Proverbs 30 (BOYCB)

1 Àwọn ọ̀rọ̀ Aguri ọmọ Jake, ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ tí ọkùnrin yìí sọ fún Itieli.Sí Itieli àti sí Ukali. 2 “Èmi ni aláìmòye ju nínú àwọn ènìyàn;n kò ní òye ènìyàn. 3 Èmi kò tilẹ̀ kọ́ ọgbọ́ntàbí ní ìmọ̀ ẹni mímọ́ nì. 4 Ta ni ó ti gòkè lọ sí ọ̀run tí ó sì padà sọ̀kalẹ̀?Ta ni ó ti kó afẹ́fẹ́ jọ sí ihò àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀?Ta ni ó ti ta kókó omi sétí aṣọ?Ta ni ó fi gbogbo ìpìlẹ̀ ayé lélẹ̀?Kí ni orúkọ rẹ̀, àti orúkọ ọmọ rẹ̀?Sọ fún mi bí o bá mọ̀. 5 “Gbogbo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ aláìlábùkù;òun ni ààbò fún gbogbo ẹni fi í ṣe ibi ìpamọ́ wọn. 6 Má ṣe fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀,àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò bá ọ wí yóò sì sọ ọ́ di òpùrọ́. 7 “Ohun méjì ni mo ń béèrè lọ́wọ́ rẹ, OLÚWA;má ṣe fi wọ́n dù mí kí ń tó kú. 8 Mú èké ṣíṣe àti irọ́ jìnnà sí mi;má ṣe fún mi ní òsì tàbí ọrọ̀,ṣùgbọ́n fún mi ní oúnjẹ òòjọ́ mi nìkan. 9 Àìṣe bẹ́ẹ̀, mo lè ní àníjù kí n sì gbàgbé rẹkí ń sì wí pé, ‘Ta ni OLÚWA?’Tàbí kí ń di òtòṣì kí ń sì jalèkí ń sì ṣe àìbọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run mi. 10 “Má ṣe ba ìránṣẹ́ lórúkọ jẹ́ lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀,kí ó má ba fi ọ́ bú, kí ìwọ má ba jẹ̀bi. 11 “Àwọn kan wá ṣépè fún àwọn baba wọntí wọn kò sì súre fún àwọn ìyá wọn. 12 Àwọn tí ó mọ́ ní ojú ara wọnsíbẹ̀ tí wọn kò sì mọ́ kúrò nínú èérí wọn; 13 àwọn ẹni tí ojú wọn gbéga nígbà gbogbo,tí ìwolẹ̀ wọn sì kún fún ìgbéraga. 14 Àwọn ẹni tí eyín wọn jẹ́ idààwọn tí èrìgì wọn kún fún ọ̀bẹláti jẹ àwọn tálákà run kúrò ní ilẹ̀ ayéàwọn aláìní kúrò láàrín àwọn ọmọ ènìyàn. 15 “Eṣúṣú ni ọmọbìnrin méjì.‘Mú wá! Mú wá!’ ní wọn ń ké. “Àwọn nǹkan mẹ́ta kan wà tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn láéláé,mẹ́rin tí kò jẹ́ wí láéláé pé, ‘Ó tó!’: 16 Ibojì, inú tí ó yàgàn,ilẹ̀ tí omi kì í tẹ́lọ́rùn láéláé,àti iná, tí kì í wí láéláé pé, ‘Ó tó!’ 17 “Ojú tí ń fi baba ṣẹ̀fẹ̀,tí ó kẹ́gàn ìgbọ́ràn sí ìyá,ẹyẹ ìwò ẹ̀bá odò ni yóò yọ ọ́,igún yóò mú un jẹ. 18 “Àwọn nǹkan mẹ́ta wà tí ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi,mẹ́rin tí kò yé mi, 19 ipa ẹyẹ idì ní òfúrufúipa ejò lórí àpátaipa ọkọ̀ ojú omi lójú agbami Òkunàti ipa ọ̀nà ọkùnrin tí ó mú wúńdíá lọ́wọ́. 20 “Èyí ni ọ̀nà alágbèrè obìnrinó jẹun ó sì nu ẹnu rẹ̀ó sì wí pé, ‘N kò ṣe ohunkóhun tí kò tọ́.’ 21 “Lábẹ́ nǹkan mẹ́ta ni ilé ayé ti ń wárìrìlábẹ́ ohun mẹ́rin ni kò ti lè mí fín ín. 22 Ìránṣẹ́ tí ó di ọbaaláìgbọ́n tí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ, 23 obìnrin tí gbogbo ènìyàn kórìíra tí ó sì wá lọ́kọìránṣẹ́bìnrin tí ó gbọkọ mọ́ ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́. 24 “Àwọn ohun mẹ́rin ló kéré láyésíbẹ̀ wọ́n gbọ́n gidigidi. 25 Àwọn èèrà jẹ́ aláìlágbára ẹ̀dá,síbẹ̀ wọ́n kó oúnjẹ wọn pamọ́ ní àsìkò òjò. 26 Ehoro jẹ́ aláìlágbára ẹ̀dá;síbẹ̀ wọ́n ń ṣe ihò wọn sí ibi pálapàla àpáta; 27 àwọn eṣú kò ní ọba,síbẹ̀ gbogbo wọ́n ń jáde lọ ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ 28 Ọmọnílé fi ọwọ́ rẹ̀ dì mú,síbẹ̀ a ń rí i ní ààfin ọba. 29 “Àwọn ohun mẹ́ta ní ń bẹ tí ń rìn rere,ohun mẹ́rin ni ó dára púpọ̀ ní ìrìn rírìn: 30 Kìnnìún, alágbára láàrín ẹranko tí kì í sá fún ohunkóhun 31 Ẹsin tí a dì lẹ́gbẹ̀ẹ́;àti òbúkọ,àti ọba láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. 32 “Bí ìwọ bá ti hùwà aṣiwèrè nípa gbígbé ara rẹ ga,tàbí tí o bá ti gbèrò ibi,da ọwọ́ rẹ bo ẹnu rẹ! 33 Nítorí bí fífún omi ọmú tí í mú wàrà wá,tí fífún imú sì ń mú ẹ̀jẹ̀ jáde,bẹ́ẹ̀ ni rírú ìbínú sókè í mú ìjà wá.”

In Other Versions

Proverbs 30 in the ANGEFD

Proverbs 30 in the ANTPNG2D

Proverbs 30 in the AS21

Proverbs 30 in the BAGH

Proverbs 30 in the BBPNG

Proverbs 30 in the BBT1E

Proverbs 30 in the BDS

Proverbs 30 in the BEV

Proverbs 30 in the BHAD

Proverbs 30 in the BIB

Proverbs 30 in the BLPT

Proverbs 30 in the BNT

Proverbs 30 in the BNTABOOT

Proverbs 30 in the BNTLV

Proverbs 30 in the BOATCB

Proverbs 30 in the BOATCB2

Proverbs 30 in the BOBCV

Proverbs 30 in the BOCNT

Proverbs 30 in the BOECS

Proverbs 30 in the BOGWICC

Proverbs 30 in the BOHCB

Proverbs 30 in the BOHCV

Proverbs 30 in the BOHLNT

Proverbs 30 in the BOHNTLTAL

Proverbs 30 in the BOICB

Proverbs 30 in the BOILNTAP

Proverbs 30 in the BOITCV

Proverbs 30 in the BOKCV

Proverbs 30 in the BOKCV2

Proverbs 30 in the BOKHWOG

Proverbs 30 in the BOKSSV

Proverbs 30 in the BOLCB

Proverbs 30 in the BOLCB2

Proverbs 30 in the BOMCV

Proverbs 30 in the BONAV

Proverbs 30 in the BONCB

Proverbs 30 in the BONLT

Proverbs 30 in the BONUT2

Proverbs 30 in the BOPLNT

Proverbs 30 in the BOSCB

Proverbs 30 in the BOSNC

Proverbs 30 in the BOTLNT

Proverbs 30 in the BOVCB

Proverbs 30 in the BPBB

Proverbs 30 in the BPH

Proverbs 30 in the BSB

Proverbs 30 in the CCB

Proverbs 30 in the CUV

Proverbs 30 in the CUVS

Proverbs 30 in the DBT

Proverbs 30 in the DGDNT

Proverbs 30 in the DHNT

Proverbs 30 in the DNT

Proverbs 30 in the ELBE

Proverbs 30 in the EMTV

Proverbs 30 in the ESV

Proverbs 30 in the FBV

Proverbs 30 in the FEB

Proverbs 30 in the GGMNT

Proverbs 30 in the GNT

Proverbs 30 in the HARY

Proverbs 30 in the HNT

Proverbs 30 in the IRVA

Proverbs 30 in the IRVB

Proverbs 30 in the IRVG

Proverbs 30 in the IRVH

Proverbs 30 in the IRVK

Proverbs 30 in the IRVM

Proverbs 30 in the IRVM2

Proverbs 30 in the IRVO

Proverbs 30 in the IRVP

Proverbs 30 in the IRVT

Proverbs 30 in the IRVT2

Proverbs 30 in the IRVU

Proverbs 30 in the ISVN

Proverbs 30 in the JSNT

Proverbs 30 in the KAPI

Proverbs 30 in the KBT1ETNIK

Proverbs 30 in the KBV

Proverbs 30 in the KJV

Proverbs 30 in the KNFD

Proverbs 30 in the LBA

Proverbs 30 in the LBLA

Proverbs 30 in the LNT

Proverbs 30 in the LSV

Proverbs 30 in the MAAL

Proverbs 30 in the MBV

Proverbs 30 in the MBV2

Proverbs 30 in the MHNT

Proverbs 30 in the MKNFD

Proverbs 30 in the MNG

Proverbs 30 in the MNT

Proverbs 30 in the MNT2

Proverbs 30 in the MRS1T

Proverbs 30 in the NAA

Proverbs 30 in the NASB

Proverbs 30 in the NBLA

Proverbs 30 in the NBS

Proverbs 30 in the NBVTP

Proverbs 30 in the NET2

Proverbs 30 in the NIV11

Proverbs 30 in the NNT

Proverbs 30 in the NNT2

Proverbs 30 in the NNT3

Proverbs 30 in the PDDPT

Proverbs 30 in the PFNT

Proverbs 30 in the RMNT

Proverbs 30 in the SBIAS

Proverbs 30 in the SBIBS

Proverbs 30 in the SBIBS2

Proverbs 30 in the SBICS

Proverbs 30 in the SBIDS

Proverbs 30 in the SBIGS

Proverbs 30 in the SBIHS

Proverbs 30 in the SBIIS

Proverbs 30 in the SBIIS2

Proverbs 30 in the SBIIS3

Proverbs 30 in the SBIKS

Proverbs 30 in the SBIKS2

Proverbs 30 in the SBIMS

Proverbs 30 in the SBIOS

Proverbs 30 in the SBIPS

Proverbs 30 in the SBISS

Proverbs 30 in the SBITS

Proverbs 30 in the SBITS2

Proverbs 30 in the SBITS3

Proverbs 30 in the SBITS4

Proverbs 30 in the SBIUS

Proverbs 30 in the SBIVS

Proverbs 30 in the SBT

Proverbs 30 in the SBT1E

Proverbs 30 in the SCHL

Proverbs 30 in the SNT

Proverbs 30 in the SUSU

Proverbs 30 in the SUSU2

Proverbs 30 in the SYNO

Proverbs 30 in the TBIAOTANT

Proverbs 30 in the TBT1E

Proverbs 30 in the TBT1E2

Proverbs 30 in the TFTIP

Proverbs 30 in the TFTU

Proverbs 30 in the TGNTATF3T

Proverbs 30 in the THAI

Proverbs 30 in the TNFD

Proverbs 30 in the TNT

Proverbs 30 in the TNTIK

Proverbs 30 in the TNTIL

Proverbs 30 in the TNTIN

Proverbs 30 in the TNTIP

Proverbs 30 in the TNTIZ

Proverbs 30 in the TOMA

Proverbs 30 in the TTENT

Proverbs 30 in the UBG

Proverbs 30 in the UGV

Proverbs 30 in the UGV2

Proverbs 30 in the UGV3

Proverbs 30 in the VBL

Proverbs 30 in the VDCC

Proverbs 30 in the YALU

Proverbs 30 in the YAPE

Proverbs 30 in the YBVTP

Proverbs 30 in the ZBP