Psalms 101 (BOYCB)
undefined Ti Dafidi. Saamu. 1 Èmi yóò kọrin ìfẹ́ àti òdodo;sí ọ OLÚWA, èmi yóò máa kọrin ìyìn. 2 Èmi yóò máa rin ìrìn mi pẹ̀lú ọgbọ́n láìlẹ́ṣẹ̀,ìgbà wo ni ìwọ yóò wá sí ọ̀dọ̀ mi? Èmi yóò máa rìn ní ilé mipẹ̀lú àyà pípé. 3 Èmi kì yóò gbé ohun búburú sí iwájú mi:iṣẹ́ àwọn tí ó yapa ni èmi kórìíra. Wọn kì yóò rọ̀ mọ́ mi. 4 Agídí ọkàn yóò kúrò lọ́dọ̀ mi;èmi kì yóò mọ ènìyàn búburú. 5 Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ẹnìkejì rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀,òun ní èmi yóò gé kúròẹni tí ó bá gbé ojú rẹ̀ ga tí ó sì ní ìgbéraga àyà,òun ní èmi kì yóò faradà fún. 6 Ojú mi yóò wà lára àwọn olóòtítọ́ lórí ilẹ̀,kí wọn kí ó lè máa bá mi gbé;ẹni tí ó bá n rin ọ̀nà pípéòun ni yóò máa sìn mí. 7 Ẹni tí ó bá ń ṣe ẹ̀tàn, kì yóò gbé ilé mi,kò sí ẹni tí ń ṣèké tí yóò dúró ní iwájú mi. 8 Ní ojoojúmọ́ ní èmi yóò wá máa pa a lẹ́nu mọgbogbo àwọn ènìyàn búburú ilẹ̀ náà;èmi yóò gé àwọn olùṣe búburúkúrò ní ìlú OLÚWA.