1T
Obadiah 1 in the NAA
Obadiah 1 in the NASB
Obadiah 1 in the NBLA
Obadiah 1 in the NBS
Obadiah 1 in the NBVTP
Obadiah 1 in the NET2
Obadiah 1 in the NIV11
Obadiah 1 in the NNT
Obadiah 1 in the NNT2
Obadiah 1 in the NNT3
Obadiah 1 in the PDDPT
Obadiah 1 in the PFNT
Obadiah 1 in the RMNT
Obadiah 1 in the SBIAS
Obadiah 1 in the SBIBS
Obadiah 1 in the SBIBS2
Obadiah 1 in the SBICS
Obadiah 1 in the SBIDS
Obadiah 1 in the SBIGS
Obadiah 1 in the SBIHS
Obadiah 1 in the SBIIS
Obadiah 1 in the SBIIS2
Obadiah 1 in the SBIIS3
Obadiah 1 in the SBIKS
Obadiah 1 in the SBIKS2
Obadiah 1 in the SBIMS
Obadiah 1 in the SBIOS
Obadiah 1 in the SBIPS
Obadiah 1 in the SBISS
Obadiah 1 in the SBITS
Obadiah 1 in the SBITS2
Obadiah 1 in the SBITS3
Obadiah 1 in the SBITS4
Obadiah 1 in the SBIUS
Obadiah 1 in the SBIVS
Obadiah 1 in the SBT
Obadiah 1 in the SBT1E
Obadiah 1 in the SCHL
Obadiah 1 in the SNT
Obadiah 1 in the SUSU
Obadiah 1 in the SUSU2
Obadiah 1 in the SYNO
Obadiah 1 in the TBIAOTANT
Obadiah 1 in the TBT1E
Obadiah 1 in the TBT1E2
Obadiah 1 in the TFTIP
Obadiah 1 in the TFTU
Obadiah 1 in the TGNTATF3T
Obadiah 1 in the THAI
Obadiah 1 in the TNFD
Obadiah 1 in the TNT
Obadiah 1 in the TNTIK
Obadiah 1 in the TNTIL
Obadiah 1 in the TNTIN
Obadiah 1 in the TNTIP
Obadiah 1 in the TNTIZ
Obadiah 1 in the TOMA
Obadiah 1 in the TTENT
Obadiah 1 in the UBG
Obadiah 1 in the UGV
Obadiah 1 in the UGV2
Obadiah 1 in the UGV3
Obadiah 1 in the VBL
Obadiah 1 in the VDCC
Obadiah 1 in the YALU
Obadiah 1 in the YAPE
Obadiah 1 in the YBVTP
Obadiah 1 in the ZBP