Proverbs 8 (BOYCB)

1 Ǹjẹ́ ọgbọ́n kò ha ń kígbe síta?Òye kò ha ń gbé ohùn rẹ sókè? 2 Ní ibi gíga ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà,ní ìkóríta, ní ó dúró; 3 ní ẹgbẹ́ ibodè tí ó wọ ìlú,ní ẹnu ibodè ni ó ń kígbe sókè: 4 “Sí i yín ẹ̀yin ènìyàn, ní mo ń kígbe pè;mo gbé ohun mi sókè sí gbogbo ènìyàn. 5 Ẹ̀yin aláìmọ̀kan, ẹ kọ́gbọ́n;ẹ̀yin aṣiwèrè, ẹ gba òye. 6 Ẹ gbọ́, nítorí tí èmi ó sọ̀rọ̀ ohun iyebíye;Èmí ṣí ètè mi láti sọ ohun tí ó tọ́, 7 ẹnu mi ń sọ ohun tí í ṣe òtítọ́,nítorí ètè mi kórìíra ibi. 8 Gbogbo ọ̀rọ̀ ẹnu mi ni ó tọ́,kò sí èyí tí ó jẹ́ ẹ̀tàn tàbí àyídáyidà níbẹ̀. 9 Fún olóye gbogbo rẹ̀ ni ó tọ̀nà;wọ́n jẹ́ aláìlẹ́gàn fún gbogbo ẹni tí ó ní ìmọ̀. 10 Yan ẹ̀kọ́ mi dípò fàdákà,ìmọ̀ dípò o wúrà àṣàyàn, 11 nítorí ọgbọ́n ṣe iyebíye jù iyùn lọ,kò sí ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ tí a sì le fiwé e. 12 “Èmi, ọgbọ́n ń gbé pẹ̀lú òye;mo ní ìmọ̀ àti ọgbọ́n-inú. 13 Ìbẹ̀rù OLÚWA ni ìkórìíra ibimo kórìíra ìgbéraga àti agídí,ìwà ibi àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn. 14 Ìmọ̀ràn àti ọgbọ́n tí ó yè kooro jẹ́ tèmimo ní òye àti agbára. 15 Nípasẹ̀ mi ni ọba ń ṣàkósotí àwọn aláṣẹ sì ń ṣe òfin tí ó dára. 16 Nípasẹ̀ mi àwọn ọmọ-aládé ń ṣàkóso,àti gbogbo ọlọ́lá tí ń ṣàkóso ilẹ̀ ayé. 17 Mo fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn mi,àwọn tí ó sì wá mi rí mi. 18 Lọ́dọ̀ mi ni ọrọ̀ àti ọlá wà,ọrọ̀ tí í tọ́jọ́ àti ìgbéga rere. 19 Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ;ohun tí mò ń mú wá ju àṣàyàn fàdákà lọ. 20 Mò ń rìn ní ọ̀nà òdodo,ní ojú ọ̀nà òtítọ́, 21 mò ń fi ọrọ̀ fún gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn mimo sì ń mú kí ilé ìṣúra wọn kún. 22 “Èmi ni OLÚWA kọ́kọ́ dá nínú iṣẹ́ rẹ̀.Ṣáájú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àtijọ́; 23 a ti yàn mí láti ayérayé,láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, kí ayé tó bẹ̀rẹ̀. 24 Nígbà tí kò tí ì sí Òkun, ni a ti bí mi,nígbà tí kò tí ì sí ìsun tí ó ní omi nínú; 25 kí a tó fi àwọn òkè sí ipò wọn,ṣáájú àwọn òkè ni a ti bí mi, 26 kí ó tó dá ilẹ̀ ayé tàbí àwọn oko rẹ̀tàbí èyíkéyìí nínú eruku ayé. 27 Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn,nígbà tí ó fi òsùwọ̀n àyíká sórí ibú omi, 28 nígbà tí ó ṣẹ̀dá òfúrufú lókètí ó sì fi orísun ibú omi sí ipò rẹ̀ láì le è yẹsẹ̀, 29 nígbà tí ó ṣe ààlà fún omi Òkunkí omi má ba à kọjá ààlà àṣẹ rẹ̀,àti nígbà tí ó pààlà ìpìlẹ̀ ayé. 30 Nígbà náà èmi ni gbẹ́nàgbẹ́nà ẹ̀gbẹ́ rẹ̀mo kún fún inú dídùn lójoojúmọ́,mo ń yọ̀ nígbà gbogbo níwájú rẹ̀. 31 Mo ń yọ̀ nínú gbogbo àgbáyé tí ó dámo sì ní inú dídùn sí àwọn ọmọ ènìyàn. 32 “Nítorí náà báyìí, ẹ̀yin ọmọ mi,ìbùkún ni fún àwọn tí ó pa ọ̀nà mi mọ́. 33 Fetí sí ìtọ́sọ́nà mi kí o sì gbọ́n;má ṣe pa á tì sápá kan. 34 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó fetísílẹ̀ sí mi,tí ń ṣọ́nà ní ẹnu-ọ̀nà mi lójoojúmọ́,tí ń dúró ní ẹnu-ọ̀nà mi. 35 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi rí ìyèó sì rí ojúrere gbà lọ́dọ̀ OLÚWA. 36 Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti rí ń pa ara rẹ̀ láragbogbo ẹni tí ó kórìíra mi fẹ́ ikú.”

In Other Versions

Proverbs 8 in the ANGEFD

Proverbs 8 in the ANTPNG2D

Proverbs 8 in the AS21

Proverbs 8 in the BAGH

Proverbs 8 in the BBPNG

Proverbs 8 in the BBT1E

Proverbs 8 in the BDS

Proverbs 8 in the BEV

Proverbs 8 in the BHAD

Proverbs 8 in the BIB

Proverbs 8 in the BLPT

Proverbs 8 in the BNT

Proverbs 8 in the BNTABOOT

Proverbs 8 in the BNTLV

Proverbs 8 in the BOATCB

Proverbs 8 in the BOATCB2

Proverbs 8 in the BOBCV

Proverbs 8 in the BOCNT

Proverbs 8 in the BOECS

Proverbs 8 in the BOGWICC

Proverbs 8 in the BOHCB

Proverbs 8 in the BOHCV

Proverbs 8 in the BOHLNT

Proverbs 8 in the BOHNTLTAL

Proverbs 8 in the BOICB

Proverbs 8 in the BOILNTAP

Proverbs 8 in the BOITCV

Proverbs 8 in the BOKCV

Proverbs 8 in the BOKCV2

Proverbs 8 in the BOKHWOG

Proverbs 8 in the BOKSSV

Proverbs 8 in the BOLCB

Proverbs 8 in the BOLCB2

Proverbs 8 in the BOMCV

Proverbs 8 in the BONAV

Proverbs 8 in the BONCB

Proverbs 8 in the BONLT

Proverbs 8 in the BONUT2

Proverbs 8 in the BOPLNT

Proverbs 8 in the BOSCB

Proverbs 8 in the BOSNC

Proverbs 8 in the BOTLNT

Proverbs 8 in the BOVCB

Proverbs 8 in the BPBB

Proverbs 8 in the BPH

Proverbs 8 in the BSB

Proverbs 8 in the CCB

Proverbs 8 in the CUV

Proverbs 8 in the CUVS

Proverbs 8 in the DBT

Proverbs 8 in the DGDNT

Proverbs 8 in the DHNT

Proverbs 8 in the DNT

Proverbs 8 in the ELBE

Proverbs 8 in the EMTV

Proverbs 8 in the ESV

Proverbs 8 in the FBV

Proverbs 8 in the FEB

Proverbs 8 in the GGMNT

Proverbs 8 in the GNT

Proverbs 8 in the HARY

Proverbs 8 in the HNT

Proverbs 8 in the IRVA

Proverbs 8 in the IRVB

Proverbs 8 in the IRVG

Proverbs 8 in the IRVH

Proverbs 8 in the IRVK

Proverbs 8 in the IRVM

Proverbs 8 in the IRVM2

Proverbs 8 in the IRVO

Proverbs 8 in the IRVP

Proverbs 8 in the IRVT

Proverbs 8 in the IRVT2

Proverbs 8 in the IRVU

Proverbs 8 in the ISVN

Proverbs 8 in the JSNT

Proverbs 8 in the KAPI

Proverbs 8 in the KBT1ETNIK

Proverbs 8 in the KBV

Proverbs 8 in the KJV

Proverbs 8 in the KNFD

Proverbs 8 in the LBA

Proverbs 8 in the LBLA

Proverbs 8 in the LNT

Proverbs 8 in the LSV

Proverbs 8 in the MAAL

Proverbs 8 in the MBV

Proverbs 8 in the MBV2

Proverbs 8 in the MHNT

Proverbs 8 in the MKNFD

Proverbs 8 in the MNG

Proverbs 8 in the MNT

Proverbs 8 in the MNT2

Proverbs 8 in the MRS1T

Proverbs 8 in the NAA

Proverbs 8 in the NASB

Proverbs 8 in the NBLA

Proverbs 8 in the NBS

Proverbs 8 in the NBVTP

Proverbs 8 in the NET2

Proverbs 8 in the NIV11

Proverbs 8 in the NNT

Proverbs 8 in the NNT2

Proverbs 8 in the NNT3

Proverbs 8 in the PDDPT

Proverbs 8 in the PFNT

Proverbs 8 in the RMNT

Proverbs 8 in the SBIAS

Proverbs 8 in the SBIBS

Proverbs 8 in the SBIBS2

Proverbs 8 in the SBICS

Proverbs 8 in the SBIDS

Proverbs 8 in the SBIGS

Proverbs 8 in the SBIHS

Proverbs 8 in the SBIIS

Proverbs 8 in the SBIIS2

Proverbs 8 in the SBIIS3

Proverbs 8 in the SBIKS

Proverbs 8 in the SBIKS2

Proverbs 8 in the SBIMS

Proverbs 8 in the SBIOS

Proverbs 8 in the SBIPS

Proverbs 8 in the SBISS

Proverbs 8 in the SBITS

Proverbs 8 in the SBITS2

Proverbs 8 in the SBITS3

Proverbs 8 in the SBITS4

Proverbs 8 in the SBIUS

Proverbs 8 in the SBIVS

Proverbs 8 in the SBT

Proverbs 8 in the SBT1E

Proverbs 8 in the SCHL

Proverbs 8 in the SNT

Proverbs 8 in the SUSU

Proverbs 8 in the SUSU2

Proverbs 8 in the SYNO

Proverbs 8 in the TBIAOTANT

Proverbs 8 in the TBT1E

Proverbs 8 in the TBT1E2

Proverbs 8 in the TFTIP

Proverbs 8 in the TFTU

Proverbs 8 in the TGNTATF3T

Proverbs 8 in the THAI

Proverbs 8 in the TNFD

Proverbs 8 in the TNT

Proverbs 8 in the TNTIK

Proverbs 8 in the TNTIL

Proverbs 8 in the TNTIN

Proverbs 8 in the TNTIP

Proverbs 8 in the TNTIZ

Proverbs 8 in the TOMA

Proverbs 8 in the TTENT

Proverbs 8 in the UBG

Proverbs 8 in the UGV

Proverbs 8 in the UGV2

Proverbs 8 in the UGV3

Proverbs 8 in the VBL

Proverbs 8 in the VDCC

Proverbs 8 in the YALU

Proverbs 8 in the YAPE

Proverbs 8 in the YBVTP

Proverbs 8 in the ZBP